Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́!

Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́!

Ọ̀RỌ̀ ÌṢÁÁJÚ

Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́!

‘Báwo ni mo ṣe lè máa bá àwọn òbí mi sọ̀rọ̀?’ ‘Báwo ni mo ṣe lè ní ọ̀rẹ́?’ ‘Kí ló burú nínú kéèyàn kàn gbé ẹnì kan sùn?’ ‘Kí nìdí tí inú mi fi máa ń bà jẹ́ báyìí?’

Tó o bá bi ara rẹ nírú àwọn ìbéèrè yìí, má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu, àwọn ẹlòmíì náà máa ń bi ara wọn bẹ́ẹ̀. Tó o bá ń wá ìdáhùn, ìmọ̀ràn tó o máa rí láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lè ta ko ara wọn, ó sinmi lórí ibi tó o bá wá a lọ. Láti ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò tí wọ́n máa lè tẹ̀ lé, ìwé ìròyìn Jí! bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn àpilẹ̀kọ́ kan tó ń fi ìlànà Bíbélì ṣàlàyé ọ̀rọ̀ jáde láti oṣù July 1983. Àkòrí rẹ̀ ni “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, àìmọye èèyàn ló ṣì ń jàǹfààní àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí tí wọ́n sì máa ń fẹ́ kà á. Ìwádìí kékeré kọ́ ni àwọn tó ń kọ ìwé ìròyìn Jí! máa ń ṣe lórí àpilẹ̀kọ kọ̀ọ̀kan kó tó jáde. Bí àpẹẹrẹ, láti lè mọ bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe máa ń ronú àti bí ọ̀rọ̀ ṣe máa ń rí lára wọn, wọ́n máa ń fọ̀rọ̀ wá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ lẹ́nu wò kárí ayé! Ohun tó tún wá ṣe pàtàkì jù ni pé, inú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la ti máa ń mú àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” yìí.

Ọdún 1994 la kọ́kọ́ tẹ ẹ̀dà ìwé tó o mú dání yìí jáde. Àmọ́ a ti tún àwọn orí àtàwọn àlàyé tó wà níbẹ̀ ṣe kó lè bá àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní mu. Èyí tó ju ọgbọ̀n [30] lọ nínú àwọn orí tó wà nínú ìwé yìí la mú látinú àwọn àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìwé ìròyìn Jí! tá a tẹ̀ jáde láàárín ọdún 2004 sí 2011.

Ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń BéèrèÀwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní, máa jẹ́ kó o ní ọgbọ́n tí wàá fi lè ṣe ojúṣe rẹ tó o bá dàgbà. A nírètí pé bó o ti ń fi àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé yìí sílò, wàá di ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ èèyàn, lọ́mọdé àti lágbà, tí wọ́n ń “tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Hébérù 5:14.

Àwa Òǹṣèwé