Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Máa Mọ̀ Bóyá Ìfẹ́ Tòótọ́ Ni?

Báwo Ni Mo Ṣe Máa Mọ̀ Bóyá Ìfẹ́ Tòótọ́ Ni?

ORÍ 29

Báwo Ni Mo Ṣe Máa Mọ̀ Bóyá Ìfẹ́ Tòótọ́ Ni?

Sọ ohun tó o mọ̀ nípa àwọn nǹkan tá a tò sísàlẹ̀ yìí:

1. Ṣàlàyé ohun tó o rò pé “ìfẹ́ tòótọ́” jẹ́. ․․․․․

2. Ṣàlàyé ohun tó o rò pé “ìfẹ́ oréfèé” jẹ́. ․․․․․

3. Lójú tìẹ, kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín méjèèjì? ․․․․․

Ó LÈ má ṣòro fún ẹ rárá láti dáhùn àwọn ohun tá a sọ yìí. Torí ó lè rọ̀ ẹ́ lọ́rùn gan-an láti sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìfẹ́ tòótọ́ àti ìfẹ́ oréfèé, tó bá jẹ pé ohun tó o kàn rò nípa rẹ̀ lò ń sọ.

Àmọ́, gbàrà tó o bá ti rí ọmọbìnrin (tàbí ọmọkùnrin) kan tó wù ẹ́ gan-an, ó lè wá ṣòro fún ẹ láti rí ìyàtọ̀ láàárín oríṣi ìfẹ́ méjèèjì yìí. Wàá kàn rí i pé o ti yófẹ̀ẹ́ ni, o ò sì ní fẹ́ gbọ́ nǹkan míì yàtọ̀ síyẹn mọ́. Ìfẹ́ á wá bẹ̀rẹ̀ sí í pa ẹ́ bí ọtí. Àbí ìfẹ́ náà kọ́ lo máa pe ìyẹn? Báwo lo ṣe máa wá mọ̀ bóyá ìfẹ́ tòótọ́ ni àbí ìfẹ́ oréfèé lásán? Jẹ́ ká kọ́kọ́ wo bí ojú tó o fi ń wo ọkùnrin (tàbí obìnrin) lẹ́nu àìpẹ́ yìí ṣe ti yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí:

● Ojú wo lo fi ń wo ọkùnrin (tàbí obìnrin) nígbà tó o wà lọ́mọ ọdún márùn-ún?

Ní báyìí ojú wo lo fi ń wo ọkùnrin (tàbí obìnrin)?

Ó ṣeé ṣe kí ìdáhùn ẹ fi hàn pé ní báyìí tó o ti bàlágà, ojú tó o fi ń wo ọkùnrin (tàbí obìnrin) ti yàtọ̀ pátápátá. Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Brian, tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá [12], sọ pé: “Mo ti wá ń kíyè sí i pé àwọn ọmọbìnrin rẹwà gan-an ju bí mo ṣe máa ń wò wọ́n tẹ́lẹ̀.” Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Elaine, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16], sọ bí ohun tí òun ń rò nípa àwọn ọkùnrin ṣe yí pa dà lẹ́nu ọdún bíi mélòó kan yìí. Ó ní: “Àwọn ọ̀rẹ́ mi bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọkùnrin, ló bá di pé ọkàn tèmi náà wá ń fà sí ọmọkùnrin tí mo bá rí.”

Ní báyìí tó o ti wá ń kíyè sí ọkùnrin (tàbí obìnrin), kí lo máa wá ṣe sí bí ọkàn rẹ ṣe ń fà sí wọn yìí? Má kàn dọ́gbọ́n ṣe bíi pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kì í wá sí ẹ lọ́kàn, torí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ á túbọ̀ jẹ́ kí ọkàn ẹ máa fà sí wọn ni. Ṣe ni kó o kúkú fi ìyẹn kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tó ń mú kí ọkàn ẹni máa fà sí ọkùnrin (tàbí obìnrin), ohun tí ìfẹ́ oréfèé jẹ́, àti ohun tí ìfẹ́ tòótọ́ jẹ́. Bó o bá lóye apá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́, wàá lè yẹra fún ìbànújẹ́ téèyàn máa ń ní nígbà téèyàn bá ní ìjákulẹ̀, tó bá sì yá, wàá lè mọ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ ẹ ní tòótọ́.

OHUN TÓ MÚ KÍ ỌKÀN RẸ FÀ SÍ ẸNI NÁÀ Ohun tó o rí

“Ìgbà gbogbo lèmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọbìnrin. A máa ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan míì lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan o, àmọ́ bí ọmọge arẹwà kan bá ti lè kọjá báyìí, ọ̀rọ̀ tá à ń sọ tẹ́lẹ̀ yí pa dà nìyẹn!”​—Alex.

“Ojú mi kì í kúrò lára ọ̀dọ́mọkùnrin tí ojú èmi àti tiẹ̀ bá ṣe mẹ́rin, tó rẹ́rìn-ín músẹ́, tí ìrìn ẹ̀ sì tún wù mí.”​—Laurie.

Kò sóhun tó burú pé kí ọkàn èèyàn fà sí ẹni tó jẹ́ arẹwà. Àmọ́, ìṣòro tó wà níbẹ̀ ni pé, gbogbo èèyàn tó rẹwà kọ́ ló máa ń níwà tó dáa. Kí nìdí? Ìdí ni pé ẹwà lè tanni jẹ. Bíbélì sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí òrùka imú oníwúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni obìnrin tí ó jẹ́ arẹwà, ṣùgbọ́n tí ó yí padà kúrò nínú ìlóyenínú.” (Òwe 11:22) Ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí kan àwọn ọkùnrin náà.

ÌFẸ́ ORÉFÈÉ Bí ọ̀rọ̀ náà kàn ṣe rí lára rẹ

“Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá [12], ìfẹ́ ọmọkùnrin kan dédé kó sí mi lórí, àmọ́ nígbà tó yá, tí ìfẹ́ yẹn dá lójú mi, mo wá mọ nǹkan tó mú kí ọkàn mi máa fà sí i. Ohun tó fà á ni pé àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọkùnrin gan-an. Bí èmi náà ṣe rí ọmọkùnrin kan, ọkàn tèmi náà kàn bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí i ni!”​—Elaine.

“Àìmọye ọmọbìnrin ni mo ti yófẹ̀ẹ́ fún, àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé bí wọ́n ṣe rẹwà lójú nìkan ni mò ń wò. Tí mo bá ti wá mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ gan-an, màá wá rí i pé ibi tí mo fojú sí ọ̀nà ò gbabẹ̀, pé ìwà wa kò bára mu rárá.”​—Mark.

Ìfẹ́ oréfèé máa ń dà bí ìfẹ́ tòótọ́ lójú ẹni. Ká sòótọ́, kéèyàn tó lè nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan, onítọ̀hún ní láti kọ́kọ́ wúni. Àmọ́ ìfẹ́ oréfèé yàtọ̀ sí ìfẹ́ tòótọ́ torí ohun tó ń fa ìfẹ́ oréfèé yàtọ̀. Ìfẹ́ oréfèé má ń dá lórí ohun téèyàn kàn fojú rí lásán tó sì wuni. Bákan náà, kì í jẹ́ kéèyàn kíyè sí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tẹ́ni náà ní, ó sì máa ń mú kéèyàn gbà pé ohun tó wuni lára ẹni náà dára ju bó ṣe rí lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, ṣe ni ìfẹ́ oréfèé kàn dà bí ilé tí ọmọdé fi yanrìn kọ́. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Fiona sọ pé: “Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ kì í tọ́jọ́. Ọkàn rẹ lè máa fà sí ẹnì kan lónìí, àmọ́ ká tó rí oṣù kan sí i, ọkàn rẹ á tún ti máa fà sí ẹlòmíì!”

ÌFẸ́ TÒÓTỌ́ Ohun tó o mọ̀

“Èmi rò pé tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ tòótọ́, ó máa ń nídìí tí ọkàn ẹni fi máa fà sí ẹnì kan, ó sì máa jẹ́ ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, kò sì ní jẹ́ ti onímọtara-ẹni-nìkan rárá.”​David.

“Ní tèmi o, mo rò pé ṣe ni ìfẹ́ tòótọ́ máa ń lágbára sí i ni bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. Ẹ máa kọ́kọ́ jọ jẹ́ ọ̀rẹ́ ara yín. Tó bá yá, wàá bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó o kíyè sí nípa ẹni yẹn. Lẹ́yìn náà, ọkàn rẹ á wá bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ẹni náà lọ́nà tó yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀.”​—Judith.

Òye téèyàn ní nípa kùdìẹ̀-kudiẹ ẹnì kan àti ìwà rere rẹ̀ ló máa pinnu bóyá èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ẹni náà. Abájọ tí ohun tí Bíbélì sọ nípa ìfẹ́ fi jẹ́ ká rí i pé ó ju kéèyàn kàn gbára lé bí nǹkan ṣe rí lára ẹni lásán lọ. Lára ohun tí Bíbélì sọ pé ìfẹ́ jẹ́ ni pé ó “ní ìpamọ́ra àti inú rere. . . . A máa mú ohun gbogbo mọ́ra, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.” (1 Kọ́ríńtì 13:4, 7, 8) Ìfẹ́ tòótọ́ ló máa mú kéèyàn lè ṣe àwọn ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ, ó sì máa dá lórí ohun téèyàn ti mọ̀ nípa ẹni téèyàn nífẹ̀ẹ́ sí náà. Kò ní dá lórí ohun téèyàn kàn gbà pé ó jẹ́ òótọ́ nípa onítọ̀hún tàbí ohun téèyàn kò tiẹ̀ mọ̀ rárá.

Àpẹẹrẹ Ìfẹ́ Tòótọ́

Ìtàn Jékọ́bù àti Rákélì tó wà nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí ìfẹ́ tòótọ́ jẹ́. Ìdí kànga ni àwọn méjèèjì ti pàdé, níbi tí Rákélì ti wá fún àwọn àgùntàn bàbá rẹ̀ lómi. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ọkàn Jékọ́bù ti fà mọ́ ọn. Kí nìdí? Ohun kan ni pé, Rákélì “jẹ́ arẹwà ní ìrísí, ó sì lẹ́wà ní ojú.”​—Jẹ́nẹ́sísì 29:17.

Àmọ́ ṣá o, má gbàgbé pé ìfẹ́ tòótọ́ kọjá ọ̀rọ̀ pé ẹnì kan dùn-ún wò. Ohun tí Jékọ́bù rí lára Rákélì kọjá pé ó kàn rẹwà. Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kì í wulẹ̀ ṣe pé ọkàn Jékọ́bù ń fà sí Rákélì nìkan ni. Ṣe ni “Jékọ́bù nífẹ̀ẹ́ Rákélì gidigidi.”​—Jẹ́nẹ́sísì 29:18.

Ṣé bí wọ́n ṣe wá di tọkọtaya nìyẹn? Rárá o, ọ̀rọ̀ náà kò tán síbẹ̀. Bàbá Rákélì mú kí Jékọ́bù dúró fún ọdún méje kó tó lè fẹ́ Rákélì sílé. Bóyá ohun tí bàbá Rákélì ṣe yìí dára bẹ́ẹ̀ tàbí kò dára, ṣe ló máa jẹ́ kí Jékọ́bù wá fi hàn pé òótọ́ lòun nífẹ̀ẹ́ Rákélì. Tó bá jẹ́ ìfẹ́ oréfèé ni Jékọ́bù ní, ó dájú pé kò ní lè dúró de Rákélì. Ìfẹ́ tòótọ́ nìkan ló lè fara dà á fún àkókò gígùn bẹ́ẹ̀. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Bíbélì sọ pé: “Jékọ́bù sì bẹ̀rẹ̀ sí sìn fún ọdún méje nítorí Rákélì, ṣùgbọ́n ní ojú rẹ̀, ó dà bí ọjọ́ díẹ̀ nítorí ìfẹ́ rẹ̀ fún ọmọbìnrin náà.”​—Jẹ́nẹ́sísì 29:20.

Kí lo rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Jékọ́bù àti Rákélì yìí? Ẹ̀kọ́ náà ni pé ìfẹ́ tòótọ́ kì í kàn wà fúngbà díẹ̀, ṣe ló máa ń wà pẹ́ títí lọ́kàn ẹni. Bákan náà, kì í dá lórí ohun téèyàn kàn fojú rí lásán lára ẹnì kan. Kódà, ojú ẹni tó o máa fẹ́ lè má fi bẹ́ẹ̀ fà ẹ́ mọ́ra nígbà tó o kọ́kọ́ rí i. Bí àpẹẹrẹ, ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Barbara sọ pé nígbà tí òun kọ́kọ́ bá ẹni tóun pa dà fẹ́ pàdé, kò wu òun. Ó ní: “Àmọ́ ojú tí mo fi ń wo Stephen wá yí pa dà bí mo ṣe túbọ̀ ń mọ̀ ọ́n. Mo wá rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn gan-an, ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì sì máa ń jẹ ẹ́ lógún. Àwọn ìwà dáadáa tí mo sì mọ̀ pé ó lè mú kí ọkùnrin kan jẹ́ ọkọ rere nìyẹn. Èyí ló jẹ́ kí n sún mọ́ ọn, tí mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Bí wọ́n ṣe di tọkọtaya nìyẹn.

Bó o bá ti dàgbà tó ẹni tó lè ní àfẹ́sọ́nà, báwo lo ṣe máa mọ ẹni tẹ́ ẹ jọ ní ìfẹ́ tòótọ́ sí ara yín? Ọkàn ẹ lè sọ pé ìfẹ́ tòótọ́ lẹ ní, àmọ́ ìlànà Bíbélì ni kó o jẹ́ kó darí rẹ. Má kàn wo ohun tó o kàn fojú rí lásán lára ẹni náà, irú ẹni tó jẹ́ nínú ni kó o kíyè sí. Ẹ fàyè sílẹ̀ kí ìfẹ́ yín túbọ̀ jinlẹ̀, ẹ má ṣe kánjú. Ẹ rántí pé ìfẹ́ oréfèé kì í tọ́jọ́. Àmọ́, ṣe ni okùn ìfẹ́ tòótọ́ máa ń lágbára sí i bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó sì “jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”​—Kólósè 3:14.

Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o lè rí ẹni tẹ́ ẹ jọ máa nífẹ̀ẹ́ tòótọ́ síra yín, ìyẹn tó bá jẹ́ pé kì í ṣe ohun tó o kàn fojú rí lásán ló mú kí ọkàn rẹ fà sí ẹni náà, tí kì í ṣe ìfẹ́ oréfèé (ìyẹn bí ọ̀rọ̀ náà kàn ṣe rí lára rẹ) ló mú ẹ ṣe bẹ́ẹ̀. Ojú ìwé mẹ́ta tó tẹ̀ lé èyí máa jẹ́ kó o mọ ohun tó o lè ṣe.

KÀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 1 ÀTI 3, NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Ká sọ pé o ti gbà pé ìfẹ́ tòótọ́ ló wà láàárín yín. Báwo lo ṣe máa mọ̀ bóyá o ti ṣe tán láti ṣègbéyàwó?

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Omi púpọ̀ pàápàá kò lè paná ìfẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn odò alára kò lè gbé e lọ.”​—Orin Sólómọ́nì 8:7.

ÌMỌ̀RÀN

Láti mọ̀ bóyá lóòótọ́ lo mọ ẹni tí ọkàn rẹ ń fà sí dáadáa, dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà ní ojú ìwé 39 (fún ọmọbìnrin) àti ojú ìwé 40 (fún ọmọkùnrin) nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Ṣe ni àwọn ọ̀dọ́ tó bá ti mọ́ lára láti máa fẹ́ ẹnì kan kí wọ́n sì máa já a jù sílẹ̀ kàn ń fi bí wọ́n ṣe máa kọ ọkọ tàbí aya wọn sílẹ̀ lọ́jọ́ iwájú kọ́ra.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Kí n lè mọ̀ bóyá ìfẹ́ tòótọ́ ló ń mú kí ọkàn mi máa fà sí ẹnì kan, tàbí bóyá ìfẹ́ oréfèé ni, màá

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá àwa èèyàn lọ́nà tí ọkàn wa fi máa ń fà sí obìnrin (tàbí ọkùnrin) lọ́nà tó lágbára bẹ́ẹ̀?

● Kí nìdí tí ìfẹ́ táwọn ọ̀dọ́ tí kò tíì pé ogún ọdún bá sọ pé àwọn ní síra àwọn kì í fi í wà pẹ́ títí?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 207]

“Ìfẹ́ tòótọ́ lágbára láti borí ìṣòro, àmọ́ ìfẹ́ oréfèé kì í pẹ́ kúrò lọ́kàn èèyàn bí nǹkan ò bá lọ bí èèyàn ṣe fẹ́ tàbí nígbà tí ìṣòro bá dé. Ó máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò kéèyàn tó lè dẹni tó ní ìfẹ́ tòótọ́.”​—Daniella

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 209]

Tí mo kọ èrò mi sí

Kí Ni Ìwọ Ì Bá Ṣe?

Ó ti tó bí oṣù mẹ́ta báyìí tí Michael àti Judy ti ń fẹ́ra wọn, Judy sì sọ pé, “ìfẹ́ ti kó sí òun lórí.” Michael náà ti yófẹ̀ẹ́ fún un pátápátá, ó máa ń sọ aṣọ tó yẹ kó wọ̀ àti bó ṣe yẹ kó máa múra, ó sì máa ń sọ ẹni tó yẹ kó máa bá rìn àti ẹni tí kò yẹ fún un. Bí ẹyin ló máa ń gbé Judy gẹ̀gẹ̀, àfìgbà tó di ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni nǹkan yí bìrí. Michael gbá Judy létí nígbà tó rí i pé ó ń bá ọkùnrin míì sọ̀rọ̀.

Michael sọ pé: “Ó yẹ kí Judy mọ̀ pé ara mi ò ní gbà á torí pé mi ò fẹ́ kóun bọ́ mọ́ mi lọ́wọ́. Ṣe ni orí mi máa gbóná bí mo bá gbọ́ pẹ́nrẹ́n pé ẹnì kan fẹ́ gba olólùfẹ́ mi mọ́ mi lọ́wọ́! Kò dùn mọ́ mi nínú pé mo gbá Judy létí. Àmọ́, torí pé ara mi kò lè gbà á kó máa bá ọkùnrin míì sọ̀rọ̀ ló jẹ́ kí n gbá a létí. Yàtọ̀ síyẹn, mo ṣáà ti bẹ̀ ẹ́!”

Judy sọ pé: “Àwọn òbí mi sọ fún mi pé bí Michael ṣe ń darí mi yìí ti le jù, àmọ́ mo mọ̀ pé ṣe ni kò gbàgbàkugbà. Kò ṣáà fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ mí rí. Òótọ́ ni pé ó ti gbá mi létí rí, àmọ́ torí pé mò ń bá ọmọkùnrin míì sọ̀rọ̀ ló ṣe gbá mi létí, mi ò sọ fáwọn òbí mi pé ó gbá mi létí ṣá o. Michael máa ń jowú gan-an, ìyẹn sì sábà máa ń mú inú mi dùn pé ó gba tèmi gan-an. Àmọ́ o, ó ti bẹ̀ mí pé kí n máà bínú, pé irú ẹ̀ ò ní wáyé mọ́.”

Ọ̀rọ̀ náà kàn ẹ́: Ǹjẹ́ o rí àmì kankan tó jẹ́ kó o fura pé wàhálà lè jẹ yọ láàárín àwọn méjèèjì lọ́jọ́ iwájú? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àmì wo lo rí? ․․․․․

Kí ló yẹ kí Judy ṣe? ․․․․․

Kí ni ìwọ ì bá ṣe? ․․․․․

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 210]

Tí mo kọ èrò mi sí

Kí Ni Ìwọ Ì Bá Ṣe?

Ó ti tó bí oṣù méjì báyìí tí Ethan ti ń fẹ́ Alyssa, ó sì ti kíyè sí i pé Alyssa máa ń jiyàn gan-an, pàápàá pẹ̀lú àwọn òbí ẹ̀. Kódà gbogbo ìgbà ni Alyssa máa ń bá àwọn òbí ẹ̀ jiyàn, ọ̀rọ̀ tiẹ̀ ló sì máa ń lékè. Ó ti mọ́ ọn lára kó máa jiyàn débi pé ó dìgbà táwọn òbí ẹ̀ bá dákẹ́ kóun náà tó dákẹ́. Alyssa ti fọ́nnu fún Ethan rí pé àwọn òbí òun ò lẹ́mìí kí wọ́n máa bá òun fa ọ̀rọ̀ mọ́.

Ethan sọ pé: “Ohun tó wà lọ́kàn Alyssa ló máa ń sọ. Kì í gba gbẹ̀rẹ́ fún ẹnikẹ́ni, títí kan àwọn òbí ẹ̀. Dádì ẹ̀ máa ń mú èèyàn bínú, ìdí nìyẹn tí Alyssa fi máa ń gbaná jẹ mọ́ wọn. Àmọ́ kì í ṣe ariwo nìkan ni Alyssa máa ń pa. Ó tún máa ń ṣe ohunkóhun tó bá ṣáà ti lè ṣe, táá jẹ́ kí dádì àti mọ́mì ẹ̀ fún un ní ohun tó bá ń fẹ́, bí àpẹẹrẹ, ó máa ń sunkún, ó máa ń dì kunkun, ó sì tún máa ń ṣe ojú ayé.”

Alyssa sọ pé: “Mi ò fẹ́ mọ̀ ẹ́, tàbí irú ẹni tó o jẹ́, bọ́rọ̀ bá ṣe rí lèmi máa ń sọ ọ́, èmi kì í pẹ́ ọ̀rọ̀ sọ ní tèmi. Ẹni tí mò ń fẹ́, ìyẹn Ethan, náà mọ irú ẹni tí mo jẹ́. Ó máa ń rí mi nígbà tí mo bá ń gbé e gbóná fún àwọn òbí mi.”

Ọ̀rọ̀ náà kàn ẹ́: Ǹjẹ́ o rí àmì kankan tó jẹ́ kó o fura pé wàhálà lè jẹ yọ láàárín àwọn méjèèjì lọ́jọ́ iwájú? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àmì wo lo rí? ․․․․․

Kí ló yẹ kí Ethan ṣe? ․․․․․

Kí ni ìwọ ì bá ṣe? ․․․․․

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 211]

Tí mo kọ èrò mi sí

Ṣé Ìfẹ́ Tòótọ́ Ni Àbí Ìfẹ́ Oréfèé?

Gbìyànjú láti wá ọ̀rọ̀ tó yẹ kó wà nínú àwọn gbólóhùn táwọn kan sọ, èyí tá a kọ sísàlẹ̀ yìí. Kọ yálà ìfẹ́ tòótọ́ tàbí ìfẹ́ oréfèé sí àlàfo tó wà nínú àwọn gbólóhùn náà.

1. “․․․․․ fọ́jú, bó sì ṣe máa ń wù ú pé kó wà nìyẹn. Kì í fẹ́ rí ohun tó jóòótọ́.”​—Calvin.

2. “Tí mo bá ní láti yí ìwà mi pa dà nígbà tí mo bá wà pẹ̀lú ọmọbìnrin tí mo nífẹ̀ẹ́, a jẹ́ pé ․․․․․ ni mo ní.”​—Thomas.

3. “Ohun kan lè máa bí ẹ nínú nípa ẹni yẹn. Àmọ́ tó o bá ní ․․․․․, wàá ṣì fẹ́ wà pẹ̀lú ẹni yẹn, kẹ́ ẹ sì wá bẹ́ ẹ ṣe máa yanjú ọ̀rọ̀ náà.”​—Ryan.

4. “Tó bá jẹ́ pé ․․․․․ lẹ ní sí ara yín, àwọn ohun tẹ́ ẹ jọ nífẹ̀ẹ́ sí nìkan ni ẹ ó máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.”​—Claudia.

5. “Tó bá jẹ́ pé ․․․․․ lẹ ní sí ara yín, ẹ ò ní fi irú ẹni tẹ́ ẹ jẹ́ pa mọ́ fúnra yín.”​—Eve.

6. “․․․․․ ló ń mú kéèyàn máa fi ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan wá bí ọwọ́ tiẹ̀ ṣe máa tẹ ohun tó ń fẹ́, ìyẹn ni pé kó ṣáà ti lè sọ pé òun ní ẹnì kan tóun ń fẹ́.”​—Allison.

7. “․․․․․ máa ń rí àwọn àléébù àtàwọn kùdìẹ̀-kudiẹ ẹnì kan, síbẹ̀ ó máa ń lè fara dà á.”​—April.

8. “Tó bá jẹ́ ․․․․․ lo ní, o kò ní lè ṣàlàyé ohun tó mú kí ọkàn ẹ máa fà sí ẹni yẹn, ṣe ni ọkàn rẹ á kàn ṣáà máa fà sí ẹni yẹn.”​—David.

9. “․․․․․ máa mú kó o gbà pé ẹni yẹn kò lè ṣe àṣìṣe rárá.”​—Chelsea.

10. “Tó bá jẹ́ pé ․․․․․ lo ní, àwọn obìnrin (tàbí ọkùnrin) míì kò tún ní máa wọ̀ ẹ́ lójú mọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀, torí o mọ̀ pé ojú kan ni àdá máa ń ní.”​—Daniel.

Ìdáhùn: Ìfẹ́ oréfèé: 1, 2, 4, 6, 8, 9. Ìfẹ́ tòótọ́: 3, 5, 7, 10.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 206, 207]

Ìfẹ́ oréfèé dà bí ilé tí ọmọdé fi yanrìn kọ́, bó pẹ́ bó yá yóò bá omi lọ