Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ó Burú Kéèyàn Tiẹ̀ Láṣìírí Ni?

Ṣé Ó Burú Kéèyàn Tiẹ̀ Láṣìírí Ni?

ORÍ 15

Ṣé Ó Burú Kéèyàn Tiẹ̀ Láṣìírí Ni?

Fi àmì ✔ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ohun tó o rò pé wàá ṣe tí àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí bá ṣẹlẹ̀:

1. O wà nínú yàrá rẹ, o sì pa ilẹ̀kùn dé, àmọ́ àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n rẹ kàn wọlé lójijì láì kan ilẹ̀kùn.

□ ‘Ìyẹn ò burú. Bí èmi náà ṣe máa ń wọ yàrá wọn nìyẹn.’

□ ‘Àrífín nìyẹn kẹ̀ẹ! Bó bá jẹ́ pé mò ń múra lọ́wọ́ ńkọ́?’

2. Bó o ṣe ń wọlé láti ibì kan làwọn òbí rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í da ìbéèrè bò ẹ́ pé: “Ibo lo lọ? Kí lo ṣe lọ́hùn-ún? Àwọn wo lẹ jọ lọ?”

□ ‘Ìyẹn ò burú. Bí wọn ò tiẹ̀ béèrè gan-an, màá sọ fún wọn.’

□ ‘Inú máa bí mi gan-an! Wọn ò fọkàn tán mi nìyẹn!’

NÍGBÀ tó o wà lọ́mọdé, bóyá lò ń fi nǹkan kan pa mọ́ nípa ara rẹ. Báwọn àbúrò ẹ bá já wọ yàrá ẹ, o ò ní torí ìyẹn bínú. Táwọn òbí ẹ bá bi ẹ́ ní ìbéèrè, o kì í rò ó lẹ́ẹ̀mejì kó o tó dá wọn lóhùn. Nígbà yẹn, o ò ní ohunkóhun tí o kò fẹ́ kí ẹlòmíì mọ̀. Àmọ́ nǹkan ti wá yí pa dà báyìí, ó wá di pé o kì í fẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó ò ń ṣe nígbà míì. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14] kan tó ń jẹ́ Corey sọ pé: “Inú mi máa ń dùn tí n bá lè fàwọn nǹkan kan pa mọ́ sọ́kàn ara mi.” Jẹ́ ká wo ọ̀nà méjì tó ti lè ṣòro fún ẹ láti ṣe àwọn nǹkan kan láṣìírí.

Tí O Bá Fẹ́ Dá Wà

Ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣe pàtàkì ló lè mú kó o fẹ́ dá wà. Ó lè jẹ́ pé o kàn fẹ́ “sinmi díẹ̀” ni. (Máàkù 6:31) Ó sì lè jẹ́ pé ṣe lo fẹ́ gbàdúrà, tó o wá fẹ́ ṣe ohun tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, pé: “Lọ sínú yàrá àdáni rẹ àti, lẹ́yìn títi ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ.” (Mátíù 6:6; Máàkù 1:35) Àmọ́, ìṣòro tó wà níbẹ̀ ni pé, tó o bá ti ilẹ̀kùn yàrá rẹ (ìyẹn tó o bá ní yàrá tìẹ), àwọn òbí rẹ lè má mọ̀ pé ńṣe lò ń gbàdúrà. Àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ sì lè má mọ̀ pé o máa ń fẹ́ dá wà nígbà míì.

Ohun tó o lè ṣe. Kàkà tó o máa fi jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí fa awuyewuye, ṣe ohun tó tẹ̀ lé e yìí:

● Tí ìṣòro náà bá jẹ́ láàárín ìwọ àtàwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ, ẹ lè jọ fi àwọn ìlànà kan tó rọrùn lélẹ̀, táá jẹ́ kó o lè máa ráyè dá wà. Tó bá pọn dandan, ẹ lè ní káwọn òbí yín ràn yín lọ́wọ́. *

● Tó bá sì jẹ́ láàárín ìwọ àtàwọn òbí rẹ ni, gbìyànjú láti lóye èrò wọn lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kan tó ń jẹ́ Rebekah sọ pé: “Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn òbí mi máa ń fẹ́ wo ohun tí mò ń ṣe. Èmi náà sì mọ̀ lóòótọ́ pé bí mo bá bímọ, bí èmi náà á ṣe máa ṣe nìyẹn, pàápàá torí àwọn ìdẹwò tí àwọn ọ̀dọ́ máa ń ní lóde òní!” Ǹjẹ́ ìwọ náà lè gbìyànjú láti mọ ohun tó fà á táwọn òbí ẹ fi máa ń fẹ́ mọ ohun tó ò ń ṣe?​—Òwe 19:11.

● Fi òótọ́ inú bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ mo ti ṣe ohun kan rí tó ń jẹ́ kí ara máa fu àwọn òbí mi pé ohun tí kò dáa ni mo fẹ́ ṣe tí mo fi ti ilẹ̀kùn mọ́rí? Ṣé kì í ṣe pé wọ́n máa ní láti lo oríṣiríṣi ọgbọ́n kí wọ́n tó lè mọ àwọn nǹkan kan nípa mi, torí pé mo ti máa ń fi àwọn ohun tí mò ń ṣe pa mọ́ jù?’ Tí nǹkan méjèèjì yìí ò bá rí bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ tí àwọn òbí rẹ ò fọkàn tán ẹ, rọra fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ṣàlàyé bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ fún wọn. Tẹ́tí sí wọn dáádáá kó o lè mọ ohun tó ń kọ wọ́n lóminú, kí ìwọ náà sì rí i pé o kì í ṣe àwọn nǹkan kan tó ń dá kún ìṣòro yẹn.​—Jákọ́bù 1:19.

Tí O Bá Fẹ́ Yan Ọ̀rẹ́

Táwọn ọmọdé bá ti ń di ọ̀dọ́, wọ́n sábà máa ń fẹ́ lọ́rẹ̀ẹ́ tiwọn, tó fi hàn pé kò burú bí ìwọ náà bá fẹ́ ní àwọn ọ̀rẹ́ tìẹ. Bákan náà, kò burú báwọn òbí rẹ bá fẹ́ mọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtàwọn nǹkan tẹ́ ẹ jọ máa ń ṣe. Àmọ́ nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé àwọn òbí ẹ ti ń tojú bọ ọ̀rọ̀ rẹ jù. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kan tó ń jẹ́ Amy sọ pé: “Mo fẹ́ máa lo fóònù mi àti ibi tí mo ti ń gba lẹ́tà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì láìjẹ́ pé àwọn òbí mi á máa yọjú wo ohun tí mò ń ṣe ní gbogbo ìgbà, tí wọ́n á sì máa bi mí pé ta ni mò ń bá sọ̀rọ̀.”

Ohun tó o lè ṣe. Dípò tí wàá fi jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí dá wàhálà sílẹ̀ láàárín ìwọ àtàwọn òbí rẹ, o lè ṣe àwọn nǹkan yìí:

● Jẹ́ káwọn òbí rẹ mọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, má fi wọ́n pa mọ́. Ó ṣe tán, o ò ní fẹ́ káwọn òbí rẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ máa fimú fínlẹ̀ torí pé wọ́n fẹ́ mọ àwọn tó ò ń bá rìn, àmọ́ kò sígbà tí wọn ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ tó o bá ń fàwọn ọ̀rẹ́ rẹ pa mọ́. Fi sọ́kàn pé, báwọn òbí rẹ bá ṣe mọ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tó, bẹ́ẹ̀ ló ṣeé ṣe kí ọkàn wọn balẹ̀ tó nípa àwọn tó ò ń bá rìn.

● Má tan ara rẹ jẹ: Ṣé o kàn fẹ́ láṣìírí tìẹ ni, àbí ṣe lo fẹ́ máa ṣe àwọn nǹkan kan tí ẹlòmíì ò gbọ́dọ̀ gbọ́? Ọmọ ọdún méjìlélógún [22] kan tó ń jẹ́ Brittany sọ pé: “Bó o bá ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí rẹ, tí wọ́n sì ń fura sí ohun kan tó ò ń ṣe, ohun tó yẹ kó wá sí ẹ lọ́kàn ni pé: ‘Ohun tí mò ń ṣe kò burú, kí ni mo wá fẹ́ máa fi pa mọ́ fún?’ Àmọ́ tó o bá ṣì ń rí i pé ó di dandan kó o fi ohun tó ò ń ṣe pa mọ́, á jẹ́ pé nǹkan míì wà níbẹ̀ nìyẹn.”

Ohun Tí Ìwọ Náà Lè Ṣe

Ní báyìí, wá ronú nípa àwọn ohun tí ìwọ náà lè ṣe láti yanjú àwọn ìṣòro tó o máa ń ní tó o bá fẹ́ ṣe àwọn nǹkan kan ní àṣírí. Kọ ìdáhùn rẹ sórí àwọn ìlà tó wà níwájú ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan tó tẹ̀ lé e yìí:

Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́: Mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro. Àwọn nǹkan wo lo máa ń ṣe tó máa wù ẹ́ pé kó o ṣe láṣìírí?

․․․․․

Ìgbésẹ̀ Kejì: Ronú nípa èrò àwọn òbí rẹ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Kí lo rò pé ó fà á tí wọ́n fi fẹ́ mọ ohun tó ò ń ṣe?

․․․․․

Ìgbésẹ̀ Kẹta: Wá ojútùú. Àṣìṣe wo lo rò pé ò ń ṣe tó lè máa dá kún ìṣòro náà? Àwọn àtúnṣe wo lo lè ṣe láti yanjú àṣìṣe tó o kọ yìí? Kí lo máa fẹ́ kí àwọn òbí rẹ ṣe láti yanjú àwọn ìṣòro tó o máa ń ní yìí?

․․․․․

Ìgbésẹ̀ Kẹrin: Ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Sọ ohun tó o lè ṣe tí ìwọ àti àwọn òbí rẹ á fi lè jọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ń wù ẹ́ pé kó o ṣe láṣìírí.

․․․․․

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ṣé ọ̀kan lára àwọn òbí rẹ ti ṣaláìsí ni? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ibo lo ti lè rí ìtùnú?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 14 Wo Orí 6 nínú ìwé yìí, fún àlàyé síwájú sí i.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú.”​—2 Tímótì 2:15.

ÌMỌ̀RÀN

Tó o bá ń bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ nípa bó o ṣe lè máa láṣìírí tìẹ, má ṣàríwísí. Ṣe ni kó o sọ ohun tó ń kọ ẹ́ lóminú. Kí ni ìyàtọ̀ méjèèjì? Ìyàtọ̀ rẹ̀ ni pé tó o bá ń ṣàríwísí ṣe ni wàá kàn máa dá àwọn òbí rẹ lẹ́bi. Àmọ́ tó bá jẹ́ ohun tó ń kọ ẹ́ lóminú lo sọ, ẹ ó lè jọ ronú nípa bẹ́ẹ̀ ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Tó bá jẹ́ pé o kì í fi gbogbo nǹkan pa mọ́ fáwọn òbí rẹ, wọn ò ní máa fura sí ẹ.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Kí àwọn òbí mi (tún) lè fọkàn tán mi, màá ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tó fi tọ́ káwọn òbí rẹ fẹ́ láti máa mọ àwọn ohun tó o bá ń ṣe?

● Bó o bá sapá láti mọ bó ṣe yẹ kó o máa bá àwọn òbí ẹ sọ̀rọ̀, báwo nìyẹn ṣe lè jẹ́ kó o mọ bí wàá ṣe máa bá àwọn tó dàgbà jù ẹ́ lọ sọ̀rọ̀?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 108]

“Àwọn òbí kì í fẹ́ kí ohun tí kò dáa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn, ìdí nìyẹn tó fi máa ń dà bíi pé wọ́n tojú bọ ọ̀rọ̀ rẹ nígbà míì. O lè rò pé kò yẹ kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ká sòótọ́, bí èmi náà bá jẹ́ òbí, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ohun tí wọ́n ṣe yẹn lèmi náà máa ṣe.”​—Alana

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 109]

Bó ṣe jẹ́ pé o gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kó o tó gbowó, o gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn nǹkan tó dáa kí wọ́n tó lè fọkàn tán ẹ