Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Máa Dá Wà?

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Máa Dá Wà?

ORÍ 9

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mi Ò Fi Ní Máa Dá Wà?

Ilẹ̀ tún ti mọ́ lónìí, o ò sì ní í lọ́kàn láti lọ síbì kankan. Àmọ́ gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ ẹ ló ti bára wọn ládèéhùn. Wọ́n ń gbádùn ara wọn. Wọ́n tún ti fi ẹ́ sílẹ̀ lọ! Bó o bá lọ nílọ mo-gbọ́-mo-yà, wàhálà nìyẹn lọ́tọ̀. Àmọ́, èyí tó burú jù níbẹ̀ ni ti pé wọn ò pè ẹ́ rárá. Wàá wá máa rò ó lọ́kàn ara ẹ pé, ‘Àbí mo ti ṣe nǹkan kan tí ò dáa ni? Kí ló dé tẹ́nì kankan kì í fẹ́ bá mi da nǹkan pọ̀?’

Ó ṢEÉ ṢE kó ti ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tírú nǹkan tá a sọ lójú ìwé tó ṣáájú èyí ti ṣẹlẹ̀ síwọ náà rí. Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kòtò ńlá kan ti pín ìwọ àtàwọn ojúgbà ẹ níyà. Ńṣe lo máa ń kólòlò ní gbogbo ìgbà tó o bá ti fẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀. Ojú sì máa ń tì ẹ́ nígbà tó o bá wà láàárín wọn. Kí nìdí tó fi máa ń ṣòro fún ẹ láti máa wà láàárín àwọn ojúgbà ẹ?

Dípò tí wàá fi dúró sí òdì kejì kòtò gìrìwò tó dà bí òkè ìṣòro tí ò jẹ́ kó o lè bẹ́gbẹ́ pé yìí, o lè wá ojútùú sí i. Jẹ́ ká jọ wo ohun tó o lè ṣe.

Ìṣòro Kìíní: Rírora rẹ pin. Àwọn ọ̀dọ́ kan sábà máa ń rora wọn pin. Wọ́n gbà pé kò sẹ́ni tó fẹ́ràn àwọn, àti pé kò sọ́rọ̀ gidi kan tó lè tẹnu àwọn jáde. Ṣóhun tíwọ náà ń rò nípa ara ẹ nìyẹn? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wàá máa mú kí kòtò gìrìwò tó wà láàárín ìwọ àtàwọn ojúgbà ẹ fẹ̀ sí i.

Ojútùú: Máa fàwọn ohun tó o lè ṣe sọ́kàn. (2 Kọ́ríńtì 11:6) Bí ara ẹ pé, ‘Àwọn ànímọ́ rere wo ni mo ní?’ Ronú nípa àwọn nǹkan tó o mọ̀ ọ́n ṣe tàbí àwọn ànímọ́ rere tó o ní kó o sì kọ wọ́n sórí ìlà yìí.

․․․․․

Òótọ́ ni pé, o láwọn ibi tó o kù sí, kò sì burú tó o bá mọ̀ bẹ́ẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 10:12) Àmọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan lo tún mọ̀ ọ́n ṣe. Bó o bá ń rántí àwọn ohun tó o lè ṣe yìí, o ò ní máa rora ẹ pin.

Ìṣòro Kejì: Ìtìjú. Ó máa ń wù ẹ́ pé kó o máa báwọn èèyàn sọ̀rọ̀, àmọ́ nígbà tó bá yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀, o kì í sábà mọ ohun tó yẹ kó o sọ. Elizabeth, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] sọ pé: “Gbogbo ìgbà lojú máa ń tì mí. Ó máa ń ni mí lára gan-an láti lọ báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípàdé ìjọ, mi ò sì ń kóyán àwọn tó bá lè ṣe bẹ́ẹ̀ kéré!” Bó o bá jẹ́ èèyàn bíi Elizabeth, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ìṣòro yìí ò lè yanjú.

Ojútùú: Fẹ́ràn àwọn míì dénú. Fọkàn balẹ̀, kò dìgbà tó o bá jẹ́ ẹni tó bẹ kó o tó máa fìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíì. O lè kọ́kọ́ sún mọ́ ẹnì kan dáadáa. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Jorge sọ pé: “Bó o bá kàn béèrè bí nǹkan ṣe ń lọ sí lọ́wọ́ àwọn èèyàn tàbí bí iṣẹ́ wọn ṣe ń lọ sí, ìyẹn lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ̀ wọ́n dáadáa.”

Ìmọ̀ràn kan rèé: Má fi àjọṣe ẹ mọ sọ́dọ̀ àwọn ojúgbà ẹ. Ọjọ́ orí àwọn kan lára àwọn tó bára wọn ṣọ̀rẹ́ àtàtà nínú Bíbélì ò dọ́gba rárá, àwọn bíi Rúùtù àti Náómì, Dáfídì àti Jónátánì, títí kan Pọ́ọ̀lù àti Tímótì. (Rúùtù 1:16, 17; 1 Sámúẹ́lì 18:1; 1 Kọ́ríńtì 4:17) Má sì gbàgbé pé ìjíròrò ò dà bí orin àdákọ, ọ̀rọ̀ láàárín ẹni méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni. Àwọn èèyàn máa ń mọyì ẹni tó bá mọ̀rọ̀ gbọ́. Torí náà, tó bá dà bíi pé ojú máa ń tì ẹ́, rántí pé ìwọ nìkan kọ́ ni wàá máa dá ọ̀rọ̀ náà sọ!

Kọ orúkọ àwọn àgbàlagbà méjì tó o máa fẹ́ láti bá ṣọ̀rẹ́ sórí ìlà yìí.

․․․․․

O ò ṣe lọ bá ọ̀kan lára àwọn tó o kọ orúkọ wọn sókè yìí, kó o sì bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn? Bó o bá ṣe ń sún mọ́ “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará” tó, ni wàá ṣe máa rẹ́ni bá ṣọ̀rẹ́ tó.—1 Pétérù 2:17.

Ìṣòro Kẹta: Ìwà tí ò dáa. Ẹni tó bá rò pé òun gbọ́n tán kì í mọ̀ ju kó ṣáà máa bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ẹlòmíì tàbí kó máa sọ̀rọ̀ sí wọn ṣàkàṣàkà kó bàa lè dójú tì wọ́n. Ẹlòmíì sì wà tó jẹ́ pé ó fẹ́ràn láti máa jiyàn, ó sì máa ń fẹ́ káwọn ẹlòmíì gba ohun tóun bá ṣáà ti sọ. Torí pé ó jẹ́ “olódodo àṣelékè,” èèyàn kéèyàn ló máa ń ka ẹnikẹ́ni tí kò bá ti ṣohun tó wù ú sí. (Oníwàásù 7:16) Ó dájú pé, o ò ní fẹ́ máa wà nítòsí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀! Ṣé kì í ṣe pé ìwọ náà nírú ìwà yẹn? Àbí ohun tó fà á nìyẹn táwọn èèyàn ò fi fẹ́ sún mọ́ ẹ? Bíbélì sọ pé: “Òmùgọ̀ sì ń sọ ọ̀rọ̀ púpọ̀,” àti pé “nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá.”—Oníwàásù 10:14; Òwe 10:19.

Ojútùú: Máa ní “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì.” (1 Pétérù 3:8) Bó ò bá tiẹ̀ fara mọ́ ohun tẹ́lòmíì bá ń sọ, máa fara balẹ̀ láti jẹ́ kí onítọ̀hún yẹn sọ tẹnu ẹ̀. Àwọn ibi tọ́rọ̀ yín bá ti dọ́gba ni kó o máa sọ̀rọ̀ lé lórí. Bó o bá sì fẹ́ sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ò fara mọ́, ṣe ni kó o fọgbọ́n àti sùúrù sọ ọ́.

Bó o bá ṣe fẹ́ káwọn ẹlòmíì máa bá ẹ sọ̀rọ̀ ni kíwọ náà máa bá wọn sọ̀rọ̀. Ìmọ̀ràn tí Bíbélì fún wa ni pé ká “máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú àti ìjiyàn.” (Fílípì 2:14) Bó o bá ń ta ko àwọn ẹlòmíì, tó ò ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí tó ò ń ṣe bíi pé ìwọ nìkan lo mọ gbogbo nǹkan ṣe, ńṣe làwọn èèyàn á máa sá fún ẹ. Àmọ́, wọ́n á túbọ̀ fẹ́ràn ẹ tí ọ̀rọ̀ ẹnu ẹ bá ń “fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́.”—Kólósè 4:6.

Ṣé Ọ̀ranyàn Ni?

Nínú àwọn nǹkan tá a jíròrò yìí, ó ṣeé ṣe kó o ti rí ojútùú sáwọn nǹkan tó fà á táwọn èèyàn kì í fi í sún mọ́ ẹ. O gbọ́dọ̀ gbà pé gbogbo èèyàn kọ́ ló máa fẹ́ràn ẹ. Jésù ṣáà sọ pé, àwọn kan tiẹ̀ máa kórìíra àwọn tó bá ń ṣe ohun tó tọ́. (Jòhánù 15:19) Torí náà, o ò ní láti báwọn èèyàn ṣọ̀rẹ́ tipátipá.

Àmọ́ ṣá o, o lè ṣe gbogbo ohun tó yẹ ní ṣíṣe káwọn èèyàn lè sún mọ́ ẹ, láì tẹ àwọn ìlànà Bíbélì tó o mọ̀ lójú. Sámúẹ́lì, tó gbé ayé nígbà tí wọ́n kọ Bíbélì, fi tọkàntọkàn pinnu pé òun máa ṣe ohun tó máa múnú Ọlọ́run dùn. Ibo nìyẹn wá yọrí sí fún un? Ó “túbọ̀ ń jẹ́ ẹni tí a fẹ́ràn ní ojú ìwòye Jèhófà àti ti àwọn ènìyàn.” (1 Sámúẹ́lì 2:26) Tíwọ náà bá gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí ojú rere Ọlọ́run, àwọn èèyàn á sì fẹ́ràn ẹ!

KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 8, NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ

Bó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo DVD wa tó dá lórí bó o ṣe lè yan àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà, ìyẹ́n,“Young People Ask—How Can I Make Real Friends?” Ó lé ní ogójì [40] èdè tá a fi ṣe é jáde

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Kí lo lè ṣe tí ọ̀rẹ́ ẹ àtàtà bá di ọ̀tá ẹ?

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Ẹni tí ó [bá] ń bomi rin àwọn ẹlòmíràn ní fàlàlà, a ó bomi rin òun náà ní fàlàlà.”—Òwe 11:25.

ÌMỌ̀RÀN

Má kàn máa sọ̀rọ̀ ṣókí. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan bá bi ẹ́ pé, ṣó o gbádùn òpin ọ̀sẹ̀, má kàn dáhùn pé mo gbádùn ẹ̀. Ṣàlàyé ìdí tó o fi gbádùn ẹ̀. Kó o wá béèrè bí ẹni yẹn ṣe lo òpin ọ̀sẹ̀ tiẹ̀.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Bíbélì sọ pé ó ṣeé ṣe kí Mósè, Jeremáyà àti Tímótì ti jẹ́ onítìjú èèyàn nígbà kan rí.—Ẹ́kísódù 3:11, 13; 4:1, 10; Jeremáyà 1:6-8; 1 Tímótì 4:12; 2 Tímótì 1:6-8.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Olórí ohun tí kì í jẹ́ kí n lè báwọn èèyàn ṣọ̀rẹ́ ni ․․․․․

Ohun tí màá ṣe láti yanjú ìṣòro yìí ni ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí ló lè fà á táwọn Krístẹ́nì kan ò fi ní rẹ́ni bá ṣọ̀rẹ́?

● Kí ni ò ní jẹ́ kó o máa rò pé o ò dáa fún ohunkóhun?

● Báwo lo ṣe máa tu àbúrò ẹ tó sábà máa ń dá wà nínú?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 88]

Arábìnrin kan gbìyànjú láti máa bá mi ṣọ̀rẹ́, àmọ́ mi ò kọ́kọ́ fojú sílẹ̀ fún un. Ìgbà tí mo wá sún mọ́ ọn ni mo wá rí i pé ìwà ọ̀dẹ̀ ni mò ń hù tẹ́lẹ̀! Ó ti wá di ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ tí mo ní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ló fi jù mí lọ!’’—Marie

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 87]

O lè rí ojútùú sí ìṣòro tó wà láàárín ìwọ àtàwọn ojúgbà ẹ