Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwòkọ́ṣe—Mósè

Àwòkọ́ṣe—Mósè

Àwòkọ́ṣe​—Mósè

Mósè jẹ́ ẹni tó ní àǹfààní tó pọ̀ gan-an. Ààfin Fáráò ni wọ́n ti tọ́ ọ dàgbà, wọ́n sì tún kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa gbogbo ọgbọ́n àwọn ará Íjíbítì. (Ìṣe 7:22) Kí ló máa wá fi àwọn ẹ̀kọ́ tó kọ́ yìí ṣe? Ó lè fi lépa bó ṣe máa di olókìkí, ọlọ́lá àti alágbára. Ṣùgbọ́n kò jẹ́ kí ohun táwọn èèyàn tó yí òun ká ń ṣe darí òun, kò sì lépa bí ó ṣe máa dé ipò ọlá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ohun tó yàn láti ṣe máa ya ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́nu. Ó “yàn pé kí a ṣẹ́ òun níṣẹ̀ẹ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run.” (Hébérù 11:25) Ǹjẹ́ Mósè kábàámọ̀ nítorí ìpinnu tó ṣe yẹn? Rárá o. Nítorí pé ó yàn láti sin Ọlọ́run àti láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ayé rẹ̀ dùn, Ọlọ́run sì san án lẹ́san rere.

Tó o bá láǹfààní láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tó o sì kàwé dáadáa, kí lo máa fi ìwé tó o kà yẹn ṣe? O lè fi lépa bó o ṣe máa lówó tàbí bó o ṣe máa di alágbára. O sì lè yàn láti ṣe bíi ti Mósè, kó o fi ṣe ohun tó máa wúlò gan-an lójú Ọlọ́run. O lè lo ìmọ̀ àti òye tó o gbà àtàwọn ohun ìní rẹ láti fi sin Ọlọ́run àti láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. (Mátíù 22:35-40) Kò sí nǹkan míì tó o tún lè fi ayé rẹ ṣe tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní gan-an tó bẹ́ẹ̀!