Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Màá Ṣe Borí Ẹ̀dùn Ọkàn Mi Bí Àfẹ́sọ́nà Mi Bá Já Mi Sílẹ̀?

Báwo Ni Màá Ṣe Borí Ẹ̀dùn Ọkàn Mi Bí Àfẹ́sọ́nà Mi Bá Já Mi Sílẹ̀?

ORÍ 31

Báwo Ni Màá Ṣe Borí Ẹ̀dùn Ọkàn Mi Bí Àfẹ́sọ́nà Mi Bá Já Mi Sílẹ̀?

“Ọdún karùn-ún rèé tá a ti jẹ́ ọ̀rẹ́, ó sì ti di oṣù mẹ́fà báyìí tá a ti ń fẹ́ra. Nígbà tí kò nífẹ̀ẹ́ mi mọ́, ó ṣòro fún un láti sọ fún mi. Ó wá pa mí tì, kò dá sí mi mọ́. Ọ̀rọ̀ náà tojú sú mi. Ìbànújẹ́ bá mi gan-an. Mo wá ń bi ara mi pé, ‘Kí lẹ̀ṣẹ̀ mi gan-an?’”​—Rachel.

ÌBÀNÚJẸ́ lè ba ayọ̀ rẹ jẹ́ bí ẹni tó ò ń fẹ́ bá já ẹ jù sílẹ̀. Wo àpẹẹrẹ Jeff àti Susan tí wọ́n fẹ́ra wọn fún ọdún méjì. Láàárín àkókò yẹn, ọ̀rọ̀ wọn wọ̀ gan-an. Ìṣẹ́jú-ìṣẹ́jú ni Jeff máa ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù sí Susan pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó tún máa ń fún un lẹ́bùn látìgbàdégbà láti fi hàn pé gbogbo ìgbà ló wà lọ́kàn òun. Susan sọ pé: “Jeff máa ń fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yé dáadáa. Kì í sì í fi ọ̀rọ̀ mi ṣeré rárá.”

Ká tó wí ká tó fọ̀, Jeff àti Susan ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó wọn àti ibi tí wọ́n máa gbé lẹ́yìn tí wọ́n bá fẹ́ra. Jeff tiẹ̀ béèrè irú òrùka tó máa bá Susan lọ́wọ́ mu. Àmọ́ lójijì, Jeff já Susan sílẹ̀! Ọ̀rọ̀ náà ba Susan lọ́kàn jẹ́ gan-an. Ayé sú u pátápátá, ìdààmú ọkàn sì bá a. Ó ní: “Ọkàn mi ò pa pọ̀ mọ́, ara mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ yá gágá.” *

Ìdí Tó Fi Máa Ń Dunni

Bí irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Susan yìí bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí, o lè máa bi ara rẹ pé, ‘Ṣé màá lè bọ́ nínú ẹ̀dùn ọkàn yìí báyìí?’ Kò sẹ́ni tírú ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀ sí tí kò ní bara jẹ́. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Ìfẹ́ lágbára bí ikú.” (Orin Sólómọ́nì 8:6) Ó lè jẹ́ pé bí ẹni tó ò ń fẹ́ ṣe já ẹ jù sílẹ̀ yìí ni ìṣòro tó le jù tó tíì dé bá ẹ rí. Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé tẹ́ni téèyàn ń fẹ́ bá jáni sílẹ̀, ńṣe ló dà bí ìgbà tó pani sáyé. Kódà inú rẹ lè bà jẹ́ gan-an débi táá fi máa ṣe ẹ́ bíi pé ńṣe lò ń ṣọ̀fọ̀. Àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí sì lè máa ṣe ẹ́:

Rírò pé irọ́ ni. ‘Kò kàn lè parí bẹ́ẹ̀ yẹn. Èrò rẹ̀ máa tó yí pa dà.’

Ìbínú. ‘Báwo ló ṣe máa ṣe irú nǹkan yìí sí mi? Mi ò ní gbà!’

Ìdààmú ọkàn. ‘Mo tẹ́. Kò sẹ́ni tó máa dẹnu ìfẹ́ kọ mí mọ́.’

Gbígba kámú. ‘Mo máa tó gbàgbé ẹ̀. Ó dùn mí o, àmọ́ mo ti ń gbé e kúrò lọ́kàn.’

Ohun tó fini lọ́kàn balẹ̀ ni pé, o gba kámú lórí ọ̀ràn náà. Ìgbà tẹ́ ẹ ti bẹ̀rẹ̀ àti ibi tẹ́ ẹ ti bá ọ̀rọ̀ yín dé ló máa pinnu bó ṣe máa yá tó láti gba kámú. Àmọ́, ní báyìí ná, báwo lo ṣe lè borí ẹ̀dùn ọkàn rẹ?

Má Rẹ̀wẹ̀sì

Ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́rọ̀ yìí rí pé, ‘Bí ẹkún pẹ́ dalẹ́, ayọ̀ ń bọ̀ lówùúrọ̀.’ Lóòótọ́, irú ọ̀rọ̀ yìí lè má tù ẹ́ nínú nígbà tí ẹni tó ò ń fẹ́ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ẹ́ sílẹ̀. Ìdí ni pé irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ kì í yanjú lójú ẹsẹ̀. Bí àpẹẹrẹ: Tó o bá fara pa, ó máa jinná tó bá yá o, àmọ́ ní báyìí, á ṣì kọ́kọ́ dùn ẹ́ ná. O ní láti dá ẹ̀jẹ̀ tó ń tibẹ̀ jáde dúró, kó o sì wá nǹkan lò, kára lè tù ẹ́. O tún gbọ́dọ̀ bójú tó o kí kòkòrò àrùn má bàa wọ̀ ọ́. Bí ẹ̀dùn ọkàn ṣe máa ń rí náà nìyẹn. Ní báyìí, ó ṣì lè máa dùn ẹ́ gan-an. Àmọ́, àwọn nǹkan tó o lè ṣe wà, tí ìrora náà á fi dín kù, tí ọ̀rọ̀ náà ò fi ní dá ọgbẹ́ sí ẹ lọ́kàn. Bó pẹ́ bó yá, ọ̀rọ̀ náà ṣì máa tán nílẹ̀ o, àmọ́ kí ló yẹ kí ìwọ fúnra rẹ ṣe? Gbìyànjú àwọn nǹkan tó wà nísàlẹ̀ yìí.

Má pa ẹkún mọ́ra. Kò burú tó o bá sunkún nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé “ìgbà sísunkún” àti “ìgbà pípohùnréré ẹkún” wà. (Oníwàásù 3:1, 4) Tó o bá sunkún, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé o ya ọ̀dẹ̀. Dáfídì tó tiẹ̀ jẹ́ jagunjagun tó nígboyà sọ nígbà kan tí ìdààmú ọkàn bá a pé: “Láti òru mọ́jú ni mo ń mú kí àga ìrọ̀gbọ̀kú mi rin gbingbin; omijé mi ni mo fi ń mú kí àga ìnàyìn mi kún àkúnwọ́sílẹ̀.”​—Sáàmù 6:6.

Tọ́jú ara rẹ. Bí àròdùn kò bá jẹ́ kó o fi bẹ́ẹ̀ lókun nínú, tó o bá ń ṣeré ìmárale, tó o sì ń jẹ oúnjẹ tó dáa, ara rẹ yóò pa dà bọ̀ sípò. Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé: “Ara títọ́ ṣàǹfààní.”​—1 Tímótì 4:8.

Kí lo rí pé ó yẹ kó o bójú tó nínú ọ̀rọ̀ ìlera rẹ?

․․․․․

Wá nǹkan ṣe. Máa ṣe àwọn nǹkan táá máa múnú ẹ dùn. Àkókò yìí gan-an ni kò yẹ kó o máa dá wà. (Òwe 18:1) Bó o bá ń bá àwọn tí ọ̀rọ̀ rẹ jẹ lógún kẹ́gbẹ́, wàá máa rí nǹkan tó dáa ronú lé lórí.

Àwọn nǹkan wo lo lè máa ṣe?

․․․․․

Sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ fún Ọlọ́run. Èyí lè má rọrùn. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń dá Ọlọ́run lẹ́bi bí ẹni tí wọ́n ń fẹ́ bá já wọn sílẹ̀. Wọ́n máa ń sọ pé, ‘Pẹ̀lú bí mo ṣe gbàdúrà tó kí n lè ẹni tí màá fẹ́, ìgbẹ̀yìn ẹ̀ náà rèé!’ (Sáàmù 10:1) Ṣé ó tiẹ̀ bójú mu pé ká kúkú wá sọ Ọlọ́run di alárinà tó ń bá tọkùnrin tobìnrin wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́? Kò yẹ bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ ká dá Ọlọ́run lẹ́bi nígbà tẹ́ni téèyàn ń fẹ́ bá lóun ò ṣe mọ́. Ohun tó dá wa lójú nípa Jèhófà ni pé: “Ó bìkítà fún [wa].” (1 Pétérù 5:7) Torí náà, sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ fún un. Bíbélì sọ pé: “Ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”​—Fílípì 4:6, 7.

Àwọn nǹkan pàtó wo lo lè sọ fún Jèhófà nínú àdúrà rẹ bó o ṣe ń gbìyànjú láti borí ẹ̀dùn ọkàn tó o ní nítorí pé ẹni tó ò ń fẹ́ fi ẹ́ sílẹ̀?

․․․․․

Mú Ọ̀rọ̀ Náà Kúrò Lọ́kàn

Tí ọ̀rọ̀ náà bá ti fúyẹ́ lọ́kàn rẹ, á dáa kó o pa dà ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ẹ ń fẹ́ra yín. Bó o bá ti ṣe tán láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa dáa kó o kọ ìdáhùn rẹ sáwọn ìbéèrè tó wà nínú àpótí tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “ Kí Ni Mo Rí Kọ́ Látinú Bí Ẹni Tí Mò Ń Fẹ́ Ṣe Já Mi Jù Sílẹ̀?” tó wà lójú ìwé 224.

Òótọ́ ni pé, bó o ṣe fẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹni tẹ́ ẹ jọ ń fẹ́ra rí kọ́ ló rí yìí. Àmọ́, má gbàgbé pé: Bí ìjì bá ń jà, tójò sì ń rọ̀, èèyàn lè máa wò ó pé ìjì náà ò ní rọlẹ̀ àti pé òjò náà ò ní dá bọ̀rọ̀, àmọ́ bó bá yá, òjò á dá, ojú ọjọ́ á sì wá mọ́lẹ̀ kedere. Bọ́rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ tá a sọ̀rọ̀ wọn níbẹ̀rẹ̀ orí yìí ṣe rí náà nìyẹn. Nígbà tó yá, wọ́n borí ẹ̀dùn ọkàn wọn, wọ́n sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn. Bó pẹ́ bó yá, ìwọ náà á lè mọ́kàn kúrò níbẹ̀!

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe kó o lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ àwọn tó máa ń fipá báni ṣèṣekúṣe?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 5 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé obìnrin làwọn tá a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ nínú orí yìí, síbẹ̀ àwọn ìlànà tó wà níbẹ̀ kan àwọn ọkùnrin náà.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“[Jèhófà] ń mú àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn lára dá, ó sì ń di àwọn ojú ibi tí ń ro wọ́n.”​—Sáàmù 147:3.

ÌMỌ̀RÀN

Susan, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan sínú ìwé kan, ó sì máa ń mú ìwé náà dání nígbà gbogbo, kó bàa lè máa ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà nígbàkigbà tí ọkàn rẹ bá gbọgbẹ́ torí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i. Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀, o lè kọ díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nínú orí yìí sínú ìwé kan, kó o sì jẹ́ kó máa wà pẹ̀lú ẹ ní gbogbo ìgbà.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọmọ tọ́jọ́ orí wọn ò tíì pé ogún ọdún tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà ni àjọṣe wọn kì í débi kí wọ́n fẹ́ra wọn sílé, àwọn tí wọ́n sì fẹ́ra wọn sílé ni wọ́n tètè máa ń kọra wọn sílẹ̀ jù.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Kí n lè máa bá ìgbésí ayé mi lọ lẹ́yìn tí ẹni tí mò ń fẹ́ ti fi mí sílẹ̀, màá ․․․․․

Ohun tí mo lè ṣe tí mo bá tún bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹlòmíì tí ọ̀rọ̀ wa á fi lè wọ̀ dáadáa ni ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí lo rí kọ́ nípa ara rẹ látinú ọ̀rọ̀ ìwọ àtẹni tó fi ẹ́ sílẹ̀?

● Kí lo rí kọ́ nípa ọkùnrin (tàbí obìnrin) látinú ohun tó o kà nínú orí yìí?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 227]

“Bọ́jọ́ ṣe ń lọ, ọ̀pọ̀ nǹkan máa wá yé ẹ. Ọkàn rẹ ò ní gbọgbẹ́ bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, ìyẹn á sì jẹ́ kó o lè ronú dáadáa kí ọ̀rọ̀ náà sì fúyẹ́ lọ́kàn rẹ. Bákan náà, wàá lè túbọ̀ mọ irú ẹni tó o jẹ́ àtàwọn ohun tó o máa wò lára ẹni tó o bá tún máa fẹ́, kírú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ yìí má bàa tún ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.”​—Corrina

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 224]

 Tí mo kọ èrò mi sí

Kí Ni Mo Rí Kọ́ Látinú Bí Ẹni Tí Mò Ń Fẹ́ Ṣe Já Mi Jù Sílẹ̀?

Ǹjẹ́ ẹni tó ò ń fẹ́ sọ ìdí tí òun fi fi ẹ́ sílẹ̀ fún ẹ? Tó bá sọ ọ́ fún ẹ, kọ ọ́ sínú àlàfo tó wà nísàlẹ̀ yìí, kódà bí o kò bá tiẹ̀ fara mọ́ ọn. ․․․․․

Àwọn nǹkan míì wo nìwọ rò pé ó fà á tó fi fi ẹ́ sílẹ̀? ․․․․․

Ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀, ǹjẹ́ o rò pé ohunkóhun wà tó yẹ kó o ti ṣe kí ohun tó wá ṣẹlẹ̀ yìí má bàa ṣẹlẹ̀? Tó bá wà, kí ni nǹkan ọ̀hún? ․․․․․

Ǹjẹ́ o ti rí ohunkóhun kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí táá jẹ́ kí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà sunwọ̀n sí i, tàbí táá jẹ́ kí ọ̀nà tó o gbà ń wo nǹkan túbọ̀ dáa sí i? ․․․․․

Ǹjẹ́  ohunkóhun wà tó o ti máa ń ṣe nígbà tí ìwọ àti ẹni tó fi ẹ́ sílẹ̀ yìí ń fẹ́ra yín, tó ò tún ní ṣe mọ́ tó o bá bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹlòmíì? ․․․․․

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 223]

Bí ẹni tó ò ń fẹ́ bá fi ẹ́ sílẹ̀, ńṣe ló máa dà bí ìgbà tó o fara pa, ó máa dùn ẹ́ o, àmọ́ ó máa jinná tó bá yá