Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Lọ̀rọ̀ Èmi àti Tẹ̀gbọ́n-Tàbúrò Mi Ṣe Lè Wọ̀ Dáadáa?

Báwo Lọ̀rọ̀ Èmi àti Tẹ̀gbọ́n-Tàbúrò Mi Ṣe Lè Wọ̀ Dáadáa?

ORÍ 6

Báwo Lọ̀rọ̀ Èmi àti Tẹ̀gbọ́n-Tàbúrò Mi Ṣe Lè Wọ̀ Dáadáa?

Báwo ni àjọṣe rẹ pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ ṣe rí? Fi àmì ✔ sí ẹ̀gbẹ́ èyí tó bá jẹ́.

□ Ọ̀rọ̀ wa wọ̀ dáadáa

□ Kì í sábà sí wàhálà láàárín wa

□ A máa ń fara dà á fún ara wa

□ Ìjà ni ṣáá ní gbogbo ìgbà

ÀWỌN tẹ̀gbọ́n-tàbúrò kan wà tí wọ́n jẹ́ kòríkòsùn. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ Felicia, sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn tí mo kà sí ọ̀rẹ́ mi àtàtà ni Irena, ìyẹn àbúrò mi ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16].” Bákan náà, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Carly sọ nípa Eric, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ogún [20] ọdún, pé: “Ọ̀rọ̀ wa wọ̀ gan-an ni. A kì í bára wa jà.”

Àmọ́, ńṣe lọ̀rọ̀ àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò míì dà bíi ti Lauren àti Marla. Lauren sọ pé: “Kò sí nǹkan tí a kì í jà lé lórí, títí kan àwọn ohun tí kò tó nǹkan.” Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ sì lè jọ ohun tí Alice, ọmọ ọdún méjìlá [12] sọ nípa Dennis, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14]. Ó sọ pé: “Ó máa ń múnú bí mi! Ṣe ló kàn máa ń já wọnú yàrá mi, tó sì máa ń mú ohun tó bá wù ú láìsọ fún mi, á wá lóun yá a. Á kàn ṣáà máa ṣe bí ẹni tí kò gbọ́n!”

Ǹjẹ́ o ní ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò tó ń ṣe nǹkan tó máa ń bí ẹ nínú? Òótọ́ ni pé, ojúṣe àwọn òbí yín ni láti máa rí i pé gbogbo yín wà ní ìrẹ́pọ̀ nínú ilé. Àmọ́, bópẹ́ bóyá, o máa ní láti kọ́ béèyàn ṣe ń bá ẹlòmíì gbé ní ìrẹ́pọ̀. O lè bẹ̀rẹ̀ sí í fi kọ́ra ní báyìí tó o ṣì wà nílé.

Ronú nípa àwọn nǹkan tó ti fa ariwo láàárín ìwọ pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ. Kí ló sábà máa ń fa ìjà yín? Wo àwọn ohun tá a kọ sí ìsàlẹ̀ yìí, kó o sì fi àmì ✔ sí ẹ̀gbẹ́ èyí tó máa ń bí ẹ nínú.

Àwọn nǹkan mi. Ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò mi máa ń mú àwọn nǹkan mi láìsọ fún mi, á wá lóun yá a.

Ìwà wa kò dọ́gba. Ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò mi ò mọ̀ ju tara rẹ̀ lọ, tàbí pé kì í ronú kó tó ṣe nǹkan, tàbí pé ó máa ń fẹ́ sọ gbogbo ohun tí màá ṣe fún mi.

Ibi àdáni mi. Ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò mi máa ń já wọ yàrá mi láì kan ilẹ̀kùn, ó máa ń ka àwọn lẹ́tà tí mo ní lórí kọ̀ǹpútà tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sórí fóònù mi láì sọ fún mi.

Nǹkan míì ․․․․․

Bí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ bá ń múnú bí ẹ, tó máa ń fẹ́ ṣe bí ọ̀gá lé ẹ lórí tàbí tó kàn máa ń já wọ ibi àdáni rẹ, ó lè ṣòro fún ẹ láti mú un mọ́ra. Àmọ́ òwe kan nínú Bíbélì sọ pé: “Fífún imú pọ̀ sì ni ohun tí ń mú ẹ̀jẹ̀ jáde, fífún ìbínú jáde sì ni ohun tí ń mú aáwọ̀ jáde.” (Òwe 30:33) Tó o bá mú ẹnì kan sínú, èyí lè mú kó o fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí onítọ̀hún, bí fífún imú pọ̀ ṣe máa ń mú kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn jáde ní imú. Ṣe ni ìyẹn sì máa dá kún ìṣòro náà. (Òwe 26:21) Kí lo lè ṣe tí ohun tó ń bí ẹ nínú kò fi ní fa awuyewuye? Ohun àkọ́kọ́ tó o ní láti ṣe ni pé kó o mọ ohun náà gan-an tó jẹ́ ìṣòro.

Ṣé Ohun Tó Kàn Ṣẹlẹ̀ Ni àbí Ó Jẹ́ Ìṣòro?

Awuyewuye tó máa ń wà láàárín tẹ̀gbọ́n-tàbúrò dà bíi rorẹ́ tó máa ń sú síni lára. Tí rorẹ́ bá sú síni lára, ṣe ló fi hàn pé kòkòrò wà nínú ara. Bákan náà, bí ìjà bá wáyé láàárín tẹ̀gbọ́n-tàbúrò, ohun tó kàn fara hàn sóde la rí yẹn, èyí tó ń fi hàn pé ìṣòro kan wà lábẹ́lẹ̀.

Èèyàn lè fọwọ́ tẹ rorẹ́ náà láti mú un kúrò. Àmọ́, tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lo kàn mú èyí tó o rí pé ó sú sí ẹ lára kúrò, èyí sì lè dá àpá sí ẹ lára tàbí kó mú kí rorẹ́ náà pọ̀ sí i. Ohun tó dáa jù ni pé kó o lo oògùn kòkòrò tó fà á, kó má bàa tàn kálẹ̀. Bí ọ̀ràn awuyewuye tó máa ń wáyé láàárín tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ṣe rí nìyẹn. Gbìyànjú láti mọ ìṣòro tó ń fà á, ìyẹn á jẹ́ kó o lè yanjú ìṣòro náà dípò tí wàá kàn fi máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn. Wàá tún lè fi ìmọ̀ràn Sólómọ́nì, ọlọ́gbọ́n ọba sílò, èyí tó sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú.”—Òwe 19:11.

Bí àpẹẹrẹ, Alice, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan, sọ nípa Dennis ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pé: “Ṣe ló kàn máa ń já wọnú yàrá mi, tó sì máa ń mú ohun tó bá wù ú láìsọ fún mi, á wá lóun yá a.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Àmọ́, kí lo rò pé ó fà á, ìyẹn ohun tó jẹ́ ìṣòro wọn? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni wọn ò bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Láti yanjú ọ̀rọ̀ yìí, Alice lè sọ fún Dennis pé kò gbọ́dọ̀ wọ yàrá òun mọ́, kò sì gbọ́dọ̀ lo nǹkan òun mọ́. Àmọ́, ṣe ni èyí á kàn yanjú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn nìkan, ó sì ṣeé ṣe kó dá wàhálà míì sílẹ̀. Ó dájú pé ọ̀rọ̀ Dennis àti Alice á túbọ̀ wọ̀ bí Alice bá lè jẹ́ kí Dennis mọ̀ pé ó yẹ kó fi ọ̀wọ̀ òun wọ òun, kó má kàn máa já wọnú yàrá òun, kó má sì máa mú àwọn nǹkan òun láì sọ fún òun.

Kọ́ Bó O Ṣe Lè Yanjú Ìṣòro Tàbí Kó O Má Ṣe Jẹ́ Kó Wáyé

Tó o bá mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro láàárín ìwọ àti ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ, apá kan lára ọ̀rọ̀ náà lo ṣì yanjú yẹn. Báwo lo ṣe lè máa yanjú ohun tó jẹ́ ìṣòro, kí ọ̀rọ̀ náà má bàa di awuyewuye? Gbìyànjú láti ṣe nǹkan mẹ́fà yìí.

1. Ẹ jọ fohùn ṣọ̀kan lórí àwọn ìlànà kan. Pa dà lọ wo ohun tó o fi àmì sí pé ó ń fa ìṣòro láàárín ìwọ àti ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ. Wò ó bóyá ẹ lè rí àwọn ìlànà kan tẹ́ ẹ jọ máa gbà láti tẹ̀ lé, tó sì máa yanjú ìṣòro náà. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé lílo nǹkan ara yín ló máa ń dá wàhálà sílẹ̀, Ìlànà Kìíní lè jẹ́: “Tó o bá fẹ́ mú ohunkóhun tó jẹ́ ti ẹlòmíì, kọ́kọ́ máa béèrè lọ́wọ́ ẹni tó ni ín.” Ìlànà Kejì lè jẹ́: “Bí oní nǹkan bá sọ pé, ‘O ò gbọ́dọ̀ mú nǹkan òun,’ má ṣe mú un.” Tẹ́ ẹ bá ń fi àwọn ìlànà yìí lélẹ̀, ẹ máa ronú nípa àṣẹ tí Jésù pa, pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Nípa báyìí, àwọn ìlànà tẹ́ ẹ bá fi lélẹ̀ á jẹ́ èyí tẹ́ ẹ máa lè tẹ̀ lé. Lẹ́yìn náà, ẹ jẹ́ kí àwọn òbí yín mọ àwọn ìlànà tẹ́ ẹ ti jọ gbà pé ẹ ó máa tẹ̀ lé, kẹ́ ẹ lè mọ̀ bóyá wọ́n fara mọ́ ọn.—Éfésù 6:1.

2. Ìwọ fúnra rẹ gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà náà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, ǹjẹ́ ìwọ, ẹni tí ń kọ́ ẹlòmíràn, kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ, ẹni tí ń wàásù pé ‘Má jalè,’ ìwọ ha ń jalè bí?” (Róòmù 2:21) Báwo lo ṣe lè fi ìlànà yìí sílò? Bí àpẹẹrẹ, bí o kò bá fẹ́ kí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ kàn máa já wọ ibi àdáni rẹ, ìwọ náà gbọ́dọ̀ máa kan ilẹ̀kùn kó o tó wọ yàrá rẹ̀ tàbí kó o máa béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ kó o tó ka àwọn lẹ́tà tó ní lórí kọ̀ǹpútà tàbí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sórí fóònù rẹ̀.

3. Má ṣe tètè máa bínú. Kí nìdí tí ìmọ̀ràn yìí fi wúlò? Ohun tí òwe kan nínú Bíbélì sọ ni pé, ‘Máṣe yara lati bínú, nitori pe ìbínú ngbe ni àyà aṣiwèrè.’ (Oníwàásù 7:9, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Tó o bá jẹ́ ẹni tó máa ń tètè bínú, o ò ní gbádùn ayé ẹ rárá. Ó dájú pé ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ máa sọ̀rọ̀ tàbí kó ṣe ohun tó máa bí ẹ nínú. Àmọ́, bi ara rẹ pé, ‘Ṣé èmi náà ti ṣe ohun tó jọ èyí fún un rí?’ (Mátíù 7:1-5) Ọmọ kan tó ń jẹ́ Jenny sọ pé: “Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13], mo máa ń ronú pé mo ti ń ní sùúrù jù fún gbogbo èèyàn, mo sì máa ń rò pé èrò ọkàn mi ló ṣe pàtàkì jù, pé dandan ni kí wọ́n gbọ́ ọ. Bí mo ṣe ń ronú nígbà yẹn ni àbúrò mi náà ṣe wá ń ronú báyìí. Torí náà, mi kì í jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bí mi nínú.”

4. Máa dárí jini pátápátá. Ó yẹ kẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tẹ́ ẹ bá ní, kẹ́ ẹ sì yanjú rẹ̀. Àmọ́, ṣé gbogbo ìgbà tí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ bá ti ṣe àṣìṣe ló wá yẹ kó o máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Rárá o! Inú Jèhófà Ọlọ́run máa dùn tó o bá lè “gbójú fo ìrélànàkọjá.” (Òwe 19:11) Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ Alison sọ pé: “Èmi àti Rachel àbúrò mi sábà máa ń yanjú aáwọ̀ tó bá wà láàárín wa. Àwa méjèèjì máa ń tètè tọrọ àforíjì, a sì máa ń ṣàlàyé ohun tá a bá rò pé ó fa èdè àìyedè náà. Ìgbà míì wà tí mo máa ń mọ̀ọ́mọ̀ dá ọ̀rọ̀ náà dúró di ọjọ́ kejì kí n lè ronú dáadáa kí n tó lọ bá àbúrò mi. Lọ́pọ̀ ìgbà, tó bá máa fi di àárọ̀ ọjọ́ kejì, màá ti mọ́kàn kúrò lórí ọ̀rọ̀ náà, mi ò tiẹ̀ ní sọ ohunkóhun nípa rẹ̀ mọ́.”

5. Jẹ́ kí àwọn òbí yín dá sí ọ̀rọ̀ náà. Bí ìwọ àti ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ ò bá lè yanjú ìṣòro tó wà láàárín yín, àwọn òbí yín lè bá yín dá sí i. (Róòmù 14:19) Àmọ́, máa rántí pé, tẹ́ ẹ bá lè máa yanjú èdè àìyedè tó bá wáyé láàárín yín láìjẹ́ pé àwọn òbí yín dá sí i, ìwà àgbà lẹ̀ ń hù yẹn.

6. Mọyì àwọn ànímọ́ rere tí àwọn ẹ̀gbọ́n àtàwọn àbúrò rẹ ní. Ó dájú pé ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ kọ̀ọ̀kan máa ní àwọn ànímọ́ kan tó o nífẹ̀ẹ́ sí. Kọ ohun kan tó o mọyì lára ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn.

Orúkọ

․․․․․

Ohun tí mo mọyì lára rẹ̀

․․․․․

Dípò tí wàá fi máa ronú ṣáá nípa àwọn ibi tí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ kù sí, o ò ṣe wá ọ̀nà láti sọ àwọn ohun tó o fẹ́ràn nípa ìwà wọn fún wọn?—Sáàmù 130:3; Òwe 15:23.

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kì í fìgbà gbogbo jẹ́ pé ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ẹni ló máa sún mọ́ni jù lọ. (Òwe 18:24) Àmọ́, ìwọ àtàwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ lè túbọ̀ mọwọ́ ara yín, tẹ́ ẹ bá ń “bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì,” kódà bí o bá ní “ìdí fún ẹjọ́” lòdì sí wọn. (Kólósè 3:13) Tó o bá ń fi ìmọ̀ràn yìí sílò, wàá rí i pé o ò ní fi bẹ́ẹ̀ máa bínú sí àwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ mọ́. Ìwọ náà sì lè má fi bẹ́ẹ̀ ṣe ohun tó máa bí wọn nínú mọ́.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá o ti tó ẹni tó lè lọ dá gbé?

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.”​—Fílípì 4:5.

ÌMỌ̀RÀN

Tó o bá ní ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò tí ọ̀rọ̀ yín kò fi bẹ́ẹ̀ wọ̀, ṣe ni kó o kà á sí pé ó ń jẹ́ kó o lè ní àwọn ìwà pàtàkì tó máa wúlò fún ẹ nígbà tó bá yá.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Tó o bá kúrò nílé, ìgbà míì wà tó jẹ́ pé àwọn èèyàn tí ìwà wọn ń bí ẹ nínú ló máa yí ẹ ká. Ó lè jẹ́ àwọn tẹ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn ẹlòmíì tí kò mọ ìwà hù, tí wọn kì í ka nǹkan sí, tí wọn ò sì mọ̀ ju tara wọn nìkan lọ. Láti ilé lo ti máa kọ́ bó o ṣe lè wà láàárín irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, tí kò sì ní sí wàhálà.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Àwọn ìlànà témi àtàwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò mi lè jọ gbà láti máa tẹ̀ lé ni ․․․․․

Ohun tí mo lè ṣe kí n má bàa máa mú (àwọn) ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò mi bínú ni ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn mọ ìyàtọ̀ nínú ohun tó kàn ṣẹlẹ̀ àti ohun tó jẹ́ ìṣòro?

● Àwọn àǹfààní wo lo rí nínú kéèyàn ní ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 46]

“Ká ní mi ò láwọn àbúrò ni, àwọn nǹkan tí mò ń rántí tó ń múnú mi dùn jù lọ báyìí kò ní sí. Torí náà, ìmọ̀ràn mi fún gbogbo àwọn tó ní ẹ̀gbọ́n àti àbúrò ni pé, ‘Ẹ mọyì wọn gan-an o!’”​—Marilyn

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 42]

Tí mo kọ èrò mi sí

Rí I Pé O Mọ Ohun Tó Jẹ́ Ìṣòro

Kó o bàa lè túbọ̀ mọ ohun tó máa ń jẹ́ ìṣòro láàárín àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò, ka àkàwé tí Jésù ṣe nípa ọmọ tó fi ilé sílẹ̀, tó wá lọ fi ogún tí bàbá rẹ̀ fún un ṣòfò. (Lúùkù 15:11-32) Kíyè sí ohun tí ẹ̀gbọ́n ọmọ náà ṣe nígbà tí àbúrò rẹ̀ pa dà wálé. Kó o wá dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.

Kí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ tí ẹ̀gbọ́n ọmọ náà fi bínú? ․․․․․

Kí lo rò pé ó jẹ́ ìṣòro àárín wọn gan-an? ․․․․․

Báwo ni bàbá wọn ṣe gbìyànjú láti yanjú ìṣòro náà? ․․․․․

Kí ni ẹ̀gbọ́n ọmọ náà ní láti ṣe kí ìṣòro náà lè yanjú? ․․․․․

Wá ronú nípa awuyewuye kan tó wáyé láàárín ìwọ àti ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ láìpẹ́ yìí. Kó o wá kọ ìdáhùn rẹ síwájú àwọn ìbéèrè yìí.

Kí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ tí awuyewuye yẹn fi wáyé? ․․․․․

Kí lo rò pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìṣòro àárín yín? ․․․․․

Àwọn ìlànà wo lẹ lè jọ gbà láti máa tẹ̀ lé, tó máa yanjú ìṣòro náà, tí awuyewuye kò fi ní wáyé mọ́ nígbà míì? ․․․․․

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 43]

Awuyewuye tó máa ń wà láàárín tẹ̀gbọ́n-tàbúrò dà bíi rorẹ́, ohun tó fà á ló yẹ kó o yanjú dípò tí wàá fi gbájú mọ́ ohun tó kàn fara hàn sóde