Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 3

Báwo Ni Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Nínú Ọgbà Édẹ́nì?

Báwo Ni Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Nínú Ọgbà Édẹ́nì?

Àìmọye nǹkan rere ni Jèhófà fún Ádámù àti Éfà. Jẹ́nẹ́sísì 1:28

Jèhófà dá Éfà tó jẹ́ obìnrin àkọ́kọ́, ó sì fà á lé Ádámù lọ́wọ́ pé kó fi ṣe aya.​—Jẹ́nẹ́sísì 2:​21, 22.

Nígbà tí Jèhófà dá wọn, ó fún wọn ní ọpọlọ pípé àti ara pípé, wọn ò ní àbùkù kankan rárá.

Ọgbà Édẹ́nì ni ilé wọn, ọgbà tó lẹ́wà gan-an ni. Odò, àwọn igi eléso àti àwọn ẹranko wà níbẹ̀.

Jèhófà máa ń bá wọn sọ̀rọ̀; ó máa ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Tí wọ́n bá tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n á wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.

Ọlọ́run sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ èso ọ̀kan lára àwọn igi tó wà nínú ọgbà náà. Jẹ́nẹ́sísì 2:​16, 17

Jèhófà fi igi eléso kan tó wà nínú ọgbà náà han Ádámù àti Éfà, ó wá sọ fún wọn pé tí wọ́n bá jẹ èso rẹ̀, wọ́n máa kú.

Ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Sátánì Èṣù ni áńgẹ́lì búburú yẹn.

Sátánì ò fẹ́ kí Ádámù àti Éfà gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu. Nítorí náà, ó lo ejò kan láti sọ fún Éfà pé tó bá jẹ èso igi náà, kò ní kú, ṣe ló máa dà bí Ọlọ́run. Ó dájú pé irọ́ ni Sátánì pa.​—Jẹ́nẹ́sísì 3:​1-5.