Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Mo Fi Ń Ṣàìsàn Tó Báyìí?

Kí Nìdí Tí Mo Fi Ń Ṣàìsàn Tó Báyìí?

ORÍ 8

Kí Nìdí Tí Mo Fi Ń Ṣàìsàn Tó Báyìí?

“Nígbà tó o ṣì kéré, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí itú tó ò lè pa. Àmọ́, ṣàdédé ni àìlera bẹ̀rẹ̀ sí í fojú ẹ rí màbo. Ó wá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ti darúgbó lọ́sàn-án kan òru kan.”—Jason.

NÍGBÀ tí Jason pọ́mọ ọdún méjìdínlógún [18] ló mọ̀ pé òun ní àrùn Crohn, tó máa ń jáni níkùn jẹ, tó sì máa ń roni lára goorogo. Bóyá àìsàn tó burú jáì tàbí irú àìlera kan ń bá ìwọ náà fínra. Ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn èèyàn ò kà sí bàbàrà, bíi kéèyàn múra, kó jẹun, tàbí kó lọ síléèwé, lè gba pé kó o sapá gan-an kó o tó lè ṣe wọ́n.

Bí àìsàn tó légbá kan bá ń ṣe ẹ́, ńṣe ló máa dà bíi pé wọ́n tì ẹ́ mẹ́wọ̀n, tí wọ́n sì gba gbogbo òmìnira lọ́wọ́ ẹ. Ó tiẹ̀ lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò ní alábàárò kankan. O wá lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé àbí o ti ṣẹ Ọlọ́run ni, tàbí kó o máa rò pé Ọlọ́run ń gbé ìdánwò ìgbàgbọ́ kò ẹ́ lójú. Àmọ́, Bíbélì sọ pé: “A kò lè fi àwọn ohun tí ó jẹ́ ibi dán Ọlọ́run wò, bẹ́ẹ̀ ni òun fúnra rẹ̀ kì í dán ẹnikẹ́ni wò.” (Jákọ́bù 1:13) Torí náà, ńṣe ni àìsàn wulẹ̀ jẹ́ apá kan ìgbé ayé ẹ̀dá, kò sì sẹ́ni tí “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ò kàn nínú wa.—Oníwàásù 9:11.

A láyọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run ti ṣèlérí ayé tuntun kan nínú èyí tí “kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Kódà, àwọn tó ti kú máa jíǹde, kí wọ́n lè láǹfààní láti gbádùn ayé tuntun náà. (Jòhánù 5:28, 29) Àmọ́, ní báyìí ná, báwo lo ṣe lè gbádùn ara ẹ ní ipòkípò tó o bá wà?

Má sọ̀rètí nù. Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà tí ó kún fún ìdùnnú ń ṣe rere gẹ́gẹ́ bí awonisàn.” (Òwe 17:22) Àwọn kan lè rò pé ńṣe ló yẹ kójú ẹni tó bá ń ṣàìsàn máa le. Àmọ́, béèyàn bá ń dára yá tí kò sì kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́, ńṣe ni inú rẹ̀ á máa dùn, ẹ̀mí rẹ̀ á sì gùn. Torí náà, ronú nípa ohun tó o lè ṣe kínú ẹ lè túbọ̀ máa dùn. Rántí pé ànímọ́ rere ni ìdùnnú, ó sì tún jẹ́ apá kan èso ti ẹ̀mí. (Gálátíà 5:22) Ẹ̀mí yìí lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da àìsàn kí inú ẹ sì máa dùn.—Sáàmù 41:3.

Má retí ohun tó pọ̀ jù. Bíbélì sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.” (Òwe 11:2) Ìmẹ̀tọ́mọ̀wà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o má bàa di aláìbìkítà tàbí kó o ki àṣejù bọ ọ̀rọ̀ rẹ. Bí àpẹẹrẹ, bí ara ẹ bá gbé e, ṣíṣe eré ìdárayá níwọ̀nba lè mú kára ẹ túbọ̀ wálẹ̀. Ìdí ẹ̀ nìyẹn táwọn ilé ìwòsàn fi máa ń láwọn ibi tí wọ́n tí máa ń tọ́jú àwọn ọ̀dọ́ aláìsàn nípa lílo onírúurú eré ìmárale dípò oògùn. Lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, bí eré ìmárale bá pọ̀ tó, ó máa jẹ́ kára tètè yá kínú ẹni sì dùn. Pàtàkì ibẹ̀ ni pé kó o mọ bọ́ràn ara ẹ ṣe rí gan-an kó o má sì retí ohun tó pọ̀ jù.

Mọ bí wàá ṣe máa ṣe sáwọn ẹlòmíì. Báwọn míì bá sọ̀rọ̀ tó tàbùkù sí ẹ nítorí ipò tó o wà ńkọ́? Bíbélì sọ pé: “Má fi ọkàn-àyà rẹ sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn lè máa sọ.” (Oníwàásù 7:21) Nígbà míì, ohun tó dáa jù lọ ni pé kó o ṣe bíi pé o ò gbọ́rọ̀ náà. Tàbí kó o yẹra fún ṣíṣe ohun tá á mú kí wọ́n sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ sí ẹ. Bí àpẹẹrẹ, bó bá dà bíi pé àwọn èèyàn máa ń fẹ́ sá fún ẹ torí pé inú kẹ̀kẹ́ arọ lo máa ń jókòó sí, gbìyànjú láti fi wọ́n lára balẹ̀. O lè sọ pé: “Ó dà bíi pé ẹ̀ ń ronú pé kí ló fà á tí mo fi ń lo kẹ̀kẹ́ arọ. Ṣé kí n sọ ohun tó fà á fún yín?”

Má ṣe jẹ́ kó sú ẹ. Nígbà tí Jésù dojú kọ ìṣòro, ó gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó gbọ́kàn lé Ọlọ́run, ó gbọ́kàn kúrò lórí ìṣòro tó ń bá a fínra, ó sì pọkàn pọ̀ sórí ayọ̀ tó máa ní lọ́jọ́ iwájú. (Hébérù 12:2) Ó kẹ́kọ̀ọ́ látinú ipò líle koko tó dojú kọ ọ́. (Hébérù 4:15, 16; 5:7-9) Ó gba ìrànlọ́wọ́ àti ìṣírí. (Lúùkù 22:43) Dípò tí ì bá fi jẹ́ kí ìrora tó ní gbà á lọ́kàn, ire àwọn ẹlòmíì ló jẹ ẹ́ lógún.—Lúùkù 23:39-43; Jòhánù 19:26, 27.

Jèhófà ‘Bìkítà Nípa Ẹ’

Bó ti wù kí ìṣòro náà pọ̀ tó, kò yẹ́ kó o máa ronú pé Ọlọ́run ti rò ẹ́ pin. Dípò bẹ́ẹ̀, ojú iyebíye ni Jèhófà fi máa ń wo àwọn tó bá ń sapá láti ṣe ohun tó wù ú, ẹni ọ̀wọ́n ni wọ́n jẹ́ fún un. (Lúùkù 12:7) Jèhófà ‘bìkítà fún ẹ’ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan, inú rẹ̀ sì dùn láti máa lò ẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, láìka àìsàn tàbí àìlera rẹ sí.—1 Pétérù 5:7.

Torí náà, má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rù tàbí iyè méjì dí ẹ lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó o bá fẹ́ àti ohun tó bá pọn dandan pé kó o ṣe. Máa wá ìrànlọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà. Ó mọ ohun tó o ṣaláìní, ó sì mọ bí ohun tó ń ṣe ẹ́ ṣe rí lára ẹ. Àti pé, ó lè fún ẹ ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” èyí tá á mú kó o lè fara dà á. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, bóyá ìwọ̀ náà á dà bíi Timothy, tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] nígbà tí àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àrùn tó máa ń mú kó rẹni, kéèyàn máa wò sùn-ùn, kó má sì rí oorun sùn, àmọ́ tó gbà pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa. Ó sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú 1 Kọ́ríńtì 10:13, Jèhófà ò ní jẹ́ kí ohun tó kọjá ìfaradà ṣẹlẹ̀ sí wa. Mo máa ń ronú pé tó bá dá Ẹlẹ́dàá mi lójú pé mo lè fara da àdánwò náà, tèmi ti jẹ́ láti máa jà á níyàn?”

Bára Ẹnì Kan Tó O Mọ̀ Ò Bá Yá Ńkọ́?

Ká sọ pé ara rẹ jí pépé, tó o wá mọ ẹnì kan tára rẹ̀ ò yá tàbí tó ní àléébù ara ńkọ́? Báwo lo ṣe lè ran onítọ̀hún lọ́wọ́? Pàtàkì ohun tó wà níbẹ̀ ni pé kó o fi “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn” kó o sì “máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn.” (1 Pétérù 3:8) Gbìyànjú láti lóye ohun tí ẹni náà ń dojú kọ. Má jà á níyàn bó bá sọ pé báyìí-báyìí ló ṣe ń ṣe òun. Nina, tí ọgbẹ́ wà nínú eegun ọ̀pá ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tí wọ́n bí i, sọ pé: “Níwọ̀n bí mo ti rí jáńjálá, tó sì jẹ́ pé inú kẹ̀kẹ́ arọ ni mo máa ń jókòó sí, ńṣe làwọn kan máa ń sọ̀rọ̀ sí mi bí ẹni pé ọmọdé ni mí, ìyẹn sì máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi gan-an ni. Àmọ́ ṣá o, àwọn míì wà tí wọ́n máa ń sapá láti jókòó tì mí tí wọ́n á sì bá mi sọ̀rọ̀. Ìyẹn máa ń múnú mi dùn gan-an ni!”

Bó o bá wò ré kọjá àbùkù ara tí wọ́n ní, wàá rí i pé o ò sàn ju àwọn tó ní àìlera lọ. Má sì tún gbàgbé pé nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ, o lágbára láti “fi ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀” fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀! Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ pẹ̀lú á rí i pé wàá jàǹfààní ẹ̀, torí pé “pàṣípààrọ̀ ìṣírí [á] wà.”—Róòmù 1:11, 12.

KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 13, NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Ní àkókò yẹn . . . kò . . . sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:23, 24.

ÌMỌ̀RÀN

Béèyàn bá mọ ibi tí ìṣòro ẹ̀ ti wá, díẹ̀ ló máa bẹ̀rù mọ. Torí náà, mọ gbogbo ohun tó o bá lè mọ̀ nípa ohun tó ń ṣe ẹ́. Báwọn ohun kan ò bá yé ẹ, sọ pé kí dókítà rẹ ṣàlàyé fún ẹ.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Àìsàn tó ń ṣe ẹ́ tàbí àléébù ara ẹ, kì í ṣe ìjìyà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àìpé tí gbogbo wa jogún látọ̀dọ̀ Ádámù ló fà á.—Róòmù 5:12.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Kí àìsàn tàbí àléébù ara má bàa mú mi sọ̀rètí nù, màá ․․․․․

Àfojúsùn kan tí mo lè gbé ka iwájú mi ni ․․․․․

Bí ẹnì kan bá bú mi, màá fojú tó tọ́ wo ọ̀ràn náà nípa ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

Báwo lo ṣe lè lo ìsọfúnni tó wà nínú orí yìí láti ran ẹnì kan tó ní àléébù ara tàbí tó ń ṣàìsàn tó le koko lọ́wọ́?

Bí àìsàn bá ń ṣe ẹ́ gan-an, àwọn nǹkan wo lo lè ṣàṣàrò lé lórí kó o má bàa sọ̀rètí nù?

Báwo lo ṣe mọ̀ pé ìpọ́njú kì í ṣe ẹ̀rí tó fi hàn pé èèyàn ò ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 75]

DUSTIN, ỌMỌ ỌDÚN 22

“Mọ́mì mi fọwọ́ gbá mi mọ́ra, àmọ́ mo rántí bí mo ṣe ń sunkún nígbà tí wọ́n sọ fún mi pé orí àga arọ ni màá máa wà. Ọmọ ọdún mẹ́jọ péré sì ni mí nígbà náà.

Àrùn tó máa ń ba iṣan ẹsẹ̀ jẹ́ ló ń ṣe mí. Àfi kí n rẹ́ni ràn mí lọ́wọ́ kí n tó wọṣọ, kí n tó wẹ̀, àti kí n tó jẹun. Mi ò tiẹ̀ lè gbé apá mi rárá. Síbẹ̀, ọwọ́ mi máa ń dí, mo máa ń láyọ̀, ìdí ọpẹ́ mi sì pọ̀. Mo máa ń lọ sóde ẹ̀rí déédéé, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ sì ni mí nínú ìjọ. Kò tiẹ̀ dà bíi pé ohunkóhun ń ṣe mí. Béèyàn bá ń sin Jèhófà, ìgbà gbogbo lá á máa rí nǹkan ṣe, ọwọ́ rẹ̀ ò sì ní dilẹ̀. Lékè gbogbo ẹ̀, mò ń retí ìgbà tí ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí náà máa dé, níbi tí màá ti máa ‘gòkè bí akọ àgbọ̀nrín.’”—Aísáyà 35:6.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 75]

TOMOKO, ỌMỌ ỌDÚN 21

“Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rin, dókítà sọ fún mi pé: ‘O gbọ́dọ̀ máa gba abẹ́rẹ́ “insulin” títí ọjọ́ ayé ẹ.’

Kì í rọrùn láti mú kí ṣúgà tó wà lára ẹni tó ní àrùn àtọ̀gbẹ wà ní ìwọ̀n tó yẹ. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mi ò lè jẹun nígbà tó bá wù mí, ó sì lè jẹ́ ìgbà tí oúnjẹ ò wù mí jẹ gan-an ni mo gbọ́dọ̀ jẹun. Títí di báyìí, mo ti gba abẹ́rẹ́ tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25,000], ibi tí mò ń gba abẹ́rẹ́ ọ̀hún sí ní apá àti ní ìbàdí ti gíràn-án. Àmọ́, àwọn òbí mi ti ràn mí lọ́wọ́ kí n lè máa bá ipò náà yí. Wọ́n máa ń dára yá, wọn ò sọ̀rètí nù, wọ́n sì tọ́ mi dàgbà lọ́nà tí màá fi mọrírì àwọn nǹkan tẹ̀mí. Jèhófà ò fi mí sílẹ̀. Nígbà tí agbára mi gbé e, mo pinnu láti fi ìmọrírì mi hàn nípa gbígba iṣẹ́ alákòókò kíkún.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 76]

JAMES, ỌMỌ ỌDÚN 18

“Àwọn èèyàn ò mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa dá sọ́ràn ẹni tó bá ní àléébù ara, irú ẹni témi sì jẹ́ nìyẹn.

Aràrá ni mí, irú aràrá bíi tèmi ò sì fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀. Ìrísí ẹni làwọn èèyàn máa ń wò, torí náà mò ń gbìyànjú nígbà gbogbo láti fi hàn pé mi ò kì í wulẹ̀ ṣe ọmọdé tí ohùn rẹ̀ kẹ̀. Dípò kí n sì máa ro àròkàn lórí ohun tí mi ò ní, ṣe ni mo máa ń gbìyànjú láti pọkàn pọ̀ sórí ohun tí mo jẹ́. Mò ń gbádùn ayé mi. Mò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mo sì máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́. Ìdílé mi náà ò sì gbẹ́yìn bó bá di pé kí wọ́n ràn mí lọ́wọ́. Mò ń retí ìgbà tí Ọlọ́run máa mú gbogbo àìsàn kúrò. Ní báyìí, ohun tó ń ṣe mi ò tíì kúrò, àmọ́ mi ò jẹ́ kíyẹn gbà mí lọ́kàn débi tá á fi máa bà mí nínú jẹ́.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 76]

DANITRIA, ỌMỌ ỌDÚN 16

“Ìgbà tó ti di pé ìrora ńlá ló máa ń jẹ́ fún mi láti gbé ife omi lásán, ni mo ti mọ̀ pé mo ní àìlera.

Àìsàn “fibromyalgia” tó ń ṣe mí máa ń mú kí n ní ìrora tó pọ̀ gan-an. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ tí kò tíì pé ogún [20] ọdún, ó wù mí kí n máa ṣe bíi tàwọn ọ̀rẹ́ mi, àmọ́ ṣe ni gbogbo nǹkan túbọ̀ le koko fún mi ju bó ṣe máa ń rí tẹ́lẹ̀ lọ. Ó tiẹ̀ wá tó ti oorun tí kì í kùn mí bọ̀rọ̀! Síbẹ̀, mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà mo lè rọ́gbọ́n dá sí ìṣòro mi. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe fún mi láti lo àkókò púpọ̀ sí i lóde ẹ̀rí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Kò rọrùn, àmọ́ mo ṣe é. Mo ṣáà ń ṣe ìwọ̀nba tí agbára mi bá ká. Bára mi bá ṣe rí ló ń pinnu ohun tí mò ń ṣe, mi kì í sì í ṣe ju agbára mi lọ. Bí mo bá sì fẹ́ ṣe àṣejù lọ́nà èyíkéyìí, mọ́mì mi máa ń rán mi létí!”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 77]

ELYSIA, ỌMỌ 20 ỌDÚN

“Mo mọ̀wé gan-an tẹ́lẹ̀. Àmọ́, àtika gbólóhùn kan ṣoṣo nínú ìwé ti dọ̀ràn fún mi báyìí, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí nǹkan tojú sú mi nígbà míì.

Mo ní àrùn tó máa ń mú kó rẹni, kéèyàn máa wò sùn-ùn, kó má sì rí oorun sùn, èyí tó máa ń mú kí àtiṣe nǹkan tó rọrùn pàápàá ṣòro fún mi. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni kì í rọrùn fún mi láti dá dìde lórí ibùsùn. Síbẹ̀, mi ò jẹ́ kí àìsàn yìí nípa lórí irú ẹni tí mo jẹ́. Mò ń ka Bíbélì mi lójoojúmọ́, ì báà tiẹ̀ jẹ́ ìwọ̀nba ẹsẹ díẹ̀ tàbí kí n sọ pé káwọn tá a jọ ń gbélé kà á fún mi. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn aráalé mi. Torí kí n bàa lè lọ sí àpéjọ àgbègbè, Dádì tiẹ̀ kọ iṣẹ́ tí wọ́n fún wọn. Wọ́n kì í ṣàròyé. Wọ́n gbà pé ojúṣe gíga jù lọ táwọn ní ni pé káwọn tọ́jú aya àtọmọ àwọn.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 77]

KATSUTOSHI, ỌMỌ 20 ỌDÚN

“Mo máa ń ṣàdédé ṣubú lulẹ̀, màá máa pariwo, ara mi á sì máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni màá máa dalé rú, táwọn nǹkan á sì máa bà jẹ́.

Látìgbà tí mo ti wà lọ́mọ ọdún márùn-ún ni wárápá ti máa ń gbé mi. Ó sì máa ń gbé mi tó ìgbà méje lóṣù. Torí ẹ̀, ojoojúmọ́ ni mo máa ń lo egbòogi, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó rẹ̀ mí. Àmọ́, mo máa ń ronú nípa àwọn míì yàtọ̀ sí ara mi nìkan. Àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún méjì tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ wà nínú ìjọ tí mò ń dara pọ̀ mọ́ tí wọ́n máa ń ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Nígbà tí mo parí iléèwé, èmi náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Wárápá ò yé gbé mi ṣánlẹ̀. Àmọ́, bí ìdààmú ọkàn bá bá mi, mo máa ń rí i dájú pé mo fún ara mi nísinmi. Bó bá fi máa dọjọ́ kejì, ọkàn mi á tún ti balẹ̀.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 78]

MATTHEW, ỌMỌ ỌDÚN 19

“Ó máa ń ṣòro kéèyàn tó lè rí ojú rere àwọn ojúgbà ẹni bí wọ́n bá rí i pé ara èèyàn ò dá.

Ó máa ń wù mí láti ṣeré ìdárayá, àmọ́, mi ò kí ń lè ṣe é. Mo ni àrùn tí kì í jẹ́ kéèyàn séra ró, tí kì í sì í jẹ́ kéèyàn lè sọ̀rọ̀ dáadáa, ìyẹn “cerebral palsy.” Síbẹ̀, mi kì í jẹ́ kí ohun tí mi ò lè ṣe gbà mí lọ́kàn. Ohun tí mo mọ̀ ọ́n ṣe dáadáa, bíi kíkàwé, ni mo máa ń lo gbogbo àkókò mi lé lórí. Ara mi máa ń balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, torí pé mo mọ̀ pé kò sẹ́ni tó máa wá ẹ̀sùn sí mi lẹ́sẹ̀ níbẹ̀. Ó tún máa ń tù mí lára láti mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ràn mi nítorí irú ẹni tí mo jẹ́. Kódà, mi ò kí ń fojú ẹni tó lábùkù ara wora mi. Mo máa ń wo ara mi bí ẹni tó ní láti borí ìṣòro tó yàtọ̀ sí tàwọn míì.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 78]

MIKI, ỌMỌ ỌDÚN 25

“Mo máa ń ṣeré ìdárayá tẹ́lẹ̀. Àmọ́, nígbà tí mi ò tíì pọ́mọ ogún ọdún, ṣe ló dà bíi pé mo ṣàdédé darúgbó.

Ibì kan wà tó lu jára wọn nínú ọkàn mi, bí wọ́n sì ṣe bí mi nìyẹn. Ìgbà tí mo lé lọ́mọ ọdún méjìlá ni àyẹ̀wò fi hàn pé mo ní àrùn náà. Ọdún mẹ́fà ti kọjá lẹ́yìn tí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ́ fún mi. Àmọ́, ní báyìí, ó ṣì tètè máa ń rẹ̀ mí, orí sì máa ń fọ́ mi kíkankíkan. Torí náà, mo gbé àwọn àfojúsùn tí mo lè lé bá kalẹ̀ fúnra mi. Bí àpẹẹrẹ, ó ti wá ṣeé ṣe fún mi láti sìn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, èyí tó sábà máa ń jẹ́ nípa kíkọ lẹ́tà àti wíwàásù lórí tẹlifóònù. Bákan náà, àìsàn tó ń ṣe mí ti ràn mí lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ tí mi ò ní tẹ́lẹ̀, bíi kéèyàn ní ìpamọ́ra kó sì mọ̀wọ̀n ara rẹ̀.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 74]

Àìlera tó burú jáì lè mú kó máa ṣe ẹ́ bíi pé o wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àmọ́ Bíbélì mú kó dájú pé ọ̀nà àbáyọ wà