Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èdè àti Àṣà Tàwọn Òbí Mi Yàtọ̀ sí Tibi Tá À Ń Gbé, Kí Ni Kí N Ṣe?

Èdè àti Àṣà Tàwọn Òbí Mi Yàtọ̀ sí Tibi Tá À Ń Gbé, Kí Ni Kí N Ṣe?

ORÍ 22

Èdè àti Àṣà Tàwọn Òbí Mi Yàtọ̀ sí Tibi Tá À Ń Gbé, Kí Ni Kí N Ṣe?

Ṣé ọmọ orílẹ̀-èdè míì ni bàbá tàbí màmá rẹ?

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Bẹ́ẹ̀ kọ́

Ṣé èdè tàbí àṣà tàwọn tẹ́ ẹ jọ ń lọ sílé ìwé yàtọ̀ sí tàwọn òbí rẹ nílé?

□ Bẹ́ẹ̀ ni □ Bẹ́ẹ̀ kọ́

“Ará Ítálì làwọn òbí mi, wọ́n lọ́yàyà wọ́n sì máa ń kóni mọ́ra. Àmọ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì là ń gbé báyìí. Níbí yìí, ṣe ni wọ́n máa ń rọra ṣe nǹkan tiwọn jẹ́jẹ́, wọ́n sì máa ń fẹ́ ṣe gbogbo nǹkan fínnífínní. Kò sí èyí tó mọ́ mi lára délẹ̀délẹ̀ nínú àṣà méjèèjì. Mi kì í lè fi taratara ṣe bí ará Ítálì, bẹ́ẹ̀ ni mi kì í fi gbogbo ara ṣe bí ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.”​—Giosuè, láti ilẹ̀ England.

“Ní ilé ìwé, olùkọ́ mi sọ fún mi pé ojú òun ni kí n máa wò tóun bá ń bá mi sọ̀rọ̀. Àmọ́, bí mo bá ń wo bàbá mi lójú nígbà tí wọ́n bá ń bá mi sọ̀rọ̀, wọ́n á ní mo bà jẹ́. Mi ò mọ èyí tí ǹ bá fara mọ́ nínú àṣà méjèèjì.”​—Patrick, tí àwọn òbí ẹ̀ ti orílẹ̀-èdè Algeria lọ gbé ní ilẹ̀ Faransé.

NÍGBÀ táwọn òbí rẹ kó lọ sí orílẹ̀-èdè míì, bóyá wọ́n ní ọ̀pọ̀ ìṣòro. Wọ́n ṣàdédé rí i pé àárín àwọn tí èdè wọn, àṣà ìbílẹ̀ àti ìmúra wọn yàtọ̀ pátápátá sí tàwọn làwọn ń gbé. Wọ́n wá dá yàtọ̀ láàárín àwọn èèyàn tó yí wọn ká. Torí náà, wọ́n lè máa fọ̀bọ lọ̀ wọ́n, kí wọ́n sì máa hùwà tí kò dáa sí wọn torí wọn kì í ṣe ọmọ ibẹ̀.

Ṣé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà? Wo àwọn ìṣòro kan táwọn ọ̀dọ́ tó ti ṣẹlẹ̀ sí ti ní. Fi àmì ✔ sẹ́gbẹ̀ẹ́ èyí tó bá ṣòro fún ẹ jù.

Fífini ṣe yẹ̀yẹ́. Ọmọdé ṣì ni ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Noor nígbà tí òun àtàwọn òbí rẹ̀ kúrò ní orílẹ̀-èdè Jordan lọ sí Amẹ́ríkà ti Àríwá. Ó sọ pé: “Àwọn èèyàn máa ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé aṣọ wa yàtọ̀. Àwàdà táwọn ará Amẹ́ríkà máa ń ṣe kì í sì í yé àwa ní tiwa.”

O ò tiẹ̀ lè sọ pé ọmọ ibi báyìí ni ẹ́. Ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ń jẹ́ Nadia sọ pé: “Orílẹ̀-èdè Jámánì ni wọ́n bí mi sí. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ará Ítálì làwọn òbí mi, ó máa ń hàn nínú bí mo ṣe ń sọ èdè Jámánì, àwọn ẹlẹgbẹ́ mi ní ilé ìwé sì máa ń pè mí ní ‘ọ̀dẹ̀ aláìgbédè.’ Àmọ́ bí mo bá lọ sí ilẹ̀ Ítálì, mo tún máa ń rí i pé èdè Jámánì máa ń hàn nínú èdè Ítálì tí mò ń sọ. Mi ò wá lè sọ pé ọmọ ibi báyìí ni mo jẹ́ nínú méjèèjì. Àjèjì ni mo máa ń jẹ́ níbikíbi tí mo bá lọ.”

Àṣà rẹ kò bá tàwọn òbí rẹ mu nílé. Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni Ana nígbà tí òun àtàwọn òbí ẹ̀ kó lọ sí ilẹ̀ England. Ó sọ pé: “Ní tèmi àti àbúrò mi, kò pẹ́ wa rárá tí àṣà wọn nílùú London fi mọ́ wa lára. Àmọ́ kò rọrùn fáwọn òbí mi torí ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń gbé ní erékùṣù kékeré tó ń jẹ́ Madeira lórílẹ̀-èdè Potogí.”

Ọmọ ọdún mẹ́ta ni Voeun nígbà táwọn òbí rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ará Kàǹbódíà kó lọ sí ilẹ̀ Ọsirélíà. Ó ní: “Àṣà ibẹ̀ kò tètè mọ́ àwọn òbí mi lára. Kódà, bàbá mi sábà máa ń bínú torí pé mi ò mọ ohun tí wọ́n rò pé ó yẹ kí n ti mọ̀ nípa ìwà wọn àti ohun tí wọ́n ní lọ́kàn.”

O ò lè sọ èdè àwọn òbí rẹ dáadáa. Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ian nígbà tí òun àtàwọn òbí rẹ̀ kúrò ní orílẹ̀-èdè Ecuador lọ sí ìlú New York, ní Amẹ́ríkà. Lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tí wọ́n ti ń gbé níbẹ̀, Ian sọ pé: “Èdè Gẹ̀ẹ́sì ti wá mọ́ mi lẹ́nu ju èdè Sípáníìṣì lọ. Èdè Gẹ̀ẹ́sì làwọn olùkọ́ mi ní ilé ìwé ń sọ, òun làwọn ọ̀rẹ́ mi ń sọ, òun náà sì lèmi àti àbúrò mi máa ń sọ síra wa. Èdè Gẹ̀ẹ́sì wá mọ́ mi lẹ́nu débi pé mo ti fẹ́ máa gbàgbé èdè Sípáníìṣì.”

Ilẹ̀ Kàǹbódíà làwọn òbí Lee ti wá, àmọ́ ilẹ̀ Ọsirélíà ni wọ́n bí i sí. Ó ní: “Bí mo bá ń báwọn òbí mi sọ̀rọ̀, tí mo sì fẹ́ ṣe ẹ̀kún rẹ́rẹ́ àlàyé nípa bí ọ̀ràn kan ṣe rí lára mi, mi kì í lè sọ èdè wọn dáadáa.”

Ọmọ tó ń jẹ́ Noor, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú sọ pé: “Bàbá mi gbìyànjú gan-an pé ká máa sọ èdè ìbílẹ̀ àwọn nínú ilé, àmọ́ kò wù wá láti máa sọ èdè Lárúbáwá. Wàhálà làwa ka kíkọ́ èdè yẹn sí. Èdè Gẹ̀ẹ́sì làwọn ọ̀rẹ́ wa ń sọ. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n ń lò nínú gbogbo ètò tá à ń wò lórí tẹlifíṣọ̀n. Kí la wá fẹ́ fi èdè Lárúbáwá ṣe?”

Kí Lo Lè Ṣe?

Ohun tí àwọn ọ̀dọ́ yìí sọ fi hàn pé ìwọ nìkan kọ́ lo ní irú àwọn ìṣòro yìí. Dípò kó o yanjú àwọn ìṣòro yìí, o lè fẹ́ kúkú gbàgbé nípa gbogbo ohun tó bá jẹ mọ́ àṣà ibi tó o ti wá, kó o wá máa ṣe bíi tàwọn ará ibi tẹ́ ẹ̀ ń gbé báyìí. Àmọ́ tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn òbí rẹ lè bínú kí ìyẹn sì wá di wàhálà sí ẹ lọ́rùn. Nítorí náà, dípò ìyẹn, o ò ṣe wo ohun tó o lè ṣe láti yanjú àwọn ìṣòrò yìí àti bó o ṣe lè mú kí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ yìí ṣe ẹ́ láǹfààní? Wo àwọn àbá yìí:

Ohun tó o lè ṣe bí wọ́n bá ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́. Kò sí ohun tó o lè ṣe tí gbogbo èèyàn fi máa fẹ́ràn ẹ. Kò sí bí àwọn tó fẹ́ràn kí wọ́n máa fini ṣe yẹ̀yẹ́ kò ṣe ní rí nǹkan tí wọ́n á fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ lé lórí. (Òwe 18:24) Torí náà má wulẹ̀ dara ẹ láàmú pé o fẹ́ máa ṣe àlàyé fún wọn kí wọ́n má fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ mọ́ nítorí ibi tó o ti wá. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Ẹlẹ́gàn kò fẹ ẹni ti nba a wi.” (Òwe 15:12, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Ṣe ni ọ̀rọ̀ àwọn tó ń fi ẹlòmíì ṣe yẹ̀yẹ́ torí ibi tó ti wá kàn máa ń fi hàn pé àwọn gan-an ni kò dákan mọ̀, kì í ṣe ẹni tí wọ́n ń bú.

Ohun tó o lè ṣe tí o kò bá lè sọ pé ọmọ ibi báyìí ni ẹ́. Ó sábà máa ń wu àwa èèyàn pé ká ní àwọn tá a fojú jọ, irú bí àwọn tá a jọ jẹ́ ìdílé kan tàbí ọmọ ibì kan náà. Ṣùgbọ́n kò yẹ ká máa ronú pé ọmọ ibi tá a jẹ́ tàbí ìdílé tá a ti wá ló ń pinnu bá a ti ṣe pàtàkì sí. Òótọ́ ni pé àwọn èèyàn lè máa fi nǹkan wọ̀nyẹn pinnu irú ẹni tó o jẹ́, àmọ́ ìyẹn kọ́ ni Ọlọ́run ń wò ní tiẹ̀. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, . . . ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Tó o bá ń sa gbogbo ipá rẹ láti ṣe ohun tí Jèhófà Ọlọ́run ń fẹ́, yóò kà ẹ́ mọ́ ara ìdílé rẹ̀. (Aísáyà 43:10; Máàkù 10:29, 30) Bí Ọlọ́run bá sì ti kà ẹ́ sí ara ìdílé rẹ̀, kò tún sí àǹfààní míì tó ju ìyẹn lọ.

Ohun tó o lè ṣe bí àṣà rẹ kò bá bá tàwọn òbí rẹ mu nílé. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé nínú gbogbo ìdílé ló ti máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà míì pé, ojú táwọn òbí àtàwọn ọmọ fi ń wo nǹkan kan máa ń yàtọ̀ síra. Àmọ́ nínú ọ̀rọ̀ tìrẹ yìí, ìyàtọ̀ yẹn lè pọ̀ gan-an. Ìyẹn ni pé, àwọn òbí rẹ fẹ́ kó o máa tẹ̀ lé àwọn àṣà ibi tẹ́ ẹ ti wá, àmọ́ ìwọ ń fẹ́ máa tẹ̀ lé àṣà ibi tẹ́ ẹ̀ ń gbé báyìí. Síbẹ̀, bó o bá fẹ́ kí nǹkan máa lọ dáadáa fún ẹ láìsí ìyọnu, o gbọ́dọ̀ “bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.”​—Éfésù 6:2, 3.

Dípò tí wàá kàn fi pa àṣà àwọn òbí rẹ tì torí pé kò wù ẹ́, ṣe ni kó o gbìyànjú láti fi òye mọ ìdí tí àwọn òbí rẹ fi ka àṣà yẹn sí pàtàkì. (Òwe 2:10, 11) Bi ara rẹ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Ṣé àwọn àṣà yẹn lòdì sí àwọn ìlànà Bíbélì ni? Tí kò bá lòdì sí i, kí ni nǹkan tí mi ò fẹ́ nínú àwọn àṣà náà gan-an? Báwo ni mo ṣe lè ṣàlàyé ara mi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fún àwọn òbí mi?’ (Ìṣe 5:29) Àmọ́ ṣá o, ohun tó máa jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún ẹ láti bọlá fún àwọn òbí rẹ, ìyẹn ni pé kó o lóye èrò wọn kí ìwọ náà sì ṣàlàyé ara rẹ dáadáa fún wọn, ni pé kó o lè sọ èdè wọn dáadáa.

Ohun tó o lè ṣe tí o kò bá lè sọ èdè àwọn òbí rẹ dáadáa. Àwọn ìdílé kan ti rí i pé báwọn bá fi dandan lé e pé káwọn máa sọ èdè ìbílẹ̀ nìkan nígbà táwọn bá wà nílé, á ṣeé ṣe fáwọn ọmọ láti gbọ́ èdè méjèèjì dáadáa. Ẹ ò ṣe gbìyànjú ìyẹn ní ilé yín? O sì tún lè ní káwọn òbí ẹ kọ́ ẹ bí wọ́n ṣe ń kọ èdè náà sílẹ̀. Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Stelios, tí wọ́n tọ́ dàgbà lórílẹ̀-èdè Jámánì, àmọ́ tó jẹ́ pé Gíríìkì lèdè ìbílẹ̀ àwọn òbí ẹ̀, sọ pé: “Àwọn òbí mi máa ń ṣàlàyé ẹsẹ Bíbélì kan fún mi lójoojúmọ́. Wọ́n máa ń kà á sókè ketekete, èmi á sì máa kọ ọ́ sílẹ̀. Mo ti wá mọ bí wọ́n ṣe ń ka èdè Gíríìkì àti èdè Jámánì báyìí, mo sì tún lè kọ èdè méjèèjì sílẹ̀.”

Àwọn àǹfààní míì wo ló tún wà níbẹ̀? Giosuè, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níṣàájú sọ pé: “Mo kọ́ èdè táwọn òbí mi ń sọ torí pé mo fẹ́ ká sún mọ́ra gan-an kí n sì túbọ̀ lóye ohun tí wọ́n ń fẹ́. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, mo fẹ́ ká lè jọ máa sin Ọlọ́run. Kíkọ́ tí mo kọ́ èdè wọn ti jẹ́ kí n mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wọn. Ìyẹn sì ti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tèmi náà túbọ̀ máa yé wọn.”

Kà Á Sí Afárá, Má Ṣe Jẹ́ Kó Dí Ẹ Lọ́wọ́

Ṣé o máa jẹ́ kí àṣà ibi tó o ti wá dí ẹ lọ́wọ́ láti sún mọ́ àwọn èèyàn àbí wàá kà á sí afárá tí wàá máa gbà kọjá láti fi túbọ̀ sún mọ́ wọn? Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni ló ti wá rí i pé ìdí míì tó ṣe pàtàkì wà tó fi yẹ káwọn túbọ̀ sún mọ́ àwọn tó jẹ́ ọmọ ibi tí àwọn àti òbí àwọn ti wá. Ìdí yẹn sì ni pé wọ́n fẹ́ láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn míì tí wọ́n ń ti orílẹ̀-èdè kan kó lọ sí orílẹ̀-èdè míì. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ọmọ kan tó ń jẹ́ Salomão, tí òun àtàwọn òbí ẹ kó lọ sí ìlú London nígbà tó wà lọ́mọ ọdún márùn-ún sọ pé: “Àǹfààní ńlá ló jẹ́ pé mo lè fi èdè méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ṣàlàyé Ìwé Mímọ́! Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbàgbé èdè àwọn òbí mi tán, àmọ́ ní báyìí tí mo ti wà ní ìjọ tó ń sọ èdè Potogí, mo ti lè sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Potogí dáadáa.”

Ọmọ tó ń jẹ́ Noor tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú wá rí i pé àwọn tó ń sọ èdè Lárúbáwá nílò àwọn tó máa wàásù ìhìn rere fún wọn gan-an. Ó ní: “Ní báyìí, mo ti ń tún èdè náà kọ́ kí n lè rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí mo ti gbàgbé. Ojú tí mo fi ń wo èdè yẹn ti yí pa dà. Ẹni tó máa ràn mí lọ́wọ́ kí n lè mọ̀ ọ́n sọ dáadáa ni mò ń wá báyìí.”

Dájúdájú, bó o bá mọ àṣà ibi méjì dáadáa tó o sì lè sọ èdè méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àǹfààní ńlá lo ní o. Àṣà oríṣi méjì tó o mọ̀ yẹn á túbọ̀ jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹ láti mọ báwọn èèyàn ṣe ń ronú, á sì yá ẹ lára láti lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọn nípa Ọlọ́run. (Òwe 15:23) Bí àpẹẹrẹ, ọmọ ilẹ̀ Íńdíà làwọn òbí ọmọ kan tó ń jẹ́ Preeti, àmọ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n bí i sí. Ó ní: “Nítorí pé mo mọ àṣà ibi méjì, ọkàn mi máa ń balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ bí mo bá wà lóde ẹ̀rí. Mo lóye àwọn èèyàn láti ibi méjèèjì dáadáa, ìyẹn ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti ìwà wọn.”

Ṣé ìwọ náà lè ka ipò tó o bá bára ẹ sí àǹfààní tó o lè fi túbọ̀ ṣe ìrànlọ́wọ́ fáwọn èèyàn dípò tí wàá fi kà á sí ìdíwọ́? Rántí pé irú ẹni tó o jẹ́ ni Jèhófà ń wò tó fi nífẹ̀ẹ́ rẹ, kì í ṣe nítorí ibi tí ìwọ tàbí ìdílé rẹ ti wá. Ṣé ìwọ náà máa ṣe bíi tàwọn ọ̀dọ́ tá a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ níbí yìí, kó o lo òye àti ìrírí tó o ní láti fi ran àwọn tẹ́ ẹ jọ ti ibì kan náà wá lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run wa tí kì í ṣe ojúṣàájú? Bó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá ní ojúlówó ayọ̀!​—Ìṣe 20:35.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.”​—Ìṣe 10:34.

ÌMỌ̀RÀN

Táwọn ojúgbà rẹ bá ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́ torí ọmọ ibi tó o jẹ́, má fi ṣe ìbínú. Ṣe ni kí ìwọ náà sọ ọ́ di àwàdà. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n lè wò ó pé yẹ̀yẹ́ tí wọ́n ń ṣe kò dùn ẹ́ kí wọ́n sì fi ẹ́ sílẹ̀.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Tó o bá mọ èdè méjì dáadáa, ìyẹn lè jẹ́ kó o tètè rí iṣẹ́.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Kí n lè túbọ̀ mọ èdè àwọn òbí mi dáadáa màá ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ dádì tàbí mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Tó o bá mọ àṣà ìbílẹ̀ àwọn òbí rẹ, báwo nìyẹn ṣe lè jẹ́ kó o túbọ̀ mọ ara rẹ dáadáa?

● Àwọn àǹfààní wo lo ní tó ju ti àwọn ọ̀dọ́ míì tí kò mọ̀ ju èdè kan àti àṣà ibì kan ṣoṣo lọ?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 160]

“Inú mi máa ń dùn pé mo lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Mo lè ṣàlàyé Bíbélì fáwọn tó ń sọ èdè Rọ́ṣíà, èdè Faransé, tàbí èdè Moldova.”​—Oleg

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 161]

O lè ka àṣà ibi tó o ti wá sí afárá tí wàá máa gbà kọjá láti fi túbọ̀ sún mọ́ àwọn èèyàn