Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí N Máa Wo Àwòrán Oníhòòhò?

Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí N Máa Wo Àwòrán Oníhòòhò?

ORÍ 33

Kí Nìdí Tí Kò Fi Yẹ Kí N Máa Wo Àwòrán Oníhòòhò?

Báwo lo ṣe máa ń ṣèèṣì rí àwọn àwòrán oníhòòhò tó?

□ Mi ò rí i rí

□ Ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan

□ Gbogbo ìgbà

Ibo lo ti sábà máa ń rí i?

□ Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì

□ Iléèwé

□ Orí tẹlifíṣọ̀n

□ Ibòmíì

Kí lo máa ń ṣe nígbà tó o bá ṣèèṣì rí àwòrán oníhòòhò?

□ Mo máa ń yára gbójú kúrò níbẹ̀.

□ Mo máa ń wò ó díẹ̀ kí n lè mọ ohun tó jẹ́.

□ Mo máa ń wò ó lọ ní tèmi ni, mo tún máa ń wá sí i pàápàá.

NÍGBÀ táwọn òbí rẹ wà lọ́dọ̀ọ́ bíi tìẹ, àwòrán oníhòòhò kì í ṣe ohun tí wọ́n ń rí káàkiri ìgboro. Àmọ́ lóde òní, ó ti wá di mẹ́ta kọ́bọ̀. Ọmọbìnrin ọlọ́dún mọ́kàndínlógún [19] kan sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà tí mo bá ń ṣe nǹkan lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, bóyá ṣe ni mò ń wo ọjà tí mo lè rà tàbí tí mo fẹ́ wo iye tí mo ní ní báńkì, ńṣe làwòrán oníhòòhò máa ń ṣàdédé yọ sójú kọ̀ǹpútà mi!” Èyí kì í ṣe tuntun mọ́. Ìwádìí kan fi hàn pé mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá lára àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ sí mẹ́rìndínlógún [16] ló sọ pé lọ́pọ̀ ìgbà táwọn bá ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n ní káwọn ṣe wá níléèwé lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ṣe làwọ́n kàn máa ń ṣèèṣì rí àwòrán oníhòòhò lórí kọ̀ǹpútà àwọn!

Bó o ti ṣe wá mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wo àwòrán oníhòòhò báyìí, o lè máa ronú pé, ‘Ṣé bẹ́ẹ̀ náà ló burú tó ni?’ Bẹ́ẹ̀ ni, ó burú tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ! Àwòrán oníhòòhò ń tàbùkù sáwọn tó ń ṣe é àtàwọn tó ń wò ó, ó sì máa ń jẹ́ kó rọrùn fáwọn tó ń wò ó láti ṣèṣekúṣe. Àmọ́, ìyẹn nìkan kọ́.

Kì í rọrùn láti jáwọ́ nínú wíwo àwòrán oníhòòhò, ó sì lè bààyàn láyé jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, gbọ́ ohun tí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jeff sọ lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá [14] tó ti jáwọ́ nínú wíwo àwòrán oníhòòhò, ó ní: “Ojoojúmọ́ ló máa ń ṣe mí bíi pé kí n tún wò ó. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í wù mí wò bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, síbẹ̀ kò tán lára. Ó ṣì máa ń wù mí wò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àwòrán náà ò kúrò lọ́kàn mi. Kò bá ti dáa jù ká ní mi ò bẹ̀rẹ̀ sí í wo ìwòkuwò yìí rárá. Ńṣe ló kọ́kọ́ ń dùn mọ́ mi, àmọ́ ní báyìí mo ti wá rí i pé ó léwu. Wíwo àwòrán oníhòòhò ń bayé ẹni jẹ́, ohun ìríra ni, ó ń tàbùkù sáwọn tó ń ṣe é, ọmọlúwàbí kan kì í sì í wò ó. Ká sòótọ́, irọ́ funfun báláú làwọn tó ń gbé àwòrán oníhòòhò jáde ń pa bí wọ́n bá sọ pé ó dáa kéèyàn máa wò ó. Kò sí nǹkan kan, bó ti wù kó mọ, tó dáa nínú wíwò ó.”

Ṣàyẹ̀wò Ara Rẹ

Kí lo lè ṣe tó ò fi ní máa ṣèèṣì fojú kan àwòrán oníhòòhò rárá? Kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò bó o ṣe máa ń rí i. Ṣé àwọn ibì kan wà tó o ti sábà máa ń rí i? Gbé àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí yẹ̀ wò:

Ṣó o rò pé àwọn kan lára àwọn ọmọléèwé rẹ lè fi àwòrán oníhòòhò ránṣẹ́ sórí tẹlifóònù alágbèéká rẹ tàbí sí àdírẹ́sì tó o fi ń gba lẹ́tà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Bó o bá ti mọ̀ bẹ́ẹ̀, á dáa kó o tètè pa á rẹ́ láìwulẹ̀ wò ó.

Ṣé àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tó o fi ń wá ìsọfúnni lórí ìkànnì Íńtánẹ́ẹ̀tì tó máa ń gbé àwòrán oníhòòhò wá pẹ̀lú ìsọfúnni tó o nílò? Bó o bá ti mọ̀ pé irú ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀, á dáa kó o mọ irú ọ̀rọ̀ tí wàá máa fi wá ìsọfúnni lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

Kọ àwọn nǹkan tó ti mú kó o rí àwòrán oníhòòhò rí sísàlẹ̀ yìí.

․․․․․

Kí lo rò pé o lè ṣe láti dín iye ìgbà tó o máa ń ṣèèṣì rí àwòrán oníhòòhò kù? Kọ àwọn ohun tó o rò pé o lè ṣe síbí yìí.

․․․․․

Bó O Bá Ti Ń Wò Ó

Ṣíṣèèṣì rí àwòrán oníhòòhò yàtọ̀ sí mímọ̀ọ́mọ̀ wò ó. Bó bá ti wá mọ́ ẹ lára ńkọ́? Jẹ́ kó yé ẹ pé kò rọrùn láti jáwọ́ ńbẹ̀ tó bá ti mọ́ra. Jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí: Ká sọ pé ẹnì kan fi òwú tín-ín-rín kan so ọwọ́ ẹ pọ̀. Ó dájú pé òwú yẹn máa já tó o bá kàn na ọwọ́ ẹ méjèèjì. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ó lọ́ owú yẹn mọ́ ẹ lọ́wọ́ láìmọye ìgbà ńkọ́? Kò sí àníàní pé ó máa ṣòro fún ẹ láti gbara ẹ. Bọ́rọ̀ àwọn tó sọ wíwo àwòrán oníhòòhò dàṣà ṣe rí náà nìyẹn. Bí wọ́n ṣe ń wò ó tó náà ló ṣe máa ń nira tó láti jáwọ́ ńbẹ̀. Bí wíwo àwòrán oníhòòhò bá ti mọ́ ẹ lára, báwo lo ṣe lè jáwọ́ ńbẹ̀?

Mọ̀ pé ohun tó burú ni wíwo àwòrán oníhòòhò. Ó dájú pé Sátánì ló ń lò ó láti sọ ẹ̀yà ìbímọ tí Jèhófà dá gẹ́gẹ́ bí ohun pàtàkì di yẹpẹrẹ. Bó bá jẹ́ pé ojú tíwọ náà fi ń wo àwòrán oníhòòhò nìyẹn, wàá máa “kórìíra ohun búburú.”—Sáàmù 97:10.

Ro ohun tó máa ń tẹ̀yìn ẹ̀ yọ. Àwòrán oníhòòhò máa ń da àárín tọkọtaya rú. Àwọn èèyàn kì í fojú ọmọlúwàbí wo àwọn tó wà níbẹ̀. Ó sì máa ń tàbùkù sáwọn tó ń wò ó. Ṣó o wá rí ìdí tí Bíbélì fi sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Kọ àkóbá tí sísọ wíwo àwòrán oníhòòhò dàṣà lè ṣe fún ẹ sórí ìlà yìí.

․․․․․

Ṣèpinnu. Jóòbù, ọkùnrin olóòótọ́, sọ pé: “Mo ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti má ṣe fi ojú àgbèrè wo ọmọbìnrin.” (Jóòbù 31:1, ìtumọ̀ Today’s English Version) Àwọn “ẹ̀jẹ́” mélòó kan tó o lè jẹ́ rèé:

Mi ò ní máa lọ sídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí kò bá ti séèyàn kankan lọ́dọ̀ mi.

Bí àwòrán oníhòòhò bá ṣèèṣì yọ lójú kọ̀ǹpútà nígbà tí mo bá wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kíá ni màá gbé e kúrò níbẹ̀.

Màá sọ fún àgbàlagbà kan tó sún mọ́ mi bí mo bá tún ti wo àwòrán oníhòòhò.

Ṣó o lè ronú nípa ohun kan tàbí méjì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú wíwo àwòrán oníhòòhò? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kọ wọ́n síbí.

․․․․․

Fọ̀ràn náà sínú àdúrà. Onísáàmù náà bẹ Jèhófà pé: “Mú kí ojú mi kọjá lọ láìrí ohun tí kò ní láárí.” (Sáàmù 119:37) Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kó o bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì máa fún ẹ ní okun tó o nílò láti máa ṣohun tó tọ́!—Fílípì 4:13.

Fọ̀rọ̀ lọ ẹnì kan. Ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn wá ẹnì kan fọ̀rọ̀ lọ̀ tó bá fẹ́ jáwọ́ nínú àṣà tí ò dáa. (Òwe 17:17) Kọ orúkọ ẹnì kan tó lóye, tó o rò pé á rọrùn fún ẹ láti fọ̀rọ̀ náà lọ̀ sórí ìlà yìí.

․․․․․

Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé á ṣeé ṣe fún ẹ láti gbara ẹ lọ́wọ́ àṣà wíwo àwòrán oníhòòhò. Àní sẹ́, ní gbogbo ìgbà tó o bá ti ń lè gbójú kúrò níbẹ̀, o ti ṣẹ́gun ẹ̀ débì kan nìyẹn. Sọ fún Jèhófà nípa àṣeyọrí tó o ṣe yẹn, kó o wá dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún okun tó fún ẹ. Máa rántí pé bó o bá ṣe ń yẹra fún wíwo àwòrán oníhòòhò tó ń bani láyé jẹ́ yìí, ńṣe lò ń múnú Jèhófà dùn!—Òwe 27:11.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.Kólósè 3:5.

ÌMỌ̀RÀN

Rí i dájú pé o ti ṣètò kọ̀ǹpútà tó o fi ń wo Íńtánẹ́ẹ̀tì láti má fàyè gba àwọn àwòrán oníhòòhò. Sì rí i dájú pé o kì í tẹ ohunkóhun tó lè mú káwọn tó ò mọ̀ rí máa kọ̀wé ránṣẹ́ sí ẹ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Ẹni tó bá fẹ́ràn wíwo àwòrán oníhòòhò kò yàtọ̀ sáwọn áńgẹ́lì tí wọ́n kúndùn ìṣekúṣe nígbà ayé Nóà.—Jẹ́nẹ́sísì 6:2.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bí mi ò bá fẹ́ kí àwòrán oníhòòhò máa ṣàdédé yọ sójú kọ̀ǹpútà mi, màá ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

Báwo ni àwòrán oníhòòhò ṣe ń sọ ohun mímọ́ di aláìmọ́?

Bó o bá ní àbúrò tó ń wo àwòrán oníhòòhò, báwo lo ṣe máa ràn án lọ́wọ́?

[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 278]

“Kó tó di pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí oògùn olóró tí mi ò tíì lò rí. Àmọ́ kò sóhun tó di bárakú fún mi tó wíwo àwòrán oníhòòhò. Bí kì í bá ṣe Jèhófà ni, mi ò rò pé màá lè jáwọ́ ńbẹ̀.”—Jeff

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 276]

Béèyàn bá ṣe ń wo àwòrán oníhòòhò tó ló ṣe máa ń mọ́ni lára tó, bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe máa ń ṣòro tó láti jáwọ́ ńbẹ̀