Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 6

Kí Ni Ìkún Omi Náà Kọ́ Wa?

Kí Ni Ìkún Omi Náà Kọ́ Wa?

Ọlọ́run pa àwọn èèyàn burúkú yẹn run, àmọ́ ó dá Nóà àti ìdílé rẹ̀ sí. Jẹ́nẹ́sísì 7:11, 12, 23

Ogójì (40) ọ̀sán àti ogójì òru ni òjò fi rọ̀, omi sì bo gbogbo ayé. Gbogbo àwọn èèyàn burúkú ló kú.

Àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ náà bọ́ ara èèyàn sílẹ̀, wọ́n sì di ẹ̀mí èṣù.

Àwọn tó wà nínú ọkọ̀ áàkì ò kú nígbà ìkún omi yẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Nóà àti ìdílé rẹ̀ kú nígbà tó yá, Ọlọ́run máa jí wọn dìde, wọ́n á sì wà láàyè títí láé.

Ọlọ́run ṣì tún máa pa àwọn ẹni burúkú run, á sì dá àwọn ẹni rere sí. Mátíù 24:​37-39

Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù kò tíì dáwọ́ dúró láti máa ṣi àwọn èèyàn lọ́nà.

Nígbà ayé Nóà, ọ̀pọ̀ èèyàn ò tẹ̀ lé ìtọ́ni tó fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn, ohun kan náà sì ni ọ̀pọ̀ ń ṣe lóde òní. Láìpẹ́, Jèhófà máa pa gbogbo àwọn èèyàn burúkú run.​—2 Pétérù 2:​5, 6.

Àwọn kan wà tó dà bíi Nóà. Wọ́n ń tẹ́tí sí Ọlọ́run, wọ́n sì ń ṣe ohun tó sọ; àwọn èèyàn náà ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.