Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Ìdẹwò?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Ìdẹwò?

ORÍ 9

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Borí Ìdẹwò?

Kò tíì ju ìṣẹ́jú mẹ́wàá lọ tí Karen débi àpèjẹ kan tó fi rí àwọn ọmọkùnrin méjì tí wọ́n gbé àwọn páálí kan wọlé. Ohun tó wà nínú àwọn páálí náà kò ṣàjèjì sí i rárá, torí ó ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ táwọn ọmọkùnrin yẹn ń sọ pé “ọtí máa ṣàn bí omi” níbẹ̀.

Karen wá gbọ́ ohùn ẹnì kan tó mọ̀ látẹ̀yìn rẹ̀ tó sọ pé: “Kí lo wá dúró síbẹ̀ yẹn fún, tó o kàn ń wò bí ọ̀dẹ̀?” Bó ṣe bojú wẹ̀yìn, ó rí Jessica ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó kó ìgò ọtí méjì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí dání. Jessica na ọ̀kan sí Karen, ó wá sọ pé, “Máà jẹ́ n gbọ́ pé o kéré láti jayé orí ẹ o!”

Karen ò fẹ́ gbà á. Àmọ́, wàhálà yẹn ti pọ̀ ju ohun tó retí lọ. Ọ̀rẹ́ ṣáà lòun àti Jessica, kò sì tún fẹ́ ṣe bí ọ̀dẹ̀ lóòótọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ọmọ dáadáa làwọn èèyàn mọ Jessica sí. Bó bá wá ń mutí, a jẹ́ pé kò sí nǹkan tó burú níbẹ̀ nìyẹn. Karen wá ń sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘Ṣebí ọtí lásán ni. Ó ṣáà yàtọ̀ sí pé kéèyàn mugbó tàbí kó ṣèṣekúṣe.’

NÍGBÀ téèyàn bá wà lọ́dọ̀ọ́, oríṣiríṣi ọ̀nà ni ìdẹwò máa ń gbà wá. Ọ̀rọ̀ ọkùnrin àti obìnrin ló sì máa ń dá lé lọ́pọ̀ ìgbà. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Ramon sọ pé: “Wàhálà àwọn ọmọbìnrin tó wà níléèwé wa ti pọ̀ jù. Wọ́n á mọ̀ọ́mọ̀ máa fọwọ́ kàn ẹ́, wọ́n á fẹ́ wo ohun tí wàá ṣe. Tó o bá ní kí wọ́n fi ẹ́ sílẹ̀, tiwọn kọ́ lò ń sọ yẹn!” Irú nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Deanna, ọmọbìnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, náà nìyẹn. Ó ní: “Ọmọkùnrin kan tí mi ò tiẹ̀ mọ̀ rí wá bá mi, ó sì fọwọ́ kọ́ mi lọ́rùn. Mo gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lọ́wọ́, mo ní, ‘Kí ló dé? Kí ló fẹ́ fa gbogbo kátikàti yẹn?’”

Àwọn nǹkan kan lè máa dẹ ìwọ náà wò lemọ́lemọ́ débi pé ó ti wá fẹ́ pọ̀ jù. Bí àwọn ìdẹwò náà ṣe ń wá léraléra tiẹ̀ lè dà bí ìgbà tẹ́nì kan kò yéé kan ilẹ̀kùn mọ́ ẹ lórí lẹ́yìn tó o ti jẹ́ kó mọ̀ pé o ò fẹ́ gbà á lálejò. Ṣé bó ṣe máa ń rí fún ẹ nìyẹn? Bí àpẹẹrẹ, ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi kó o ṣe èyíkéyìí lára àwọn nǹkan tá a tò sísàlẹ̀ yìí?

□ Mu sìgá

□ Wo àwòrán oníhòòhò

□ Mu ọtí

□ Ṣe ìṣekúṣe

□ Lo oògùn olóró

□ Nǹkan míì ․․․․․

Tó o bá fi àmì ✔ sí èyíkéyìí lára àwọn nǹkan tá a kọ yìí, má rò pé o kò lè jẹ́ Kristẹni tòótọ́ o. O lè dẹni tó mọ bó ò ṣe ní máa gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìdẹwò láyè. Báwo lo ṣe lè ṣe é? Ṣe ló yẹ kó o kọ́kọ́ mọ ohun tó ń fa ìdẹwò. Wo àwọn nǹkan mẹ́ta tó lè fa ìdẹwò.

1. Àìpé ẹ̀dá. Gbogbo èèyàn ni àìpé máa ń fẹ́ tì láti ṣe ohun tí kò tọ́. Kódà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa gbà pé: “Nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi.” (Róòmù 7:21) Èyí fi hàn pé ẹni tó tiẹ̀ jẹ́ èèyàn dáadáa pàápàá máa ń rí i pé “ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú” máa ń fẹ́ nípa lórí òun lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (1 Jòhánù 2:16) Téèyàn bá tún wá ń gba èròkerò láyè lọ́kàn rẹ, ṣe ló ń dá kún ìṣòro náà, torí Bíbélì sọ pé: “Ìfẹ́-ọkàn náà, nígbà tí ó bá lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.”—Jákọ́bù 1:15.

2. Àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní àyíká ẹni. Kò síbi tí ìdẹwò ò sí. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Trudy sọ pé: “Ní iléèwé àti níbi iṣẹ́, gbogbo ìgbà làwọn èèyàn máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀. Lórí tẹlifíṣọ̀n àti nínú fíìmù, wọ́n máa ń jẹ́ kó dà bíi pé kò sóhun tó dùn tó o. Wọn kì í sábà jẹ́ káwọn èèyàn rí ohun tó burú nípa rẹ̀!” Trudy kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òun fúnra rẹ̀ pé ohun táwọn ojúgbà ẹni bá ń ṣe, ohun téèyàn ń kà nínú ìwé àti ohun téèyàn ń wò nínú tẹlifíṣọ̀n máa nípa tó lágbára gan-an lórí ẹni. Ó ní: “Mi ò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] lọ nígbà tí ìfẹ́ ọmọkùnrin kan kó sí mi lórí. Mọ́mì mi pè mí jókòó, wọ́n sì sọ fún mi pé tí mi ò bá jáwọ́ nínú ohun tí mò ń ṣe yẹn, mo máa gboyún gbẹ̀yìn ni. Ó yà mí lẹ́nu gan-an pé mọ́mì mi lè sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀! Àmọ́, oṣù méjì péré lẹ́yìn náà ni mo gboyún.”

3. “Ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn.” (2 Tímótì 2:22) Gbólóhùn yìí ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó sábà máa ń gba àwọn ọ̀dọ́ lọ́kàn, irú bíi fífẹ́ káwọn èèyàn máa gba tiwọn tàbí kí wọ́n fẹ́ máa fi han àwọn èèyàn pé àwọn ti kúrò lọ́mọdé. Àwọn ohun tí wọ́n ń fẹ́ yìí lè má burú láyè ara wọn, àmọ́ téèyàn bá ti àṣejù bọ̀ ọ́, ó lè jẹ́ kéèyàn kó sí ìdẹwò. Bí àpẹẹrẹ, bó o bá ṣáà ń fẹ́ máa fi han àwọn èèyàn pé o ti kúrò lọ́mọdé, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ohun tó lòdì sí ìlànà rere táwọn òbí rẹ fi tọ́ ẹ dàgbà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Steve nìyẹn. Ó ní: “Kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi ni mo kẹ̀yìn sáwọn òbí mi, tí mò ń ṣe bó ṣe wù mí. Kódà gbogbo ohun tí wọ́n ti kọ́ mi pé kí n ṣe gan-an ni mo wá ń ṣe.”

Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Wàá Fi Lè Borí Ìdẹwò

Ká sòótọ́, àwọn nǹkan mẹ́ta tá a sọ pé ó lè fa ìdẹwò yìí máa ń nípa tó lágbára gan-an lórí ẹni. Àmọ́, àwọn nǹkan kan ṣì wà tó o lè ṣe tí wàá fi lè borí ìdẹwò. Kí làwọn nǹkan náà?

● Kọ́kọ́ mọ ohun tó jẹ́ ìdẹwò tó máa ń ṣòro jù fún ẹ láti yẹra fún. (O lè ti fi àmì sí ohun náà lójú ìwé 65.)

● Lẹ́yìn náà, bi ara rẹ pé, ‘Ìgbà wo gan-an ni ìdẹwò yìí sábà máa ń wáyé?’ Fi àmì ✔ sí èyí tó jẹ́ nísàlẹ̀ yìí:

□ Tí mo bá wà níléèwé

□ Tí mo bá dá wà

□ Tí mo bá wà níbi iṣẹ́

□ Ibòmíì ․․․․․

Tó o bá mọ ìgbà tí ìdẹwò lè wáyé, ìyẹn tiẹ̀ lè jẹ́ kó o yẹra fún un pátápátá. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ohun tá a sọ pé ó ṣẹlẹ̀ sí Karen ní ìbẹ̀rẹ̀ orí yìí. Ọ̀rọ̀ wo ni Karen ti gbọ́ táá ti jẹ́ kó mọ̀ pé òun máa bá wàhálà pàdé níbi àpèjẹ tó lọ?

․․․․․

Kí ni ì bá ti ṣe láti yẹra fún ìdẹwò yẹn?

․․․․․

● Ní báyìí tó o ti mọ ohun tó sábà máa ń jẹ́ ìdẹwò fún ẹ, tó o sì ti mọ ìgbà tó ṣeé ṣe kó wáyé, o ti lè ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀ nìyẹn. Ohun tó yẹ kó o kọ́kọ́ ṣe ni pé kó o ronú nípa bó o ṣe lè dín ohun tó ń fa ìdẹwò yẹn kù tàbí bó o ṣe lè yẹra fún un pátápátá. Kọ ohun tó o lè ṣe sórí ìlà yìí.

․․․․․

(Bí àpẹẹrẹ: Ká sọ pé nígbà tẹ́ ẹ bá jáde níléèwé, o sábà máa ń pàdé àwọn ọmọ iléèwé yín kan tó máa ń fi sìgá lọ̀ ẹ́, o lè máa gba ọ̀nà míì lọ sílé kó o má bàa pàdé wọn. Bí àwọn nǹkan tó ń mọ́kàn èèyàn fà sí ìṣekúṣe bá kàn ń dédé wọlé sórí kọ̀ǹpútà rẹ látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì, o lè ṣe àwọn nǹkan kan sí kọ̀ǹpútà rẹ tí kò ní jẹ́ kí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ wọlé mọ́. Ó sì lè jẹ́ pé wàá túbọ̀ máa ṣọ́ irú ọ̀rọ̀ tó ò ń tẹ̀ sí kọ̀ǹpútà láti fi wá ìsọfúnni dípò tí wàá kàn fi máa tẹ ọ̀rọ̀ tó ní ìtumọ̀ tó pọ̀.)

Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìdẹwò pátá lo máa lè yẹra fún o. Bó pẹ́ bó yá, wàá bá ìdẹwò kan tó ṣòro pàdé, bóyá nígbà tí o kò tiẹ̀ rò pé ó lè wá pàápàá. Kí lo wá lè ṣe?

Múra Sílẹ̀

Nígbà tí Sátánì “ń dẹ [Jésù] wò,” Jésù kò rò ó lẹ́ẹ̀mejì kó tó kọ̀ jálẹ̀. (Máàkù 1:13) Kí nìdí? Torí Jésù ti ní ìpinnu tó ti ṣe lórí àwọn nǹkan tí Èṣù fi dẹ ẹ́ wò. Jésù ti pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé Bàbá òun lòun máa ṣègbọràn sí nígbà gbogbo. (Jòhánù 8:28, 29) Ohun tí Jésù ń ṣe gan-an ló sọ, nígbà tó sọ pé: “Èmi sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.”—Jòhánù 6:38.

Ní ojú ìwé tó tẹ̀ lé èyí, kọ ìdí méjì tí kò fi yẹ kó o fàyè gba ohun tó sábà máa ń jẹ́ ìdẹwò fún ẹ, kó o sì kọ ohun méjì tó o lè ṣe tó ò fi ní gbà á láyè.

Ìdí tí kò fi yẹ kó o fàyè gbà á:

1 ․․․․․

2 ․․․․․

Àwọn ohun tó o lè ṣe tó ò fi ní gbà á láyè:

1 ․․․․․

2 ․․․․․

Rántí pé tó o bá gba ìdẹwò láyè, ńṣe lo sọ ara rẹ di ẹrú fáwọn ìfẹ́ ọkàn rẹ. (Títù 3:3) Ǹjẹ́ ó sì yẹ kó o jẹ́ kí ìfẹ́ ọkàn rẹ wá máa darí rẹ? Rárá o. Ìwọ ló yẹ kó máa darí ìfẹ́ ọkàn rẹ, kì í ṣe ìfẹ́ ọkàn rẹ ló yẹ kó máa darí rẹ. Ìyẹn ló máa fi hàn pé o mọ ohun tó ò ń ṣe. (Kólósè 3:5) Sì máa bẹ Ọlọ́run pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa darí ìfẹ́ ọkàn rẹ.​—Mátíù 6:13. *

KÀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 15, NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ṣé ara rẹ kì í yá gágá tó lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni? Wo bó o ṣe lè mú kí ara rẹ túbọ̀ jí pépé!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.”​—1 Kọ́ríńtì 10:13.

ÌMỌ̀RÀN

Lo àtẹ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Mímúra Sílẹ̀ De Ìṣòro,lójú ìwé 132 àti 133 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, láti fi pinnu ohun tó o máa ṣe bí ẹnì kan bá fẹ́ tàn ẹ́ pé kó o ṣe ohun tí kò dáa.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù máa jẹ́ olóòótọ́, àmọ́ ìyẹn kò túmọ̀ sí pé Jésù wá dà bí ẹ̀rọ róbọ́ọ̀tì tó jẹ́ pé ó kàn máa ń tẹ̀ lé ohun tí wọ́n ti pinnu pé kó máa ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù lè fúnra rẹ̀ pinnu láti ṣe ohun tó bá wù ú. Fúnra rẹ̀ ló sì pinnu láti jẹ́ olóòótọ́, kì í ṣe pé Ọlọ́run ti dá a látilẹ̀ wá pé ó gbọ́dọ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi gbàdúrà kíkankíkan nígbà tí ìdánwò dé bá a.​—Hébérù 5:7.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Ohun tí màá ṣe láti rí i dájú pé mi ò gba ìdẹwò láyè rárá ni pé ․․․․․

Lára àwọn èèyàn tí màá fẹ́ yẹra fún, àwọn ibi tí mi ò ní fẹ́ lọ àtàwọn ohun tí mi ò ní fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ ni ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Ṣé àwọn ẹ̀dá pípé náà máa ń rí ìdẹwò?​—Jẹ́nẹ́sísì 6:1-3; Jòhánù 8:44.

● Tí o kò bá fàyè gba ìdẹwò, ipa wo ni bó o ṣe jẹ́ olóòótọ́ máa ní lórí àwọn ẹlòmíì?​—Òwe 27:11; 1 Tímótì 4:12.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 68]

“Ohun tó ń fi mí lọ́kàn balẹ̀ ni mímọ̀ tí mo mọ̀ pé Ọlọ́run Olódùmarè wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo àti pé mo lè bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn mí lọ́wọ́ nígbàkigbà!”​—Christopher

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 67]

Rò Ó Wò Ná!

Wo ohun èlò tó dà bí aago nínú àwòrán yìí. Kọ́ńpáàsì ni wọ́n ń pè é. Ó ní ọwọ́ kúkúrú kan tó máa ń tọ́ka sí àríwá nígbà gbogbo. Àmọ́ tó o bá fi irin tútù, ìyẹn mágínẹ́ẹ̀tì, sẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ́ńpáàsì náà, ọwọ́ kúkúrú náà kò ní tọ́ka sí àríwá mọ́, apá ibi tí mágínẹ́ẹ̀tì náà wà ló máa tọ́ka sí. Ọwọ́ kúkúrú náà kò ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́ nìyẹn.

A lè fi ẹ̀rí ọkàn rẹ wé kọ́ńpáàsì yẹn. Tó o bá kọ́ ẹ̀rí ọkàn rẹ dáadáa, á máa ṣiṣẹ́ dáadáa bí ìgbà tí ọwọ́ kọ́ńpáàsì yẹn tọ́ka sí àríwá, wàá sì lè máa ṣe àwọn ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Àmọ́ bí mágínẹ́ẹ̀tì yẹn ò ṣe jẹ́ kí kọ́ńpáàsì náà ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹgbẹ́ búburú ṣe lè jẹ́ kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣìwà hù. Ẹ̀kọ́ wo ni èyí kọ́ ẹ? Ẹ̀kọ́ náà ni pé kó o máa ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti yẹra fún àwọn èèyàn tàbí ohunkóhun tó bá lè jẹ́ kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣìwà hù!​—Òwe 13:20.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 69]

Tó o bá gba ìdẹwò láyè, ńṣe lo sọ ara rẹ di ẹrú fáwọn ìfẹ́ ọkàn rẹ