Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ó Burú Bí Ọkùnrin àti Obìnrin Bá Kàn Gbé Ara Wọn Sùn?

Ṣé Ó Burú Bí Ọkùnrin àti Obìnrin Bá Kàn Gbé Ara Wọn Sùn?

ORÍ 26

Ṣé Ó Burú Bí Ọkùnrin àti Obìnrin Bá Kàn Gbé Ara Wọn Sùn?

“Àwọn ọ̀dọ́ á kàn pàdé ara wọn, wọ́n á sì gbé ara wọn sùn, wọ́n á máa wá wo iye ẹni táwọn lè bá sùn.”​—Penny.

“Àwọn ọmọkùnrin kì í fọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ bò. Wọ́n máa ń yangàn pé àwọn ní ọ̀rẹ́bìnrin, síbẹ̀ àwọn ń bá ọ̀pọ̀ ọmọbìnrin míì sùn.”​—Edward.

Ọ̀PỌ̀ ọ̀dọ́ lónìí ló máa fi ń ṣakọ pé àwọn gbé ẹnì kan sùn, àwọn sì ń lọ nílọ tàwọn. Àwọn ọ̀dọ́ kan tiẹ̀ tún láwọn kan tí wọ́n kàn jọ máa ń bára wọn lò pọ̀, tí oníkálukú á sì máa bá tiẹ̀ lọ.

Má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu bí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ń wù ẹ́ ṣe! (Jeremáyà 17:9) Edward, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọmọbìnrin ló ti sọ pé kí n wá bá àwọn sùn, àtisọ pé mi ò ṣe lohun tó tíì nira jù fún mi nínú gbogbo ìṣòro tí mò ń ní gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. Kò rọrùn láti sọ pé mi ò ṣe!” Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló yẹ kó o fi sọ́kàn tẹ́nì kan bá ní kẹ́ ẹ jọ gbéra yín sùn?

Mọ Ìdí Tí Gbígbéra Ẹni Sùn Fi Burú

Àgbèrè jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an débi pé àwọn tó bá ń ṣe é kò ní “jogún ìjọba Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Èyí sì kan àwọn tó ń sọ pé torí àwọn nífẹ̀ẹ́ ara àwọn làwọn ṣe ń bára àwọn lò pọ̀ tàbí àwọn tó kàn ń gbé ara wọn sùn lásán. Tó o bá fẹ́ borí ìdẹwò èyíkéyìí ní ọ̀nà méjèèjì yìí, ojú tí Jèhófà fi ń wo àgbèrè ni ìwọ náà gbọ́dọ̀ máa fi wò ó.

“Ó dá mi lójú hán-únhán-ún pé ọ̀nà Jèhófà lọ̀nà tó dára jù lọ láti máa tọ̀.”​—Karen, láti orílẹ̀-èdè Kánádà.

“Rántí pé ẹnì kan ló bí ẹ o, o ní ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́rẹ̀ẹ́, ara ìjọ Ọlọ́run sì ni ẹ́. Gbogbo àwọn èèyàn yìí lo máa ṣẹ̀ bó o bá ṣèṣekúṣe!”​—Peter, láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Bó o bá kórìíra àgbèrè bí Jèhófà ṣe kórìíra rẹ̀, á ṣeé ṣe fún ẹ láti “kórìíra ohun búburú,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun náà lè máa wu ẹran ara wa yìí.​—Sáàmù 97:10.

Ẹsẹ Bíbélì tá a dábàá pé kó o kà: Jẹ́nẹ́sísì 39:7-9. Nígbà tó o bá ń kà á, kíyè sí ohun tó mú kí Jósẹ́fù fìgboyà kọ̀ jálẹ̀ láti ṣàgbèrè àti ohun tí kò jẹ́ kó juwọ́ sílẹ̀.

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ohun Tó O Gbà Gbọ́ Tì Ẹ́ Lójú

Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ni kì í tijú láti gbèjà ìgbàgbọ́ wọn. Àǹfààní ló jẹ́ fún ẹ láti máa fi ìwà rere rẹ gbé ìlànà Ọlọ́run ga. Má ṣe jẹ́ kójú tì ẹ́ nítorí pé o gbà pé kò tọ́ kéèyàn ní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó.

“Tètè máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé o ò ní gba ìwàkiwà láyè.”​—Allen, láti orílẹ̀-èdè Jámánì.

“Àwọn ọmọkùnrin tá a jọ lọ sílé ẹ̀kọ́ girama mọ irú ẹni tí mo jẹ́, wọ́n sì mọ̀ pé pàbó ni gbogbo ìsapá àwọn máa já sí.”​—Vicky, láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Bó o bá dúró lórí ìgbàgbọ́ ẹ, ìyẹn ló máa fi hàn pé ìwọ náà ti di Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀.​—1 Kọ́ríńtì 14:20.

Ẹsẹ Bíbélì tá a dábàá pé kó o kà: Òwe 27:11. Kíyè sí bó o ṣe lè múnú Jèhófà dùn bó o bá ń ṣe ohun tó tọ́!

Dúró Lórí Ọ̀rọ̀ Ẹ!

Ó ṣe pàtàkì kó o jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé o ò ní lọ́wọ́ sí ìwàkiwà. Àmọ́ ṣá, àwọn míì lè rò pé ọ̀rọ̀ tó o sọ yẹn kò dénú ẹ.

“Nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe, ì báà jẹ́ bó o ṣe ń múra ni o, bó o ṣe ń sọ̀rọ̀ ni o, irú àwọn èèyàn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ ni o àti bó o ṣe ń ṣe sáwọn èèyàn, o gbọ́dọ̀ máa fi hàn pé o ò gbàgbàkugbà láàyè.”​—Joy, láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

“Jẹ́ kó ṣe kedere pé o ò ní gbarú ẹ̀ láyè. Má ṣe gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n bá ń wá bí wọ́n ṣe máa bá ẹ sùn. Bó bá yá, wọ́n lè ní kó o wá pọ ohun tó o jẹ nípa bíbá àwọn lò pọ̀.”​—Lara, láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó o bá dúró lórí ọ̀rọ̀ ẹ. Látinú ìrírí tí Dáfídì ní, ó sọ nípa Jèhófà nínú ìwé Sáàmù pé: “Ìwọ yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin.”​—Sáàmù 18:25.

Ẹsẹ Bíbélì tá a dábàá pé kó o kà: 2 Kíróníkà 16:9. Kíyè sí i pé ó ń wu Jèhófà gan-an láti ran àwọn tó fẹ́ ṣe ohun tó tọ́ lọ́wọ́.

Máa Ro Ìgbẹ̀yìn Ọ̀rọ̀

Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:3) Báwo lo ṣe lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò? Nípa ríro ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ ni!

“Bó bá ṣe lè ṣeé ṣe tó, má ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀.”​—Naomi, láti ilẹ̀ Japan.

“Má ṣe máa sọ gbogbo nǹkan nípa ara ẹ fáwọn èèyàn, ìyẹn àwọn nǹkan bí àdírẹ́sì tàbí nọ́ńbà tẹlifóònù rẹ.”​—Diana, láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

Ronú lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó o máa ń sọ, ìwà tó ò ń hù, àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtàwọn ibi tó o máa ń lò sí. Lẹ́yìn náà, kó o wá bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mi kì í ṣe àwọn nǹkan lọ́nà táá mú káwọn èèyàn máa rò pé ṣe ni mo fẹ́ kí wọ́n fi ìbálòpọ̀ lọ̀ mí?’

Ẹsẹ Bíbélì tá a dábàá pé kó o kà: Jẹ́nẹ́sísì 34:1, 2. Kíyè sí bí wíwà níbi tí kò yẹ ṣe kó ọmọ kan tó ń jẹ́ Dínà sí wàhálà.

Má ṣe gbàgbé pé gbígbéra ẹni sùn kì í ṣe ọ̀ràn kékeré lójú Jèhófà Ọlọ́run; kò yẹ kó jẹ́ ọ̀ràn kékeré lójú tìẹ náà. Bí o kò bá fàyè gba ìgbàkugbà, ohunkóhun ò ní ba ẹ̀rí ọkàn rere tó o ní níwájú Ọlọ́run jẹ́, àwọn èèyàn á sì máa bọ̀wọ̀ fún ẹ. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Carly sọ pé: “Kí nìdí tí wàá fi jẹ́ kí ẹlòmíì fi ẹ́ wá ìtura ojú ẹsẹ̀ fún ara rẹ̀? O ti ṣiṣẹ́ ribiribi láti rí ojú rere Ọlọ́run, má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni bà á jẹ́ mọ́ ẹ lọ́wọ́ o!”

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Irú àwọn ọmọbìnrin wo làwọn ọmọkùnrin máa ń sọ pé ó wu àwọn? Ohun tó o máa gbọ́ lè yà ẹ́ lẹ́nu!

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

‘Sa gbogbo ipá rẹ kí Ọlọ́run lè bá ọ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà.’​—2 Pétérù 3:14.

ÌMỌ̀RÀN

Rí i dájú pé ìwà rere lò ń hù. (1 Pétérù 3:3, 4) Tó o bá ń hùwà dáadáa, àwọn èèyàn dáadáa ni yóò máa sún mọ́ ẹ.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Jèhófà tó dá wa pé ká máa ní ìbálópọ̀ fẹ́ kó o gbádùn rẹ̀ láìsí ìdààmú, àbámọ̀ àti àìbalẹ̀ ọkàn tí àwọn tó ń ṣàgbèrè máa ń ní. Ìdí nìyẹn tó fi sọ pé àárín tọkọtaya nìkan ló ti gbọ́dọ̀ máa wáyé.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Mo lè ṣe bíi ti Jósẹ́fù tó pinnu pé òun ò ní lọ́wọ́ nínú ìwà ìṣekúṣe tí mo bá ․․․․․

Mi ò ní ṣe àṣìṣe tí Dínà ṣe tí mo bá ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Bó tilẹ̀ jẹ́ pé níní ìbálòpọ̀ nígbà téèyàn ò tíì lẹ́tọ̀ọ́ sí i lè máa wu àwa èèyàn torí a jẹ́ aláìpé, kí nìdí tí kò fi dára?

● Kí lo máa ṣe bí ẹnì kan bá ní kó o jẹ́ kẹ́ ẹ jọ ní ìbálòpọ̀?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 185]

“Má gbàgbàkugbà láyè! Nígbà tí ọmọkùnrin kan gbọ́wọ́ ẹ̀ lé mi lára tó sì sọ pé ṣé màá jẹ́ kóun gbé mi sùn, ṣe ni mo sọ fún un pé, ‘Ó pẹ́ kó o tó gbọ́wọ́ ẹ kúrò léjìká mi!’ mo tún fójú kó o mọ́lẹ̀, mo sì fibẹ̀ sílẹ̀.”​—Ellen

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 187]

Tó o bá gbà kí wọ́n gbé ẹ sùn, o ta ara rẹ lọ́pọ̀ nìyẹn