Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Táwọn Òbí Mi Kì Í Fi Í Jẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi?

Kí Nìdí Táwọn Òbí Mi Kì Í Fi Í Jẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi?

ORÍ 37

Kí Nìdí Táwọn Òbí Mi Kì Í Fi Í Jẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi?

Ọ̀dọ́bìnrin kan láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Allison sọ bí wàhálà tó ń bá òun nílé ìwé láàárọ̀ ọjọ́ Monday ṣe máa ń pọ̀ jù fún òun.

Ó ní: “Gbogbo èèyàn ló máa ń sọ ohun tí wọ́n ṣe ní òpin ọ̀sẹ̀, àwọn nǹkan tí wọ́n ń sọ sì máa ń dùn mọ́ mi. Wọ́n lè sọ iye ibi àríyá tí wọ́n lọ, iye àwọn ọmọkùnrin tí wọ́n fẹnu kò lẹ́nu, kódà wọ́n máa ń sọ bí wọ́n ṣe sá mọ́ àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ . . . Ìyẹn máa ń já mi láyà o, àmọ́ mo máa ń wò ó pé wọ́n gbádùn ara wọn gan-an! Tí wọ́n bá jáde lọ, aago márùn-ún ìdájí ni wọ́n máa ń pa dà wọlé, àwọn òbí wọn kò sì ní bá wọn wí. Kódà, ìgbà táwọn òbí tèmi retí pé kí n ti wà lórí ibùsùn mi làwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ń múra òde tiwọn.

“Tí àwọn ọmọ kíláàsì mi bá ti wá sọ ohun tí wọ́n ṣe lópin ọ̀sẹ̀, wọ́n á wá béèrè ohun tí èmi náà ṣe. Kí sì ni mo ṣe? Mo lọ sí ìpàdé. Mo sì tún lọ sóde ẹ̀rí. Ó máa ń ṣe mí bíi pé, mò ń pàdánù àkókò tó yẹ kí n fi gbádùn ara mi. Torí náà, ṣe ni mo kàn máa ń sọ fún wọn pé mi ò ṣe nǹkan kan. Wọ́n á wá máa sọ pé mi ò ṣe kúkú bá àwọn jáde.

“Bí ọjọ́ Monday bá ti kọjá, màá rò pé ẹjọ́ ti tán nìyẹn, àmọ́ irọ́ ni! Tó bá fi máa di ọjọ́ Tuesday, gbogbo wọn á tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí wọ́n máa ṣe ní òpin ọ̀sẹ̀! Ńṣe ni mo kàn máa ń jókòó tí màá máa wo ẹnu wọn. Ó máa ń ṣe mí bíi pé tèmi nìkan ló dá yàtọ̀!”

ṢÉ OHUN kan náà ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ ní gbogbo ọjọ́ Monday nílé ìwé? Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé ìgbádùn wà níta, àmọ́ àwọn òbí ẹ kì í jẹ́ kó o gbádùn ara rẹ, tàbí kó máa ṣe ẹ́ bí ìgbà tó o wà níbi ìgbafẹ́ kan, àmọ́ tí wọn ò jẹ́ kó o fi àwọn nǹkan tó wà níbẹ̀ ṣeré. Kì í kúkú ṣe pé gbogbo nǹkan táwọn ojúgbà rẹ ń ṣe nìwọ náà ń fẹ́ ṣe, ó kàn jẹ́ pé ó wu ìwọ náà pé kó o máa gbádùn ara rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni. Bí àpẹẹrẹ, kí ni wàá fẹ́ ṣe láti gbádùn ara rẹ lópin ọ̀sẹ̀ yìí?

□ mo fẹ́ lọ jó ijó

□ mo fẹ́ lọ wo olórin kan

□ nǹkan míì

□ mo fẹ́ lọ síbi àríyá

□ mo fẹ́ wo fíìmù ․․․․․

Ó yẹ kó o máa ṣe eré ìtura. Kódà Ẹlẹ́dàá rẹ fẹ́ kó o gbádùn ìgbà ọ̀dọ́ rẹ. (Oníwàásù 3:1, 4) Àwọn òbí rẹ náà fẹ́ kó o gbádùn ara rẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì ìwọ lè máa wò ó pé wọn ò fẹ́ kó o gbádùn ara rẹ. Àmọ́, ohun méjì kan wà tó ṣeé ṣe kó máa jẹ àwọn òbí rẹ lọ́kàn: (1) ohun tó o máa ṣe àti (2) àwọn tẹ́ ẹ jọ máa lọ.

Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ kan ní kó o jẹ́ kẹ́ ẹ jọ jáde, àmọ́ tí o kò mọ ohun tí àwọn òbí rẹ máa sọ ńkọ́? Wo àwọn nǹkan mẹ́tà kan tó o lè ṣe àtàwọn ohun tó lè yọrí sí.

ÀKỌ́KỌ́ MÁ SỌ FÚN ẸNIKẸ́NI, ṢÁÀ KÀN LỌ NÍ TÌẸ

Ìdí tó fi lè wù ẹ́ pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀: O fẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ rí i pé o ní òmìnira láti ṣe ohun tó wù ẹ́. O fẹ́ fi hàn pé o mọ̀ ju àwọn òbí rẹ lọ, tàbí pé o ò ka ọ̀rọ̀ wọn sí.​—Òwe 14:18.

Ohun tó lè yọrí sí: Ohun tó o ṣe lè wú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lórí, àmọ́ wọ́n á wá rí ohun kan nípa rẹ, ìyẹn ni pé ẹlẹ̀tàn èèyàn ni ẹ́. Torí tó o bá fi lè tan àwọn òbí rẹ jẹ, á jẹ́ pé o lè tan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ jẹ náà nìyẹn. Tí àwọn òbí ẹ bá wá mọ̀, ó máa dùn wọ́n gan-an, wọ́n á sì gbà pé o ti já àwọn kulẹ̀, wọ́n sì lè má máa fún ẹ láyè bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Ìwà òpònú ló máa jẹ́ tó o bá ṣàìgbọràn sáwọn òbí ẹ, tó o sì ń jáde bó ṣe wù ẹ́ láì dágbére fún wọn.​—Òwe 12:15.

ÌKEJÌ MÁ SỌ FÚN ẸNIKẸ́NI, MÁ SÌ LỌ

Ìdí tó fi lè wù ẹ́ pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀: O ronú nípa ìkésíni náà, o sì pinnu pé ohun tí wọ́n máa ṣe níbẹ̀ kò bá ìlànà tó ò ń tẹ̀ lé mu, tàbí pé àwọn kan lára àwọn tó máa wà níbẹ̀ lè jẹ́ ẹgbẹ́ búburú. (1 Kọ́ríńtì 15:33; Fílípì 4:8) Yàtọ̀ síyẹn, ó lè wù ẹ́ láti lọ, àmọ́ ẹ̀rù ń bà ẹ́ láti sọ fún àwọn òbí rẹ.

Ohun tó lè yọrí sí: Tí o kò bá lọ torí o mọ̀ pé kò tọ́ láti lọ, wàá lè fi ìgboyà sọ ìdí tí o kò fi wá fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Àmọ́ tó bá jẹ́ nítorí pé ẹ̀rù ń bà ẹ́ láti sọ fún àwọn òbí rẹ ni o kò ṣe lọ, bóyá ńṣe lo kàn máa kárí sọ sílé, tí wàá máa ronú pé ìwọ nìkan ni kì í gbádùn ara rẹ.

ÌKẸTA SỌ FÚN ÀWỌN ÒBÍ RẸ, KÓ O WÁ GBỌ́ OHUN TÍ WỌ́N MÁA SỌ

Ìdí tó fi lè wù ẹ́ pé kó o ṣe bẹ́ẹ̀: O gbà pé àwọn òbí rẹ láṣẹ lórí rẹ, o sì máa ń ka èrò wọn sí gan-an. (Kólósè 3:20) O nífẹ̀ẹ́ àwọn òbí rẹ, o kò sì fẹ́ ṣe ohun tó máa dùn wọ́n nípa yíyọ́ jáde láìsọ fún wọn. (Òwe 10:1) Wàá tún láǹfààní láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún wọn.

Ohun tó lè yọrí sí: Àwọn òbí rẹ á mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn, o sì bọ̀wọ̀ fún àwọn. Tí wọ́n bá sì rí i pé ohun tó mọ́gbọ́n dání lo fẹ́ ṣe, wọ́n lè jẹ́ kó o lọ.

Ohun Tó Lè Mú Kí Àwọn Òbí Rẹ Sọ Pé Kí O Má Lọ

Bí àwọn òbí rẹ kò bá wá jẹ́ kó o lọ ńkọ́? Ìyẹn lè dùn ẹ́ gan-an. Àmọ́, tó o bá mọ ìdí tí wọ́n fi ní kí o má lọ, kò ní jẹ́ kí ohun tí wọ́n sọ dùn ẹ́ kọjá bó ṣe yẹ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè sọ pé kó o má lọ nítorí ìdí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ìdí tá a kọ síbí yìí.

Wọ́n ní ìmọ̀ àti ìrírí jù ẹ́ lọ. Ká sọ pé o fẹ́ lọ lúwẹ̀ẹ́ ní odò kan, ó dájú pé odò tí wọ́n ti ní àwọn òmùwẹ̀ tó ń yọ ẹni tó bá rì sínú omi ni wàá fẹ́ lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé tó o bá wà nínú omi tó o sì ń ṣeré, o lè má mọ̀ nígbà tí ewu bá ń bọ̀. Àmọ́, ńṣe làwọn òmùwẹ̀ tó ń yọ ẹni tó bá rì sómi máa ń wà lórí òkè téńté kan, níbi tí wọ́n ti máa tètè rí ohun tó lè jẹ́ ewu.

Bẹ́ẹ̀ náà lọ̀rọ̀ àwọn òbí rẹ ṣe rí. Torí pé ìmọ̀ àti ìrírí tí àwọn òbí rẹ ní ju tìẹ lọ, wọ́n lè rí àwọn ewu kan tí ìwọ kò rí. Àwọn òbí rẹ tún dà bíi tàwọn òmùwẹ̀ yẹn, ní ti pé wọ́n fẹ́ kó o gbádùn ara rẹ, àmọ́ wọn ò kàn fẹ́ kó o kó sí wàhálà tí kò ní jẹ́ kó o gbádùn ayé rẹ ni.

Wọ́n fẹ́ràn rẹ. Àwọn òbí rẹ kò fẹ́ kí nǹkan kan ṣẹlẹ̀ sí ẹ rárá. Torí pé wọ́n fẹ́ràn rẹ ni wọ́n ṣe máa ń jẹ́ kó o ṣe àwọn nǹkan kan, tí wọn ò sì ní jẹ́ kó o ṣe àwọn nǹkan míì. Tó o bá sọ fún wọn pé o fẹ́ ṣe nǹkan kan, wọ́n á bi ara wọn pé, táwọn bá jẹ́ kó o ṣe nǹkan náà, ṣé àwọn máa lè fara mọ́ ohun tó bá yọrí sí? Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti rò ó dáadáa tí wọ́n sì rí i pé kò ní sí ewu kankan fún ẹ ni ọkàn wọn máa tó balẹ̀ láti sọ pé kó o ṣe nǹkan náà.

Àwọn Nǹkan Tó O Lè Ṣe Tó O Bá Fẹ́ Kí Wọ́n Máa Fún Ẹ Láyè

Àwọn nǹkan mẹ́rin kan wà tó o lè ṣe.

Máa sọ òótọ́: Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó yẹ kó o bi ara rẹ pé: ‘Kí nìdí tí mo fi fẹ́ lọ gan-an? Ṣé ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ ló wù mí ni àbí torí káwọn ọ̀rẹ́ mi lè gba tèmi ni mo ṣe fẹ́ lọ? Ṣé torí pé ẹnì kan tí mo gba tiẹ̀ máa wà níbẹ̀ ni mo ṣe fẹ́ lọ?’ Lẹ́yìn náà, sọ òótọ́ fún àwọn òbí rẹ. Àwọn náà ti ṣe ọmọdé rí, wọ́n sì mọ̀ ẹ́ dáadáa. Torí náà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n mọ ohun tó o fẹ́ ṣe gan-an. Inú wọn á dùn sí ẹ tó o bá sọ òótọ́ fún wọn, ìwọ náà á sì jàǹfààní látinú ọgbọ́n wọn. (Òwe 7:1, 2) Àmọ́, tó o bá parọ́ fún wọn, wọn ò ní gbà ẹ́ gbọ́ mọ́, kò sì dájú pé wọ́n á fún ẹ láyè.

Mọ ìgbà tó yẹ kó o lọ tọrọ àyè: Má ṣe máa lọ yọ àwọn òbí rẹ lẹ́nu pé kí wọ́n fún ẹ láyè nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ibi iṣẹ́ dé tàbí nígbà tí wọ́n bá ń bójú tó àwọn ọ̀ràn kan. Ìgbà tí ara wọn bá balẹ̀ dáadáa ni kó o lọ bá wọn. Àmọ́ ṣá o, má ṣe dúró dìgbà tó bá ti fẹ́ pẹ́ jù kó o tó lọ bá wọn, kó o wá máa yọ wọ́n lẹ́nu lẹ́yìn náà pé kí wọ́n tètè dá ẹ lóhùn. Àwọn òbí rẹ kò ní fẹ́ kánjú ṣe ìpinnu wọn. Inú wọn máa dùn gan-an tó o bá tètè tọrọ àyè, tí o kò jẹ́ kó pẹ́ jù.

Mọ ohun tó o fẹ́ sọ: Má ṣe fọ̀rọ̀ pa mọ́ fún wọn. Sọ ohun tó o fẹ́ ṣe gan-an fún wọn. Àwọn òbí kì í fẹ́ gbọ́ káwọn ọmọ wọn sọ pé, “Mi ò mọ̀,” nígbà tí wọ́n bá bi ọmọ láwọn ìbéèrè bí: “Àwọn wo lẹ jọ ń lọ?” “Ṣé àgbàlagbà kan máa wà níbẹ̀?” tàbí “Ìgbà wo lẹ máa ṣe tán?”

Ìwà rẹ: Má ṣe sọ àwọn òbí rẹ di ọ̀tá. Ṣe ló yẹ kẹ́ ẹ jọ fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Tó o bá sì rò ó dáadáa, wàá rí i pé ìyẹn ló máa pé ẹ. Tó o bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí rẹ, o ò ní máa ta kò wọ́n, àwọn náà á sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ. Má ṣe máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ bí, “Ẹ ò fọkàn tán mi,” “Gbogbo èèyàn ló ń lọ,” tàbí “Àwọn òbí àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣáà máa ń jẹ́ kí wọ́n lọ ní tiwọn!” Jẹ́ kí àwọn òbí ẹ mọ̀ pé o ti gbọ́n débi tí wàá fi fara mọ́ ìpinnu wọn. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á máa fọ̀wọ̀ rẹ wọ̀ ẹ́. Tó bá di ìgbà míì, wọ́n á wá bí wọ́n á ṣe jẹ́ kó o lọ síbi tó o bá fẹ́ lọ.

KÀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 32 NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀.”​—Òwe 27:11.

ÌMỌ̀RÀN

Bó o bá fẹ́ lọ síbi àpèjẹ kan, kọ́kọ́ ronú nípa bó o ṣe máa kúrò níbẹ̀. Kó o tó lọ, rí i pé o mọ ohun tó o máa ṣe tàbí ohun tó o máa sọ, tó fi jẹ́ pé tó bá di pé kó o kúrò níbẹ̀, wàá ṣì lè ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ máa fẹ́ ṣe ìpinnu tó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpinnu yẹn lè máà dáa tó. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n má gbà kó o lọ tí ohun tí o sọ pé o fẹ́ ṣe kò bá yé wọn tàbí tí wọ́n bá rí i pé àwọn nǹkan kan wà tí o kò sọ.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Bí ohun tí mo rí tàbí ohun tí mo gbọ́ nínú fíìmù tàbí ní àpèjẹ kan bá ń da ẹ̀rí ọkàn mi láàmú, ohun tí màá ṣe ni ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí lo rò pé kò ní jẹ́ kó o fẹ́ sọ gbogbo ohun tó yẹ kó o sọ fún àwọn òbí rẹ kí wọ́n lè mọ ìpinnu tó yẹ kí wọ́n ṣe?

● Kí lo rò pé ó lè yọrí sí bó o bá fàwọn nǹkan kan pa mọ́ fáwọn òbí rẹ tí wọ́n fi gbà ẹ́ láyè láti ṣe ohun tó o fẹ́ ṣe?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 268]

“Mo hùwà òmùgọ̀ gan-an nígbà tí mo ṣì kéré. Àṣé ọ̀pọ̀ nǹkan tí mo máa fi ń ṣeré nígbà yẹn kì í ṣe nǹkan ṣeréṣeré rárá. Èèyàn ṣì máa kórè ohun tó ṣe nígbà tó wà ní kékeré. Ó dùn mí gan-an pé mi ò gbọ́ràn sí àwọn òbí mi lẹ́nu.”​—Brian

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 269]

Àwọn òbí rẹ dà bí àwọn tó máa ń yọ ẹni tó bá rì sínú omi, àwọn ló tètè máa ń rí ohun tó lè jẹ́ ewu fún ẹ