Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Táyà Mi Fi Máa Ń Já Láti Sọ Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nílé Ìwé?

Kí Nìdí Táyà Mi Fi Máa Ń Já Láti Sọ Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nílé Ìwé?

ORÍ 17

Kí Nìdí Táyà Mi Fi Máa Ń Já Láti Sọ Ohun Tí Mo Gbà Gbọ́ Nílé Ìwé?

“Àwọn ìgbà kan wà tí mo ti láǹfààní láti sọ ohun tí mo gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì nílé ẹ̀kọ́. Àmọ́ ṣe ni mo dákẹ́.”​—Kaleb.

“Olùkọ́ wa béèrè lọ́wọ́ gbogbo kíláàsì pé kí lèrò wa nípa ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n tó sọ pé ara ẹranko lèèyàn ti wá. Mo mọ̀ pé àǹfààní ńlá nìyí fún mi láti sọ ohun tí mo gbà gbọ́. Àmọ́ ṣe lẹ̀rù bà mí, tí mo kàn dákẹ́. Lẹ́yìn náà, ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí wá ń dùn mí gan-an.”​—Jasmine.

BÓ O bá jẹ́ Kristẹni, irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Kaleb àti Jasmine yìí lè ti ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà rí. Ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó o ti kọ́ nínú Bíbélì lè wú ìwọ náà lórí bíi tiwọn, kó o sì fẹ́ sọ ọ́ fáwọn ẹlòmíì. Àmọ́, o rí i pé bó o bá ti ń ronú nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tó o bá sọ ọ́, ńṣe lẹ̀rù máa ń bà ẹ́. Síbẹ̀, o lè dẹni tó ń fìgboyà sọ̀rọ̀. Báwo lo ṣe lè ṣe é? O lè lo àwọn àbá yìí:

1. Mọ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù. Bó o bá ti ń ronú nípa bó o ṣe máa ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́, ẹ̀rù lè máa bà ẹ́ torí ohun tó lè ṣẹlẹ̀! Àmọ́ nígbà míì, ẹ̀rù tó ń bà ẹ́ lè dín kù tó o bá sọ ohun tó ń bà ẹ́ lẹ́rù tàbí tó o kọ ọ́ sílẹ̀.

Kọ èrò rẹ síwájú gbólóhùn yìí:

● Bí mo bá ń sọ ohun tí mo gbà gbọ́ ní ilé ìwé, nǹkan tí mo rò pé ó lè ṣẹlẹ̀ ni: ․․․․․

Àmọ́ fọkàn balẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ làwọn nǹkan yẹn ń bà lẹ́rù. Ó ń ba àwọn ọ̀dọ́ míì tí wọ́n jẹ́ Kristẹni bíi tìẹ náà lẹ́rù. Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14] kan tó ń jẹ́ Christopher sọ pé: “Mo máa ń bẹ̀rù pé àwọn ẹlẹgbẹ́ mi á fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì tún lè máa sọ fáwọn ẹlòmíì pé mo gba wèrè mẹ́sìn.” Kaleb, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí, sọ pé: “Mo máa ń bẹ̀rù pé ẹnì kan lè bi mí ní ìbéèrè tí mi ò ní lè dáhùn.”

2. Fi dára ẹ lójú pé wàá ṣe é. Ṣé ohun tí kò lè ṣẹlẹ̀ rárá ló ń bà ẹ́ lẹ́rù ni? Ó lè ṣàì rí bẹ́ẹ̀. Ọmọ ogún [20] ọdún kan tó ń jẹ́ Ashley sọ pé: “Àwọn ọmọ kan máa ń ṣe bíi pé àwọn fẹ́ gbọ́rọ̀ mi. Àmọ́ tó bá yá wọ́n á wá máa lo ọ̀rọ̀ tí mo sọ láti fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ lójú àwọn yòókù.” Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Nicole, sọ pé: “Ọmọ kan fi ẹsẹ Bíbélì kan nínú Bíbélì tiẹ̀ wé tinú Bíbélì tèmi, ó rí i pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò yàtọ̀ síra. Ló bá ní wọ́n ti yí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì mi pa dà. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá mi lójijì! Mi ò mohun tí mo lè sọ.” *

Irú àwọn nǹkan báyìí lè fẹ́ bà ẹ́ lẹ́rù gan-an! Àmọ́, dípò kó o torí ìyẹn panu mọ́, ńṣe ni kó o fi dára rẹ lójú pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ní ṣàì ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó bá jẹ́ Kristẹni. (2 Tímótì 3:12) Ọmọ ọdún mẹ́tàlá kan tó ń jẹ́ Matthew sọ pé: “Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣe inúnibíni sáwọn ọmọlẹ́yìn òun, torí náà ó dá wa lójú pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa fẹ́ràn wa nítorí ohun tá a gbà gbọ́.”​—Jòhánù 15:20.

3. Ronú nípa àǹfààní tó wà níbẹ̀. Ǹjẹ́ àǹfààní kankan tiẹ̀ lè wà nínú kéèyàn máa sọ ohun tó gbà gbọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń fi èèyàn ṣe yẹ̀yẹ́? Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] kan tó ń jẹ́ Amber gbà pé àǹfààní wà níbẹ̀. Ó sọ pé: “Kò rọrùn rárá láti ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn tí kò ka Bíbélì sí, àmọ́ ṣe ló máa jẹ́ kó o túbọ̀ lóye ohun tó o gbà gbọ́.”​—Róòmù 12:2.

Tún pa dà lọ ka ohun tó o kọ sílẹ̀ pé ó ń bà ẹ́ lẹ́rù ní Àbá 1. Wá ronú nípa àǹfààní méjì, ó kéré tán, tó lè wà níbẹ̀ tó ò bá bẹ̀rù láti sọ ohun tó o gbà gbọ́, kó o sì kọ ọ́ sórí ìlà yìí.

1 ․․․․․

2 ․․․․․

Ohun tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Tó o bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́, báwo ló ṣe lè jẹ́ kí yẹ̀yẹ́ táwọn ojúgbà ẹ ń fi ẹ́ ṣe dín kù? Báwo ló ṣe máa jẹ́ kíwọ fúnra rẹ dára ẹ lójú? Báwo ló ṣe lè jẹ́ kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run? Báwo ló ṣe máa jẹ́ kí Jèhófà túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ?​—Òwe 23:15.

4. Múra sílẹ̀. Ìwé Òwe 15:28 sọ pé: “Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn.” Yàtọ̀ sí ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tó o máa sọ, tún gbìyànjú láti ronú kan àwọn ìbéèrè tí wọ́n lè bi ẹ́. Ṣe ìwádìí lórí àwọn ìbéèrè yẹn, kó o sì múra ìdáhùn tó máa rọ̀ ẹ́ lọ́rùn.​—Wo àtẹ tá a pè ní “ Múra Ohun Tó O Máa Sọ Sílẹ̀,” lójú ìwé 127.

5. Bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. Bó o bá ti ṣe tán láti sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì, báwo lo ṣe lè bẹ̀rẹ̀? Oríṣiríṣi ọ̀nà lo lè gbà bẹ̀rẹ̀. Lọ́nà kan, a lè fi sísọ̀rọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́ wé wíwẹ̀ lódò: Àwọn kan máa ń rọra wọnú odò; àwọn míì máa ń bẹ́ sódò. Lọ́nà kan náà, o lè rọra bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ láìtíì mú ti ẹ̀sìn wọ̀ ọ́, kó o fi mọ̀ bóyá wọ́n máa gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ. Àmọ́, tó o bá rí i pé ẹ̀rù máa ń bà ẹ́ nítorí ohun tó lè ṣẹlẹ̀ bí wọn ò bá fẹ́ gbọ́, o kàn lè dédé bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ bí ìgbà téèyàn bẹ́ sódò. (Lúùkù 12:11, 12) Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Andrew sọ pé: “Ó máa ń rọ̀ mí lọ́rùn kí n kàn bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ nípa ohun tí mo gbà gbọ́ ju kí n kọ́kọ́ máa ronú nípa bí mo ṣe máa sọ ọ́. Tí mo bá ti lè bẹ̀rẹ̀, ó sábà máa ń rọ̀ mí lọ́rùn ju bí mo ṣe rò lọ!” *

6. Jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Sólómọ́nì sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n máa ń ronú kó tó hùwà.” (Òwe 13:16, Bíbélì Today’s English Version) Bó ṣe jẹ́ pé o kò ní fò sínú odò tí kò jìn rárá, ó yẹ kó o ṣọ́ra kó o má lọ tọrùn bọ àríyànjiyàn tí ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Rántí pé ìgbà míì wà tó yẹ kó o sọ̀rọ̀, àwọn ìgbà míì sì wà tó yẹ kó o dákẹ́. (Oníwàásù 3:1, 7) Jésù pàápàá kì í fèsì ìbéèrè tí wọ́n bá bi í nígbà míì.​—Mátíù 26:62, 63.

Tó o bá wá fẹ́ dáhùn ìbéèrè wọn, ṣe ni kó o fọgbọ́n dáhùn ní ṣókí. Bí àpẹẹrẹ, tọ́mọ kan tẹ́ ẹ jọ wà ní ilé ìwé bá fẹ́ tì ẹ́ mu sìgá tó wá ń bi ẹ́ pé, ‘Kí ló dé tíwọ kì í mu sìgá?’ O lè dá a lóhùn pé, ‘Mi ò fẹ́ fa ìdọ̀tí ságbárí ni!’ Ohun tó bá wá sọ tẹ̀ lé e ló máa pinnu bóyá wàá ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fún un.

Bó o bá tẹ̀ lé àbá mẹ́fà tá a sọ nínú orí yìí, wàá lè “wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà” ìgbàgbọ́ rẹ. (1 Pétérù 3:15) Àmọ́ ṣá o, pé o múra tán láti ṣàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ nígbàkigbà kò ní kí ẹ̀rù má bà ẹ́ mọ́ o. Ohun tí ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Alana sọ ni pé: “Bó o bá lè ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíì bó tiẹ̀ jẹ́ pé àyà rẹ ń já, ṣe ló máa dà bíi pé o ti ṣe àṣeyọrí ńlá kan, ìyẹn ni pé o borí ìbẹ̀rù rẹ, o kò sì wò ó pé nǹkan lè yíwọ́. Tí wọ́n bá wá gba ohun tó o sọ, ayọ̀ ẹ á tún légbá kan! Inú ẹ máa dùn pé o fìgboyà sọ ohun tó o gbà gbọ́ jáde.”

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ṣé wàhálà ilé ìwé ti pọ̀ jù fún ẹ ni? Wo ohun tó o lè ṣe nípa rẹ̀.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 10 Àwọn tó túmọ̀ Bíbélì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ máa ń fi ọ̀rọ̀ tó yàtọ̀ síra ṣàlàyé ohun kan náà. Àmọ́ ṣá o, àwọn kan lo ọ̀rọ̀ tó bá àwọn èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu dáadáa ju àwọn míì lọ.

^ ìpínrọ̀ 18 Wo àpótí tá a pè ní “ Àwọn Ìbéèrè Tó O Lè Fi Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀,” lójú ìwé 124.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Kí ẹ wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ yín ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n kí ẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”​—1 Pétérù 3:15.

ÌMỌ̀RÀN

Dípò tí wàá kàn fi máa sọ àwọn ohun tó yẹ káwọn ọmọ kíláàsì rẹ gbà gbọ́ tàbí ohun tí kò yẹ kí wọ́n gbà gbọ́ fún wọn, ṣe ni kó o fìgboyà sọ ohun tí ìwọ gbà gbọ́ àti ìdí tó o fi rò pé ó bọ́gbọ́n mu.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Bó o ṣe ń fi ìlànà Bíbélì sílò lè wu àwọn ọmọ kíláàsì rẹ kan, àmọ́ ojú lè máa tì wọ́n láti béèrè nípa àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ẹ̀sìn tó ò ń ṣe.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Ọmọ kíláàsì mi tí mo lè sọ àwọn ohun tí mo gbà gbọ́ fún ni [kọ orúkọ ẹnì kan ó kéré tán] ․․․․․

Ọ̀rọ̀ tí mo rò pé ó máa wu ẹni yẹn láti gbọ́ jù ni ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí lo rò pé ó lè fà á táwọn ọmọ ilé ìwé rẹ fi máa ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ẹ̀sìn rẹ?

● Tó o bá wá fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́, kí nìdí tó fi yẹ kó o sọ ọ́ lọ́nà tó máa fi hàn pé ó dá ẹ lójú?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 126]

“Nígbà tí mo ṣì wà lọ́mọdé, mi kì í fẹ́ ṣe ohun tó yàtọ̀ sí tàwọn ọmọdé yòókù. Àmọ́ nígbà tó yá, mo wá ń rí bí ìgbàgbọ́ mi ṣe ń jẹ́ kí ayé mi dára ju tiwọn lọ. Èyí túbọ̀ fún mi nígboyà, ó sì ń jẹ́ kí ohun tí mo gbà gbọ́ wú mi lórí.”​—Jason

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 124]

 Àwọn Ìbéèrè Tó O Lè Fi bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀

“Kí làwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe nígbà ọlidé?” [Tó bá ti dáhùn, sọ àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn rẹ, tó o fẹ́ ṣe fún un, irú bíi lílọ sí àpéjọ àgbègbè tàbí bó o ṣe fẹ́ lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run.]

● Sọ ohun kan tó o gbọ́ nínú ìròyìn, kó o wá béèrè pé: “Ṣé ìwọ náà gbọ́ ìròyìn yẹn? Kí lo rò nípa ẹ̀?”

“Ṣé o rò pé ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ lágbàáyé báyìí [tàbí ìṣòro míì] tún ṣì lè dáa? [Jẹ́ kó dáhùn.] Kí nìdí tó o fi rò bẹ́ẹ̀?”

“Ẹ̀sìn wo lò ń ṣe?”

“Ibo lo rò pé o máa wà lọ́dún márùn-ún sí ìgbà tá a wà yìí?” [Tó bá ti dáhùn, sọ àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run tó o fẹ́ ṣe fún un.]

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 127]

 (Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Tí mo kọ èrò mi sí

Múra Ohun Tó O Máa Sọ Sílẹ̀

Ṣe ẹ̀dà ojú ìwé yìí!

Àbá: Jíròrò ìsọfúnni tó wà nínú àtẹ yìí pẹ̀lú àwọn òbí àtàwọn ọ̀dọ́ tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni. Kọ ìdáhùn rẹ sínú àwọn àlàfo tó wà níbẹ̀. Kó o wá gbìyànjú láti ronú kan àwọn ìbéèrè míì táwọn ọmọ kíláàsì ẹ lè bi ẹ́, kó o sì múra ìdáhùn tó máa rọ̀ ẹ́ lọ́rùn láti fi fèsì sílẹ̀.

Àìdásí-tọ̀túntòsì

Ìbéèrè

Kí ló dé tó o kì í kí àsíá? Ṣé o ò fẹ́ràn orílẹ̀-èdè ẹ ni?

Ìdáhùn

Mo bọ̀wọ̀ fún orílẹ̀-èdè tí mo wà àmọ́ mi ò ní jọ́sìn rẹ̀.

Ìbéèrè Míì

Ṣé pé o ò ní jà fún orílẹ̀-èdè rẹ?

Ìdáhùn

Mi ò ní jà o, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè míì náà kò ní wá bá orílẹ̀-èdè yìí jà.

Ẹ̀jẹ̀

Ìbéèrè

Kí ló dé tó ò fi ní gba ẹ̀jẹ̀ sára?

Ìdáhùn

Mo lè gbà kí wọ́n fa àwọn nǹkan míì tí kò ní ṣàkóbá fún mi sí mi lára, pàápàá àwọn téèyàn ò lè tipa rẹ̀ kó àrùn Éèdì tàbí àrùn mẹ́dọ̀wú. Àmọ́ Bíbélì sọ pé ká ta kété sí ẹ̀jẹ̀, ìdí nìyẹn témi kì í fi í gba ẹ̀jẹ̀ sára.

Ìbéèrè Míì

Tó bá jẹ́ pé o máa kú tó ò bá gba ẹ̀jẹ̀ ńkọ́? Ṣé Ọlọ́run ò lè torí ìyẹn dárí jì ẹ́ ni?

Ìdáhùn

․․․․․

Yíyàn kálukú

Ìbéèrè

Ẹ̀sìn kan náà ṣáà ni ìwọ àti lágbájá ń ṣe, òun sì ṣe nǹkan báyìí báyìí. Kí ló wádé tíwọ ò fi lè ṣe é?

Ìdáhùn

Wọ́n ń kọ́ wa ní ìlànà Ọlọ́run, àmọ́ wọn kì í fipá mú wa tẹ̀ lé e! Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló máa yan ohun tóun máa ṣe.

Ìbéèrè Míì

Ṣé kì í ṣe pé ẹ̀sìn yín ń gba ìgbàkugbà láyé nìyẹn?

Ìdáhùn

․․․․․

Ìṣẹ̀dá

Ìbéèrè

Kí nìdí tí o kò fi gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́?

Ìdáhùn

Kí nìdí tó fi yẹ kí n gbà á gbọ́? Ẹ̀kọ́ tó jẹ́ pé àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n tún ń pè ní ọ̀jọ̀gbọ́n gan-an kò fẹnu kò lórí ẹ̀!

Ìbéèrè Míì

․․․․․

Ìdáhùn

․․․․․

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 125]

Sísọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ dà bí ẹní fẹ́ wẹ̀ lódò. O lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ bí ìgbà tó o rọra wọnú odò, tàbí kó o kàn dédé bẹ̀rẹ̀ bíi pé o bẹ́ sódò!