Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí N Ní Ìbálòpọ̀ Kí N Tó Ṣègbéyàwó?

Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí N Ní Ìbálòpọ̀ Kí N Tó Ṣègbéyàwó?

ORÍ 5

Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí N Ní Ìbálòpọ̀ Kí N Tó Ṣègbéyàwó?

“Ó máa ń ṣe mí bíi kí ọkùnrin bá mi sùn.”—Kelly.

“Bí mi ò ṣe tíì bá obìnrin sùn rí máa ń ṣe mí bákan.”—Jordon.

“ṢÉ ÌWỌ náà ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí?” Ìbéèrè yẹn lè ṣe ẹ́ bákan! Ká sòótọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ibi téèyàn máa dé láyé yìí tí wọn ò ní fojú ọ̀dẹ̀ tí ò rọ́ọ̀ọ́kán wo ọ̀dọ́ tí ò bá tíì ní ìbálòpọ̀ rí. Abájọ tí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ fi sábà máa ń ní ìbálòpọ̀ kí wọ́n tó pé ọmọ ogún ọdún!

Bó Ṣe Ń Wù Mí Ṣe Làwọn Ojúgbà Mi Náà Ń Tì Mí Sí I

Bó o bá jẹ́ Kristẹni, ìwọ náà mọ̀ pé Bíbélì ní kó o “ta kété sí àgbèrè.” (1 Tẹsalóníkà 4:3) Àmọ́ ó lè má rọrùn fún ẹ láti kápá wíwù tó ń wù ẹ́ láti ní ìbálòpọ̀. Paul sọ pé: “Nígbà míì, màá kàn rí i pé mò ń ronú nípa ìbálòpọ̀ ṣáá, láìnídìí.” Fọkàn ẹ balẹ̀, bó ṣe ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn náà nìyẹn.

Àmọ́ ṣá o, ó máa ń káàyàn lára gan-an bí wọ́n bá ń fèèyàn ṣe yẹ̀yẹ́ léraléra, tí wọn ò sì yé sọ̀rọ̀ ẹ̀ torí pé kò tíì ní ìbálòpọ̀ rí! Bí àpẹẹrẹ, kí lo máa ṣe báwọn ẹgbẹ́ ẹ bá sọ fún ẹ pé, ó dìgbà tó o bá ní ìbálòpọ̀ kó o tó lè pera ẹ ní ọkùnrin tàbí obìnrin? Ellen sọ pé: “Àwọn ojúgbà ẹ á jẹ́ kó o máa wo ìbálòpọ̀ bí ohun tí kò burú, tó máa ń múnú èèyàn dùn. Bó ò bá tíì máa ṣèṣekúṣe, ńṣe ni wọ́n á máa fojú ẹni tí ò bẹ́gbẹ́ mu wò ẹ́.”

Àmọ́ àwọn nǹkan kan wà nípa níní ìbálòpọ̀ kéèyàn tó ṣègbéyàwó táwọn ojúgbà ẹ lè má sọ fún ẹ. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí ọmọkùnrin tóun àti Maria jọ ń fẹ́ra bá a sùn tán, Maria sọ pé: “Ojú tì mí wẹ̀lẹ̀mù lẹ́yìn ìgbà yẹn. Mo sì kórìíra ara mí àti bọ̀bọ́ yẹn.” Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ni ò mọ̀ pé ibi tọ́rọ̀ sábà máa ń já sí nìyẹn. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé níní ìbálòpọ̀ kéèyàn tó ṣègbéyàwó sábà máa ń mú kéèyàn ki ìka àbámọ̀ bẹnu, ìbànújẹ́ kékeré sì kọ́ ló máa ń yọrí sí!

Síbẹ̀, ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Shanda béèrè pé, “Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fi ìfẹ́ ìbálòpọ̀ sọ́kàn àwọn ọ̀dọ́ nígbà tó mọ̀ pé kò yẹ kí wọ́n ní ìbálòpọ̀ àyàfi bí wọ́n bá ti ṣègbéyàwó?” Ìbéèrè tó mọ́gbọ́n dání nìyẹn. Àmọ́, ronú lórí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ná:

Ṣé ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ nìkan lohun tó máa ń wù ẹ́ gan-an? Rárá o. Jèhófà Ọlọ́run ti dá agbára tó máa ń jẹ́ kí oríṣiríṣi nǹkan wu èèyàn mọ́ ẹ.

Ṣé gbogbo nǹkan tó bá ti ń wù ẹ́ náà lo gbọ́dọ̀ máa ṣe lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tó bá ti wá sí ẹ lọ́kàn? Rárá o, ìdí ni pé Ọlọ́run dá ẹ lọ́nà tí wàá fi lè máa darí ara ẹ.

Kí nìyẹn fi kọ́ ẹ? Ẹ̀kọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn nǹkan kan wà tí ò lè ṣe kó má wù ẹ́, àmọ́ o lè darí ara rẹ láti mọ ohun tó yẹ kó o ṣe. Àti pé, tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà tó bá ti ń wùùyàn láti ní ìbálòpọ̀ náà lèèyàn máa ń tẹra ẹ̀ lọ́rùn, ńṣe lèèyàn máa dà bí ẹni tó jẹ́ pé gbogbo ìgbà tínú bá ń bí i ló máa ń lu àwọn èèyàn, ìwà òpònú gbáà nìyẹn.

Òótọ́ kan tí kò ṣeé já ní koro ni pé, Ọlọ́run ò fún wa ní ẹ̀yà ìbímọ torí ká lè máa fi ṣèṣekúṣe. Bíbélì sọ pé: “Kí olúkúlùkù yín mọ bí yóò ti ṣèkáwọ́ ohun èlò tirẹ̀ nínú ìsọdimímọ́ àti ọlá.” (1 Tẹsalóníkà 4:4) Bí “ìgbà nínífẹ̀ẹ́ àti ìgbà kíkórìíra” ṣe wà, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbà tó yẹ kéèyàn ní ìbálòpọ̀ àti ìgbà tí kò yẹ kéèyàn ní in wà. (Oníwàásù 3:1-8) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ìwọ fúnra ẹ lo lè ṣèkáwọ́ ara ẹ!

Àmọ́, kí lo lè ṣe, bí ẹnì kan bá fẹ́ gbọ́ tẹnu ẹ, tó wá sọ bí ẹni tọ́rọ̀ yà lẹ́nu pé, “Ṣóòótọ́ ni pé o ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí?” Máà jẹ́ kí wọ́n ko ẹ láyà jẹ. Bó bá jẹ́ pé ẹni yẹn kàn fẹ́ wọ́ ẹ nílẹ̀ lásán ni, o lè fèsì pé: “Hẹn, mi ò tíì ṣe é rí, ojú ò sì tì mí láti sọ ọ́!” O sì tún lè sọ pé, “Èmi ni mo mọ̀yẹn lọ́kàn ara mi, mi ò kì ń sọ ọ́ síta.” * (Òwe 26:4; Kólósè 4:6) Bó o bá sì wá rí i pé ó yẹ kẹ́ni yẹn mọ púpọ̀ sí i lóòótọ́, o lè ṣàlàyé àwọn ohun tó o mọ̀ látinú Bíbélì, tó mú kó o pinnu láti má ṣe ní ìbálòpọ̀, àyàfi bó o bá ṣègbéyàwó.

Kí lo tún lè sọ fẹ́ni tó bá bi ẹ́, torí àtigbọ́ tẹnu ẹ, pé: “Ṣó ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí lóòótọ́ ni?” Kọ èsì tó o tún lè fún un sórí ìlà yìí.

․․․․․

Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye

Irú ojú wo ni Ọlọ́run fi máa ń wo àwọn tó bá ń bára wọn sùn láì tíì ṣègbéyàwó? Ó dáa, jẹ́ ká sọ pe o ra ẹ̀bùn kan fún ọ̀rẹ́ rẹ kan. Àmọ́, ọ̀rẹ́ rẹ yẹn ò dúró kó o fún òun lẹ́bùn yẹn tó fi ṣí i wò! Ṣéyẹn ò ní bí ẹ nínú? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, wo bó ṣe máa rí lójú Ọlọrun, bó o bá ní ìbálòpọ̀ kó o tó ṣègbéyàwó. Ọlọ́run fẹ́ kó o dúró dìgbà tó o bá ṣègbéyàwó kó o tó gbádùn ẹ̀bùn ìbálòpọ̀ tó fún ẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.

Kí ló wá yẹ kó o ṣe nípa ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ tó máa ń wá sí ẹ lọ́kàn? Ńṣe ni wàá kọ́ bó ò ṣe ní jẹ́ kírú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ mú ẹ ṣe ohun tí kò tọ́! Agbára ẹ sì gbé e láti ṣe bẹ́ẹ̀! Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ẹ̀mí rẹ̀ á fún ẹ lókun láti máa kóra ẹ níjàánu. (Gálátíà 5:22, 23) Má gbàgbé pé, Jèhófà “kì yóò fawọ́ ohunkóhun tí ó dára sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ń rìn ní àìlálèébù.” (Sáàmù 84:11) Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Gordon sọ pé: “Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí wá sí mi lọ́kàn pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn ní ìbálòpọ̀ láì tíì ṣègbéyàwó, mo ronú lórí bó ṣe máa mú kí n pàdánù ojúure Jèhófà, mo wá rí i pé kò sóhun tí mo lè fi wé àjọṣe tó wà láàárín èmi àti Jèhófà.”

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, kò sóhun tó burú nínú ẹ̀ béèyàn ò bá ní ìbálòpọ̀ kó tó ṣègbéyàwó. Ìṣekúṣe ló burú jáì, kò yẹ ọmọlúwàbí rárá, àkóbá tó sì ń ṣe fáwọn èèyàn ò mọ níwọ̀n. Torí náà, má ṣe jẹ́ kí wọ́n firọ́ tàn ẹ́ jẹ, kó o wá lọ máa ronú pé ìlànà Bíbélì tó ò ń tẹ̀ lé ni ò jẹ́ kó o mọ ohun tó ò ń ṣe. Bó o bá kọ̀ láti ní ìbálòpọ̀ kó o tó ṣègbéyàwó, o ò ní í kó àrùn, ọkàn ẹ ò sì ní máa dá ẹ lẹ́bi. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, wàá ní àjọṣe tó dán mọ́ràn pẹ̀lú Ọlọ́run.

KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 23, NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 15 O ò rí i pé, Jésù pàápàá ò sọ̀rọ̀ nígbà tí Hẹ́rọ́dù béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. (Lúùkù 23:8, 9) Ohun tó máa ń dáa jù ni pé kéèyàn má fèsì bí wọ́n bá bi í ní ìbéèrè tí kò mọ́gbọ́n dání.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Bí ẹnikẹ́ni bá ti pinnu . . . nínú ọkàn-àyà ara rẹ̀, láti pa ipò wúńdíá tirẹ̀ mọ́, òun yóò ṣe dáadáa.1 Kọ́ríńtì 7:37.

ÌMỌ̀RÀN

Má ṣe bá àwọn tí kò níwà ọmọlúwàbí rìn, àní bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀sìn kan náà lẹ jọ ń ṣe.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Ìgbéyàwó ò ní kí ẹni tó bá ti sọ ìṣekúṣe dàṣà tẹ́lẹ̀ yí pa dà. Àmọ́ àwọn tó bá ti mọ́ lára láti máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run kí wọ́n tó ṣègbéyàwó, kì í sábà yẹ àdéhùn ìgbéyàwó wọn.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Kí n má bàa ní ìbálòpọ̀ kí n tó ṣègbéyàwó, ohun tí màá ṣe ni pé ․․․․․

Báwọn tí mò ń bá rìn ò bá fẹ́ jẹ́ kí n ṣe ohun tí mo ti pinnu yìí, ohun tí màá ṣe ni pé ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

Kí lo rò pé ó fà á táwọn kan fi máa ń fàwọn tí kò bá tíì ní ìbálòpọ̀ rí ṣe yẹ̀yẹ́?

Kí ló lè mú kó ṣòro láti wà láìní ìbálòpọ̀?

Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn má tíì ní ìbálòpọ̀ kó tó ṣègbéyàwó?

Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé fún àbúrò ẹ pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kéèyàn má tíì ní ìbálòpọ̀ kó tó ṣègbéyàwó?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 51]

“Bí mo bá ti ń rántí pé ‘kò sí alágbèrè kankan tàbí aláìmọ́ tí ó ní ogún èyíkéyìí nínú ìjọba Ọlọ́run,’ ńṣe ni mo máa ń gbọ́kàn kúrò lórí ìbálòpọ̀.” (Éfésù 5:5)—Lydia

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 49]

Tí mo kọ èrò mi sí

Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Gan-an?

Àwọn ojúgbà ẹ, àwọn eléré àtàwọn olórin kì í sábà sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, tó bá kan àwọn àkóbá tí ìbálòpọ̀ láàárín àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó máa ń fà. Wo àwọn àpẹẹrẹ mẹ́ta yìí, kí lo rò pé ó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí gan-an? ․․․․․

● Ọmọléèwé ẹ kan ń ṣakọ pé àìmọye ọmọbìnrin lòun ti bá sùn. Ó ní àwọn jọ gbádùn ara àwọn ni, nǹkan kan ò sì ṣe ẹnì kankan nínú àwọn. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sóun àtàwọn ọmọbìnrin yẹn gan-an? ․․․․․

● Nígbà tí wọ́n máa parí fíìmù kan, àwọn ọ̀dọ́ méjì tí kò tó ọmọ ogún ọdún bára wọn sùn láti fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Tó bá jẹ́ pé ojú ayé ni, kí ló lè tẹ̀yìn ẹ̀ yọ gan-an? ․․․․․

● O rí bọ̀bọ́ kan tó dáa lọ́mọkùnrin, ó sì ní kó o jẹ́ kóun bá ẹ sùn. Ó ní kò sẹ́ni táá mọ̀. Bó o bá gbà fún un, tíwọ náà sì ṣẹnu mẹ́rẹ́n, kí ló máa ṣẹlẹ̀ gan-an? ․․․․․

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 54]

Bó o bá ń ní ìbálòpọ̀ láì tíì ṣègbéyàwó, ńṣe ló dà bí ìgbà tó ò ń ṣí ẹ̀bùn tí wọn ò tíì fún ẹ wò