Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àbí Kí N Para Mi Ni?

Àbí Kí N Para Mi Ni?

ORÍ 14

Àbí Kí N Para Mi Ni?

“Ó SÀN fun mi lati kú ju ati wa laaye lọ.” Ta ló sọ ọ̀rọ̀ yìí? Ṣé ẹnì kan tí kò gba Ọlọ́run gbọ́ ni? Ṣé ẹni tó ti fi Ọlọ́run sílẹ̀ ni? Ṣé ẹni tí Ọlọ́run ti kọ̀ ni? Rárá o. Jónà, ọkùnrin kan tó fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run àmọ́ tí nǹkan tojú sú, ló sọ bẹ́ẹ̀.​—Jónà 4:3, Bibeli Yoruba Atọ́ka.

Bíbélì ò sọ pé Jónà fẹ́ para ẹ̀. Síbẹ̀, ohun tó ń bẹ̀bẹ̀ fún nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí jẹ́ ká mọ òótọ́ ọ̀rọ̀ kan tí kò ṣeé já ní koro; òótọ́ ọ̀rọ̀ náà sì ni pé ìbànújẹ́ ńlá lè dé bá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nígbà míì.​—Sáàmù 34:19.

Ìbànújẹ́ ti sorí àwọn ọ̀dọ́ kan kodò débi pé ìgbésí ayé pàápàá tiẹ̀ sú wọn. Ó lè máa ṣe wọ́n bíi ti ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kan tó ń jẹ́ Laura, tó sọ pé: “Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ìbànújẹ́ sábà máa ń sorí mi kodò. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo sì máa ń ronú pé ikú yá jẹ̀sín.” Tó o bá mọ ẹnì kan tó máa ń sọ pé òun fẹ́ para òun, tàbí tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ń wá sí ìwọ náà lọ́kàn, kí lo lè ṣe? Jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ohun tó lè fa irú èròkérò bẹ́ẹ̀.

Ohun Tó Ń Fà Á

Kí ló lè mú kí ẹnì kan ronú pé òun fẹ́ para òun? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè fà á. Àkọ́kọ́ ni pé, “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira” gan-an la wà báyìí, àwọn ọ̀dọ́ sì ń mọ̀ ọ́n lára lọ́nà tó kàmàmà. (2 Tímótì 3:1) Yàtọ̀ síyẹn, àìpé ẹ̀dá lè mú káwọn kan ro ara wọn pin, kí wọ́n sì tún ro gbogbo nǹkan pin. (Róòmù 7:22-24) Ó lè jẹ́ torí pé àwọn èèyàn kan hùwà ìkà sí wọn. Ó sì tún lè jẹ́ pé àìsàn tó ń ṣe wọ́n ló mú kí wọ́n máa ronú pé ikú ló kàn. Lórílẹ̀-èdè kan ẹ̀rí fi hàn pé, tí wọ́n bá rí èèyàn mẹ́wàá tó para wọn, àwọn mẹ́sàn-án lára wọn máa jẹ́ àwọn tó ní oríṣi àrùn ọpọlọ kan tàbí òmíràn. *

Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tí ìṣòro ò lè dé bá o. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé “gbogbo ìṣẹ̀dá ń bá a nìṣó ní kíkérora pa pọ̀ àti ní wíwà nínú ìrora pa pọ̀.” (Róòmù 8:22) Ìyẹn ò sì yọ àwọn ọ̀dọ́ sílẹ̀. Kódà ìbànújẹ́ àwọn ọ̀dọ́ máa ń pọ̀ gan-an nígbà táwọn ohun tí kò dáa bá ṣẹlẹ̀, irú bíi:

Tí èèyàn wọn tàbí ọ̀rẹ́ wọn bá ṣaláìsí

Tí èdèkòyédè bá wà láàárín ìdílé

Tí wọ́n bá fìdí rẹmi níléèwé

Tí olólùfẹ́ wọn bá já wọn jù sílẹ̀

Tí wọ́n bá hùwà ìkà sí wọn (irú bíi kí wọ́n fìyà jẹ wọ́n tàbí kí wọ́n fipá bá wọn lò pọ̀)

Ká sòótọ́, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ọ̀dọ́ ni ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ohun tá a sọ yìí máa ń ṣẹlẹ̀ sí. Kí wá nìdí tí àwọn kan fi máa ń tètè mú àwọn ìṣòro yìí kúrò lọ́kàn ju àwọn míì lọ? Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ pé àwọn ọ̀dọ́ tí gbogbo nǹkan ti sú máa ń parí èrò sí pé kò sí ọ̀nà àbáyọ mọ́ rárá àti pé kò sẹ́ni tó lè ran àwọn lọ́wọ́. Lọ́rọ̀ kan ṣá, ṣe ni irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ ti ro ọ̀rọ̀ ara wọn pin. Kì í ṣe pé ó kàn ń wù wọ́n láti kú o, ìrora ọkàn yẹn ni wọ́n fẹ́ kó dópin.

Kí Lọ̀nà Àbáyọ?

O lè mọ ẹnì kan tó ṣáà ń fẹ́ kí ìrora ọkàn òun dópin débi pé ó pinnu láti para ẹ̀. Tọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe?

Tó o bá ní ọ̀rẹ́ tí ìbànújẹ́ ti sorí ẹ̀ kodò débi pé ó ń ronú pé ó sàn kí òun kú, ṣe ni kó o jẹ́ kó mọ̀ pé ó nílò ìrànlọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, rí i pé o fọ̀rọ̀ náà tó àgbàlagbà kan létí, yálà ó fẹ́ kó o sọ ọ́ tàbí kò fẹ́. Ìwọ gbàgbé ti pé àárín yín lè dà rú. Tó o bá sọ fún àgbàlagbà yẹn, o lè tipa bẹ́ẹ̀ gba ẹ̀mí ọ̀rẹ́ rẹ là!

Tó bá jẹ́ pé ìwọ fúnra rẹ lò ń ronú pé àbí kó o tiẹ̀ para ẹ ńkọ́? Má kàn fi ọ̀rọ̀ náà sínú. Rí i pé o sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fún ẹnì kan, bóyá òbí rẹ, ọ̀rẹ́ rẹ, tàbí ẹlòmíì tí kì í fọ̀rọ̀ rẹ ṣeré, táá tẹ́tí sí ẹ, táá sì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Tó o bá sọ ohun tó ń ṣe ẹ́ fún ẹnì kan, o ò ní kábàámọ̀ láé, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wàá tún máa dúpẹ́ pé o sọ. *

Òótọ́ ni pé tó o bá sọ ìṣòro rẹ fún ẹlòmíì, ìyẹn kò ní kí ìṣòro náà kúrò. Àmọ́ ó lè jẹ́ ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ ẹnì kan tó o lè fọ̀ràn lọ̀ ló máa jẹ́ kí ọ̀ràn náà fúyẹ́ díẹ̀ lọ́kàn rẹ. Ó tiẹ̀ lè jẹ́ kó o mọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà.

Nǹkan Máa Ń Yí Pa Dà

Nígbàkigbà tí nǹkan kan bá ń bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́, máa rántí pé: Kò sí bí ìṣòro kan ṣe lè le tó, bó pẹ́ bó yá nǹkan máa yí pa dà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìbànújẹ́ ti bá Dáfídì tó kọ lára ìwé Sáàmù. Síbẹ̀, ó sọ nínú àdúrà kan tó gbà pé: “Ìwọ ti sọ ọ̀fọ̀ mi di ijó fún mi.”​—Sáàmù 30:11.

Àmọ́ ṣá o, Dáfídì ò retí pé gbogbo ìgbà ni nǹkan á máa dùn yùngbà táá máa yọrí sí ijó fún òun. Ó mọ̀ pé ìṣòro á máa yọjú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ kì í wà títí ayé. Ṣé ìwọ náà ti kíyè sí i pé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe máa ń rí nìyẹn? Lóòótọ́, ó lè dà bíi pé àwọn ìṣòro kan fẹ́ ju agbára èèyàn lọ. Àmọ́, sùúrù ló gbà. Lọ́pọ̀ ìgbà, nǹkan máa ń yí pa dà sí rere. Nígbà míì sì rèé, ṣe ni ìṣòro wa kàn máa fúyẹ́ lọ́nà tá ò rò tẹ́lẹ̀. O sì lè wá rí ọ̀nà kan tí o kò ronú kàn tẹ́lẹ̀ tí wàá máa gbà bá ìṣòro náà yí. Lọ́rọ̀ kan ṣá, àwọn ìṣòro tó ń bani nínú jẹ́ kò ní máa wà bẹ́ẹ̀ títí ayé.​—2 Kọ́ríńtì 4:17.

Àdúrà Ṣe Pàtàkì

Ṣùgbọ́n ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù tá a lè gbà sọ ohun tó ń ṣe wá ni pé ká fi tó Ọlọ́run létí nínú àdúrà. Ìwọ náà lè gbàdúrà bíi ti Dáfídì tó sọ pé: “Yẹ̀ mí wò látòkè délẹ̀, Ọlọ́run, kí o sì mọ ọkàn-àyà mi. Wádìí mi wò, kí o sì mọ àwọn ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè, kí o sì rí i bóyá ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára wà nínú mi, kí o sì ṣamọ̀nà mi ní ọ̀nà àkókò tí ó lọ kánrin.”​—Sáàmù 139:23, 24.

Àdúrà kọjá ohun téèyàn kàn máa ń gbà láti fi yanjú ìṣòro. Ó jẹ́ ọ̀nà kan tá a gbà ń bá Bàbá wa ọ̀run sọ̀rọ̀, Bàbá wa ọ̀run yìí sì fẹ́ kó o “tú ọkàn-àyà [rẹ] jáde” fún òun. (Sáàmù 62:8) Wo àwọn òótọ́ ọ̀rọ̀ tá a sọ nísàlẹ̀ yìí nípa Ọlọ́run:

Ó mọ ohun tó fa ìbànújẹ́ rẹ.​—Sáàmù 103:14.

Ó mọ̀ ẹ́ ju bó o ṣe mọ ara rẹ lọ.​—1 Jòhánù 3:20.

‘Ó bìkítà nípa rẹ.’​—1 Pétérù 5:7.

Nínú ayé tuntun, Ọlọ́run máa “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [rẹ].”​—Ìṣípayá 21:4.

Tí Ìṣòro Rẹ Bá Jẹ Mọ́ Ọ̀ràn Ìlera

Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, nígbà míì àìsàn ló máa ń mú kéèyàn máa ronú pé òun máa para òun. Tó bá jẹ́ pé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn, má ṣe jẹ́ kójú tì ẹ́ láti wá ẹni tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jésù pàápàá sọ pé àwọn tó ń ṣàìsàn nílò oníṣègùn. (Mátíù 9:12) Ohun kan tó sì fini lọ́kàn balẹ̀ ni pé púpọ̀ lára àìsàn wọ̀nyẹn ló ṣeé tọ́jú. Ìtọ́jú yẹn sì lè mú kára rẹ yá gágá! *

Bíbélì ṣèlérí kan tó tuni nínú gan-an, ìyẹn ni pé nínú ayé tuntun Ọlọ́run, “kò [ní] sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Ọlọ́run sọ pé ní ìgbà yẹn, “àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà.” (Aísáyà 65:17) Àmọ́ ní báyìí ná, ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti máa forí ti àwọn ìṣòro tó wà nínú ayé yìí, kó o mọ̀ dájú pé tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run, àárẹ̀ ọkàn máa di ohun ìgbàgbé.​—Ìṣípayá 21:1-4.

KÀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 9, NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ṣé gbogbo nǹkan tó o bá ń ṣe pátá làwọn òbí ẹ máa ń fẹ́ mọ̀, títí kan àwọn nǹkan tí kò wù ẹ́ pé kó o sọ fáwọn èèyàn? Ǹjẹ́ o rò pé wàá lè ní àṣírí tìẹ báyìí?

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 7 Àmọ́ ṣá o, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọ̀dọ́ tó ní àrùn ọpọlọ ni kì í pa ara wọn.

^ ìpínrọ̀ 18 Ibòmíì tún wà táwọn Kristẹni tí ìbànújẹ́ ti sorí wọn kodò lè wá ìrànlọ́wọ́ lọ, ìyẹn ni ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà ìjọ.​—Jákọ́bù 5:14, 15.

^ ìpínrọ̀ 31 Wo Orí 13 nínú ìwé yìí, fún àlàyé síwájú sí i.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín.”​—Fílípì 4:6, 7.

ÌMỌ̀RÀN

Bí ìbànújẹ́ bá fẹ́ gbà ẹ́ lọ́kàn, rìn jáde lọ, kó o rìn kánmọ́kánmọ́ káàkiri fúngbà díẹ̀. Tó o bá jáde síta tó o sì dára yá, ìyẹn lè jẹ́ kí ọkàn rẹ fúyẹ́ kí ara rẹ sì yá gágá.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Bí ẹnì kan bá pa ara rẹ̀, kì í ṣe ara rẹ̀ nìkan ló ṣàkóbá fún, ó tún ṣàkóbá fún àwọn èèyàn rẹ̀ náà.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bó bá ń ṣe mí bíi pé mi ò wúlò fún nǹkan kan àti pé kò sẹ́ni tó fẹ́ràn mi, ẹni tí màá sọ fún ni (kọ orúkọ ẹni tí o lè fọ̀rọ̀ ara rẹ lọ̀) ․․․․․

Ohun rere kan tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi, tó sì ń múnú mi dùn tí mo bá ti rántí ni ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Àwọn ìṣòro tó le gan-an pàápàá kì í wà títí ayé. Tó o bá ń ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí, báwo nìyẹn ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

● Téèyàn bá pa ara rẹ̀, ọ̀nà wo ló gbà di ìṣòro tirẹ̀ kún ti ẹlòmíì?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 104]

“Nígbà míì, ìbànújẹ́ mi máa ń pọ̀ lápọ̀jù débi pé ó máa ń wù mí pé kí n tiẹ̀ kú, àmọ́ ní báyìí ara mi ti yá dáadáa, ọpẹ́lọpẹ́ àdúrà tí mò ń gbà láìdabọ̀ àti ìtọ́jú tí mo gbà.”​—Heidi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 100]

Bí Ìṣòro Rẹ Bá Fẹ́ Pin Ẹ́ Lẹ́mìí

Ìgbà míì wà tí ìṣòro máa ń fẹ́ pin àwọn olóòótọ́ èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn pàápàá lẹ́mìí. Wo àwọn àpẹẹrẹ kan.

Rèbékà: “Bí ó bá jẹ́ pé bí ó ti rí nìyí, èé ṣe tí mo fi wà láàyè gan-an?”​Jẹ́nẹ́sísì 25:22.

Mósè: “Jọ̀wọ́ kúkú pa mí dànù, . . . má sì ṣe jẹ́ kí n fojú rí ìyọnu àjálù mi.”​Númérì 11:15.

Èlíjà: “Jèhófà, gba ọkàn mi kúrò, nítorí èmi kò sàn ju àwọn baba ńlá mi.”​1 Àwọn Ọba 19:4.

Jóòbù: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fi mí pa mọ́ sínú Ṣìọ́ọ̀lù, . . . pé ìwọ yóò yan àkókò kan kalẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi!”​Jóòbù 14:13.

Gbogbo àwọn tá a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ yìí ni nǹkan yí pa dà sí rere fún nígbà tó yá, àní lọ́nà táwọn pàápàá ò rò tẹ́lẹ̀. Mọ̀ dájú pé nǹkan lè yí pa dà sí rere fún ìwọ náà!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 102]

Ṣe ni ìdààmú ọkàn tó ń mú kéèyàn ro ara rẹ̀ pin dà bí ìkùukùu lójú sánmà, kì í pẹ́ tó fi máa ń kọjá lọ