Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 8

Kí Ni Ikú Jésù Mú Kó Ṣeé Ṣe fún Ọ?

Kí Ni Ikú Jésù Mú Kó Ṣeé Ṣe fún Ọ?

Jésù kú torí ká lè ní ìyè. Jòhánù 3:16

Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn tí Jésù kú, àwọn obìnrin kan lọ síbi ibojì rẹ̀, wọ́n sì rí i pé ibẹ̀ ṣófo. Jèhófà ti jí Jésù dìde.

Lẹ́yìn náà, Jésù fara han àwọn àpọ́sítélì rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà jí Jésù dìde, Jésù sì ti di ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára tí kò lè kú mọ́. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rí i bó ṣe ń lọ sí ọ̀run.

Ọlọ́run jí Jésù dìde, ó sì sọ ọ́ di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Dáníẹ́lì 7:13, 14

Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ kó lè fi san ìràpadà fún aráyé. (Mátíù 20:28) Ìràpadà yẹn ni Ọlọ́run lò láti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti wà láàyè títí láé.

Jèhófà fi Jésù jẹ Ọba tó máa ṣàkóso ayé. Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) olóòótọ́ èèyàn tí Ọlọ́run jí dìde láti ayé sí ọ̀run ló máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀. Jésù àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) yìí ló máa para pọ̀ di Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n á sì fi òdodo ṣàkóso láti ọ̀run.​—Ìfihàn 14:​1-3.

Ìjọba Ọlọ́run máa sọ ayé di Párádísè. Kò ní sí ogun, ìwà ọ̀daràn, ipò òṣì àti ebi mọ́. Inú àwọn èèyàn á máa dùn gan-an.​—Sáàmù 145:16.