Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìbẹ́yà-Kannáà-Lòpọ̀?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìbẹ́yà-Kannáà-Lòpọ̀?

ORÍ 23

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàlàyé Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Ìbẹ́yà-Kannáà-Lòpọ̀?

Níbi ayẹyẹ ìfúnnilẹ́bùn kan, àwọn èèyàn pariwo gèè nígbà tí àwọn obìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèré fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu bíi tàwọn tọkọtaya nígbà tí wọ́n ń kí ara wọn. Ó kọ́kọ́ ṣe àwọn tó ń wò wọ́n ní kàyéfì, àmọ́ nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sà wọ́n. Àṣeyọrí làwọn tó ń bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn lò pọ̀ ka ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí sí. Àmọ́ àwọn ẹlòmíì sọ pé ńṣe ni wọ́n fi polongo ìwàkiwà wọn. Torí pé, fúngbà pípẹ́, wọ́n á máa gbé ìròyìn ohun tí wọ́n ṣe yìí jáde léraléra lórí tẹlifíṣọ̀n, àìmọye èèyàn á sì máa wò ó lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

BÍ OHUN tó ṣẹlẹ̀ yìí ṣe fi hàn, kò sóhun tó ń tà nínú ìròyìn bíi kí ẹnì kan tó jẹ́ gbajúgbajà sọ ní gbangba pé òun jẹ́ ẹni tó ń bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tòun lò pọ̀, ìyẹn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, tàbí pé tọkùnrin tobìnrin lòun máa ń bá lò pọ̀. Àwọn kan máa ń gbóríyìn fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ pé wọ́n ní ìgboyà, àmọ́ àwọn míì máa ń bẹnu àtẹ́ lù wọ́n pé wọ́n ń hu ìwàkiwà. Àwọn míì sì wà tí wọn kò fara mọ́ èrò méjèèjì yìí, torí wọ́n gbà pé ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà mìíràn tí èèyàn lè gbà gbádùn ayé ara rẹ̀. Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21] kan tó ń jẹ́ Daniel sọ pé: “Nígbà tí mo ṣì wà nílé ìwé, àwọn ọ̀dọ́ tí kì í ṣe abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ pàápàá gbà pé bí o kò bá fi ojú tó dáa wo àṣà náà, á jẹ́ pé ẹlẹ́tanú àti alárìíwísí ni ẹ́.”

Ojú táwọn èèyàn fi ń wo àṣà náà lè yàtọ̀ síra láti ìran kan sí òmíràn àti láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Àmọ́, ní ti àwọn Kristẹni, wọn kì í jẹ́ káwọn èèyàn tì wọ́n “kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun, tí a ń gbé síhìn-ín sọ́hùn-ún nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́.” (Éfésù 4:14) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Bíbélì sọ ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé.

Kí tiẹ̀ ni Bíbélì sọ nípa ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀? Bó bá jẹ́ pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù lò ń tẹ̀ lé, báwo lo ṣe lè fèsì nígbà táwọn kan bá pè ẹ́ ní ẹlẹ́tanú, alárìíwísí, tàbí ẹni tó kàn ní ẹ̀mí ìkórìíra sáwọn èèyàn tó jẹ́ abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀? Wo àwọn ìbéèrè kan tàbí ohun táwọn kan ń sọ àti bó o ṣe lè fèsì.

“Kí ni Bíbélì sọ nípa ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀?”

“Bíbélì sọ ní kedere pé àárín ọkùnrin kan àti obìnrin kan tó bá jẹ́ tọkọtaya nìkan ni Ọlọ́run ṣètò pé kí ìbálòpọ̀ ti máa wáyé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; Léfítíkù 18:22; Òwe 5:18, 19) Nígbà tí Bíbélì sọ pé àgbèrè kò dáa, kì í ṣe ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin àti obìnrin tí kì í ṣe tọkọtaya nìkan ló ń sọ, ó tún kan ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀.” *​—Gálátíà 5:19-21.

“Kí ni èrò tìrẹ nípa ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀?”

“Mi ò kórìíra àwọn èèyàn tó jẹ́ abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ o, ohun tí wọ́n ń ṣe ni mi ò fara mọ́.”

Má gbàgbé pé: Bó bá jẹ́ pé ìlànà Bíbélì nípa ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù lò ń tẹ̀ lé, á jẹ́ pé irú ìgbé ayé tó wu ìwọ náà lo yàn yẹn, o sì ní ẹ̀tọ́ láti yan ohun tó wù ẹ́. (Jóṣúà 24:15) Má ṣe jẹ́ kí ojú tì ẹ́ láti sọ èrò rẹ jáde.​—Sáàmù 119:46.

“Ṣebí gbogbo èèyàn ló yẹ káwọn Kristẹni máa bọ̀wọ̀ fún láìka ọ̀nà yòówù kí àwọn èèyàn máa gbà ní ìbálòpọ̀, àbí?”

“Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì sọ pé: ‘Ẹ máa bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo.’ (1 Pétérù 2:17) Torí náà, gbogbo èèyàn ni àwọn Kristẹni máa ń fi inúure hàn sí, títí kan àwọn tó jẹ́ abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀. Wọn kì í ní ẹ̀mí ìkórìíra sáwọn èèyàn tó sọ ara wọn di abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀.”​Mátíù 7:12.

“Ṣé irú èrò tó o ní nípa ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ yìí kò ní mú kí àwọn èèyàn máa ṣe ẹ̀tanú sí àwọn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ báyìí?”

“Rárá o. Ìwà bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀ ni mo kórìíra, mi ò kórìíra ẹnikẹ́ni.”

O lè fi kún un pé: “Bí àpẹẹrẹ, mi kì í mu sìgá. Kódà, mo kórìíra rẹ̀ gan-an. Àmọ́, ká sọ pé ìwọ máa ń mu sìgá, o ò sì rí ohun tó burú nínú sìgá mímu. Mi ò lè torí ìyẹn kí n máa ṣe ẹ̀tanú sí ẹ, ó sì dá mi lójú pé ìwọ náà kò ní ṣe ẹ̀tanú sí mi torí pé èmi kì í mu sìgá. Àbí? Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí náà nìyẹn nípa èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tá a ní lórí ọ̀rọ̀ ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀.”

“Ṣebí Jésù sọ pé ká tẹ́wọ́ gba gbogbo èèyàn? Torí náà, ṣé kò wá yẹ kí àwọn Kristẹni fàyè gba ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀?”

“Jésù kò sọ pé káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ fara mọ́ ọ̀nà yòówù káwọn èèyàn máa gbà gbé ìgbé ayé wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, o sọ pé ọ̀nà ìgbàlà ṣí sílẹ̀ fún ‘olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú [òun].’ (Jòhánù 3:16) Ẹni tó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ nípa ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù àti èyí tí kò yẹ. Lára àwọn ìwà tó sì sọ pé kò yẹ ká máa hù ni ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀.”​—Róòmù 1:26, 27.

“Àwọn tó jẹ́ abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ kò lè yí pa dà, bí Ọlọ́run ṣe dá wọn nìyẹn.”

“Bíbélì kò ṣàlàyé ohun tó ń fa bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀, àmọ́ ó sọ pé àwọn ìwà kan wà tó ti wọ àwọn èèyàn kan lára gan-an. (2 Kọ́ríńtì 10:4, 5) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọkàn àwọn kan máa ń fà sí níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn, ohun tí Bíbélì sọ ni pé kí àwọn Kristẹni kórìíra irú ìwà bẹ́ẹ̀.”

Àbá kan rèé: Dípò tí wàá fi máa báwọn jiyàn nípa ohun tó ń mú kí ọkàn èèyàn máa fà sí bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tẹni lò pọ̀, ńṣe ni kó o máa ṣàlàyé fún wọn pé Bíbélì ka irú ìwà bẹ́ẹ̀ léèwọ̀. O lè lo àpẹẹrẹ kan pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń sọ pé àwọn tó ń hùwà ipá jogún rẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn ni, àti pé ìyẹn ló jẹ́ kí àwọn ẹlòmíì fẹ́ràn ìjà. (Òwe 29:22) Ká tiẹ̀ wá gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yìí. Ìwọ náà mọ̀ pé Bíbélì ní ká má ṣe máa bínú sódì. (Sáàmù 37:8; Éfésù 4:31) Ǹjẹ́ a lè sọ pé ohun tí Bíbélì sọ yìí kò dáa torí pé àwọn kan fẹ́ràn ìwà jàgídíjàgan?”

“Báwo ni Ọlọ́run ṣe lè sọ pé kí ẹni tí ọkàn rẹ̀ máa ń fà sí bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ lò pọ̀ má ṣe ṣe bẹ́ẹ̀? Òfin yẹn ti le jù.”

“Ohun tó máa ń fa irú èrò yìí ni ohun tí kò tọ̀nà táwọn èèyàn máa ń sọ pé, ọ̀nà yòówù tó bá wu èèyàn pé kó gbà ní ìbálòpọ̀ náà ló gbọ́dọ̀ gbà ṣe é. Bíbélì buyì kún àwa èèyàn nípa bó ṣe mú kó dá wa lójú pé, bí ọkàn èèyàn bá tiẹ̀ ń fà sí ìbálòpọ̀ lọ́nà tí kò tọ́, èèyàn lè kọ̀ jálẹ̀ láti hùwà yẹn.”​—Kólósè 3:5.

“Ká tiẹ̀ wá sọ pé ìwọ kì í ṣe abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, ó yẹ kó o tiẹ̀ lè máa fi ojú tó dáa wo àṣà náà.”

“Ká sọ pé mi ò fẹ́ràn tẹ́tẹ́ títa, àmọ́ ìwọ máa ń ta tẹ́tẹ́. Ṣé ó máa bọ́gbọ́n mu pé kó o ní kí n fẹ́ràn tẹ́tẹ́ títa torí pé àìmọye èèyàn ló ń ta tẹ́tẹ́?”

Rántí pé: Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn, tó fi mọ́ àwọn tó ń bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn lò pọ̀, ló gbà pé àwọn ìwà kan wà tí kò yẹ ọmọlúwàbí, èyí tó mú kí wọ́n kórìíra àwọn nǹkan bíi jìbìtì, ìwà ìrẹ́jẹ tàbí ogun. Bíbélì náà ka irú ìwà bẹ́ẹ̀ léèwọ̀, ó sì tún ka oríṣi àwọn ìbálòpọ̀ kan léèwọ̀ pẹ̀lú, lára rẹ̀ ni bíbá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tẹni lò pọ̀.​—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.

Ohun tí Bíbélì sọ bọ́gbọ́n mu, kò sì sọ pé kéèyàn máa ṣe ẹ̀tanú. Ohun tó sọ fún àwọn abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ náà ló sọ fún àwọn tí kì í ṣe abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, ó ní kí wọ́n máa “sá fún àgbèrè.”​—1 Kọ́ríńtì 6:18.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ńṣe ni àìmọye àwọn tí ọkàn wọn máa ń fà sí ìbálòpọ̀ láàárín ọkùnrin sí obìnrin pàápàá máa ń kó ara wọn níjàánu torí pé wọ́n fẹ́ ṣègbọràn sí àwọn ìlànà Bíbélì, láìka ìdẹwò tí wọ́n lè dojú kọ sí. Lára wọn ni àwọn tọkùnrin tobìnrin tí kò tíì ṣègbéyàwó, tí kò sì dájú pé wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀, àti ọ̀pọ̀ àwọn tó ti ṣègbéyàwó àmọ́ tí ọkọ tàbí aya wọn ní àìsàn tí kò jẹ́ kí wọ́n lè ní ìbálòpọ̀. Tayọ̀tayọ̀ ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ fi ń gbé ìgbé ayé wọn láìsí ìbálòpọ̀. Àwọn tó ń bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn lò pọ̀ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ bí wọ́n bá fẹ́ mú inú Ọlọ́run dùn lóòótọ́.​—Diutarónómì 30:19.

KÀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 28, NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Àwọn ọmọbìnrin kan gbà pé báwọn bá ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí àwọn ń fẹ́, ìyẹn máa jẹ́ kí àwọn túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara àwọn. Kò jọ pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí! Kà nípa rẹ̀ fúnra rẹ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 8 Nígbà tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa “àgbèrè,” kì í ṣe ìbálòpọ̀ nìkan ló ń sọ, ó tún kan fífi ọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì, fífi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì tàbí kéèyàn máa ti ihò ìdí báni lò pọ̀.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.”​—Kólósè 3:5.

ÌMỌ̀RÀN

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà àwọn míì lè máa bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́, rí i pé o kò sọ̀rọ̀ sí wọn bíi pé o jẹ́ olódodo jù wọ́n lọ. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti yan ohun tí wọ́n fẹ́, bí ìwọ náà ṣe ní ẹ̀tọ́ láti yan ohun tó wù ẹ́.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Àwọn Kristẹni kan ní ọ̀rúndún kìíní tó ti lọ́wọ́ nínú bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀ rí jáwọ́ nínú ìwà àìmọ̀ yẹn, wọ́n sì dẹni tí Ọlọ́run kà sí ẹni tí a ti ‘wẹ̀ mọ́.’​—1 Kọ́ríńtì 6:9-11.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bí ẹnì kan bá sọ pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ kò bágbà mu, màá sọ pé ․․․․․

Láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àṣà ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ ni mo kórìíra, kì í ṣe àwọn èèyàn tó ń lọ́wọ́ nínú rẹ̀, màá sọ pé ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Ọlọ́run lẹ́tọ̀ọ́ láti gbófin kalẹ̀ nípa irú ìwà tó yẹ káwa èèyàn máa hù?

● Bó o bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nípa ìwà híhù, àǹfààní wo ló máa ṣe ẹ́?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 170]

“Ọmọkùnrin kan nílé ìwé wa sọ pé èèyàn burúkú ni mí torí pé mi ò nífẹ̀ẹ́ sí bó ṣe ń gbé ìgbé ayé ẹ̀. Àmọ́ nígbà tí mo ṣàlàyé fún un pé mi ò kórìíra ẹ̀, ìwà tó ń hù ni mo kórìíra, ó wá rí i pé kì í ṣe ìwà ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ nìkan ni mo kórìíra, pé gbogbo ìṣekúṣe ni mo kórìíra, ìyẹn ló mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í fọ̀wọ̀ tèmi wọ̀ mí tó sì tún máa ń gbèjà mi nígbà táwọn ẹlòmíì bá ń yọ mí lẹ́nu.”​—Aubrey

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 168]

Téèyàn Bá Ń Bá Tọkùnrin Tobìnrin Lò Pọ̀ Ńkọ́?

Òótọ́ ni pé àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin ló ń lọ́wọ́ sí àṣà kéèyàn máa bá tọkùnrin tobìnrin lò pọ̀, síbẹ̀ ó jọ pé àárín àwọn obìnrin ni àṣà yìí ti wọ́pọ̀ jù báyìí. Torí kí wọ́n lè mọ bó ṣe máa ń rí ni àwọn kan ṣe ń lọ́wọ́ nínú ẹ̀. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] kan tó ń jẹ́ Lisa sọ pé: “Tí wọ́n bá gbé àwòrán àwọn obìnrin tó ń fi ẹnu ko obìnrin bíi tiwọn lẹ́nu jáde nínú fíìmù, lórí tẹlifíṣọ̀n àti nínú orin, àwọn ọ̀dọ́ á fẹ́ gbìyànjú ẹ̀ wò, pàápàá jù lọ tí wọn kò bá rí ohun tó burú níbẹ̀.”

Àwọn ọ̀dọ́ míì ní tiwọn nífẹ̀ẹ́ sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13] kan to ń jẹ́ Vicky sọ pé: “Mo bá àwọn ọmọbìnrin méjì kan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí bíbá ọkùnrin àti obìnrin lò pọ̀ pàdé níbi ayẹyẹ kan. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni ọ̀rẹ́ mi kan wá sọ fún mi pé àwọn ọmọbìnrin méjèèjì yẹn fẹ́ràn mi. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù sí ọ̀kan lára wọn, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bíi pé ọkùnrin ni.”

Ǹjẹ́ ohun tó ṣe Vicky yìí ti ṣe ẹ́ rí? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa sọ fún ẹ pé kò sí nǹkan tó burú níbẹ̀ àti pé kó o má ṣe tijú láti sọ ní gbangba pé o nífẹ̀ẹ́ sí bíbá tọkùnrin tobìnrin lò pọ̀. Àmọ́, nǹkan pàtàkì kan tó yẹ kó o mọ̀ ni pé téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ sí ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀, kì í sábà pẹ́ tí irú èrò bẹ́ẹ̀ fi máa ń kúrò lọ́kàn ẹni. Ohun tí Vicky wá mọ̀ nígbà tó yá nìyẹn. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kan tó ń jẹ́ Lisette sọ pé: “Ara máa ń tù mí tí mo bá ń sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára mi fún àwọn òbí mi. Nígbà tá a ń kẹ́kọ̀ọ́ nílé ìwé nípa àwọn nǹkan alààyè, ìyẹn biology, wọ́n kọ́ wa pé téèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, àwọn èròjà kan tí wọ́n ń pè ní hormone, kì í ṣiṣẹ́ bákan náà ní gbogbo ìgbà nínú ara ẹni. Ó dá mi lójú pé bí ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ bá túbọ̀ mọ bí ara wọn ṣe ń ṣiṣẹ́ dáadáa, ó máa yé wọn pé ìfẹ́ téèyàn máa ń ní láti bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiẹ̀ lò pọ̀ kì í wà pẹ́ lọ títí, wọn ò sì ní fẹ́ láti máa bá ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwọn lò pọ̀ mọ́ tó bá yá.”

Bí ọkàn rẹ bá tiẹ̀ sábà máa ń fà sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ gan-an débi pé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti mọ́kàn kúrò nínú rẹ̀, má gbàgbé pé Bíbélì sọ nǹkan kan tó o lè ṣe, ìyẹn ni pé: O lè pinnu pé o ò ní ṣe ohun búburú èyíkéyìí tó bá wá sí ẹ lọ́kàn.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 169]

Tó bá dọ̀rọ̀ ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí, àwọn Kristẹni kì í bẹ̀rù láti ṣe ohun tó yàtọ̀ sí táwọn èèyàn yòókù