Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Táwọn Obìnrin Kì Í Fi Í Gba Tèmi?

Kí Nìdí Táwọn Obìnrin Kì Í Fi Í Gba Tèmi?

ORÍ 28

Kí Nìdí Táwọn Obìnrin Kì Í Fi Í Gba Tèmi?

Mo ti dánnu fún un gan-an. Mo ti sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún un nípa ara mi, nǹkan tí mo ní, ibi tí mo ti dé rí, àwọn èèyàn tí mo mọ̀. Ìfẹ́ mi á ti máa pa á bí ọtí!

Ńṣe ló dà bíi pé kílẹ̀ lanu kó gbé mi mì! Ṣé kò yẹ kí nǹkan tí mò ń sọ ti yé e ni? Ọgbọ́n wo ni mo máa dá báyìí, kó lè fi mí lọ́rùn sílẹ̀ láìjẹ́ pé mo wọ́ ọ nílẹ̀?

O TI tó ní àfẹ́sọ́nà. Ọmọbìnrin tó lẹ́wà tí ẹ̀sìn yín sì pa pọ̀ ló máa wù ẹ́ kó jẹ́ àfẹ́sọ́nà rẹ. (1 Kọ́ríńtì 7:39) Àmọ́ ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé tí ọ̀rọ̀ ìwọ àti ọmọbìnrin kan bá ti fẹ́ máa wọ̀ báyìí, gbogbo rẹ̀ á kàn tún dà rú. Kí ló wá ń fà á? Àbí àwọn tó dáa lọ́mọkùnrin nìkan làwọn obìnrin ń wá ni? Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Lisa sọ pé: “Mo máa ń gba ti ọkùnrin tó bá ní igẹ̀ dáadáa.” Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn obìnrin ló máa ń wò ju ìyẹn lọ lára ọkùnrin. Ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] kan tó ń jẹ́ Carrie sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọkùnrin tó dùn ún wò ni kì í sábà ní ìwà tó dáa.”

Kí làwọn “ìwà tó dáa” táwọn obìnrin máa ń wá lára ọkùnrin? Tó o bá rí ọmọbìnrin kan tó wù ẹ́ pé kó o fẹ́, àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o fi sọ́kàn? Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló sì yẹ kó o máa rántí?

Ohun Tó Yẹ Kó O Kọ́kọ́ Ṣe

Kó o tó lọ bá ọmọbìnrin kan pé o fẹ́ fẹ́ ẹ, àwọn nǹkan kan wà tó yẹ kó o mọ̀, nǹkan wọ̀nyẹn á sì jẹ́ kó o lè bá ẹnikẹ́ni tó bá wù ẹ́ ṣọ̀rẹ́. Wo àwọn nǹkan wọ̀nyí.

Kọ́ bá a ṣe ń hùwà ọmọlúwàbí. Bíbélì sọ pé “ìfẹ́ kì í ṣe ohun tí kò tọ́.” (1 Kọ́ríńtì 13:5, Ìròhìn Ayọ̀) Ìwà ọmọlúwàbí kò ní jẹ́ kó o máa yájú sáwọn ẹlòmíì, á sì mú kó o máa hùwà tó yẹ ẹni tó bá jẹ́ Kristẹni. Àmọ́ ṣá o, ìwà ọmọlúwàbí kì í ṣe ohun tí wàá máa gbé wọ̀ bí ẹ̀wù kó o lè gbayì lójú àwọn èèyàn, kó o wá bọ́ ọ sílẹ̀ nígbà tó o bá délé. Torí náà, máa bi ara rẹ pé, ‘Ṣé ìwà tó yẹ ọmọ dáadáa ni mò ń hù nínú ilé?’ Bí o kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ńṣe lò ń fagídí hùwà ọmọlúwàbí lójú àwọn ẹlòmíì. Torí náà, ó máa dáa kó o mọ̀ pé ọmọbìnrin tó bá gbọ́n máa kíyè sí bó o ṣe ń ṣe sí àwọn ará ilé rẹ kó bàa lè mọ irú ẹni tó o jẹ́.​—Éfésù 6:1, 2.

Ohun táwọn ọmọbìnrin kan sọ: “Ó máa ń dá mi lọ́rùn tí ọmọkùnrin kan bá ń hùwà ọmọlúwàbí nínú àwọn nǹkan kékeré bíi kó ṣílẹ̀kùn fún mi, àti nínú àwọn nǹkan pàtàkì bíi kó jẹ́ onínúure kó sì máa gba tèmi àtàwọn ẹbí mi rò.”​—Tina.

“Mo kórìíra kẹ́ni tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ bá pàdé máa bi mí láwọn ìbéèrè bíi ‘Ṣé o ti lẹ́ni tó ò ń fẹ́?’ tàbí ‘Kí làwọn nǹkan pàtàkì tó o fẹ́ ṣe?’ Kò pọ́n mi lé, ó sì máa ń rí bákan lára mi!”​—Kathy.

“Mo máa ń kà á sí ìwà àìkanisí táwọn ọkùnrin bá rò pé àwọn kàn lè ṣe àwa obìnrin bó ṣe wù wọ́n, kí wọ́n má tiẹ̀ fẹ́ mọ bí nǹkan ṣe rí lára tàwa náà, kí wọ́n sì wá máa fojú ẹni tó ń wá ọkọ lójú méjèèjì wò wá bíi pé ṣe la fẹ́ kí wọ́n ṣáà ṣàánú wa.”​—Alexis.

Jẹ́ kí ara rẹ máa mọ́ tónítóní. Ìmọ́tótó máa ń fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fáwọn ẹlòmíì àti ara rẹ. (Mátíù 7:12) Bó o bá fọ̀wọ̀ wọ ara rẹ, àwọn míì á fọ̀wọ̀ wọ̀ ẹ́. Àmọ́, bí o kì í bá ń túnra ṣe, kò sí báwọn ọmọbìnrin á ṣe máa gba tìẹ.

Ohun táwọn ọmọbìnrin kan sọ: “Nǹkan tí kò jẹ́ kí n gba ti ọmọkùnrin kan tó lóun nífẹ̀ẹ́ mi ni pé ẹnu ẹ̀ máa ń rùn, mi ò sì lè fara dà á rárá.”​—Kelly.

Mọ béèyàn ṣe ń báni sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dára. Ohun tó máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn olólùfẹ́ méjì wọ̀ dáadáa ni pé kí wọ́n jọ máa sọ̀rọ̀ dáadáa. Èyí túmọ̀ sí pé wàá máa sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tó jẹ ẹni tó ò ń fẹ́ lógún, kì í ṣe tìẹ nìkan ni wàá máa sọ ṣáá. (Fílípì 2:3, 4) Wàá máa fara balẹ̀ gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ, o ò sì ní máa kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ dà nù.

Ohun táwọn ọmọbìnrin kan sọ: “Ó máa ń dá mi lọ́rùn tọ́rọ̀ bá yọ̀ mọ́ ọkùnrin kan lẹ́nu, tó tètè ń rántí nǹkan tí mo sọ fún un, tó sì ń bi mí láwọn ìbéèrè tó ń mú kọ́rọ̀ tá à ń sọ máa dùn lọ.”​—Christine.

“Nǹkan témi rò ni pé, ohun táwọn ọkùnrin bá rí ló máa ń dá wọn lọ́rùn, àmọ́ nǹkan táwọn obìnrin bá gbọ́ ló máa ń wú wọn lórí.”​—Laura.

“Ká fúnni lẹ́bùn dáa lóòótọ́ o. Àmọ́, ó ti máa lọ wà jù tọ́rọ̀ bá dá mọ́ ọmọkùnrin lẹ́nu, tó mọ bá a ṣe ń fọ̀rọ̀ tuni nínú tó sì mọ̀ọ̀yàn fún níṣìírí. Áà, á ti lọ wà jù!”​—Amy.

“Mo mọ ọkùnrin kan tó máa ń pọ́n èèyàn lè tí kì í sì í ki àṣejù bọ ọ̀rọ̀ rẹ̀. A máa ń sọ̀rọ̀ tó nítumọ̀ láìsí pé ó ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ bí, ‘Mo gba ti bí ara ẹ ṣe ń ta sánsán yìí o’ tàbí ‘O dùn gan-an lónìí ṣá.’ Ó máa ń fara balẹ̀ gbọ́ mi, ìyẹn sì tó láti kó sí ọmọbìnrin èyíkéyìí lórí.”​—Beth.

“Ó máa ń wú mi lórí tẹ́nì kan bá ń ṣàwàdà, tó sì tún máa ń sọ bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ láìsí pé ó kàn ń dánnu lásán.”​—Kelly.

Tẹpá mọ́ṣẹ́. Bíbélì sọ pé: “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Gálátíà 6:5) Àwọn ọmọbìnrin ò ní gba ti ọmọkùnrin tí kò níṣẹ́ kan pàtó lọ́wọ́, wọ́n á rò pé bóyá torí pé ó ya ọ̀lẹ tàbí tórí pé eré rẹ̀ pọ̀ jù ni iṣẹ́ ṣe ń bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀.

Ohun táwọn ọmọbìnrin kan sọ: “Ì bá dáa táwọn ọkùnrin kan bá lè túbọ̀ tẹpá mọ́ṣẹ́. Kò sẹ́ni tó máa fẹ́ gba tiwọn tí wọ́n bá ya ọ̀lẹ. Torí ìyẹn máa fi hàn pé wọn ò mọ nǹkan tí wọ́n ń ṣe.”​—Carrie.

“Àwọn ọmọkùnrin kan kì í mọ nǹkan tí wọ́n máa ṣe láyé tiwọn. Tí wọ́n bá rí ọmọbìnrin kan tí wọ́n fẹ́ fẹ́, wọ́n á wá bi í pé kí lohun tó fẹ́ fi ayé rẹ̀ ṣe, tí ọmọbìnrin náà bá ti dáhùn tán, àwọn á ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé, ‘Irọ́ o, ohun témi náà fẹ́ ṣe nìyẹn!’ Àmọ́ ohun tí wọ́n á máa hù níwà fi hàn pé irọ́ pátápátá ni wọ́n ń pa.”​—Beth.

Tó o bá tẹpá mọ́ṣẹ́ bá a ṣe sọ lókè yìí, ìyẹn á jẹ́ kó o lè láwọn ọ̀rẹ́ gidi tó máa sún mọ́ ẹ. Ká wá sọ pé o ti ṣe tán láti máa fẹ́ ọmọbìnrin kan sọ́nà, kí làwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe?

Ohun Tó Kàn Láti Ṣe

Ìwọ ni kó o dá ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀. Tó o bá rí ọmọbìnrin kan tó wù ẹ́, tó o sì rí i pé ó ṣeé fi ṣaya, sọ fún un pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ gan-an fún un ní kedere. Lóòótọ́ ó lè má dùn-ún sọ. O ò sì ní fẹ́ kó sọ pé òun ò gbà. Àmọ́, pé o tiẹ̀ gbẹ́nu lé e pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ lásán ti fi hàn pé ìwọ náà ti dọkùnrin. Àmọ́ ṣá, ohun kan rèé o: O ò tíì ní bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ ìgbéyàwó o. Torí náà, ṣe ni kó o fọgbọ́n ṣe é. Tó o bá ti jẹ́ kọ́rọ̀ náà ká ẹ lára jù tàbí tí o kò fún ọmọbìnrin náà láyè láti ronú, ìyẹn lè dẹ́rù bà á, kó sì sá dípò kó gbà fún ẹ.

Ohun táwọn ọmọbìnrin kan sọ: “Inú mi ni mo mọ̀, mi ò mọ ti ẹlòmíì. Tẹ́nì kan bá fẹ́ fẹ́ mi, ṣe ni kó lanu sọ̀rọ̀.”​—Nina.

“Ó lè má rọrùn láti gbé ọ̀rọ̀ fífẹ́ wọ̀ ọ́ bó bá ti ṣe díẹ̀ tẹ́ ẹ ti ń bá ọ̀rẹ́ yín bọ̀. Àmọ́, mi ò ní bínú tí ọmọkùnrin kan bá dìídì sọ fún mi pé òun fẹ́ kí ọ̀rẹ́ wà ju ọ̀rẹ́ lásán lọ.”​—Helen.

Ka ìpinnu ọmọbìnrin náà sí. Tí ọmọbìnrin tí ó ń wù ẹ́ yìí bá wá sọ pé òun ò fẹ́ kẹ́ ẹ fẹ́ra ńkọ́? Bọ̀wọ̀ tiẹ̀ fún un tó bá lóun ò gbà. Tó o bá ní àforí àfọrùn kó ṣe tìẹ, a jẹ́ pé ò ń ṣe bí ọmọdé nìyẹn. Tí o kò bá ka ohun tó sọ sí, tó o tún ń bínú torí pé kò gbà fún ẹ, ṣé kì í ṣe pé tára rẹ nìkan lò ń rò, tí o kò ro tiẹ̀ mọ́ tìẹ?​—1 Kọ́ríńtì 13:11.

Ohun táwọn ọmọbìnrin kan sọ: “Ó máa ń rí bákan lára mi bí mo bá sọ fún ọkùnrin kan pé mi ò ṣe, tó wá ní dandan àfi kí n gbà.”​—Colleen.

“Mo ṣàlàyé fún ọmọkùnrin kan pé mi ò gba tiẹ̀, síbẹ̀, ńṣe ló ń dà mí láàmú pé kí n fún òun ní nọ́ńbà fóònù mi. Mi ò fẹ́ dójú tì í. Torí mo mọ̀ pé kò rọrùn fún un láti wá bá mi. Àmọ́ nígbà tó yá, mo ní láti là á mọ́lẹ̀ fún un pé mi ò ṣe sẹ́ẹ̀!”​—Sarah.

Àwọn Nǹkan Tí Kò Yẹ Kó O Ṣe

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin kan máa ń rò pé kò ṣòro fáwọn láti fa ojú àwọn ọmọbìnrin mọ́ra. Kódà, wọ́n tún lè máa bá àwọn ojúgbà wọn fà á kí wọ́n lè mọ ẹni táwọn ọmọge máa gba tiẹ̀ jù. Àmọ́, irú ìbára-ẹni-díje bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìwà òǹrorò, ó sì lè sọ ẹ́ lórúkọ tí ò dáa. (Òwe 20:11) O lè yẹra fún irú nǹkan tá a sọ yìí tó o bá ṣe àwọn nǹkan tó wà nísàlẹ̀ yìí.

Má ṣe tage. Ẹni tó ń tage máa ń lo ọ̀rọ̀ dídùn, ó sì máa ń fara sọ̀rọ̀ lọ́nà tó lè mú kí ọkàn ẹni fà sí ìbálòpọ̀. Kì í ṣe pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ dìídì fẹ́ fi ẹni tó ń bá tage ṣe aya, nǹkan míì ló ní lọ́kàn. Irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ lòdì sí ọ̀rọ̀ Bíbélì tó sọ pé ká máa hùwà sí “àwọn ọ̀dọ́bìnrin gẹ́gẹ́ bí arábìnrin pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.” (1 Tímótì 5:2) Àwọn tó ń tage kì í ṣe ọ̀rẹ́ tó wúlò, wọn kì í sì í jẹ́ ọkọ rere. Àwọn obìnrin tí orí wọn pé mọ ìyẹn dájú.

Ohun táwọn ọmọbìnrin kan sọ: “Nǹkan tí ò dáa rárá ni pé kí ọkùnrin kan sọ̀rọ̀ dídùn fún ẹ tó o sì mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ ló ṣe sọ ọ́ fún ọ̀rẹ́ ẹ kan lóṣù tó kọjá.”​—Helen.

“Nígbà kan, ọmọkùnrin tó wà pa yìí fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fa ojú mi mọ́ra, ó wá ń pọ́n ara ẹ̀. Ohun tó wá ṣẹlẹ̀ ni pé nǹkan kan náà ló ṣe sí ọmọbìnrin kan tó wá bá wa níbẹ̀, ìgbà tí ọmọbìnrin kẹta sì dé, ó tún ṣe bẹ́ẹ̀ síyẹn náà. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò dáa rárá!”​—Tina.

Má kàn máa fi ìfẹ́ àwọn ọmọbìnrin ṣeré. Ó yẹ kó o mọ̀ pé bíbá ọkùnrin bíi tìẹ ṣọ̀rẹ́ yàtọ̀ sí bíbá obìnrin ṣọ̀rẹ́ o. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Wo àpẹẹrẹ yìí ná: Ọ̀rẹ́ rẹ tó jẹ́ ọkùnrin kò lè ronú pé o fẹ́ fẹ́ òun ni tó o bá ń yẹ́ ẹ sí pé aṣọ rẹ̀ dáa tàbí tó o bá ń bá a sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìgbà, tó o sì ń finú hàn án. Àmọ́, ọmọbìnrin kan lè rò pé o fẹ́ fẹ́ òun ni tó o bá sọ fún un pé aṣọ tó wọ̀ dáa lára ẹ̀ tàbí tó o bá ń bá a sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìgbà, tó o sì ń finú hàn án.

Ohun táwọn ọmọbìnrin kan sọ: “Mi ò rò pé àwọn ọkùnrin mọ̀ pé báwọn ṣe ń ṣe síra wọn kọ́ ló yẹ kí wọ́n máa ṣe sí obìnrin.”​—Sheryl.

“Ọmọkùnrin kan gba nọ́ńbà fóònù mi, ó sì kọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí mi lórí fóònù. Tí kò bá ní nǹkan kan lọ́kàn, kí ló ń ṣe gbogbo ìyẹn fún? Ìgbà míì wà tó jẹ́ pé bẹ́ ẹ ṣe ń kọ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ síra yín lórí fóònù, ẹ ti máa yófẹ̀ẹ́ fún ara yín. Ó ṣe tán, ìwọ̀nba lára ohun téèyàn ní lọ́kàn lèèyàn kúkú máa ń kọ ránṣẹ́ lórí fóònù.”​—Mallory.

“Mi ò rò pé àwọn ọkùnrin kan máa ń mọ bí ìfẹ́ ṣe tètè ń wọ obìnrin lára tó, àgàgà kí ọkùnrin yẹn lọ jẹ́ ẹni tó mọ obìnrin tọ́jú tó sì ṣeé bá sọ̀rọ̀. Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé irú obìnrin bẹ́ẹ̀ ń wọ́kọ lójú méjèèjì o. Mo kàn rò pé ṣe ni ọ̀pọ̀ ọmọbìnrin máa ń fẹ́ lẹ́nì kan tí wọ́n yófẹ̀ẹ́ fún, ọkàn wọn sì máa ń wá ẹni tó máa jẹ́ olólùfẹ́ yẹn.”​—Alison.

KÀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 3, NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Báwo lo ṣe lè mọ ìyàtọ̀ láàárín ìfẹ́ tòótọ́ àti ìfẹ́ oréfèé?

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin.”​—Éfésù 4:24.

ÌMỌ̀RÀN

Béèrè lọ́wọ́ àwọn àgbàlagbà mélòó kan pé ìwà wo ló ṣe pàtàkì pé kí ọ̀dọ́ kan máa hù, kó o sì wá rí i pé o ní àwọn ìwà yẹn.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Bó o ṣe rí lóde kò ṣe pàtàkì tó irú ẹni tó o jẹ́ nínú lọ́hùn-ún.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Ìwà mi kan tí kò dáa tó, tí màá fẹ́ rí i pé mo ṣàtúnṣe sí ni ․․․․․

Kí n lè túbọ̀ mọ bá a ṣe ń bá èèyàn sọ̀rọ̀ dáadáa, màá ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí lo lè máa ṣe tó ò fi ní wọ́ ara ẹ nílẹ̀?

● Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o ka èrò ọmọbìnrin kan sí, àti pé o ro tiẹ̀ mọ́ tìẹ?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 198]

“Àwọn ọkùnrin máa ń rò pé àwọn gbọ́dọ̀ múra lọ́nà kan káwọn tó lè fa ojú àwọn ọmọge mọ́ra. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn déwọ̀n àyè kan, mo rò pé nǹkan tó ń fa àwọn ọmọbìnrin lójú mọ́ra jù ni ìwà ọmọlúwàbí.“​—Kate

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 197]

Ìwà ọmọlúwàbí kì í ṣe ohun tí wàá máa gbé wọ̀ bí ẹ̀wù kó o lè gbayì lójú àwọn èèyàn, kó o wá bọ́ ọ sílẹ̀ nígbà tó o bá délé