Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwòkọ́ṣe—Rúùtù

Àwòkọ́ṣe—Rúùtù

Àwòkọ́ṣe​—Rúùtù

Tó bá dọ̀rọ̀ ìdúróṣinṣin, àpẹẹrẹ pàtàkì ni Rúùtù jẹ́. Ó yàn láti dúró ti ìyá ọkọ rẹ̀ tó ti dàgbà, ìyẹn Náómì, dípò kó pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ níbi tí ayé ti dẹrùn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé, ohun tó yàn láti ṣe yìí lè jẹ́ kó ṣòro fún un láti rí ẹlòmíì tó máa fẹ́ ẹ, síbẹ̀ ọ̀rọ̀ tara rẹ̀ nìkan kọ́ ni Rúùtù gbájú mọ́. Ìfẹ́ Náómì tó ní àti bó ṣe wù ú láti wà pẹ̀lú àwọn èèyàn Jèhófà jẹ ẹ́ lógún gan-an ju pé kó ṣáà ti rí ọkọ míì fẹ́.​—Rúùtù 1:8-17.

Ṣé ìwọ náà ń ronú nípa ìgbéyàwó? A jẹ́ pé ó máa dáa kó o tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Rúùtù. Má kàn máa ro bí nǹkan ṣe rí lára tìẹ nìkan, ronú lórí àwọn ìwà dáadáa tó yẹ kó o ní tí wàá fi lè jẹ́ ọkọ tàbí aya rere. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ olóòótọ́ èèyàn ni ẹ́, ṣé o sì lè lo ara rẹ nítorí àwọn ẹlòmíì? Ǹjẹ́ ò ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run, kódà nígbà tí ẹran ara aláìpé bá fẹ́ kó o ṣe nǹkan míì? Kì í ṣe pé Rúùtù ń wá ọkọ lójú méjèèjì. Síbẹ̀ nígbà tó yá, ó rí ọkùnrin kan tó jẹ́ olóye èèyàn, tí ìwà wọn jọra fẹ́. Èyí tó tiẹ̀ tún wá ṣe pàtàkì jù ni pé ọkùnrin náà nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ tìẹ náà lè rí bíi ti Rúùtù.