Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 4

Kí Ló Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Tí Wọ́n Tẹ́tí sí Sátánì?

Kí Ló Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Tí Wọ́n Tẹ́tí sí Sátánì?

Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wọ́n sì kú. Jẹ́nẹ́sísì 3:​6, 23

Éfà tẹ́tí sí ejò yìí, ó sì jẹ èso igi náà. Lẹ́yìn náà, ó fún Ádámù lára rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.

Ohun tí wọ́n ṣe yìí ò dáa rárá, ẹ̀ṣẹ̀ ni. Ọlọ́run lé wọn jáde nínú Párádísè tí wọ́n ń gbé.

Nǹkan wá nira fún àwọn àti àwọn ọmọ wọn. Wọ́n darúgbó, wọ́n sì kú. Wọn ò lọ sí ibi tí àwọn ẹ̀mí ń gbé o; ṣe ni wọ́n ṣaláìsí.

Àwọn tó ti kú dà bí erùpẹ̀ lásán. Jẹ́nẹ́sísì 3:19

Ìdí tí àwa èèyàn fi ń kú ni pé àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà ni gbogbo wa. Àwọn òkú ò lè ríran, wọn ò lè gbọ́ràn, wọn ò sì lè ṣe nǹkan kan.​—Oníwàásù 9:​5, 10.

Jèhófà ò fẹ́ kí àwa èèyàn máa kú. Láìpẹ́, ó máa jí àwọn tó ti kú dìde. Tí wọ́n bá tẹ́tí sí i, wọ́n á wà láàyè títí láé.