Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọgbọ́n Wo Ni Mo Lè Dá sí Wàhálà Ilé Ìwé?

Ọgbọ́n Wo Ni Mo Lè Dá sí Wàhálà Ilé Ìwé?

ORÍ 18

Ọgbọ́n Wo Ni Mo Lè Dá sí Wàhálà Ilé Ìwé?

“Wàhálà tójú mi ń rí nílé ìwé máa ń pọ̀ gan-an débi pé ó máa ń ṣe mí bíi kí n máa sunkún kí n máa kígbe gan-an.”​—Sharon.

“Bó o tiẹ̀ dàgbà ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ìyẹn ò ní kí wàhálà tójú ẹ ń rí nílé ìwé dín kù, ohun tó ń fà á ló kàn lè yí pa dà.”​—James.

ṢÉ Ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé àwọn òbí ẹ ò mọ irú wàhálà tójú ẹ ń rí nílé ìwé? Wọ́n lè máa sọ fún ẹ pé o ò ṣáà sanwó ilé, o ò tọ́mọ, o ò sì lọ́gàá ibi iṣẹ́ tó ń dà ẹ́ láàmú. Lójú tìẹ sì rèé, o lè máa wò ó pé bí nǹkan ò ṣe rọrùn fún àwọn òbí ẹ náà ni kò ṣe rọrùn fún ìwọ náà, àfi tí wàhálà tìẹ bá tún máa pọ̀ ju tiwọn lọ pàápàá.

Lílọ sí ilé ìwé àti pípadà sílé tiẹ̀ tó wàhálà lọ́tọ̀. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Tara, tó ń gbé nílẹ̀ Amẹ́ríkà, sọ pé: “Àwọn ọmọ ilé ìwé wa sábà máa ń jà nínú mọ́tò tó máa ń gbé wa lọ síléèwé. Ẹni tó ń wakọ̀ á dúró, á lé gbogbo wa bọ́ sílẹ̀, ibẹ̀ la sì máa wà fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ kó tó tún ní ká wọlé ká wá máa lọ.”

Ṣé tó o bá wá dé ilé ìwé, wàhálà tán nìyẹn? Rárá, kì í tán síbẹ̀ o! Ó lè jẹ́ pé ṣe ni wàá tún bẹ̀rẹ̀ àwọn wàhálà tó tẹ̀ lé e yìí:

Wàhálà àwọn olùkọ́.

“Àwọn olùkọ́ mi máa ń fẹ́ kí n ta yọ, kí n gbapò kìíní, àmọ́ wàhálà tí mò ń ṣe kí n bàa lè tẹ́ wọn lọ́rùn ò kéré rárá.”​Sandra.

“Àwọn olùkọ́ máa ń fúngun mọ́ àwọn ọmọ ilé ìwé pé kí wọ́n rí i pé àwọn ta yọ, àgàgà tó bá jẹ́ ọmọ tó mọ̀wé.”​April.

“Bó o tiẹ̀ láwọn ohun tó o fẹ́ fayé ẹ ṣe, ńṣe làwọn olùkọ́ á máa kà ẹ́ sí ẹni tí kò wúlò tí o kò bá ti fẹ́ kàwé débi tí wọ́n rò pé ó yẹ kó o kàwé dé.” *​—Naomi.

Ipa wo ni wàhálà àwọn olùkọ́ máa ń ní lórí rẹ?

․․․․․

Wàhálà àwọn ọ̀dọ́ bíi tìrẹ.

“Nílé ìwé girama, àyè máa ń gba àwọn ọmọ ilé ìwé gan-an, torí náà wọ́n sábà máa ń yàyàkuyà. Tí o kò bá sì ṣe bíi tiwọn, wọ́n á máa pè ẹ́ lọ́dẹ̀.”​Kevin.

“Ojoojúmọ́ ni mo máa ń bá àwọn ipò àtàwọn tó lè mú kí n ṣe ìṣekúṣe tàbí kí n mutí pàdé. Nígbà míì, ó sì máa ń dà bíi pé kí èmi náà ṣe bíi tiwọn.”​—Aaron.

“Ní báyìí tí mo ti pé ọmọ ọdún méjìlá [12], wàhálà tí mo máa ń ní jù ni ọ̀rọ̀ pé kí n ṣáà lẹ́ni tí mò ń fẹ́. Gbogbo àwọn ọmọ ilé ìwé wa ló máa ń sọ pé, ‘Ìgbà wo nìwọ tiẹ̀ máa wá ẹnì kan fẹ́ ní tìẹ?’”​Alexandria.

“Wọ́n fẹ́ fipá mú mi láti máa fẹ́ ọmọkùnrin kan. Nígbà tí mo ní mi ò ṣe, ńṣe ni wọ́n ń sọ pé obìnrin bíi tèmi ni mò ń bá lò pọ̀. Mi ò sì tíì ju ọmọ ọdún mẹ́wàá lọ nígbà yẹn o!”​Christa.

Ipa wo ni wàhálà àwọn ọ̀dọ́ bíi tìrẹ máa ń ní lórí rẹ?

․․․․․

Àwọn nǹkan míì tó jẹ́ wàhálà fún ẹ. Fàmì ✔ sí èyí tó máa ń já ẹ láyà jù nínú àwọn ohun tá a kọ yìí tàbí kó o kọ tìrẹ sísàlẹ̀.

□ Àwọn ìdánwò tẹ́ ẹ fẹ́ ṣe nílé ìwé

□ Iṣẹ́ àṣetiléwá

□ Àwọn ohun táwọn òbí ẹ fẹ́ kó o lé bá

□ Bọ́wọ́ ẹ ṣe máa tẹ àwọn ohun tó o gbà pé o gbọ́dọ̀ lé bá

□ Àwọn tó ń yọ ẹ́ lẹ́nu àtàwọn tó ń fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́

□ Nǹkan míì ․․․․․

Ohun Mẹ́rin Tó O Lè Ṣe Láti Dín Wàhálà Rẹ Kù

Ká sòótọ́, kò sí bí wàá ṣe lè parí ilé ìwé rẹ láìṣe wàhálà kankan rárá. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, tí wàhálà bá tún pọ̀ jù, ó lè ni èèyàn lára. Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n ọba kọ̀wé pé: “Ìnilára pàápàá lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bí ayírí.” (Oníwàásù 7:7) Àmọ́, kò yẹ kó o jẹ́ kí wàhálà tìẹ ṣàkóbá fún ẹ. Nǹkan pàtàkì tó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni pé kó o mọ ohun tó o lè ṣe sí àwọn wàhálà yẹn.

Béèyàn bá fẹ́ wá ọgbọ́n dá sí àwọn wàhálà kan, ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn fẹ́ gbé irin tó wúwo. Ẹni tó bá fẹ́ gbé irin tó wúwo máa ń múra sílẹ̀ dáadáa. Kì í gbé irin tó ju agbára rẹ̀ lọ, ó sì máa rí i pé òun gbé e dáadáa. Tó bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, iṣan ara ẹ̀ á máa lágbára sí i, kò sì ní ṣe ara rẹ̀ léṣe. Àmọ́, tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè ṣèpalára fún iṣan ara rẹ̀, tàbí kó tiẹ̀ kán ara rẹ̀ ní eegun.

Ìwọ náà lè rí nǹkan kan ṣe sí àwọn wàhálà rẹ, kó o sì tún ṣàṣeyọrí nínú àwọn nǹkan tó o fẹ́ ṣe láì ṣèpalára fún ara rẹ. Lọ́nà wo? Ṣe àwọn ohun tá a tò sísàlẹ̀ yìí:

1. Mọ ohun tó ń fa wàhálà náà. Òwe ọlọ́gbọ́n kan sọ pé: “Ọlọgbọn eniyan ti ri ibi tẹlẹ̀, o si pa ara rẹ̀ mọ.” (Òwe 22:3, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Ṣùgbọ́n o kò lè para ẹ mọ́ lọ́wọ́ wàhálà kan tí o kò bá mọ ohun tó ń fa wàhálà ọ̀hún. Torí náà pa dà lọ wo ohun tó o fi àmì ✔ sí pé ó jẹ́ wàhálà fún ẹ níṣàájú. Èwo ló máa ń já ẹ láyà jù báyìí?

2. Ṣèwádìí nípa rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ àṣetiléwá tó pọ̀ jù ló jẹ́ wàhálà fún ẹ, o lè lọ wo àwọn àbá tó wà nínú Orí 13 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì. Tí wọ́n bá sì ń fi ọ̀rọ̀ ṣíṣe ìṣekúṣe pẹ̀lú ọmọ kíláàsì ẹ kan dà ẹ́ láàmú ṣáá, ìmọ̀ràn tó wà nínú Orí 2, 5, àti Orí 15 nínú ìwé yẹn kan náà, máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ gan-an.

3. Má fòní dónìí, fọ̀la dọ́la. Ṣàṣà ni ìṣòro tó máa ń yanjú tí o kò bá wá nǹkan ṣe sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni á tún máa burú sí i, tí á sì máa jẹ́ kí wàhálà rẹ pọ̀ sí i. Tó o bá ti wá pinnu ohun tó o máa ṣe sí ìṣòro náà, tètè ṣe é. Má fi falẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, tó o wá ń sa ipá rẹ láti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, ṣe ni kó o tètè jẹ́ káwọn ọmọ ilé ìwé rẹ mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́ àti pé ìlànà Bíbélì lò ń tẹ̀ lé. Tó o bá tètè jẹ́ kí wọ́n mọ̀, ìyẹn lè jẹ́ kí wàhálà rẹ dín kù gan-an. Ọmọ ogún [20] ọdún kan tó ń jẹ́ Marchet sọ pé: “Gbàrà tá a bá ti wọlé sáà ẹ̀kọ́ tuntun nílé ìwé ni mo ti máa ń dá àwọn ọ̀rọ̀ kan sílẹ̀ tí mo mọ̀ pé ó máa jẹ́ kí n lè ṣàlàyé àwọn ìlànà Bíbélì tí mo gbà gbọ́. Mo ti rí i pé bí mo bá ṣe pẹ́ tó kí n tó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí ni mí ló ṣe máa ń nira fún mi tó láti ṣàlàyé ara mi. Àmọ́, tí n bá ti jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí mo gbà gbọ́, tí mo sì ń jẹ́ kó hàn nínú ìwà mi jálẹ̀ ọdún náà, ìyẹn máa ń ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni.”

4. Wá ìrànlọ́wọ́. Kódà ẹni tó lè gbé irin tó wúwo jù ṣì níbi tí agbára rẹ̀ mọ. Ìwọ náà níbi tí agbára rẹ mọ. Torí náà, kò yẹ kó o dá ìṣòro ẹ wà mọ́rùn. (Gálátíà 6:2) O ò ṣe sọ ọ́ fáwọn òbí ẹ tàbí àwọn Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn? Fi àwọn nǹkan tó o kọ pé ó jẹ́ wàhálà fún ẹ níṣàájú nínú orí yìí hàn wọ́n. Ní kí wọ́n fún ẹ nímọ̀ràn lórí rẹ̀.

Wàhálà Lè Ṣeni Láǹfààní Kẹ̀?

Ó lè má rọrùn fún ẹ láti gbà gbọ́ o, àmọ́ ó dáa kéèyàn ṣe àwọn wàhálà kan. Ìdí tó sì fi dáa ni pé, ó ń fi hàn pé ò ń fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan àti pé ẹ̀rí ọkàn rẹ ń ṣiṣẹ́ dáadáa. Ìwọ náà wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹni tí kì í fẹ́ ṣe wàhálà kankan rárá, ó ní: “Yóò ti pẹ́ tó, ìwọ ọ̀lẹ, tí ìwọ yóò fi wà ní ìdùbúlẹ̀? Ìgbà wo ni ìwọ yóò dìde kúrò lójú oorun rẹ? Oorun díẹ̀ sí i, ìtòògbé díẹ̀ sí i, kíká ọwọ́ pọ̀ díẹ̀ sí i ní ìdùbúlẹ̀, ipò òṣì rẹ yóò sì dé dájúdájú gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri kan.” Òṣì ẹni náà yóò dà bí ìgbà tí olè wá kó gbogbo nǹkan tí ẹnì kan ní lọ.​—Òwe 6:9-11.

Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kan tó ń jẹ́ Heidi sọ ohun kan tó parí ọ̀rọ̀ yìí síbi tó dáa, ó ní: “Ó lè dà bíi pé wàhálà ti pọ̀ jù nílé ìwé, àmọ́ irú wàhálà yẹn náà lèèyàn máa ń rí tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́.” Ká sòótọ́, kì í rọrùn láti rí ọgbọ́n dá sí i. Àmọ́ tó o bá ṣe nǹkan tó yẹ nípa rẹ̀, wàhálà náà kò ní ṣèpalára fún ẹ. Kódà, ó tiẹ̀ lè sọ ẹ́ di alágbára.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ṣé pípa ilé ìwé tì ló máa yanjú ìṣòro rẹ?

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 11 Wo Orí 20 nínú ìwé yìí, fún àlàyé síwájú sí i.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

‘Kó gbogbo àníyàn rẹ lé Ọlọ́run, nítorí ó bìkítà fún ọ.’​—1 Pétérù 5:7.

ÌMỌ̀RÀN

Pín àwọn nǹkan tó ń fa wàhálà rẹ sí méjì, kí apá kan jẹ́ àwọn tó o lè yanjú, kí apá kejì sì jẹ́ àwọn tó kọjá agbára rẹ. Kọ́kọ́ wá nǹkan ṣe sí àwọn èyí tó o lè yanjú ná. Tí àwọn tó o lè yanjú bá ti wá tán pátá, ìyẹn tó bá lè tán o, wàá lè wá ráyè dáadáa láti ronú nípa àwọn èyí tó kọjá agbára rẹ.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ  . . . ?

Tó o bá ń sùn dáadáa lóru, tó ò ń sùn tó wákàtí mẹ́jọ ó kéré tán, á máa rọrùn fún ẹ láti lè wá nǹkan ṣe sí wàhálà tó o bá ní, wàá sì tún lè máa rántí nǹkan dáadáa.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Kó lè máa rọrùn fún mi láti wá nǹkan ṣe sí wàhálà tí mo bá ní, màá rí i dájú pé, nígbàkigbà tó bá ṣeé ṣe, màá lọ sùn ní aago ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tó fi jẹ́ pé tó o bá ń fẹ́ láti máa ṣe gbogbo nǹkan fínnífínní láìsí àṣìṣe rárá, ṣe nìyẹn á máa dá kún wàhálà rẹ?

● Ta lo lè sọ fún tí wàhálà bá pọ̀ jù fún ẹ?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 132]

“Ojoojúmọ́ ni dádì mi máa ń gbàdúrà pẹ̀lú mi kí wọ́n tó gbé mi lọ sílé ìwé. Ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀.”​—Liz

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 131]

Téèyàn bá ń gbé irin tó wúwo lọ́nà tó yẹ, á máa lágbára sí i, tó o bá ṣe nǹkan tó yẹ nípa wàhálà rẹ, ó lè sọ ẹ́ di alágbára tí kì í jáyà nítorí wàhálà rẹ̀