Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Ìbànújẹ́ Kúrò Lọ́kàn Mi?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Ìbànújẹ́ Kúrò Lọ́kàn Mi?

ORÍ 13

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Ìbànújẹ́ Kúrò Lọ́kàn Mi?

“Tí ìṣòro ńlá bá ń kó ìdààmú ọkàn bá àwọn ọ̀rẹ́ mi, mo máa ń bá wọn yanjú ẹ̀, tí ara wọn á sì yá gágá. Àmọ́, ohun tí ọ̀pọ̀ ò mọ̀ ni pé, tí n bá pa dà délé, ṣe ni mò ń bọ́ sínú yàrá tí màá bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún.”​—Kellie.

“Tí inú mi kò bá dùn, ṣe ni mo máa ń fẹ́ dá wà. Bí wọ́n bá pè mí pé kí n wá síbì kan, màá wá nǹkan kan sọ tí mi ò fi ní lọ. Mi kì í sì í jẹ́ káwọn ará ilé mi mọ̀ rárá pé inú mi ò dùn. Ṣe ni wọ́n máa ń rò pé mi ò níṣòro kankan.”​—Rick.

ǸJẸ́ ìwọ náà ti ronú bíi ti Kellie àti Rick tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí rí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe yára rò pé nǹkan kan ń ṣe ẹ́. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, gbogbo èèyàn ni ìbànújẹ́ máa ń bá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Kódà, ó bá àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn náà.​—1 Sámúẹ́lì 1:6-8; Sáàmù 35:14.

Láwọn ìgbà míì, o lè mọ ìdí tínú rẹ ò fi dùn, ìgbà míì sì rèé, o lè má mọ̀ ọ́n. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ Anna, sọ pé: “Kò dìgbà tí ìṣòro èèyàn bá pọ̀ gan-an kí ìbànújẹ́ tó dé bá a. Ìgbàkigbà ló lè dé, kódà téèyàn ò bá tiẹ̀ níṣòro kankan. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún gan-an ò tiẹ̀ yé èèyàn, àmọ́ ó máa ń ṣẹlẹ̀!”

Ohun yòówù kó fa ìbànújẹ́ tó sorí rẹ kodò, bóyá o mọ̀ ọ́n tàbí o kò mọ̀ ọ́n, kí lo lè ṣe sí i? Gbìyànjú àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí:

1. Sọ fún ẹnì kan. Nígbà tí Jóòbù wà nínú ìpọ́njú, ó sọ pé: “Èmi yóò sọ̀rọ̀ nínú ìkorò ọkàn mi!”​—Jóòbù 10:1.

Kellie sọ pé: “Ara máa ń tù mí gan-an tí mo bá ti sọ ohun tó ń ṣe mí fẹ́nì kan. Ọkàn mi á wá balẹ̀ pé ẹnì kan ti mọ ohun tó ń bá mi fínra. Á lè ràn mí lọ́wọ́ kí n lè bọ́ nínú ìbànújẹ́ mi, bíi pé wọ́n yọ mí nínú kòtò!”

Àbá: Kọ orúkọ ọ̀rẹ́ rẹ kan tó o lè sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ fún nígbà tí inú rẹ kò bá dùn. Kọ ọ́ sórí ìlà yìí.

․․․․․

2. Kọ ọ́ sílẹ̀. Bí ìbànújẹ́ bá ń mú kí gbogbo nǹkan tojú sú ẹ, o lè gbìyànjú láti kọ èrò ọkàn rẹ sínú ìwé kan. Láwọn ìgbà kan, Dáfídì náà kọ bí inú rẹ̀ ṣe bà jẹ́ tó sínú àwọn sáàmù tí Ọlọ́run mí sí i láti kọ. (Sáàmù 6:6) Tó o bá ń kọ èrò ọkàn rẹ sílẹ̀, ìyẹn lè jẹ́ kó o ní “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú.”​—Òwe 3:21.

Heather sọ pé: “Bí mo bá kọ èrò ọkàn mi sílẹ̀ nígbà tí mo wà nínú ìbànújẹ́, ìyẹn máa ń jẹ́ kí n mọ àwọn nǹkan tó ń dà mí lọ́kàn rú. Téèyàn bá ti lè kọ èrò ọkàn rẹ̀ sílẹ̀, tó sì ti lóye ohun tó ń fà á, ìbànújẹ́ náà á dín kù.”

Àbá: Lo àtẹ tó wà  lójú ìwé 93, ó máa jẹ́ kó o mọ àwọn ohun tó máa dáa kó o ṣe nígbà tí àwọn nǹkan kan bá ń bà ẹ́ nínú jẹ́. Ìyẹn á jẹ́ kí ìbànújẹ́ ọkàn rẹ fúyẹ́.

3. Gbàdúrà nípa rẹ̀. Bíbélì sọ pé, tó o bá sọ ohun tó ń dùn ẹ́ lọ́kàn fún Ọlọ́run nínú àdúrà, ‘àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò máa ṣọ́ ọkàn-àyà rẹ àti agbára èrò orí rẹ.’​—Fílípì 4:6, 7.

Esther sọ pé: “Mo gbìyànjú láti mọ ohun tó kàn ń bà mí nínú jẹ́ ṣáá, àmọ́ mi ò mọ̀ ọ́n. Ìbánújẹ́ náà wá sú mi torí mi ò rí ìdí tó fi yẹ kí n máa banú jẹ́. Mo bá gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kí n lè láyọ̀. Bí mo ṣe bọ́ nínú ẹ̀ nìyẹn o. Má ṣe fojú kéré agbára àdúrà!”

Àbá: Bó o bá fẹ́ gbàdúrà sí Jèhófà, o lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tó wà nínú Sáàmù 139:23, 24. Sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún Ọlọ́run, kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ kó o lè mọ ohun tó ń fa ìbànújẹ́ rẹ.

Láfikún sí àwọn àbá tá a dá lókè yìí, àwọn nǹkan míì tó tún lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ dáadáa wà nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tó o bá ń ka àwọn ọ̀rọ̀ rere tó wà nínú Bíbélì dáadáa, tó o sì ń jẹ́ kó wọ̀ ẹ́ lọ́kàn, yóò máa nípa rere lórí bó o ṣe ń ronú. (Sáàmù 1:1-3) Àwọn àbá tó máa jẹ́ kó o jàǹfààní nínú Bíbélì kíkà wà ní àwọn ojú ìwé tá a pè ní “Àwòkọ́ṣe” nínú ìwé tó ò ń kà yìí àti nínú Apá Kejì rẹ̀. Tó o bá wo ojú ìwé 227 nínú Apá Kejì yẹn, wàá rí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàápàá ṣe kó lè bọ́ lọ́wọ́ èrò tí kò tọ́ tó ń wá sí i lọ́kàn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan torí pé ó jẹ́ aláìpé.

Bí Ìbànújẹ́ Bá Kọ̀ Tí Kò Lọ

Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ryan sọ pé: “Nígbà míì, mi kì í fẹ́ dìde lórí bẹ́ẹ̀dì láàárọ̀, torí pé mi ò tún fẹ́ jí sínú ìbànújẹ́ àtàárọ̀ ṣúlẹ̀.” Àárẹ̀ ọkàn ló ń da Ryan láàmú, kì í sì í ṣe òun nìkan ló níṣòro yìí. Ìwádìí fi hàn pé tá a bá kó ọ̀dọ́ mẹ́rin jọ, ó ṣeé ṣe kí ọ̀kan nínú wọn ní oríṣi àwọn àárẹ̀ ọkàn kan kí wọ́n tó dàgbà.

Báwo lo ṣe máa mọ̀ tí àárẹ̀ ọkàn bá ń dà ẹ́ láàmú? Lára àwọn àmì tó o máa rí ni pé ìṣesí àti ìwà rẹ máa ṣàdédé yí pa dà lọ́nà tó ṣàjèjì, wàá fẹ́ máa dá wà, ọ̀pọ̀ nǹkan ni kò ní máa wù ẹ́ ṣe, bó o ṣe ń jẹun àti bó o ṣe ń sùn á kàn dédé yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀, wàá máa wo ara rẹ bí ẹni tí kò wúlò fún nǹkan kan tàbí kó o kàn máa dá ara rẹ lẹ́bi ṣáá.

Ká sòótọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èèyàn ni ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ohun tá a mẹ́nu bà yìí máa ń ṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, bí àwọn nǹkan yìí bá ń ṣe ẹ́, tí kò sì lọ lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan, o lè sọ fáwọn òbí rẹ pé kí wọ́n jẹ́ kó o lọ rí dókítà. Dókítà máa lè pinnu bóyá àìsàn kan ló ṣe ẹ́ tó ń fa ìbànújẹ́ rẹ. *

Tí àárẹ̀ ọkàn bá ń yọ ẹ́ lẹ́nu, má ṣe jẹ́ kí ìyẹn kó ìtìjú bá ẹ. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ní irú àìsàn yìí ni ara wọn bẹ̀rẹ̀ sí í yá nígbà tí wọ́n gba ìtọ́jú, tó sì jẹ́ pé ó ti pẹ́ tí ara wọn ti yá bẹ́ẹ̀ gbẹ̀yìn! Nítorí náà, tó bá jẹ́ pé àárẹ̀ ọkàn tàbí nǹkan míì ló ń fa ìbànújẹ́ rẹ, máa rántí ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Sáàmù 34:18 pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Tí ìbànújẹ́ èèyàn bá ti wá pọ̀ lápọ̀jù débi pé onítọ̀hún ń ronú pé kí òun kúkú pa ara òun ńkọ́?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 22 Bí ìbànújẹ́ kò bá kúrò lọ́kàn àwọn ọ̀dọ́ kan, wọ́n lè máa ronú pé àwọn á kúkú pa ara àwọn. Bí irú èrò yìí bá wá sí ẹ lọ́kàn, tètè fọ̀rọ̀ náà lọ àgbàlagbà kan tó o fọkàn tán.​—Wo Orí 14 nínú ìwé yìí, fún àlàyé síwájú sí i.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”​—Sáàmù 34:18.

ÌMỌ̀RÀN

Kọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ nígbà tí inú rẹ kò dùn àti ohun tó o rò pé ó fà á. Lẹ́yìn oṣù kan, ka ohun tó o kọ. Ṣé bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe rí lára rẹ ti wá yàtọ̀ báyìí? Tó bá yàtọ̀, kọ ohun tó ràn ẹ́ lọ́wọ́ sílẹ̀.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Kò burú tó o bá sunkún tó o bá tiẹ̀ jẹ́ ọkùnrin. Kódà ìgbà kan wà tí Dáfídì Ọba sọ pé: ‘Ni òru . . . emi fi omije mi rin ìbùsùn mi.”​—Orin Dafidi 6:6, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Àwọn ohun tí mo lè ṣe láti mú ìbànújẹ́ kúrò lọ́kàn mi ni ․․․․․

Àwọn ọ̀rẹ́ mi tí mo lè sún mọ́, tí màá fi lè mú ìbànújẹ́ kúrò lọ́kàn mi ni ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Ǹjẹ́ àǹfààní kankan wà nínú ẹkún sísun?

● Tó o bá ń rí i pé o wà láàárín àwọn èèyàn, báwo nìyẹn ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà tí ìbànújẹ́ bá wà lọ́kàn rẹ?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 96]

“Bí inú mi kò bá dùn, kò yẹ kí n máa dá nìkan wà. Lóòótọ́, ó lè gba pé kí n wà ní èmi nìkan nígbà míì kí n lè ronú jinlẹ̀ láti mọ ohun tó ń ṣe mí, ó tiẹ̀ lè gba pé kí n sunkún pàápàá. Àmọ́ lẹ́yìn ìyẹn, mo mọ̀ pé á dáa kí n wà láàárín àwọn èèyàn kí ọkàn mi lè kúrò nínú ohun tó ń bà mí nínú jẹ́.”​—Christine

[Àtẹ ìsọfúnni/​Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 93]

 Tí mo kọ èrò mi sí

Kí Ìbànújẹ́ Rẹ Lè Fúyẹ́

Kọ tìẹ sí àwọn àlàfo ibí yìí

Ohun tó ṣẹlẹ̀

Olùkọ́ kan sọ̀rọ̀ burúkú sí mi

Ohun tí kò dáa láti ṣe

Mi ò tiẹ̀ ní fọkàn sí ohun tó ń kọ́ wa mọ́

Ohun tó dáa láti ṣe

Àbá: Wo Orí 20 nínú ìwé yìí

Ohun tó ṣẹlẹ̀

Ọ̀rẹ́ mi kan wọ́ mi ńlẹ̀

Ohun tí kò dáa láti ṣe

Màá lọ parọ́ mọ́ ọn lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀

Ohun tó dáa láti ṣe

Àbá: Wo Orí 10 nínú ìwé “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé,” Apá Kejì

Ohun tó ṣẹlẹ̀

Àwọn òbí mi kọ ara wọn sílẹ̀

Ohun tí kò dáa láti ṣe

Màá bínú sí ọ̀kan lára wọn tàbí àwọn méjèèjì

Ohun tó dáa láti ṣe

Àbá: Wo Orí 4 nínú ìwé yìí

Ohun tó ṣẹlẹ̀

․․․․․

Ohun tí kò dáa láti ṣe

․․․․․

Ohun tó dáa láti ṣe

․․․․․

Ohun tó ṣẹlẹ̀

․․․․․

Ohun tí kò dáa láti ṣe

․․․․․

Ohun tó dáa láti ṣe

․․․․․

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 95]

Tó o bá sapá, táwọn ẹlòmíì sì ràn ẹ́ lọ́wọ́, o lè bọ́ nínú ìbànújẹ́ bí ìgbà tó o jáde kúrò nínú kòtò jíjìn