Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Apá 21

Jésù Jíǹde!

Jésù Jíǹde!

Jésù fara han àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, ó fún wọn nítọ̀ọ́ni, ó gbà wọ́n níyànjú

NÍ ỌJỌ́ kẹta lẹ́yìn ikú Jésù, àwọn obìnrin kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí i pé wọ́n ti yí òkúta tí wọ́n gbé dí ẹnu ibojì Jésù kúrò. Àwọn ẹ̀ṣọ́ tó wà níbẹ̀ dà bí òkú èèyàn, ibojì náà sì ṣófo!

Àwọn áńgẹ́lì méjì yọ sí wọn. Ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Jésù ará Násárétì ni ẹ ń wá.” Ó wá fi kún un pé: “A ti gbé e dìde.” (Máàkù 16:6) Láìfi àkókò ṣòfò, àwọn obìnrin yẹn sáré lọ sọ fáwọn àpọ́sítélì. Bí wọ́n ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, wọ́n pàdé Jésù. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ má bẹ̀rù! Ẹ lọ, ẹ ròyìn fún àwọn arákùnrin mi, kí wọ́n lè lọ sí Gálílì; wọn yóò sì rí mi níbẹ̀.”—Mátíù 28:10.

Nígbà tó ṣe lọ́jọ́ yẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì ń ti Jerúsálẹ́mù lọ sí abúlé Ẹ́máọ́sì. Àjèjì kan dara pọ̀ mọ́ wọn ó sì béèrè ohun tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Àmọ́ Jésù tó jíǹde ni, ọ̀nà tó gbà fara hàn wọ́n ni ò jẹ́ kí wọ́n kọ́kọ́ dá a mọ̀. Bí ojú wọn ti kún fún ìbànújẹ́, wọ́n dá a lóhùn pé ọ̀rọ̀ Jésù làwọn ń sọ. Ni àjèjì náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Mèsáyà fún wọn látinú àwọn Ìwé Mímọ́. Ó ṣe kedere wàyí pé gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ni Jésù ti mú ṣẹ kínníkínní. * Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn náà wá mọ̀ pé Jésù, tí Ọlọ́run jí dìde ní ẹni ẹ̀mí, ni àjèjì tó ń bá wọn sọ̀rọ̀, ó pòórá mọ́ wọn lójú.

Àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjèèjì yára pa dà sí Jerúsálẹ́mù. Wọ́n bá àwọn àpọ́sítélì níbẹ̀ tí wọ́n kóra jọ sínú ilé tí ilẹ̀kùn ẹ̀ wà ní títìpa. Báwọn méjì yìí ṣe ń sọ ohun tójú wọ́n rí, Jésù fara hàn. Bí àlá ló jọ lójú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀! Jésù wá bi wọ́n pé: “Èé sì ti ṣe tí iyèméjì fi dìde nínú ọkàn-àyà yín?” Ó wá fi kún un pé: “Lọ́nà yìí ni a kọ̀wé rẹ̀ pé Kristi yóò jìyà, yóò sì dìde kúrò láàárín àwọn òkú ní ọjọ́ kẹta.”—Lúùkù 24:38, 46.

Fún ogójì [40] ọjọ́ lẹ́yìn àjíǹde Jésù, ó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìgbà tó yàtọ̀ síra. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó fara han iye tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] èèyàn lọ! Ó tiẹ̀ lè jẹ́ pé ìgbà yẹn ló gbé iṣẹ́ bàǹtà-banta lé wọn lọ́wọ́ pé: “Ẹ lọ . . . ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́. Sì wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mátíù 28:19, 20.

Ní ìpàdé tí Jésù báwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ṣe kẹ́yìn, ó ṣèlérí fún wọn pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Lẹ́yìn náà ni Jésù gbéra kúrò nílẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ sọ́run, wọ́n ń wò ó lọ títí tí kùrukùru fi gbà á mọ́ wọn lójú.

—A gbé e ka Mátíù orí 28; Máàkù orí 16; Lúùkù orí 24; Jòhánù orí 20 àti 21; 1 Kọ́ríńtì 15:5, 6.

^ ìpínrọ̀ 6 Bó o bá fẹ́ kà nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà, èyí tí Jésù mú ṣẹ, wo ojú ìwé 17 sí 19 nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí àti ojú ìwé 199 sí 201 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?