Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Màá Fi Ní Òmìnira Sí I?

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Màá Fi Ní Òmìnira Sí I?

ORÍ 3

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Màá Fi Ní Òmìnira Sí I?

“Ó wù mí kí àwọn òbí mi tiẹ̀ jẹ́ kí n máa dá jáde lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.”—Sarah, ọmọ ọdún méjìdínlógún [18].

“Gbogbo ìgbà ni mo máa ń bi àwọn òbí mi pé kí ló dé tí wọn kì í fọkàn tán mi tí n bá sọ pé mo fẹ́ bá àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣeré jáde. Wọ́n sábà máa ń dá mi lóhùn pé: ‘A fọkàn tán ẹ, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ tẹ́ ẹ jọ ń lọ ló ń kọ wá lóminú.’”—Christine, ọmọ ọdún méjìdínlógún [18].

ṢÉ Ó ń wu ìwọ náà kó o túbọ̀ ní òmìnira, bó ṣe ń wu Sarah àti Christine tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí? Kó o tó lè ní òmìnira yẹn, ṣe ni wàá kọ́kọ́ ṣe ohun tó máa jẹ́ kí àwọn òbí rẹ lè fọkàn tán ẹ. A lè fi fífọkàn tánni wé owó. Kéèyàn tó rí owó, èèyàn ní láti ṣiṣẹ́ kára, àmọ́ ó lè tètè tán tàbí kó sọ nù, bẹ́ẹ̀ sì rèé owó kì í tó olówó. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kan tó ń jẹ́ Iliana sọ pé: “Gbogbo ìgbà tí mo bá fẹ́ jáde làwọn òbí mi máa ń da ìbéèrè bò mí, wọ́n á máa béèrè ibi tí mò ń lọ, àwọn tá a jọ ń lọ, ohun tí mo fẹ́ ṣe lọ́hùn-ún àti ìgbà tí mo máa pa dà dé. Mo mọ̀ pé òbí mi ni wọ́n o, àmọ́ inú máa ń bí mi tí wọ́n bá ń da àwọn ìbéèrè yẹn bò mí!”

Kí lo lè ṣe táwọn òbí rẹ á fi lè túbọ̀ fọkàn tán ẹ kí wọ́n sì fún ẹ lómìnira sí i? Ká tó dáhùn ìbéèrè yẹn, jẹ́ ká wo ìdí tí fífọkàn tánni fi jẹ́ nǹkan ẹlẹgẹ́ láàárín ọ̀pọ̀ òbí àtàwọn ọ̀dọ́.

Wàhálà Àárín Àwọn Ọ̀dọ́ Àtàwọn Òbí

Bíbélì sọ pé “ọkùnrin yóò . . . fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Èyí ò sì yọ àwọn obìnrin náà sílẹ̀. Yálà ọkùnrin ni ẹ́ tàbí obìnrin, bó o bá ti ń bàlágà, àgbà ń kàn ẹ́ bọ̀ nìyẹn, torí náà ó yẹ kó o máa kọ́ ìwà àgbà, èyí tó máa wúlò fún ẹ nígbà tó o bá dẹni tó ń dá gbé tó o sì ní ìdílé tìẹ. *

Àmọ́ ṣá o, èèyàn kì í ṣàdédé kúrò ní ọ̀dọ́ kó sì bára rẹ̀ nípò àgbà bí ìgbà téèyàn kàn gba ẹnu ọ̀nà kan kọjá sí òdìkejì. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, bí ẹní ń gun àtẹ̀gùn ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé, lèèyàn máa ń dépò àgbà. Òótọ́ ni pé èrò tìẹ àti tàwọn òbí rẹ lè ta kora lórí ibi tó o ti dàgbà dé. Maria, tó gbà pé àwọn òbí òun ò fọkàn tán òun tó bá dọ̀rọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ tóun ń bá rìn, sọ pé: “Ọmọ ogún [20] ọdún ni mí, síbẹ̀, ọ̀rọ̀ yìí ò tíì yéé dá ìjà sílẹ̀! Àwọn òbí mi rò pé mi ò tíì gbọ́n débi tí màá fi lè kúrò níbi tí kò yẹ kí n wà. Mo ti gbìyànjú láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé mi ò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa kúrò láwọn ibi tí kò yẹ kí n wà, àmọ́ ìyẹn ò tẹ́ wọn lọ́rùn!”

Ohun tí Maria sọ fi hàn pé ọ̀rọ̀ fífọkàn tánni máa ń fa wàhálà láàárín àwọn òbí àti àwọn ọ̀dọ́. Ṣé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín ìwọ àtàwọn òbí rẹ? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe táwọn òbí rẹ á fi túbọ̀ fọkàn tán ẹ dáadáa? Tó bá sì jẹ́ pé wọn ò fọkàn tán ẹ mọ́ torí àwọn ìwà kan tí kò bójú mu tó o hù, kí lo lè ṣe tí wọ́n á fi tún máa fọkàn tán ẹ?

Fi Hàn Pé O Ṣeé Fọkàn Tán

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ pé: “Ẹ máa wádìí ohun tí ẹ̀yin fúnra yín jẹ́.” (2 Kọ́ríńtì 13:5) Òótọ́ ni pé kì í ṣe àwọn ọ̀dọ́ ló dìídì kọ ọ̀rọ̀ yìí sí, síbẹ̀ ìlànà tó wà níbẹ̀ kan ohun tá à ń sọ yìí. Bó o bá ṣe fi hàn pé o yẹ lẹ́ni tó ṣeé fọkàn tán tó, làwọn òbí rẹ ṣe máa fún ẹ ní òmìnira tó. Kì í ṣe pé o ò ní máa ṣàṣìṣe o, torí pé kò sẹ́ni tí kì í ṣàṣìṣe. (Oníwàásù 7:20) Ṣùgbọ́n, ṣé àwọn ìwà tó ò ń hù lè jẹ́ káwọn òbí rẹ fọkàn tán ẹ?

Bí àpẹẹrẹ, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “A [ń] dàníyàn láti máa hùwà láìṣàbòsí nínú ohun gbogbo.” (Hébérù 13:18) Bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mo máa ń sòótọ́ fáwọn òbí mi nípa ibi tí mò ń lọ, ibi tí mo wà àtàwọn ohun tí mò ń ṣe?’ Wo ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n ti rí àwọn ibi tó yẹ káwọn ti ṣàtúnṣe lórí kókó yìí. Tó o bá ti ka ohun tí wọ́n sọ, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tá a kọ tẹ̀ lé e.

Lori: “Mo máa ń kọ lẹ́tà sí ọmọkùnrin kan tí mo fẹ́ràn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láìjẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀. Àṣírí tú sáwọn òbí mi lọ́wọ́, wọ́n sì sọ pé kí n jáwọ́ ńbẹ̀. Mo ṣèlérí pé mi ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, àmọ́ mi ò jáwọ́. Odindi ọdún kan ni mo fi ń kọ lẹ́tà sí ọmọkùnrin yìí. Tí n bá ti kọ ọ́, àṣírí á tú sí àwọn òbí mi lọ́wọ́. Màá tún ṣèlérí fún wọn pé màá jáwọ́ ńbẹ̀, àmọ́ mi ò jáwọ́. Nígbà tó yá, àwọn òbí mi ò tiẹ̀ wá fọkàn tán mi lórí ohunkóhun mọ́!”

Kí lo rò pé ó fà á táwọn òbí Lori ò fi fọkàn tán an mọ́? ․․․․․

Ká ní ìwọ ni òbí Lori, kí lo máa ṣe, kí sì nìdí tí wàá fi ṣe bẹ́ẹ̀? ․․․․․

Kí ni Lori ì bá ti ṣe nígbà táwọn òbí rẹ̀ kọ́kọ́ bá a sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro yìí láti fi hàn pé ó ṣeé fọkàn tán? ․․․․․

Beverly: “Àwọn òbí mi ò fọkàn tán mi tó bá dọ̀rọ̀ ọkùnrin, àmọ́ mo ti wá mọ ohun tó fà á. Nígbà yẹn, èmi àtàwọn ọmọkùnrin kan tí wọ́n fi ọdún méjì jù mí lọ jọ máa ń tage. Mo tún máa ń fi ọ̀pọ̀ wákàtí bá àwọn ọmọkùnrin yìí sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù, tá a bá sì wà níbi àpèjẹ, àwọn nìkan ni mo sábà máa ń bá sọ̀rọ̀. Àwọn òbí mi wá gba fóònù mi fún odindi oṣù kan, wọn ò sì jẹ́ kí n lọ sáwọn ibi témi àtàwọn ọmọkùnrin yẹn ti lè pàdé.”

Ká ní ìwọ ni òbí Beverly, kí lo máa ṣe, kí sì nìdí tí wàá fi ṣe bẹ́ẹ̀? ․․․․․

Ǹjẹ́ o rò pé ohun tí àwọn òbí Beverly ṣe yìí ti le jù? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀? ․․․․․

Kí ni Beverly ì bá wá ṣe kí wọ́n tún lè fọkàn tán an? ․․․․․

Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Kí Wọ́n Pa Dà Fọkàn Tán Ẹ

Bó bá jẹ́ pé ìwà ẹ ló fà á táwọn òbí ẹ kò fi fọkàn tán ẹ mọ́ bíi tàwọn ọ̀dọ́ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ wọn yìí ńkọ́? Fọkàn balẹ̀, ìyẹn pàápàá ò tíì kọjá àtúnṣe. Àmọ́, kí lo lè ṣe?

Ó ṣeé ṣe káwọn òbí rẹ túbọ̀ fọkàn tán ẹ kí wọ́n sì túbọ̀ fún ẹ ní òmìnira tó o bá yíwà pa dà tó o sì ń hùwà tó dáa. Ohun tí ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Annette wá mọ̀ nígbà tó yá nìyẹn. Ó sọ pé: “Téèyàn bá ṣì wà ní kékeré, èèyàn kì í mọyì kí wọ́n fọkàn tán òun. Àmọ́ ní báyìí tí mo ti ń dàgbà, mo máa ń rí i pé mi ò ṣe ohun tí ò ní jẹ́ káwọn òbí mi fọkàn tán mi.” Ẹ̀kọ́ wo lo lè kọ́ nínú èyí? Dípò tí wàá fi máa ṣàròyé pé àwọn òbí ẹ kò fọkàn tán ẹ, o ò ṣe kúkú sa gbogbo ipá rẹ láti máa hùwà tó máa jẹ́ kí wọ́n lè fọkàn tán ẹ. Ìyẹn lè jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ fún ẹ lómìnira.

Bí àpẹẹrẹ, ṣé àwọn òbí ẹ lè fọkàn tán ẹ lórí àwọn nǹkan tá a tò sísàlẹ̀ yìí? Fi àmì ✔ sí àpótí tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tó bá yẹ kó o ṣàtúnṣe lé lórí.

□ Dídé sílé lákòókò tí wọ́n fẹ́ kí n máa wọlé

□ Mímú àwọn ìlérí mi ṣẹ

□ Ṣíṣe nǹkan lákòókò tó yẹ

□ Ṣíṣọ́wó ná

□ Píparí àwọn iṣẹ́ ilé

□ Jíjí lásìkò

□ Mímú kí yàrá mi wà ní mímọ́ tónítóní

□ Sísọ òótọ́

□ Lílo tẹlifóònù tàbí kọ̀ǹpútà láì ti àṣejù bọ̀ ọ́

□ Gbígba àṣìṣe mi àti títọrọ àforíjì

□ Nǹkan míì ․․․․․

O ò ṣe pinnu pé wàá fi hàn pé o ṣeé fọkàn tán nínú àwọn nǹkan tó o fàmì sí yìí? Fetí sí ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀, èyí tí ó bá ipa ọ̀nà ìwà [rẹ] àtijọ́ ṣe déédéé.” (Éfésù 4:22) Jẹ́ “kí Bẹ́ẹ̀ ni [rẹ] túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni.” (Jákọ́bù 5:12) “Kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.” (Éfésù 4:25) “Jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí [rẹ] nínú ohun gbogbo.” (Kólósè 3:20) Láìpẹ́, wàá rí i pé ìlọsíwájú rẹ máa hàn kedere sáwọn èèyàn, títí kan àwọn òbí rẹ.—1 Tímótì 4:15.

Àmọ́ tó bá ṣì ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn òbí rẹ kò tíì fún ẹ ní òmìnira tó ńkọ́, láìka pé ò ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe? O ò ṣe kúkú bá wọn sọ ọ́? Fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ béèrè ohun tí wọ́n rò pé ó yẹ kí ìwọ ṣe tí wọ́n á fi lè fọkàn tán ẹ dípò kó o máa ṣàròyé pé àwọn ló yẹ kí wọ́n túbọ̀ fọkàn tán ẹ. Kó o ṣàlàyé ohun tó o ní lọ́kàn fún wọn dáadáa.

Má ṣe retí pé àwọn òbí rẹ á yí ọ̀rọ̀ wọn pa dà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ o. Torí wọ́n lè kọ́kọ́ fẹ́ rí i dájú pé wàá mú àwọn ìlérí rẹ ṣẹ. Lo àǹfààní yìí láti jẹ́ kí wọ́n rí i pé o ṣeé fọkàn tán lóòótọ́. Àwọn òbí ẹ lè túbọ̀ fọkàn tán ẹ tó bá yá kí wọ́n sì wá fún ẹ lómìnira sí i. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Beverly tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan nìyẹn. Ó sọ pé: “Nǹkan kékeré kọ́ lèèyàn máa ṣe kí wọ́n tó lè fọkàn tán an, ohun kékeré báyìí sì lè sọni di ẹni tí wọn ò fọkàn tán mọ́. Wọ́n ti ń fọkàn tán mi báyìí, inú mi sì ń dùn gan-an!”

KÀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 22, NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ṣé àwọn òbí rẹ kọra wọn sílẹ̀ ni? Kí làwọn nǹkan tó o lè ṣe tí o kò fi ní dààmú jù lásìkò tó dà bíi pé gbogbo nǹkan dojú rú fún ẹ yìí?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 8 Wo Orí 7 nínú ìwé yìí fún àlàyé síwájú sí i.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Ẹ má ṣe dọ́gbọ́n lo òmìnira yín láti hùwà búburú.”—1 Pétérù 2:16, Bíbélì Contemporary English Version.

ÌMỌ̀RÀN

Dípò tí wàá fi máa ronú nípa àwọn ohun tí ẹ̀gbọ́n rẹ ní òmìnira láti ṣe ṣùgbọ́n táwọn òbí yín kò gba ìwọ láyè láti ṣe, máa wo bí òmìnira tó o ní báyìí ṣe pọ̀ ju ti ìgbà tó o ṣì kéré lọ.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Táwọn òbí bá fún ọmọ lómìnira púpọ̀ jù, kì í ṣe pé wọ́n fẹ́ràn rẹ̀, ṣe ni wọn ò bójú tó o bó ṣe yẹ.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Màá ṣe ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ fọkàn tán mi lórí ọ̀rọ̀: ․․․․․

Tí mo bá ṣe ohun tí kò jẹ́ káwọn òbí mi fọkàn tán mi mọ́, màá ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí ló lè fà á tí àwọn òbí rẹ kò fi ní fẹ́ fún ẹ lómìnira sí i, kódà lẹ́yìn tó o ti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti fi hàn pé o ṣeé fọkàn tán?

● Bó o bá ń ṣàlàyé ara rẹ dáadáa fún àwọn òbí rẹ, báwo nìyẹn ṣe lè jẹ́ kí wọ́n fẹ́ láti fún ẹ lómìnira sí i?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]

“Témi àtàwọn òbí mi bá jọ ń sọ̀rọ̀, mi kì í fi nǹkan kan pa mọ́ nípa ìṣòro mi àtàwọn ohun tó bá ń jẹ mí lọ́kàn. Mo rò pé ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ fọkàn tán mi.”​—Dianna

[Ihe Osise/​Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, bí ẹní ń gun àtẹ̀gùn ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé, lèèyàn máa ń di àgbà tó ṣeé fọkàn tán

[Ihe Osise]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

IPÒ ÀGBÀ

ÌGBÀ Ọ̀DỌ́

ÌGBÀ ỌMỌDÉ