Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Òbí Mi Bá Ń Mutí Lámujù Tó Sì Ń Lòògùn Olóró Ńkọ́?

Bí Òbí Mi Bá Ń Mutí Lámujù Tó Sì Ń Lòògùn Olóró Ńkọ́?

ORÍ 23

Bí Òbí Mi Bá Ń Mutí Lámujù Tó Sì Ń Lòògùn Olóró Ńkọ́?

“Dádì sọ pé àwọn fẹ́ lọ tún mọ́tò ṣe, àmọ́ a ò gbúròó wọn mọ́ látàárọ̀. Mọ́mì pè wọ́n sórí fóònù wọn, àmọ́ wọn ò gbé e. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni mo rí i pé ara Mọ́mì ò balẹ̀ mọ́. Wọ́n wá sọ fún mi pé ‘Mo fẹ́ wá dádì ẹ lọ.’

“Nígbà tí Mọ́mì máa pa dà dé, àwọn nìkan ló wọlé. Mo wá bi wọ́n pé ‘Ṣẹ́ ẹ rí Dádì?’ Wọ́n dáhùn pé, ‘Rárá.’

“Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo ti mọ̀ pé Dádì tún ti jẹ wá lójèé. Wọn ò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí ni pé dádì mi máa ń lòògùn olóró. Nígbà tí wọ́n sì máa wọlé, wọ́n ti kó èmi àti Mọ́mì láyà sókè. Mi ò ta sí wọn lọ́jọ́ kejì, kò sì wù mí bẹ́ẹ̀.”—Karen, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14].

Ọ̀KẸ́ àìmọye ọ̀dọ́ ló máa ń káyà sókè lójoojúmọ́, nítorí pé wọ́n ń gbé pẹ̀lú òbí kan tí ò lè ṣe kó má lòògùn olóró tó sì ń mutí lámujù. Bí ọ̀kan lára àwọn òbí ẹ bá ti sọ ọtí mímu àti lílo oògùn olóró dàṣà, ó lè máa kó ìtìjú bá ẹ, kó máa mú nǹkan sú ẹ, kó sì máa múnú bí ẹ pàápàá.

Bí àpẹẹrẹ, dádì Mary ló tọ́ ọ dàgbà, gbogbo ẹni tó bá sì rí dádì Mary ló máa ń sọ pé èèyàn dáadáa ni. Àmọ́, ó máa ń yọ́ ọtí mu, ó sì máa ń ṣépè lé àwọn ará ilé ẹ̀ lórí. Mary rántí pé: “Àwọn èèyàn máa ń wá bá àwa ọmọ, wọ́n á sì sọ fún wa pé bàbá rere la ní àti pé ó dáa tá a nírú bàbá bẹ́ẹ̀.” *

Bí ọ̀kan lára àwọn òbí ẹ bá ti sọ ọtí mímu àti lílo oògùn olóró dàṣà, báwo lo ṣe lè fara dà á?

Ohun Tó Fà Á

Ohun àkọ́kọ́ ni pé kó o lóye ìṣòro tí òbí ẹ yẹn ní gan-an. Òwe 1:5 sọ pé: “Ẹni òye . . . ni ènìyàn tí ó ní ìdarí jíjáfáfá.” Torí náà, ó máa dáa kó o lóye ohun tí mímu ọtí lámujù àti lílo oògùn olóró túmọ̀ sí àti ohun tó ń sún àwọn èèyàn ṣe bẹ́ẹ̀.

Bí àpẹẹrẹ, mímutí yó lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ò fi dandan sọ ẹnì kan di alámujù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni tó ń mutí yó léraléra tí ò sì fẹ́ jáwọ́ ńbẹ̀ ni alámujù. * Onítọ̀hún ti sọ ọtí mímu di ọlọ́run débi pé tó bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í mutí kì í lè kúrò nídìí ẹ̀. Ọtí tó ń mu lámujù á wá kó ìṣòro bá ìdílé ẹ̀, iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀, ó sì lè sọ ọ́ di aláìsàn.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan kàn máa ń kúndùn ọtí mímu ni, ẹ̀dùn ọkàn ló máa ń sún àwọn míì sí i. Kódà, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń mutí lámujù ló máa ń kórìíra ara wọn. (Òwe 14:13) Alámujù tiẹ̀ ni òbí àwọn kan lára wọn. Fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n máa ń fi ọtí pa ẹ̀dùn ọkàn tó ti bá wọn ní kékeré rẹ́. Ohun kan náà lè fà á táwọn kan á fi máa lòògùn olóró.

Òótọ́ ni pé, ọtí mímu àti lílo oògùn olóró máa ń dá kún ìṣòro, àmọ́ ó tún máa ń jẹ́ kí wọ́n ro èròkerò kì í sì í jẹ́ kára wọn lélẹ̀. Ìdí nìyẹn tí òbí ẹ yẹn fi nílò ìrànlọ́wọ́ ẹni tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa béèyàn ṣe lè ran irú wọn lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ mímu ọtí lámujù àti lílo oògùn olóró.

Má Retí Ohun Tó Pọ̀ Jù

Òótọ́ ni pé mímọ ohun tó fà á tí òbí ẹ fi ń hu irú ìwà tó ń tini lójú bẹ́ẹ̀ ò lè yanjú ìṣòro tó wà nílẹ̀. Síbẹ̀, tó o bá lóye bó ṣe ń ṣe òbí ẹ, wàá lè máa gba tiẹ̀ náà rò.

Bí àpẹẹrẹ, ṣé wàá retí pé kí òbí ẹ tí ẹsẹ̀ ń dùn bá ẹ gbá bọ́ọ̀lù? Bó o bá wá mọ̀ pé àfọwọ́fà òbí ẹ ló jẹ́ kẹ́sẹ̀ máa dùn ún ńkọ́? Ó dájú pé, ó máa dùn ẹ́ gan-an. Síbẹ̀, ó máa yé ẹ pé, òbí ẹ ò ní lè bá ẹ gbá bọ́ọ̀lù àyàfi tí ẹsẹ̀ rẹ̀ bá jinná. Bó o bá mọ òkodoro òtítọ́ yìí, o ò ní máa retí ohun tí òbí ẹ ò lè ṣe.

Bọ́ràn ṣe rí náà nìyẹn tó bá dọ̀rọ̀ òbí tó ń mutí lámujù tàbí tó ń lòògùn olóró, torí ńṣe ló dà bí ìgbà tí ìrònú wọn ti yarọ. Òótọ́ ni pé àfọwọ́fà ni. Kò sì burú bínú ẹ ò bá dùn nítorí ìwà tí kò yẹ ọmọlúwàbí tí wọ́n ń hù. Síbẹ̀, àyàfi tí òbí ẹ bá bọ́ lọ́wọ́ àṣà mímu ọtí lámujù tàbí lílo oògùn olóró, kò ní lè bójú tó ẹ bó ṣe yẹ. Bó o bá ń fojú pé ohun tó ń ṣe òbí ẹ ò ní jẹ́ kó lè ṣe tó bó ṣe yẹ wò ó, ìyẹn á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe máa retí ohun tí kò lè ṣe.

Ohun Tó O Lè Ṣe

Òótọ́ kan tí ò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ ni pé kò sóhun tó o lè ṣe ju pé kó o máa fara da ohun tí ìmukúmu òbí ẹ yẹn ń fà títí tó fi máa wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ ara ẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, kí lo lè ṣe?

Má ru ẹrù òbí ẹ tó ń mùmukúmu fún un. Òbí ẹ fúnra ẹ̀ ló máa ru ẹrù ohun tí ọtí àmujù bá fà, kò sẹ́ni tó máa bá a gbé e. Gálátíà 6:5 sọ pé: “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.” Kì í ṣe ojúṣe ẹ láti wo òbí ẹ sàn, ìwọ sì kọ́ lo máa dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn nǹkan tó fọwọ́ ara ẹ̀ fà. Bí àpẹẹrẹ, kò sídìí fún ẹ láti bá a parọ́ fún ọ̀gá ẹ̀ níbiṣẹ́ tàbí láti lọ wọ́ ọ kúrò níbi tó ṣubú sí nígbà tó mutí yó tán.

Gba òbí ẹ nímọ̀ràn láti wá ìrànlọ́wọ́ lọ. Ìṣòro tó ga jù tí òbí ẹ lè ní ni pé ó lè má gbà pé òun níṣòro. Nígbà tára ẹ̀ bá ti wálẹ̀, ìyàwó tàbí ọkọ ẹni tó ń mutí lámujù náà, àtàwọn tó dàgbà nínú ẹ̀yin ọmọ lè lọ bá a sọ̀rọ̀ nípa bí ìwà tó ń hù ṣe ń nípa lórí ìdílé, kí wọ́n sì jẹ́ kó mọ ohun tó lè ṣe láti yanjú ìṣòro tó wà ńlẹ̀.

Yàtọ̀ síyẹn, ó máa dáa gan-an tí òbí ẹ tó ń mutí lámujù bá lè kọ ìdáhùn tó ní sáwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí síbì kan: Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí èmi àtàwọn aráalé mi tí mi ò bá jáwọ́ nínú ọtí àmujù àti lílo oògùn nílòkulò? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tí mo bá jáwọ́? Kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe láti rí ìrànlọ́wọ́ gbà?

Tọ́rọ̀ bá ti fẹ́ di wàhálà, tètè kúrò níbẹ̀. Òwe 17:14 sọ pé: “Kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.” Má ṣera ẹ léṣe nípa dídá sí ìjà tí ò kàn ẹ́. Bó bá ṣeé ṣe, gba yàrá ẹ lọ tàbí kó o lọ sílé ọ̀rẹ́ ẹ kan. Bó o bá sì rí i pé òbí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ mọ́-ọn yín, yáa tètè pe àwọn aráàdúgbò.

Gba bí nǹkan ṣe rí lára ẹ. Àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń rò pé àwọn ti ṣàìdáa nítorí pé wọ́n bínú sí òbí wọn tó ń mutí lámujù. Kò sóhun tó burú níbẹ̀ téèyàn bá bínú níwọ̀nba, pàápàá tó bá jẹ́ pé ọtí tí òbí ẹ ń mu lámujù ni ò jẹ́ kó bójú tó ẹ bó ṣe yẹ. Òótọ́ ni pé Bíbélì pa á láṣẹ pé kó o bọlá fáwọn òbí ẹ. (Éfésù 6:2, 3) Àmọ́, ohun tí ‘bíbọlá’ túmọ̀ sí ni pé kó o bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ tí ẹnì kan ní, kò kọjá bó o ṣe máa ń bọ̀wọ̀ fún ọlá àṣẹ tí ọlọ́pàá tàbí adájọ́ ní. Ìyẹn ò ní kó o ka àmujù òbí ẹ sóhun tó dáa. (Róòmù 12:9) O kì í sì í ṣe ẹni ibi torí pé bó ṣe ń mu ọtí lámujù tó sì ń lòògùn olóró ń rí ẹ lára; ó ṣe tán, ṣíṣe nǹkan ní àṣerégèé máa ń ríni lára lọ́tọ̀!—Òwe 23:29-35.

Wá àwọn tó máa gbé ẹ ró. Tínú ilé bá ti dogun, o lè má mọ ohun tó tọ́ mọ́. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé kó o wá àwọn tó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà tí inú ilé wọn sì tòrò bá ṣọ̀rẹ́. Àwọn ará tó wà nínú ìjọ Kristẹni lè ṣe púpọ̀ láti bójú tó ẹ, wọ́n sì lè máa tù ẹ́ nínú tó o bá tọ̀ wọ́n lọ. (Òwe 17:17) Bó o bá ń bá àwọn ìdílé tó wà nínú ìjọ ṣọ̀rẹ́, wàá lè ráwọn àpẹẹrẹ rere tó o lè fara wé, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó o tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí ò dáa tí òbí ẹ ń fi lélẹ̀.

Wá ìrànlọ́wọ́. Wàá rí ìrànlọ́wọ́ gbà bó o bá ní àgbàlagbà kan tí òye jinlẹ̀ nínú ẹ̀ tó o lè sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún. Àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbàkigbà tó o bá nílò wọn. Bíbélì sọ pé àwọn ọkùnrin yìí lè dà bí “ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.” (Aísáyà 32:2) Torí náà, kò sídìí fún ẹ láti máa bẹ̀rù tàbí tijú láti lọ bá wọn nígbà tó o bá nílò ìtùnú àti ìmọ̀ràn.

Kọ èyí tó o máa kọ́kọ́ fẹ́ ṣe lára àwọn kókó mẹ́fà tá a tò sókè yìí. ․․․․․

O lè má lè tún bí nǹkan ṣe ń rí nílé yín ṣe báyìí, àmọ́ o lè ṣiṣẹ́ lórí bóhun tó ń ṣẹlẹ̀ ṣe ń nípa lórí ẹ. Kàkà kó o máa gbìyànjú láti darí òbí ẹ, yáa gbájú mọ́ ẹnì kan ṣoṣo tó o lè darí, ìyẹn ìwọ fúnra ẹ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Máa ṣiṣẹ́ ìgbàlà [rẹ] yọrí.” (Fílípì 2:12) Ìyẹn á jẹ́ kó o lẹ́mìí pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa, ó sì lè jẹ́ pé ìyẹn gan-an ló máa jẹ́ kí òbí ẹ wá ìrànlọ́wọ́ lọ.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Bó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà làwọn òbí ẹ máa ń jà ńkọ́? Báwo lo ṣe lè fara da ẹ̀dùn ọkàn tó lè bá ẹ?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 7 Bí òbí ẹ tó ń mutí lámujù bá ń fìyà jẹ ẹ́, ohun tó máa dáa jù ni pé kó o wá ìrànlọ́wọ́ lọ. Finú han àgbàlagbà kan tó o fọkàn tán. Bó bá sì jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, o lè sọ fún alàgbà kan nínú ìjọ yín tàbí Kristẹni kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 11 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọkùnrin la sọ pé wọ́n ń mutí lámujù nínú orí yìí, àwọn nǹkan tá a jíròrò níbí náà kan àwọn obìnrin.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú.Òwe 19:11.

ÌMỌ̀RÀN

Dípò tó ò bá fi kórìíra òbí ẹ tó ṣìwà hù, ìwà tí ò dáa tí wọ́n ń hù yẹn gan-an ni kó o kórìíra.—Òwe 8:13; Júúdà 23.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Bí wọ́n bá lo ọ̀rọ̀ náà “bọlá” nínú Bíbélì, ó lè túmọ̀ sí wíwulẹ̀ gbà pé ẹnì kan ní ọlá àṣẹ kan. (Éfésù 6:1, 2) Torí náà, pé ò ń bọlá fún òbí kan ò wá túmọ̀ sí pé gbogbo ìgbà ni wàá máa gbà pé ohun tó ń ṣe tọ̀nà.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bí òbí mi bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣépè tàbí tó fẹ́ máa lù mí, màá ․․․․․

Mo lè rọ òbí mi láti wá ìrànlọ́wọ́ lọ nípa ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

Kí ló fà á táwọn kan fi máa ń sọ ọtí mímu àti lílo oògùn nílòkulò dàṣà?

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìwọ kọ́ lo fà á tí òbí ẹ fi ń ṣe àṣerégèé nídìí ọtí àti oògùn?

Apá wo nínú ipò tó o bára ẹ lo lè bójú tó, báwo lo sì ṣe lè ṣe é?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 192]

“Mo mọ̀ pé àwọn òbí mi ṣì lè dójú tì mí lọ́jọ́ iwájú, àmọ́ mo tún mọ̀ pé tí mo bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa fún mi lókun tí mo nílò láti fara dà á.”—Maxwell

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 198]

Bí Ọ̀kan Nínú Àwọn Òbí Ẹ Ò Bá Sin Jèhófà Mọ́

Bí ọ̀kan nínú àwọn òbí ẹ ò bá fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù mọ́, bóyá tó tiẹ̀ sọ pé òun fẹ́ yọ ara òun kúrò nínú ìjọ Kristẹni, kí lo lè ṣe?

Mọ̀ dájú pé Jèhófà ò lè dá lẹ́bi torí pé òbí ẹ ṣìwà hù. Bíbélì sọ pé: “Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.”—Róòmù 14:12.

Má máa jowú àwọn ọ̀dọ́ tí ipò wọn dáa ju tìẹ lọ. (Gálátíà 5:26) Ọ̀dọ́kùnrin kan tí bàbá rẹ̀ pa ìdílé wọn tì sọ pé: “Kàkà kéèyàn máa ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó máa dáa kó pọkàn pọ̀ sórí bó ṣe lè fara dà á.”

Máa bá a nìṣó láti bọ̀wọ̀ fún òbí tó ń ṣìwà hù náà, tí òfin ẹ̀ ò bá ti ta ko òfin Ọlọ́run, máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Àṣẹ Jèhófà pé káwọn ọmọ máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn ò kan bóyá òbí yẹn jẹ́ onígbàgbọ́ tàbí kì í ṣe onígbàgbọ́. (Éfésù 6:1-3) Bó o bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí ẹ láìfi àwọn ìkùdíẹ̀ káàtó wọn pè, ńṣe lò ń fi hàn pé o fẹ́ràn Jèhófà.—1 Jòhánù 5:3.

Sún mọ́ àwọn ará nínú ìjọ Kristẹni ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Kó o sì rí ìtùnú gbà látọ̀dọ̀ ìdílé ńlá tó o ní nípa tẹ̀mí. (Máàkù 10:30) Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ David máa ń bẹ̀rù pé àwọn ará máa bẹ̀rẹ̀ sí pa òun àtàwọn mọ̀lẹ́bí òun tì torí pé bàbá àwọn ò sin Jèhófà mọ́. Àmọ́, David wá rí i pé ọ̀ràn ò rí bóun ṣe rò. Ó ní: “Wọn ò ta wá nù rárá. Èyí sì jẹ́ kó dá mi lójú pé àwọn ará ìjọ fẹ́ràn wa gan-an ni.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 194]

Bó o bá ń fojú pé ohun tó ń ṣe òbí ẹ ò ní jẹ́ kó lè ṣe tó bó ṣe yẹ wò ó, ìyẹn á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe retí ohun tí kò lè ṣe