Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Tọ́jú Ara Mi?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Tọ́jú Ara Mi?

ORÍ 10

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Tọ́jú Ara Mi?

Fi àmì ✔ sẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tó o máa fẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ̀ nínú àwọn ohun tá a kọ síbí.

□ Mi ò fẹ́ máa dààmú púpọ̀ jù lórí àwọn nǹkan mọ́

□ Mi ò fẹ́ tètè máa bínú mọ́

□ Mo fẹ́ túbọ̀ dá ara mi lójú

□ Mo fẹ́ kí ọpọlọ mi túbọ̀ jí pépé

□ Mo fẹ́ túbọ̀ lókun àti agbára

□ Mo fẹ́ kí àwọ̀ mi dáa sí i

□ Mo fẹ́ dín bí mo ṣe sanra kù

ÀWỌN nǹkan kan wà tí ọmọdé kì í yàn fúnra rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, o ò lè yan àwọn òbí tó o fẹ́ kó bí ẹ, o ò lè yan àwọn tó máa jẹ́ ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ, títí kan ibi tó o máa gbé àtàwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ti ìlera rẹ yàtọ̀ sí àwọn ohun tá a sọ yìí. Òótọ́ ni pé èèyàn lè jogún àìlera látọ̀dọ̀ àwọn òbí ẹni, síbẹ̀, bó o ṣe ń gbé ìgbé ayé rẹ ló sábà máa ń pinnu bí ìrísí rẹ àti ìlera rẹ ṣe máa rí. *

O lè máa ronú pé, ‘ọmọdé ṣì ni mí jàre, kò yẹ kí n máa da ara mi láàmú nípa ìlera mi!’ Ṣé pé kò yẹ kó o dara rẹ láàmú nípa ìlera rẹ lóòótọ́? Wo àwọn ohun tá a kọ sójú ìwé 71 yẹn ná. Mélòó nínú rẹ̀ lo sàmì sí? Ohun kan tó dájú ni pé ara rẹ gbọ́dọ̀ le dáadáa kí ọwọ́ rẹ tó lè tẹ èyíkéyìí lára àwọn ohun tó o sàmì sí yẹn.

Àmọ́ ṣá o, o lè máa ronú bíi ti Amber, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] tó sọ pé: “Èmi ò mà lè máa jẹ àwọn oúnjẹ tí kò dùn lẹ́nu, tí kò ní ṣúgà, tí kò ní iyọ̀, ní gbogbo ìgbà ńtèmi o!” Bó o bá ní irú èrò bẹ́ẹ̀, fọkàn balẹ̀, kò dìgbà tó o bá ń fi gbogbo nǹkan dídùn du ara rẹ, tó o sì ń sáré lọ síbi tó jìnnà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kí ara rẹ tó le dáadáa. O tiẹ̀ lè má ṣe ju àwọn àyípadà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ kan lọ tí ìrísí rẹ á fi túbọ̀ dára, tí ara rẹ á túbọ̀ dá ṣáṣá, tí ọpọlọ rẹ á sì jí pépé. Jẹ́ ká wo bí àwọn ọ̀dọ́ kan ṣe ṣé e.

Máa Jẹ Oúnjẹ Tó Ṣara Lóore Kí Ìrísí Rẹ Lè Dára!

Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa ṣe nǹkan níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Òwe 23:20 sọ pé: “Máṣe wà ninu awọn . . . alájẹkì.” (Bibeli Yoruba Atọ́ka) Kì í sábà rọrùn láti tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ yìí.

“Gbogbo ìgbà ni ebi máa ń pa mí, bó ṣe máa ń pa àwọn ọ̀dọ́ bíi tèmi. Àwọn òbí mi tiẹ̀ máa ń sọ pé ikùn mi dà bíi kòtò ńlá tí kò ní ìsàlẹ̀!”​—Andrew, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15].

“Èmi ò rí ìṣòro kankan táwọn oúnjẹ kan tí mò ń jẹ ń fà sí mi lára báyìí, torí náà, mi ò rò pé àwọn oúnjẹ yẹn ò dáa.”​—Danielle, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19].

Ǹjẹ́ o ti kíyè sí i pé ó yẹ kó o máa kó ara rẹ níjàánu tó bá dọ̀rọ̀ oúnjẹ? Wo ohun táwọn ojúgbà rẹ kan sọ pé àwọn ṣe.

Má jẹun jù. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ Julia sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, bí oúnjẹ kan ṣe yó mi tó ni mo máa ń wò tí mo bá ń jẹun, àmọ́ ní báyìí, ńṣe ni mo máa ń ṣíwọ́ oúnjẹ tí mo bá rí i pé mo ti fẹ́ yó.”

Má ṣe máa jẹ àwọn oúnjẹ tí kì í ṣe ara lóore. Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] kan tó ń jẹ Peter sọ pé: “Láàárín oṣù kan péré tí mi ò mu ọtí ẹlẹ́rìndòdò, kìlógíráàmù márùn-ún ni mo fi jò sí i!”

Máa ṣọ́ bó o ṣe ń jẹun. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ Erin sọ pé: “Mo máa ń rí i pé mi kì í pa dà lọ bu oúnjẹ sí i lẹ́yìn tí àkọ́kọ́.”

Ohun Tó Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí: Rí i pé ò ń jẹun lákòókò! Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ebi tó máa pa ẹ́ lè jẹ́ kó o jẹun ju bó ṣe yẹ lọ.

Túbọ̀ Máa Ṣe Eré Ìmárale Kí Ara Rẹ Lè Dá Ṣáṣá!

Bíbélì sọ pé: “Ara títọ́ ṣàǹfààní.” (1 Tímótì 4:8) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ kì í fẹ́ ṣe eré ìmárale.

“Nígbà tí mo wà ní ilé ìwé girama, ó máa ń yà mí lẹ́nu gan-an pé ọ̀pọ̀ ọmọ ilé ìwé ni kì í ṣe dáadáa nínú ẹ̀kọ́ eré ìmárale. Kò sì sí nǹkan tó le nínú ẹ̀ o, àfi bí ẹni fi àkàrà jẹ̀kọ!”​—Richard, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21].

“Àwọn kan rò pé, ‘Kò yẹ kéèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ tún máa sáré kiri nínú oòrùn títí táá fi rẹ̀ ẹ́, kó wá máa làágùn yọ̀bọ̀ torí pé ó fẹ́ ṣeré ìmárale, nígbà téèyàn lè máa lo géèmù orí kọ̀ǹpútà láti fi ṣe bí ẹni pé òun lòun ń sáré kiri.’”​—Ruth, ọmọ ọdún méjìlélógún [22].

Ṣé kì í wù ẹ́ láti ṣeré ìmárale rárá? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, wo àwọn àǹfààní mẹ́ta tó o máa rí tó o bá ń ṣe eré ìmárale déédéé.

Àǹfààní àkọ́kọ́. Eré ìmárale máa jẹ́ kí àwọn èròjà tó ń gbógun ti àrùn nínú ara rẹ túbọ̀ lágbára. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ Rachel ní: “Bàbá mi máa ń sọ pé, ‘Bí o kò bá ráyè eré ìmárale, àìsàn tó máa gba àyè yẹn lò ń kọ̀wé sí o.’”

Àǹfààní kejì. Eré ìmárale máa ń jẹ́ kí ọpọlọ tú àwọn èròjà kan jáde sínú ara, èyí tó máa ń jẹ́ kí ara ẹni balẹ̀. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kan tó ń jẹ́ Emily sọ pé: “Bí ọ̀pọ̀ nǹkan bá ń dààmú ọkàn mi, bí mo bá ti sáré báyìí, ńṣe ni ọkàn mi máa ń fúyẹ́. Ó máa ń jẹ́ kí ara tù mí, ọkàn mi á sì wá balẹ̀.”

Àǹfààní kẹta. Eré ìmárale máa jẹ́ kó o lè dára yá. Ọmọ ọdún méjìlélógún [22] kan tó ń jẹ́ Ruth, sọ pé: “Mo fẹ́ràn kí n máa ṣe eré ìdárayá ní ìta gbangba, irú bíi rírìn lọ síbi tó jìn díẹ̀, lílúwẹ̀ẹ́, ṣíṣeré lórí yìnyín àti gígun kẹ̀kẹ́.”

Ohun Tó Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí: Ó kéré tán, máa fi ogún [20] ìṣẹ́jú ṣe eré àṣelàágùn kan tó o fẹ́ràn lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́sẹ̀.

Máa Sùn Dáadáa, Kí Ọpọlọ Rẹ Lè Jí Pépé!

Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.” (Oníwàásù 4:6) Tó bá jẹ́ pé o kì í sùn dáadáa, o ò ní lè máa ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ kó o ṣe é!

“Bí mi ò bá ti sùn dáadáa, wàhálà dé nìyẹn. Mi kì í lè pọkàn pọ̀ sórí ohun tí mo bá ń ṣe!”​—Rachel, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19].

“Bó bá ti ń di nǹkan bí aago méjì ọ̀sán, ó máa ń rẹ̀ mí gan-an débi pé mo lè sùn lọ níbi tí mo bá ti ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀!”​—Kristine, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19].

Ǹjẹ́ o ti kíyè sí i pé o kì í sùn tó bó ṣe yẹ? Wo ohun táwọn ojúgbà rẹ kan ti ṣe.

Máa tètè sùn. Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Catherine sọ pé, “Mo máa ń rí i dájú pé mi kì í pẹ́ kí n tó sùn.”

Má ṣe máa rojọ́ lóru. Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] kan tó ń jẹ́ Richard sọ pé: “Nígbà míì, àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń pè mí lóru tàbí kí wọ́n fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sórí fóònù mi, ohun tí mo wá ń ṣe báyìí ni pé, mo máa ń tètè sọ fún wọn pé mo fẹ́ sùn, màá sì lọ sùn.”

Yan àkókò pàtó tí wàá máa sùn àti ìgbà tó o fẹ́ máa jí. Ọmọ ogún [20] ọdún kan tó ń jẹ́ Jennifer sọ pé: “Ní báyìí, mo máa ń gbìyànjú láti rí i pé mi ò jẹ́ kí àkókò tí mò ń sùn àti àkókò tí mò ń jí lójoojúmọ́ yẹ̀.”

Ohun Tó Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí: Rí i pé, ó kéré tán, ò ń sun oorun wákàtí mẹ́jọ ní òru mọ́jú.

Wàá jàǹfààní gan-an tó o bá kàn ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ mélòó kan láti fi tọ́jú ara rẹ. Rántí pé bí ara rẹ bá le dáadáa, ìrísí rẹ á túbọ̀ dára, ara rẹ á dá ṣáṣá, ọpọlọ rẹ á sì jí pépé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan kan wà tí kò sí ohun tó o lè ṣe nípa rẹ̀, rántí pé dé ìwọ̀n àyè kan, o lè pinnu bó o ṣe fẹ́ kí ìrísí rẹ àti ìlera rẹ rí. Erin tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] sọ pé: “Tá a bá ní ká wò ó, ọwọ́ ìwọ fúnra rẹ gan-an lọ̀rọ̀ ìlera rẹ wà.”

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ṣé ọ̀rọ̀ nípa irú aṣọ tó yẹ kó o wọ̀ máa ń dá wàhálà sílẹ̀ láàárín ìwọ àtàwọn òbí rẹ? Kà nípa ohun tẹ́ ẹ lè máa ṣe tí ò fi ní sí wàhálà!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 11 A mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ló ní àìlera tàbí àrùn tó jẹ́ pé kò sóhun tí wọ́n lè ṣe nípa rẹ̀. Orí yìí lè jẹ́ kí àwọn tó ní irú ìṣòro yìí mọ ohun tí wọ́n lè ṣe tí ara wọn á fi túbọ̀ le sí i dé ìwọ̀n tó bá ṣeé ṣe.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Ara títọ́ ṣàǹfààní.”​—1 Tímótì 4:8.

ÌMỌ̀RÀN

Wá ẹnì kan tẹ́ ẹ ó jọ máa ṣeré ìmárale. Ìyẹn á jẹ́ kó o lè máa ṣe é déédéé torí o ò ní fẹ́ já ẹni yẹn kulẹ̀.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Eré ìmárale máa ń jẹ́ kí ọpọlọ tú àwọn èròjà kan (endorphins) jáde sínú ara, ìyẹn àwọn èròjà tó máa ń dín ìrora kù tó sì máa ń jẹ́ kí ara ẹni yá gágá.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Ohun tí mo rò pé màá lè ṣe lórí ọ̀rọ̀ irú oúnjẹ tí mò ń jẹ ni ․․․․․

Ohun tí mo rò pé màá lè ṣe lórí ọ̀rọ̀ eré ìmárale ni ․․․․․

Ní oṣù tó ń bọ̀, màá gbìyànjú láti máa sun oorun nǹkan bíi wákàtí mọ́jú. ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Ipa wo ni bó o ṣe ń tọ́jú ara rẹ lè ní lórí ojú tó o máa fi wo ara rẹ?

● Kí ló tiẹ̀ tún ṣe pàtàkì ju títọ́jú ara rẹ lọ?​—1 Tímótì 4:8.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 74]

“Mo máa ń gbádùn ara mi bí mo bá ṣe eré ìmárale. Nígbà tí mo sì wá rí i pé ìrísí mi túbọ̀ ń dáa sí i, mo túbọ̀ ń dára mi lójú sí i!”​—Emily

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 73]

“Mo Yí Àwọn Nǹkan Tí Mò Ń Ṣe Pa Dà”

“Mi ò tíì tó ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] tí mo ti sanra jọ̀kọ̀tọ̀, kò sì wù mí kí n sanra bẹ́ẹ̀ rárá. Bí mo ṣe rí ò tẹ́ mi lọ́rùn, inú mi kì í sì í dùn. Àìmọye ìgbà ni mo máa ń jẹ oríṣi àwọn oúnjẹ kan kí n lè fọn díẹ̀, àmọ́ ṣe ni mo máa ń tóbi pa dà. Torí náà, nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo pinnu pé mo ní láti wá nǹkan míì ṣe sí ọ̀rọ̀ yìí! Mo fẹ́ dín bí mo ṣe sanra kù lọ́nà tó yẹ, tí mi ò fi ní tóbi jù bẹ́ẹ̀ lọ mọ́. Mo ra ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó yẹ kéèyàn máa jẹ àti béèyàn ṣe lè máa ṣe eré ìmárale dáadáa, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ohun tí mò ń kà nínú ìwé náà. Mo wá pinnu pé bí àwọn ohun tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe yìí bá tiẹ̀ fẹ́ sú mi tàbí tí mo dáwọ́ rẹ̀ dúró fúngbà díẹ̀, mi ò ní jáwọ́ níbẹ̀. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fọn lóòótọ́ nìyẹn o! Láàárín ọdún kan mo dín kù ní ìwọ̀n kìlógíráàmù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27]. Ọdún méjì ti kọjá báyìí tí mi ò pa dà sanra mọ́. Tẹ́lẹ̀, mi ò tiẹ̀ rò pé ìyẹn lè ṣeé ṣe rárá! Mo rò pé ohun tó jẹ́ kí n lè ṣàṣeyọrí ni pé, mi ò kàn ṣọ́ irú oúnjẹ tí mò ń jẹ, ṣe ni mo yí àwọn nǹkan tí mò ń ṣe pa dà.”​—Catherine, ọmọ ọdún méjìdínlógún [18].

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 74]

Bí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ ìlera rẹ ṣe rí, bí o kò bá bójú tó o bó ṣe yẹ, ńṣe ló máa dẹnu kọlẹ̀