Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbọ́kàn Mi Kúrò Lórí Ìbálòpọ̀?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbọ́kàn Mi Kúrò Lórí Ìbálòpọ̀?

ORÍ 29

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbọ́kàn Mi Kúrò Lórí Ìbálòpọ̀?

Ọ̀DỌ́MỌKÙNRIN kan tó ń jẹ́ Michael sọ pé: “Ìgbà gbogbo ni mo máa ń ronú nípa àwọn ọmọbìnrin, bí wọn ò tiẹ̀ sí nítòsí pàápàá. Etí wo ló ń báni gbọ́rú ẹ̀. Ó burú débi pé n kì í lè pọkàn pọ̀ nígbà míì!”

Ṣé èrò nípa ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ ló máa ń gba ìwọ náà lọ́kàn ṣáá bíi ti Michael? Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè dà bíi pé ìjàkadì ńlá kan ń wáyé nínú ọkàn rẹ lọ́hùn-ún. Èrò nípa ìbálòpọ̀ lè máa jà gùdù lọ́kàn ẹ bí ìgbà táwọn ọmọ ogun ọ̀tá bá dìde ogun. Michael sọ pé: “Ńṣe lèrò ìbálòpọ̀ máa ń gbani lọ́kàn pátápátá. Ó lè mú kéèyàn wakọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ gba ọ̀nà jíjìn kọjá nítorí àtirí ọmọbìnrin kan tó fi gbogbo ara ṣẹwà, tàbí kéèyàn kúrò níbi tó ti fẹ́ rajà nínú ṣọ́ọ̀bù ìtajà ńlá kan, nítorí àtilọ wo ojú ẹnì kan tó fà á mọ́ra lápá ibòmíì nínú ilé ìtajà náà.”

Àmọ́ ṣá o, rántí pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn ní èrò àtigbádùn ìbálòpọ̀ o. Ó ṣe tán, Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin lọ́nà tí wọ́n á fi máa ní òòfà ìfẹ́ síra wọn. Kò sì sóhun tó burú bí ìbálòpọ̀ bá wáyé láàárín àwọn tó gbéra wọn níyàwó lọ́nà tó bójú mu. Bó ò bá tíì ṣègbéyàwó, ara rẹ lè máa wà lọ́nà fún ìbálòpọ̀. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe rò pé oníṣekúṣe ni ẹ́ tàbí pé o ò sì lára àwọn tó lè mára dúró dìgbà tí wọ́n máa ní ọkọ tàbí aya tiwọn. O lè para ẹ mọ́ láìṣe ìṣekúṣe bó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀! Ohun tó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o máa gbọ́kàn ẹ kúrò lórí ìbálòpọ̀. Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

Mọ irú àwọn tí wàá máa bá ṣọ̀rẹ́. Báwọn ọmọ iléèwé ẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa ìṣekúṣe, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o bá wọn dá sí i, kí tìẹ má bàa dá yàtọ̀. Àmọ́, ńṣe nìyẹn á wulẹ̀ mú kó túbọ̀ ṣòro fún ẹ láti gbọ́kàn ẹ kúrò níbẹ̀. Ṣé wàá wá dìde kúrò láàárín wọn ni? Ohun tó o gbọ́dọ̀ ṣe náà nìyẹn, o ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kíyẹn tì ẹ́ lójú! Lọ́pọ̀ ìgbà, o lè dọ́gbọ́n fibẹ̀ sílẹ̀ lọ́nà tó ò fi ní dà bí olódodo àṣelékè tàbí lọ́nà tí wọn ò fi ní fi ẹ́ ṣẹ̀sín.

Má ṣe lọ́wọ́ sí eré ìnàjú oníṣekúṣe. Òótọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo fíìmù tàbí orin ló burú. Síbẹ̀, ohun tí ọ̀pọ̀ eré ìnàjú tí wọ́n ń ṣe lónìí wà fún ni láti máa mú kára èèyàn wà lọ́nà fún ìbálòpọ̀. Ìmọ̀ràn wo ni Bíbélì fún wa lórí ọ̀ràn yìí? “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Máa sá fún eré ìnàjú èyíkéyìí tó bá lè ru ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ sókè. *

Ìṣòro Fífọwọ́ Pa Ẹ̀yà Ìbímọ

Àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ wọn nígbà tí ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ bá ru sókè nínú wọn. Àmọ́, èyí lè yọrí sí ìṣòro tó burú jáì. Bíbélì gba àwa Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò.” (Kólósè 3:5) Òdì kejì gbáà ni fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ jẹ́ sí ‘sísọ ẹ̀yà ara ẹni dòkú.’ Kódà, ńṣe ló máa ń tanná ran irú èrò bẹ́ẹ̀, tí ò sì ní í jẹ́ kó o mọ́kàn kúrò níbẹ̀!

Bó o bá ń fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹ, ó máa sọ ẹ́ di ẹrú fún ìfẹ́ ọkàn rẹ. (Títù 3:3) Ọ̀nà kan tó o lè gbà bẹ̀rẹ̀ sí í jáwọ́ nínú àṣà náà ni pé kó o wá ẹni finú hàn. Kristẹni kan tó fi ọ̀pọ̀ ọdún sapá láti jáwọ́ nínú àṣà fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ sọ pé: “Ká ní mo mọ̀ ni, ìgbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́ ni mi ò bá ti gbé ìtìjú tà tí ǹ bá sì ti sọ fẹ́nì kan! Ọ̀pọ̀ ọdún ni ẹ̀rí ọkàn mi fi dà mí láàmú, kékeré sì kọ́ ni àkóbá tó ti ṣe fún àjọṣe èmi àtàwọn ẹlòmíì, èyí tó tiẹ̀ burú jù ni bó ṣe kó bá àjọṣe èmi àti Jèhófà.”

Ta ló yẹ kó o sọ fún? Òbí lẹni tó sábà máa ń bọ́gbọ́n mu jù lọ pé kéèyàn sọ fún. Ó sì ṣeé ṣe kí ẹnì kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ nínú ìjọ ṣèrànlọ́wọ́. O lè bẹ̀rẹ̀ nípa sísọ pé: “Màá fẹ́ láti sọ fún un yín nípa ìṣòro kan tó ń yọ mi lẹ́nu gidigidi.”

André fi ọ̀rọ̀ náà tó Kristẹni alàgbà kan létí, inú rẹ̀ sì dùn pé ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ní: “Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ yẹn lọ, ṣe ni ojú alàgbà yẹn lé ròrò fún omijé. Nígbà tí mo sọ̀rọ̀ tán, ó jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ mi. Ó ní àwọn ẹlòmíì náà nírú ìṣòro tí mo ní. Ó ní kí n máa fi bí nǹkan bá ṣe ń lọ sí fún mi lórí ọ̀ràn náà tó òun létí, ó sì ṣèlérí pé òun á bá mi mú àwọn ìtẹ̀jáde tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ wá. Lẹ́yìn tí mo ti sọ fún un, mo pinnu pé mi ò ní juwọ́ sílẹ̀, kódà bó bá ń wá sí mi lọ́kàn jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

Mário pinnu láti sọ fún dádì ẹ̀. Nígbà tí dádì ẹ̀ sì gbọ́ ohun tó sọ, àánú ṣe é, ó sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ tó sọ yé òun dáadáa. Ó jẹ́ kí Mário mọ̀ pé ó ṣòro fóun alára láti borí ìṣòro náà nígbà tóun wà lọ́dọ̀ọ́. Mário ní: “Ìṣírí ńlá lọ̀rọ̀ tí dádì mi sọ fún mi nípa ara wọn jẹ́ fún mi. Mo pinnu pé bí dádì mi bá lè jáwọ́ nínú àṣà náà, a jẹ́ pé èmi náà lè jáwọ́ nìyẹn. Ohun tí dádì mi ṣe wú mi lórí débi tí mi ò fi mọ̀gbà tí mo bú sẹ́kún.”

Bíi ti André àti Mário, ìwọ náà lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà bó o ṣe ń sapá láti jáwọ́ nínú àṣà fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ. Kódà, bó o bá tún ṣe é, má ṣe juwọ́ sílẹ̀! Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o ja àjàṣẹ́gun. *

Yéé Ro Èròkerò

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú.” (1 Kọ́ríńtì 9:27) Ìwọ pẹ̀lú ò gbọ́dọ̀ fàyè gbàgbàkugbà bí èrò tí kò tọ́ nípa ìbálòpọ̀ bá gbà ẹ́ lọ́kàn. Bí èrò náà ò bá kúrò lọ́kàn ẹ, wá eré ìdárayá ṣe. Bíbélì sọ pé: “Ara títọ́ ṣàǹfààní fún ohun díẹ̀.” (1 Tímótì 4:8) Rírìn kánmọ́kánmọ́ tàbí wíwulẹ̀ ṣeré ìdárayá fún ìṣẹ́jú bíi mélòó kan lè ti tó láti mú èrò tí kò tọ́ yẹn kúrò lọ́kàn ẹ.

Ju gbogbo ẹ̀ lọ, má ṣe gbójú fo ìrànlọ́wọ́ tó o lè rí gbà lọ́dọ̀ Bàbá rẹ ọ̀run. Kristẹni àpọ́n kan sọ pé: “Bí ara mi bá wà lọ́nà fún ìbálòpọ̀, ṣe ni mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́.” Kì í ṣe pé Ọlọ́run á mú ìfẹ́ tó o ní sí ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ kúrò o. Àmọ́, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti rí i pé ọ̀pọ̀ nǹkan míì wà tó o lè máa ronú lé lórí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 7 Nínú Apá Kẹjọ ìwé yìí la ti jíròrò eré ìtura àti eré ìnàjú ní kíkún.

^ ìpínrọ̀ 14 Bó o bá fẹ́ ka púpọ̀ sí i nípa fífọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ, wo orí 25 nínú Apá Kìíní ìwé yìí.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.Fílípì 4:8.

ÌMỌ̀RÀN

Bó o bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ rẹ, àfi kó o jáwọ́ ńbẹ̀! Ronú lórí ohun tó ń mú kó o ṣe bẹ́ẹ̀, kó o wá gbìyànjú láti má ṣe jẹ́ kírú ẹ̀ wáyé mọ́.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Ohun tó o bá ń ronú lé lórí lè pinnu irú ẹni tó o máa jẹ́ àtàwọn ohun tí wàá máa ṣe.—Jákọ́bù 1:14, 15.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bí mo bá fẹ́ gbọ́kàn mi kúrò lórí ríronú nípa ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tèmi, màá ․․․․․

Bọ́rọ̀ ìbálòpọ̀ bá ti ń wọ ọ̀rọ̀ témi àtàwọn ọmọléèwé mi ń sọ, màá ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tí kò fi yẹ kéèyàn máa fojú tí kò dára wo ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀?

● Kí nìdí tó ò fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ fún ìbálòpọ̀ máa gbà ẹ́ lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ?

● Irú àwọn eré ìnàjú wo ló lè mú kó o máa ronú ṣáá nípa ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ?

● Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o bẹ́sẹ̀ rẹ sọ̀rọ̀ bí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ bá ti ń wọnú ìjíròrò?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 240]

“Ohun tó ràn mí lọ́wọ́ ni gbígbé tí mo máa ń gbọ́kàn mi kúrò lórí ohun tó ń mú kí ìbálòpọ̀ wá sí mi lọ́kàn. Mo máa ń rán ara mi létí pé bó pẹ́ bó yá, èrò náà á kúrò lọ́kàn mi.”—Scott

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 239]

Ṣé wàá gbà káwọn ìsọfúnni tó máa ń ba kọ̀ǹpútà jẹ́ wọnú kọ̀ǹpútà ẹ? Kí wá nìdí tí wàá fi jẹ́ kí èròkerò wọ̀ ẹ́ lọ́kàn?