Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Témi Àtàwọn Òbí Mi Fi Máa Ń Bára Wa Jiyàn?

Kí Nìdí Témi Àtàwọn Òbí Mi Fi Máa Ń Bára Wa Jiyàn?

ORÍ 2

Kí Nìdí Témi Àtàwọn Òbí Mi Fi Máa Ń Bára Wa Jiyàn?

Nínú ọ̀rọ̀ Rachel àti màmá rẹ̀ tá a fi bẹ̀rẹ̀ orí yìí, ọ̀nà mẹ́ta ni Rachel gbà dá kún ohun tó ṣẹlẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ọ̀nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta? Kọ ìdáhùn rẹ sí ìsàlẹ̀ yìí, kó o wá fi wé èyí tó wà nínú àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “ Ìdáhùn” lójú ìwé 20.

․․․․․

Ní alẹ́ ọjọ́ Wednesday kan, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Rachel parí àwọn iṣẹ́ ilé tó yẹ kó ṣe, ó wá fẹ́ sinmi. Ó tan tẹlifíṣọ̀n, ó sì jókòó sórí àga tó fẹ́ràn jù.

Bó ṣe ń jókòó báyìí ni màmá rẹ̀ wọlé, ó dúró lẹ́nu ọ̀nà, ó sì hàn lójú rẹ̀ pé inú rẹ̀ ò dùn. Ó wá sọ pé: “Rachel! Kí lò ń ṣe nídìí tẹlifíṣọ̀n nígbà tó yẹ kó o máa ran àbúrò ẹ lọ́wọ́ nídìí iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ̀? Kò sóhun téèyàn ní kó o ṣe tó o máa ń ṣe láyé tìẹ!”

Rachel wá ráhùn pé: “Wọ́n tún ti bẹ̀rẹ̀ nìyẹn!” Màmá rẹ̀ sì gbọ́ ohun tó sọ.

Màmá ẹ̀ wá tẹ orí síwájú díẹ̀, ó sì bi í pé: “Kí lo wí ná?”

Rachel mí kanlẹ̀, ó fi kọ̀rọ̀ ojú wo màmá ẹ̀, ó wá fèsì pé, “Mi ò sọ nǹkan kan.”

Inú bí màmá ẹ̀ gan-an. Màmá ẹ̀ wá sọ pé: “Ṣémi lò ń bá sọ ìyẹn?”

Rachel wá dá wọn lóhùn pé: “Ṣé bí ẹ̀yin náà ṣe sọ̀rọ̀ sí mi yẹn dáa?”

Bí wàhálà tún ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, tí Rachel ò fi lè sinmi mọ́.

ǸJẸ́ irú ohun tá a sọ yìí máa ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ? Ṣé ìwọ àtàwọn òbí rẹ sábà máa ń bára yín jiyàn? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ronú nípa ohun tó máa ń fà á. Kí làwọn ohun tó sábà máa ń fa awuyewuye láàárín yín? Fi àmì ✔ sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn nǹkan tó sábà máa ń fà á tàbí kó o kọ àwọn nǹkan míì tó o rò pé ó ń fà á síwájú “Nǹkan míì.”

□ Ìwà rẹ

□ Iṣẹ́ ilé

□ Aṣọ wíwọ̀

□ Àkókò tí wọ́n fẹ́ kó o máa wọlé

□ Eré Ìnàjú

□ Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ

□ Ọ̀rọ̀ ọkùnrin àti obìnrin

□ Nǹkan míì ․․․․․

Ohun yòówù kó máa fa ìjiyàn láàárín ìwọ àtàwọn òbí rẹ, ó dájú pé inú ẹ̀yin méjèèjì kò ní dùn pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń wáyé. Lóòótọ́, o lè panu mọ́ o, kó o kàn máa ṣe bíi pé o gba gbogbo ohun tí wọ́n bá ń sọ. Àmọ́, ṣé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó o ṣe nìyẹn? Rárá o. Òótọ́ ni pé Bíbélì sọ pé kó o “bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.” (Éfésù 6:2, 3) Àmọ́, ó tún gbà ẹ́ níyànjú pé kó o di ẹni tó ní “agbára láti ronú” kó o sì máa lo “agbára ìmọnúúrò” rẹ. (Òwe 1:1-4; Róòmù 12:1) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá máa ní ìdí pàtàkì tó o fi ń ṣe àwọn nǹkan rẹ, ìyẹn sì lè yàtọ̀ sí tàwọn òbí rẹ nígbà míì. Àmọ́, nínú ìdílé tí wọ́n ti ń tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì, àwọn òbí àtàwọn ọmọ máa ń lè bára wọn sọ̀rọ̀ láìsí awuyewuye, kódà bí èrò wọn kò bá tiẹ̀ dọ́gba lórí ọ̀rọ̀ kan.—Kólósè 3:13.

Báwo lo ṣe lè máa sọ èrò ọkàn rẹ jáde láìjẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà di ariwo? O lè yára sọ pé: “Àwọn òbí mi ló níṣòro jàre. Àwọn gan-an ni kì í jẹ́ n sinmi!” Àmọ́, rò ó wò ná: Ṣé o rò pé wàá lè yí ìwà ẹlòmíì pa dà, títí kan àwọn òbí rẹ? Ó dájú pé, ara rẹ nìkan lo lè yí pa dà. Ibi tí ọ̀rọ̀ yìí wá dáa sí ni pé, tó o bá ń ní sùúrù fún àwọn òbí rẹ, àwọn náà á lè máa fara balẹ̀ gbọ́ tìẹ, tó o bá lóhun tó o fẹ́ sọ fún wọn.

Jẹ́ ká wá wo ohun tí ìwọ gan-an lè ṣe tí ẹ ò fi ní máa bá ara yín fa ọ̀rọ̀. Tó o bá ṣe àwọn ohun tá a fẹ́ dábàá yìí, ó lè ya ìwọ àtàwọn òbí rẹ lẹ́nu bó o ṣe máa mọ béèyàn ṣe ń bá àwọn ẹlòmíì sọ̀rọ̀ dáadáa tó.

Máa ronú kó o tó fèsì. Táwọn òbí rẹ bá sọ̀rọ̀ tó bí ẹ nínú, má kàn sọ ohun tó bá kọ́kọ́ wá sí ẹ lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, bí mọ́mì ẹ bá sọ pé: “Kí ló dé tí o kò fọ abọ́? Kò síṣẹ́ téèyàn fún ẹ tó o máa ń ṣe láyé tìẹ!” Èsì tó ṣeé ṣe kó kọ́kọ́ wá sí ẹ lọ́kàn ni: “Ẹ tún ti dé nìyẹn o!” Àmọ́, ńṣe ni kó o kọ́kọ́ ronú. Gbìyànjú láti ro ohun tó mú kí mọ́mì ẹ sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, tí wọ́n bá lo ọ̀rọ̀ bíi “gbogbo ìgbà” tàbí “láyé tìẹ,” kì í ṣe ohun tí wọ́n ní lọ́kàn gan-an nìyẹn. Ṣe ló kàn fi hàn pé nǹkan kan ń dùn wọ́n lọ́kàn. Kí ló lè máa dùn wọ́n lọ́kàn?

Ó lè máa dun mọ́mì ẹ pé iṣẹ́ ilé tó o fi sílẹ̀ fún òun ti pọ̀ jù. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n kàn fẹ́ kó o fi dá àwọn lójú pé wàá máa ran àwọn lọ́wọ́. Èyí ó wù kó jẹ́, tó o bá sọ pé, “Ẹ tún ti dé nìyẹn o!” kò ní yanjú ìṣòro náà, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa dojú ọ̀rọ̀ rú! Torí náà, ńṣe ni kó o fi mọ́mì ẹ lọ́kàn balẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé: “Mọ́mì, ẹ má bínú. Màá lọ fọ abọ́ yẹn báyìí.” Àmọ́ ṣá o: Má ṣe sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa bí mọ́mì ẹ nínú. Ṣe ni kó o sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Ìyẹn lè mú kí ọkàn wọn rọ̀, kí wọ́n wá sọ ohun tó ń dùn wọ́n lọ́kàn. *

Kọ ohun tó o rò pé dádì tàbí mọ́mì rẹ lè sọ tó lè bí ẹ nínú, tí o kò bá mú ọ̀rọ̀ náà mọ́ra.

․․․․․

Wá ronú nípa bó o ṣe lè rọra fèsì lọ́nà tó máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀.

․․․․․

Máa sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Michelle ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i, pé ó yẹ kí òun máa ṣọ́ bí òun ṣe ń bá mọ́mì òun sọ̀rọ̀. Ó ní: “Gbogbo ìgbà témi àti Mọ́mì bá ti jọ ń sọ̀rọ̀ ni wọ́n máa ń sọ pé ohùn mi ti le jù.” Tó bá jẹ́ pé ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà nìyẹn, kọ́ béèyàn ṣe ń rọra sọ̀rọ̀ láìsọ ọ́ di ariwo, má ṣe fi kọ̀rọ̀ ojú wò wọ́n tàbí kó o ṣe àwọn nǹkan míì láti fi hàn pé inú ń bí ẹ. (Òwe 30:17) Bó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé kó o fara ya, gbàdúrà ìdákẹ́jẹ́ẹ́ sí Ọlọ́run, nínú ọkàn rẹ. (Nehemáyà 2:4) Kì í ṣe láti bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ káwọn òbí ẹ fi ẹ́ lọ́rùn sílẹ̀ o, àmọ́ pé kí Ọlọ́run jẹ́ kó o lè kó ara rẹ níjàánu, kó o má bàa dá kún ìṣòro náà.—Jákọ́bù 1:26.

Kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó o mọ̀ pé o máa ń sọ tí kò sì yẹ kó o máa sọ àtàwọn ohun tó o máa ń ṣe tí kò yẹ kó o máa ṣe, sí ìsàlẹ̀ yìí.

Àwọn ọ̀rọ̀ tó o máa ń sọ:

․․․․․

Àwọn ohun tó o máa ń ṣe:

․․․․․

Máa fetí sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ninu ọ̀rọ̀ pupọ, a kò lè fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù.” (Owe 10:19, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Tí dádì tàbí mọ́mì ẹ bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀, máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn. Má máa já lu ọ̀rọ̀ wọn torí pé o fẹ́ ṣàlàyé ara rẹ. Ṣáà fetí sílẹ̀. Tí wọ́n bá ti wá sọ̀rọ̀ tán, wàá ráyè dáadáa láti béèrè ọ̀rọ̀ tó o bá fẹ́ tàbí láti ṣàlàyé ara ẹ. Àmọ́, tó o bá yarí, tó o ní àfi kí ìwọ náà máa sọ tìẹ, ńṣe ni gbogbo ẹ̀ máa dojú rú. Bó o bá tiẹ̀ ṣì ní ọ̀rọ̀ tó o fẹ́ sọ, ó máa dáa kó o mọ̀ pé “ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́” nìyí.—Oníwàásù 3:7.

Máa múra tán láti tọrọ àforíjì. Ó yẹ kó o lè máa sọ pé, “Ẹ má bínú” nígbàkigbà tó o bá ṣe ohun tó dá kún awuyewuye. (Róòmù 14:19) O tiẹ̀ lè bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe bínú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn wáyé. Tó bá ṣòro fún ẹ láti lọ bá wọn kó o tọrọ àforíjì, o lè kọ ọ́ síwèé kan kó o fún wọn. Kó o sì wá ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti jáwọ́ nínú ìwà yòówù kó fa awuyewuye náà. (Mátíù 5:41) Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ ilé tó o pa tì ló fa wàhálà yẹn, o lè ṣe ohun tó máa ya àwọn òbí rẹ lẹ́nu, kó o ṣe iṣẹ́ náà. Bí iṣẹ́ yẹn ò bá tiẹ̀ wù ẹ́ ṣe, ǹjẹ́ kò ní dáa kó o ṣe é dípò tíyẹn á fi dá wàhálà sílẹ̀ nígbà táwọn òbí rẹ bá rí i pé o ò ṣe é? (Mátíù 21:28-31) Ronú nípa àǹfààní tó o máa rí tó o bá ṣe ipa tìrẹ láti dín wàhálà àárín ìwọ àtàwọn òbí rẹ kù.

Àwọn ìdílé tó wà níṣọ̀kan pàápàá máa ń ní ìṣòro, àmọ́ wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè yanjú ìṣòro wọn láìsí ariwo. Tó o bá ṣe àwọn ohun tá a sọ nínú orí yìí, wàá rí i pé o lè bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ láìsí pé ẹ̀ ń bá ara yín jiyàn, títí kan àwọn ọ̀rọ̀ tó lè má rọrùn láti jọ sọ pàápàá!

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ṣé o ronú pé ó yẹ kí àwọn òbí rẹ fún ẹ ní òmìnira sí i? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Ọmọlúwàbí máa ń ronú kó tó fèsì ọ̀rọ̀.”—Òwe 15:28, Bíbélì Today’s English Version.

ÌMỌ̀RÀN

Tí àwọn òbí rẹ bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀, pa orin tó ò ń gbọ́, pa ìwé tó ò ń kà tì, kó o sì fara balẹ̀ gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kí ọ̀rọ̀ má di awuyewuye tàbí kó o máa rí i pé ẹ yanjú èyí tó bá wáyé, ìyẹn máa jẹ́ kí nǹkan rọ ìwọ fúnra rẹ lọ́rùn. Bíbélì pàápàá sọ pé èèyàn tó “ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ń bá ọkàn ara rẹ̀ lò lọ́nà tí ń mú èrè wá.”—Òwe 11:17.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Àbá tó yẹ kí n ṣiṣẹ́ lé lórí jù nínú orí yìí ni ․․․․․

Ọjọ́ tí màá rí i pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tí àbá yìí sọ ni (kọ ọjọ́ náà) ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tí àwọn ọ̀dọ́ kan fi gbà pé ó dáa kéèyàn mọ bí wọ́n ṣe ń jiyàn?

● Kí nìdí tí Jèhófà Ọlọ́run fi ka ẹni tó bá fẹ́ràn láti máa jiyàn sí òmùgọ̀?—Òwe 20:3.

● Àǹfààní wo ni ìwọ fúnra rẹ máa rí tó o bá jẹ́ kí wàhálà dín kù láàárín ìwọ àtàwọn òbí rẹ?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 18]

“Nígbà míì, mọ́mì mi máa ń sọ pé ‘Má bínú,’ wọ́n á fọwọ́ pa mí lára, ìyẹn sì dáa. Ọ̀rọ̀ á sì parí síbẹ̀. Èmi náà máa ń bẹ̀ wọ́n. Òótọ́ ni pé kò rọrùn o, àmọ́ bí mo ṣe máa ń rẹ ara mi sílẹ̀, tí mò ń fi tinútinú sọ pé ‘Ẹ má bínú,’ máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tètè yanjú.”—Lauren

 [Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]

Ìdáhùn

1. Ọ̀rọ̀ ìráhùn tó sọ (ìyẹn “Wọ́n tún ti bẹ̀rẹ̀ nìyẹn”) mú kí inú túbọ̀ bí màmá rẹ̀.

2. Bí Rachel ṣe ṣojú (tó fi kọ̀rọ̀ ojú wo màmá ẹ̀), ṣe ló tọ́ wọn níjà.

3. Ọ̀rọ̀ àrífín tó fi fèsì (“Ṣé bí ẹ̀yin náà ṣe sọ̀rọ̀ sí mi yẹn dáa?”) sábà máa ń dá wàhálà sílẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Tó o bá ń bá àwọn òbí rẹ jiyàn, ńṣe ló dà bí ìgbà tó ò ń sáré lójú kan náà, o lè lo gbogbo agbára rẹ, síbẹ̀ o ò ní kúrò lójú kan náà