Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwòkọ́ṣe—Jóòbù

Àwòkọ́ṣe—Jóòbù

Àwòkọ́ṣe​—Jóòbù

Gbogbo nǹkan dojú rú pátápátá fún Jóòbù. Àkọ́kọ́, ó pàdánù gbogbo nǹkan tó fi ń gbọ́ bùkátà. Ìkejì, gbogbo ọmọ ẹ̀ pátá kú. Ìkẹta, ó ṣàìsàn kan tó le gan-an. Òjijì ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí kàn dédé ṣẹlẹ̀ sí i. Jóòbù wá ronú pé kò sí ọ̀nà àbáyọ mọ́, ó ní: “Dájúdájú, ọkàn mi kórìíra ìgbésí ayé mi tẹ̀gbintẹ̀gbin.” Ó sì sọ pé òun jẹ́ “ẹni tí ó kún fún àbùkù, tí a sì fi ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́ pá lórí.” (Jóòbù 10:1, 15) Ṣùgbọ́n nínú gbogbo ìpọ́njú yìí, Jóòbù kò fi Ẹlẹ́dàá rẹ̀ sílẹ̀. (Jóòbù 2:10) Kò torí àwọn ìṣòro tó dé bá a kó wá yí gbogbo dáadáa tó ti ń ṣe bọ̀ pa dà. Ìdí nìyẹn tí Jóòbù fi jẹ́ àpẹẹrẹ rere ní ti pé kéèyàn ní ìfaradà.

Tó o bá ní ìṣòro tó pọ̀, gbogbo nǹkan lè sú ẹ, kí ìwọ náà wá ‘kórìíra ìgbésí ayé rẹ.’ Àmọ́ o lè ṣe bíi ti Jóòbù, kó o má gbà kí àwọn ìṣòro náà mú ẹ yí dáadáa tó o ti ń ṣe bọ̀ pa dà, kó o sì máa bá ìjọsìn Jèhófà Ọlọ́run lọ láìyẹsẹ̀. Jákọ́bù sọ pé: “Wò ó! Àwọn tí wọ́n lo ìfaradà ní a ń pè ní aláyọ̀. Ẹ ti gbọ́ nípa ìfaradà Jóòbù, ẹ sì ti rí ìyọrísí tí Jèhófà mú wá, pé Jèhófà jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi nínú ìfẹ́ni, ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jákọ́bù 5:11) Ọlọ́run ò fi Jóòbù sílẹ̀, kò ní fi ìwọ náà sílẹ̀!