Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Táwọn Ọkùnrin Kì Í Fi Í Gba Tèmi?

Kí Nìdí Táwọn Ọkùnrin Kì Í Fi Í Gba Tèmi?

ORÍ 27

Kí Nìdí Táwọn Ọkùnrin Kì Í Fi Í Gba Tèmi?

Bọ̀bọ́ yìí mọ̀ pé mo gbajúmọ̀ gan-an torí mo ti sọ fún un pé àwọn ọkùnrin gba tèmi. Ó rẹ́rìn-ín nígbà tí mo sọ fún un nípa bí àwọn ọ̀rẹ́ mi kan ṣe ya ọ̀dẹ̀ tó. Ó mọ̀ pé mo gbọ́n gan-an, mo tiẹ̀ ti tọ́ ọ sọ́nà nígbà tó sọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tí kò yẹ kó sọ. Mi ò wá mọ ìdí tí kò fi tíì sọ fún mi pé ká máa fẹ́ra wa.

Ọmọ yìí lẹ́wà lóòótọ́, àmọ́ ó jọ pé ẹwà ojú lásán ni! Kì í tiẹ̀ ń fún mi láyè láti sọ̀rọ̀! Bí mo bá wá jàjà sọ̀rọ̀, àṣìṣe mi ló máa ń rí! Bí mo bá ti rí i báyìí, ńṣe ló máa ń ṣe mí bíi kí n wábi gbà.

ṢÉ Ó máa ń dùn ẹ́ pé àwọn ọkùnrin ò rí tìẹ rò? Ọ̀pọ̀ ọmọbìnrin ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń dùn, títí kan àwọn tó o rò pé àwọn ọkùnrin gba tiwọn gan-an! Wo àpẹẹrẹ Joanne. Ó jẹ́ ọmọbìnrin tó lẹ́wà gan-an, tó ní làákàyè, tó sì mọ ọ̀rọ̀ sọ. Àmọ́, ó sọ pé: “Ó máa ń ṣe mí bíi pé àwọn ọmọkùnrin ò gba tèmi. Àwọn kan tí mo fẹ́ràn tiẹ̀ kọ́kọ́ ń gba tèmi, àmọ́ nígbà tó yá wọn ò tiẹ̀ dá sí mi mọ́ rárá!”

Kí ló máa ń fa àwọn ọmọkùnrin mọ́ra lára ọmọbìnrin? Kí ló sì máa ń lé wọn sá? Kí lo lè ṣe tí ọmọkùnrin tó jẹ́ ọmọlúwàbí á fi wá bá ẹ pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ?

Ohun Tó O Lè Ṣe

Mọ ara ẹ dunjú. Ó ṣeé ṣe kó o rí i pé nígbà tó o bẹ̀rẹ̀ sí í bàlágà o bẹ̀rẹ̀ sí í wu àwọn ọmọkùnrin gan-an. Ọkàn ẹ tiẹ̀ lè ti fà sí ọmọkùnrin bíi mélòó kan. Ìyẹn kì í ṣohun tuntun. Àmọ́ tó o bá lọ jẹ́ kí ìfẹ́ ọmọkùnrin tó kọ́kọ́ wù ẹ́ lára wọn kó sí ẹ lórí kíákíá, ó ṣeé ṣé kí ìyẹn ṣàkóbá fún ẹ kó o má lè ronú bó ṣe yẹ mọ́, kó o má sì lè tẹ̀ síwájú bó ṣe yẹ nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ó máa gba àkókò kó o tó lè dàgbà tó láti ní àwọn ìwà rere tó yẹ, kó o tó lè mọ bí wàá ṣe máa ‘yí èrò inú rẹ padà’ tó bá kan àwọn ohun tó ṣe pàtàkì, kí ọwọ́ ẹ sì tó lè tẹ àwọn nǹkan pàtàkì tí ìwọ fúnra rẹ ń fẹ́.​Róòmù 12:2; 1 Kọ́ríńtì 7:36; Kólósè 3:9, 10.

Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ ọmọkùnrin ló máa ń fẹ́ láti fa ojú àwọn ọmọbìnrin tí kò tíì gbọ́n dáadáa tàbí tí kò tíì ní ìrírí mọ́ra. Àmọ́, kì í ṣe ìwà tí ọmọbìnrin náà ní ló wu irú àwọn ọmọkùnrin bẹ́ẹ̀, ìrísí rẹ̀ lásán ló kàn wù wọ́n. Ohun tó dájú ni pé obìnrin tó láwọn ìwà tó máa wúlò nílé ọkọ ni ọkùnrin tó gbọ́n máa fẹ́ fi ṣe aya.​—Mátíù 19:6.

Ohun táwọn ọmọkùnrin kan sọ: “Ó máa ń wù mí kí ọmọbìnrin lè ṣèpinnu, kó sì mọ ohun tó ń ṣe.”​—James.

“Irú ọmọbìnrin tó ń wù mí kí n fẹ́ ni ọmọbìnrin tí kì í kàn gbà pé gbogbo ohun tí mo bá ṣáà ti sọ náà ló tọ̀nà, àmọ́ tó máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Mi ò fẹ́ ọmọbìnrin tó jẹ́ pé ohun tó bá ṣáà ti wù mí gbọ́ ló máa ń sọ, ì báà tiẹ̀ jẹ́ ọmọ tó rẹwà.”​—Darren.

Báwo lọ̀rọ̀ táwọn ọmọkùnrin yìí sọ ṣe rí lára rẹ?

․․․․․

Máa bọ̀wọ̀ fáwọn ẹlòmíì. Bó ṣe máa ń wù ẹ́ pé kí ọmọkùnrin nífẹ̀ẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ náà ló máa ń wu àwọn ọmọkùnrin gan-an pé kéèyàn bọ̀wọ̀ fún wọn. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé kí ọkọ fẹ́ràn aya rẹ̀, àmọ́ kí aya ní “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” fún ọkọ rẹ̀. (Éfésù 5:33) Ìwádìí táwọn kan ṣe fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, torí pé ọ̀dọ́kùnrin mẹ́fà nínú mẹ́wàá ló sọ pé àwọn ka ọ̀wọ̀ sí pàtàkì ju ìfẹ́ lọ. Nínú ìwádìí yẹn, èyí tó ju méje lọ nínú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tó jẹ́ àgbàlagbà ló fara mọ́ ohun táwọn ọ̀dọ́kùnrin wọ̀nyẹn sọ.

Bíbọ̀wọ̀ fáwọn ẹlòmíì kò túmọ̀ sí pé èrò rẹ ò ní yàtọ̀ sí tiwọn tàbí pé o ò ní máa sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 21:10-12) Bó o bá ṣe sọ èrò rẹ ló máa pinnu bóyá ọmọkùnrin máa sún mọ́ ẹ tàbí ó máa sá fún ẹ. Bó o bá ń ta ko gbogbo ohun tó bá sọ tàbí tó ò ń tún ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe, ó lè máa rò pé o ò bọ̀wọ̀ fóun bó ṣe yẹ. Àmọ́ tó o bá jẹ́ kó mọ̀ pé o gba ohun tó sọ, tó o sì mẹ́nu ba àwọn nǹkan tó dáa nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó fara mọ́ èrò ẹ, kó sì ka ọ̀rọ̀ ẹ sí. Tún rántí pé ọmọkùnrin tó bá lákìíyèsí á mọ̀ tó o bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn ará ilé rẹ àtàwọn ẹlòmíì.

Ohun táwọn ọmọkùnrin kan sọ: “Lójú tèmi, ọ̀wọ̀ ló ṣe pàtàkì jù nígbà táwọn méjì bá kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra wọn. Wọ́n lè wá nífẹ̀ẹ́ ara wọn nígbà tó bá yá.”​—Adrian.

“Bí ọmọbìnrin kan bá lè bọ̀wọ̀ fún mi, á jẹ́ pé kò ní ṣòro fún un láti nífẹ̀ẹ́ mi nìyẹn.”​—Mark.

Báwo lọ̀rọ̀ táwọn ọmọkùnrin yìí sọ ṣe rí lára rẹ?

․․․․․

Máa múra lọ́nà tó tọ́, kó o sì máa mọ́ tónítóní nígbà gbogbo. A lè fi aṣọ àti ìmúra ẹ wé ẹ̀rọ gbohùn-gbohùn tó ń sọ ohun tó ò ń rò àti irú ẹni tó o jẹ́ fáwọn èèyàn. Kó tiẹ̀ tó di pé ìwọ àti ọmọkùnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í jọ sọ̀rọ̀, ìmúra rẹ á ti jẹ́ kó mọ irú ẹni tó o jẹ́. Ojú tó dáa ló máa fi wò ẹ́ bí ìmúra rẹ bá jẹ́ ti ọmọlúwàbí. (1 Tímótì 2:9) Àmọ́ tí aṣọ bá fún mọ́ ẹ lára pinpin, tó ṣí ara sílẹ̀ tàbí tí kò dúró dáadáa lára rẹ, kíá lá ti máa wò ó pé o kì í ṣe ọmọlúwàbí!

Ohun táwọn ọmọkùnrin kan sọ: “Bí ọmọbìnrin kan bá ṣe múra máa ń sọ irú ẹni tó jẹ́. Tó bá wọ aṣọ tó ṣí ara sílẹ̀ tàbí èyí tí kò dúró dáadáa lára, màá wò ó pé ńṣe ló ń pe àfiyèsí sí ara rẹ̀.”​—Adrian.

“Mo fẹ́ràn ọmọbìnrin tó bá ń tọ́jú irun ẹ̀, tí ara ẹ̀ kì í rùn, tí ohùn ẹ̀ sì tuni lára. Ìgbà kan wà tí mo rí ọmọbìnrin kan tí ẹwà ẹ̀ kọ́kọ́ fà mí mọ́ra, àmọ́ nígbà tí mo wá rí i pé ọ̀bùn ni, ńṣe ni ìfẹ́ yẹn kàn kúrò lọ́kàn mi.”​—Ryan.

“Ká sòótọ́, ọkàn mi máa kọ́kọ́ fà sí ọmọbìnrin tó bá wọ aṣọ tó fún mọ́ra pinpin tàbí tó ṣí ara sílẹ̀, àmọ́, mi ò lè fẹ́ irú ọmọbìnrin bẹ́ẹ̀.”​—Nicholas.

Báwo lọ̀rọ̀ táwọn ọmọkùnrin yìí sọ ṣe rí lára rẹ?

․․․․․

Ohun Tí Kò Yẹ Kó O Ṣe

Má ṣe tage. Ìfẹ́ obìnrin máa ń lágbára lórí àwọn ọkùnrin gan-an. Àwọn obìnrin sì lè lo ìyẹn lórí àwọn ọkùnrin lọ́nà tó tọ́ tàbí lọ́nà tí kò tọ́. (Jẹ́nẹ́sísì 29:17, 18; Òwe 7:6-23) Bó bá jẹ́ pé gbogbo ọmọkùnrin tó o bá ṣáà ti rí lo máa ń fẹ́ wò bóyá ó máa gba tìẹ, oníṣekúṣe làwọn èèyàn máa kà ẹ́ sí.

Ohun táwọn ọmọkùnrin kan sọ: “Tí ọmọkùnrin bá kàn jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọmọbìnrin kan tó wà pa tí wọ́n sì ń fara kanra lásán, ó máa ń dùn mọ́ ọmọkùnrin. Torí náà, tí ọmọbìnrin kan bá tún wá ń fọwọ́ jẹ ọmọkùnrin lára ṣáá nígbà tí wọ́n bá jọ ń sọ̀rọ̀, ojú oníṣekúṣe ni mo máa fi wo ọmọbìnrin yẹn.”​—Nicholas.

“Bó bá jẹ́ pé gbogbo ọmọkùnrin tí ọmọbìnrin kan bá ṣáà ti pàdé ló máa ń fẹ́ fọwọ́ jẹ lára tàbí tójú ẹ̀ kì í kúrò lára gbogbo ọmọkùnrin tó bá ń kọjá, oníṣekúṣe lèmi ka irú wọn sí, mi ò sì ń wo irú wọn pé ẹ̀ẹ̀mejì.”​—José.

Má kàn máa so mọ́ ẹni tó ò ń fẹ́ káàkiri. Bíbélì sọ pé tí ọkùnrin àti obìnrin bá ti ṣègbéyàwó, wọ́n á di “ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Lẹ́yìn ìgbéyàwó, àwọn tó di tọkọtaya kì í sábà ní òmìnira púpọ̀ mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀, torí pé wọ́n á fẹ́ ṣe ara wọn lọ́kan. (1 Kọ́ríńtì 7:32-34) Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ìwọ àti ọmọkùnrin kan ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mọra yín ni, o ò lẹ́tọ̀ọ́ láti máa retí pé gbogbo ohun tó bá ń ṣe ni kó máa sọ fún ẹ, òun náà ò sì gbọ́dọ̀ retí ìyẹn látọ̀dọ̀ rẹ. * Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, tó o bá jẹ́ kó mọ̀ pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ yàtọ̀ síwọ nìkan, ìyẹn lè jẹ́ kó túbọ̀ gba tìẹ gan-an. Bó sì ṣe ń lo òmìnira tó ní yẹn máa jẹ́ kó o mọ irú èèyàn tó jẹ́ gan-an.​—Òwe 20:11.

Ohun táwọn ọmọkùnrin kan sọ: “Tó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tí mo bá ń ṣe ni ọmọbìnrin kan máa ń fẹ́ mọ̀, tó sì dà bíi pé kì í fẹ́ bá àwọn míì da nǹkan pọ̀, tí kò sì tún ní nǹkan míì tó ń rò mọ́ àfi èmi nìkan ṣáá, a jẹ́ pé ó ń so mọ́ mi jù nìyẹn.”​—Darren.

“Bí ọmọbìnrin tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdé bá ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sórí fóònù mi ṣáá, tó sì ń fẹ́ mọ àwọn tá a jọ wà níbi tí mo wà, pàápàá tó bá fẹ́ mọ orúkọ àwọn ọmọbìnrin tó wà láàárín wa, á jẹ́ pé ọ̀rọ̀ wa ò lè wọ̀ nìyẹn.”​—Ryan.

“Èmi ò fẹ́ ọmọbìnrin tí kò bá ti ní jẹ́ kí n gbádùn ara mi pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi ọkùnrin, tó sì máa ń bínú pé mi kì í pe òun wá sọ́dọ̀ mi nígbà gbogbo.”​—Adrian.

Báwo lọ̀rọ̀ táwọn ọmọkùnrin yìí sọ ṣe rí lára rẹ?

․․․․․

Má Ṣe Fi Ara Rẹ Wọ́lẹ̀

Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn ọmọbìnrin kan tó jẹ́ pé kò sóhun tí wọn ò lè ṣe kí ọmọkùnrin lè gba tiwọn. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń wọ́ ara wọn nílẹ̀ kí wọ́n ṣáà lè rí ọkùnrin tó máa gba tiwọn tàbí torí kí wọ́n lè rí ọkọ. Àmọ́, ó yẹ kó o máa rántí ìlànà tó sọ pé ‘ohun tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn ló máa ká.’ (Gálátíà 6:7-9) Bó o bá tara ẹ lọ́pọ̀, tó o sì pa ìwà ọmọlúwàbí tì, àwọn ọmọkùnrin tí kò mọyì ẹ, tí wọn ò sì ka ìwà ọmọlúwàbí sí pàtàkì ló máa gba tìẹ.

Ká sòótọ́, kì í ṣe gbogbo ọmọkùnrin ló máa gba tìẹ, ohun tó dáa sì nìyẹn! Àmọ́ tó bá jẹ́ pé bó o ṣe ń fún ẹwà ara ẹ láfiyèsí náà lò ń fún ẹwà inú ẹ láfiyèsí, wàá “níye lórí gidigidi lójú Ọlọ́run,” irú ọkùnrin tó tọ́ sí ẹ lo sì máa rí fi ṣe ọkọ.​—1 Pétérù 3:4.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ká sọ pé ọ̀dọ́kùnrin ni ẹ́, kí lo lè ṣe tó o bá ti máa ń rò ó pé, ‘Kí nìdí táwọn ọmọbìnrin kì í fi í gba tèmi?’

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 30 Àmọ́ ṣá o, bí ẹni méjì bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra wọn, ó yẹ kí wọ́n máa finú han ara wọn.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Òòfà ẹwà lè jẹ́ èké, ẹwà ojú sì lè jẹ́ asán; ṣùgbọ́n obìnrin tí ó bẹ̀rù Jèhófà ni ẹni tí ó gba ìyìn fún ara rẹ̀.”​—Òwe 31:30.

ÌMỌ̀RÀN

Má ṣe ki àṣejù bọ bó o ṣe ń tọ́jú-tọ́tè! Tó bá ti pọ̀ jù, ó lè jẹ́ káwọn èèyàn máa ro nǹkan míì nípa rẹ, kí wọ́n rò pé ṣe lò ń gbéra ga tàbí pé ṣe lò ń pe àfiyèsí sí ara rẹ.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Bó o bá ń retí pé kí ọ̀dọ́kùnrin kan máa gbọ́ tìẹ ní gbogbo ìgbà ṣáá, èyí lè pa iná ìfẹ́ tó wà láàárín yín.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Ìwà tí màá rí i pé mo ṣàtúnṣe sí ni ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o ka èrò ọ̀dọ́kùnrin kan sí, àti pé o ò kàn sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di ṣeréṣeré?

● Kí lo lè ṣe tó ò fi ní wọ́ ara rẹ nílẹ̀?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 190]

“Lóòótọ́ ẹwà àwọn ọmọbìnrin ló sábà máa ń jẹ́ kí n kọ́kọ́ fẹ́ràn wọn. Àmọ́, ìfẹ́ yẹn lè pòórá bí ọmọbìnrin náà ò bá láwọn ohun pàtó kan tó fẹ́ fayé ẹ̀ ṣe. Ṣùgbọ́n bí ọmọbìnrin kan bá ti mọ ohun tó fẹ́ fí ayé ẹ̀ ṣe, tọ́wọ́ rẹ̀ tún ti tẹ àwọn nǹkan kan tó ń lé, ìyẹn ti tó fún mi láti gba tiẹ̀ gan-an.”​—Damien

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 191]

Bó ṣe jẹ́ pé táyà kẹ̀kẹ́ méjèèjì ló ṣe pàtàkì, bẹ́ẹ̀ náà ni ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ ṣe pàtàkì