Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwòkọ́ṣe—Jékọ́bù

Àwòkọ́ṣe—Jékọ́bù

Àwòkọ́ṣe​—Jékọ́bù

Fún ọ̀pọ̀ ọdún, Jékọ́bù àti Ísọ̀ kò bá ara wọn sọ̀rọ̀. Ísọ̀ kórìíra Jékọ́bù gan-an ni. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jékọ́bù kọ́ ló jẹ̀bi ohun tó ṣẹlẹ̀ náà, òun ló kọ́kọ́ ṣe ohun tó jẹ́ kí wọ́n lè parí ìjà àárín wọn. Jékọ́bù rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ó sì yááfì àwọn nǹkan kan. Kò wá ọ̀nà láti fi hàn pé òun lòun jàre ọ̀rọ̀ náà, bí inú Ísọ̀ tí wọ́n jọ jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ṣe máa yọ́ sí i ló ń wá. Àmọ́ kì í ṣe pé Jékọ́bù wá fàyè gba ohun tí kò dáa o, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ pé àfi kí Ísọ̀ kọ́kọ́ wá bẹ̀bẹ̀ kí àwọn tó lè yanjú ọ̀rọ̀ náà.Jẹ́nẹ́sísì 25:27-34; 27:30-41; 32:3-22; 33:1-9.

Kí lo máa ń ṣe bí èdè àìyedè bá wáyé láàárín ìwọ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìdílé? Nígbà míì, ó tiẹ̀ lè dá ẹ lójú pé ìwọ lo jàre, pé ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ tàbí òbí rẹ ló jẹ̀bi. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé o máa ń retí pé ẹni yẹn ló yẹ kó kọ́kọ́ wá bá ẹ kí ọ̀rọ̀ náà tó lè yanjú? Ǹjẹ́ o lè máa ṣe bíi Jékọ́bù? Níbi tí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ kò bá ti ta ko ìlànà Bíbélì, ǹjẹ́ wàá lè rẹ ara rẹ sílẹ̀, kó o yááfì àwọn nǹkan kan kí àlàáfíà bàa lè wà? (1 Pétérù 3:8, 9) Jékọ́bù kò jẹ́ kí ẹ̀mí ìgbéraga pín ìdílé àwọn níyà. Ṣe ló rẹ ara rẹ sílẹ̀ kí òun àti Ísọ̀ lè pa dà di ọ̀rẹ́. Ṣé ìwọ náà máa ṣe bẹ́ẹ̀ tí ọ̀rọ̀ bá wáyé láàárín ìwọ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ wà nínú ìdílé?