Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Òbí Ń Béèrè

Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Òbí Ń Béèrè

ÀFIKÚN

Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Òbí Ń Béèrè

“Kí ni mo lè ṣe kí ọmọ mi lè máa sọ tinú ẹ̀ fún mi?”

“Ṣé ó yẹ kí n fún ọmọ mi ní òfin nípa àkókò tí mo fẹ́ kó máa wọlé?”

“Báwo ni mo ṣe lè ran ọmọ mi lọ́wọ́ kó má ṣe àṣejù nínú bó ṣe ń ṣọ́ oúnjẹ jẹ?”

Díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè mẹ́tàdínlógún [17] tá a dáhùn nínú Àfikún yìí nìyẹn. Apá mẹ́fà la pín àwọn ìsọfúnni náà sí, a sì tọ́ka sí àwọn orí tó o ti lè rí àlàyé nípa wọn nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè​—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní àti Apá Kejì.

Ka Àfikún yìí. Tó bá ṣeé ṣe, kí ìwọ àti ọkọ (tàbí aya) rẹ jọ jíròrò rẹ̀. Kẹ́ ẹ wá lo àwọn ìmọ̀ràn tó wà níbẹ̀ láti fi ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́. Àwọn ìdáhùn tó o máa kà nínú Àfikún yìí ṣeé fọkàn tẹ̀. Inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la ti mú un jáde, kì í ṣe látinú ọgbọ́n èèyàn, èyí tí kò láyọ̀lé.​—2 Tímótì 3:16, 17.

290  Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀

297  Òfin

302  Òmìnira

307  Ọ̀rọ̀ Nípa Ìbálòpọ̀ àti Àfẹ́sọ́nà

311  Àwọn Ohun Tó Jẹ Mọ́ Ẹ̀dùn Ọkàn

315  Ọ̀rọ̀ Nípa Ìjọsìn Ọlọ́run

 ÌJÙMỌ̀SỌ̀RỌ̀

Ǹjẹ́ nǹkan kan tiẹ̀ burú nínú pé kí n máa bá ọkọ (tàbí aya) mi tàbí àwọn ọmọ mi fa ọ̀rọ̀?

Èdè àìyedè ò lè ṣe kó máà máa wáyé láàárín tọkọtaya. Àmọ́, ẹ̀yin lẹ máa mọ bẹ́ ẹ ó ṣe máa yanjú rẹ̀. Bí àwọn òbí bá ń bára wọn jiyàn, ó máa nípa lórí àwọn ọmọ gan-an. Ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì nítorí pé ọwọ́ tí ẹ̀yin òbí bá fi mú ara yín máa nípa lórí ọwọ́ tí àwọn ọmọ yín máa fi mú ọkọ tàbí aya wọn lọ́jọ́ iwájú. Bí èdè àìyedè bá wáyé, ẹ ò ṣe kúkú fi ìyẹn jẹ́ kí àwọn ọmọ yín rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára yín nípa béèyàn ṣe lè yanjú èdèkòyédè? Ẹ lè lo àwọn àbá yìí:

Fetí sílẹ̀. Bíbélì sọ fún wa pé ká “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Má ṣe fi “ibi san ibi” torí ṣe nìyẹn tún máa dá kún èdè àìyedè náà. (Róòmù 12:17) Bó bá tiẹ̀ dà bíi pé ọkọ tàbí aya rẹ ò fẹ́ láti fetí sílẹ̀, ìwọ fetí sílẹ̀ ní tìẹ.

Gbìyànjú láti ṣàlàyé dípò kó o máa wá àṣìṣe. Fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ fún ọkọ tàbí aya rẹ nípa bí ìwà tó ń hù ṣe rí lára rẹ. (Bí àpẹẹrẹ: “Ó máa ń dùn mí bó o bá . . . ”) Gbìyànjú láti má ṣe dẹ́bi fún ẹnì kejì rẹ, má sì ṣe wá àṣìṣe rẹ̀. (Má ṣe sọ pé: “O ò kà mí kún nǹkan kan,” tàbí “O kì í tẹ́tí sí mi.”)

Ṣì fi ọ̀rọ̀ yẹn sílẹ̀ ná. Ìgbà míì wà tó máa ń dáa kí tọkọtaya gbé ọ̀rọ̀ kan tì ná, kí wọ́n wá pa dà yanjú rẹ̀ nígbà tínú wọn bá rọ̀. Bíbélì sọ pé: “Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ asọ̀ dà bí ẹni tí ń tú omi jáde; nítorí náà, kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.”​—Òwe 17:14.

Ẹ máa tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ara yín, àti lọ́wọ́ àwọn ọmọ yín, tọ́rọ̀ náà bá kàn wọ́n. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan tó ń jẹ́ Brianne sọ pé: “Nígbà míì, táwọn òbí mi bá ti bára wọn fa ọ̀rọ̀ tán, wọ́n á tọrọ àforíjì lọ́wọ́ èmi àti ẹ̀gbọ́n mi torí wọ́n mọ bó ṣe máa ń rí lára wa.” Ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye jù tó o lè kọ́ àwọn ọmọ rẹ ni bí wọ́n ṣe lè máa fìrẹ̀lẹ̀ sọ pé, “Ẹ máà bínú.”

Tó bá wá jẹ́ pé ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ lẹ jọ fa ọ̀rọ̀ ńkọ́? Ronú dáadáa, kó má lọ jẹ́ pé ṣe lò ń dá kún wàhálà náà láìmọ̀. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Rachel àti màmá rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ Orí 2 nínú ìwé yìí, ní ojú ìwé 15. Ǹjẹ́ o lè sọ ohun tí ìyá Rachel ṣe tó dá kún awuyewuye náà? Kí lo lè ṣe tí ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ ò fi ní jọ máa fa ọ̀rọ̀? Fi àwọn kókó yìí sọ́kàn:

● Yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ àsọrégèé bíi, “Gbogbo ìgbà lo máa ń . . . ” tàbí “O kì í . . . láyé tìẹ.” Ṣe ni irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ kí ọmọ rẹ fẹ́ gbèjà ara rẹ̀. Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ àsọdùn lásán, ọmọ rẹ náà á sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ọmọ rẹ sì mọ̀ pé ìbínú ló jẹ́ kó o máa sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé òun ò ṣe ojúṣe òun.

● Ohun tó dùn ẹ́ nínú ìwà ọmọ rẹ ló yẹ kó o sọ, dípò tí wàá kàn fi máa sọ̀rọ̀ gbá a lórí. Bí àpẹẹrẹ, dípò tí wàá fi máa lo ọ̀rọ̀ bí “ìwọ,” tàbí “o,” ṣe ni kó o sọ bọ́rọ̀ ṣe ń rí lára rẹ, bóyá kó o sọ pé: “Tó o bá ṣe báyìí-báyìí, inú mi kì í . . . ” Ká sòótọ́, bí ọmọ rẹ bá mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára rẹ, kò ní fẹ́ ṣe ohun tó máa bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́. Tó o bá jẹ́ kó mọ bí ìwà rẹ̀ ṣe rí lára rẹ, á lè túbọ̀ bá ọ fọwọ́ sowọ́ pọ̀. *

● Bó ṣe wù kí ọ̀rọ̀ kan dùn ẹ́ tó, gbìyànjú láti ní sùúrù títí dìgbà tí ìbínú rẹ bá rọlẹ̀. (Òwe 29:22) Bí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ilé bá wà lára ohun tó ń fa awuyewuye, pe ọmọ rẹ jókòó kẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Sọ ohun tó o fẹ́ kó ṣe gan-an, tó bá sì pọn dandan, sọ ohun tó lè yọrí sí tí kò bá ṣe é. Fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohun tí ọmọ rẹ bá fẹ́ sọ, kódà bí ohun tó ń sọ ò bá tiẹ̀ tọ̀nà lójú rẹ. Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń gbọ́ tẹni tó bá fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn ju ti ẹni tó bá kàn ń sọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe lọ.

● Kó o tó yára pinnu pé ẹ̀mí tinú-mi-ni-màá-ṣe ló ń da ọmọ rẹ láàmú, mọ̀ pé èyí tó pọ̀ jù nínú ìwà tó ń hù jẹ́ ara nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ tí ọmọdé bá ń dàgbà. Ọmọ rẹ lè bá ẹ jiyàn lórí ohun kan torí kó o lè mọ̀ pé òun náà ti ń dàgbà. Má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà di awuyewuye. Rántí pé ọmọ rẹ ń kíyè sí ohun tó o máa ń ṣe tínú bá bí ẹ. Fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún un ní ti béèyàn ṣe ń ní sùúrù àti ìpamọ́ra, wàá rí i pé ó lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ.​—Gálátíà 5:22, 23.

WO ORÍ 2 NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ, ÀTI ORÍ 24 NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ

Báwo ló ṣe yẹ kí n sọ fún àwọn ọmọ mi tó nípa ìgbésí ayé mi àtẹ̀yìnwá?

Fojú inú yàwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ná: Ìwọ, ọkọ (tàbí aya) rẹ, ọmọ rẹ obìnrin àtàwọn ọ̀rẹ́ yín kan jọ ń jẹun. Bí ẹ ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni ọ̀rẹ́ rẹ sọ nípa ẹnì kan tó ò ń fẹ́ nígbà kan, àmọ́ tẹ́ ẹ fira yín sílẹ̀, kó tó di pé o wá pàdé ẹni tẹ́ ẹ jọ fẹ́ra báyìí. Ọ̀rọ̀ yẹn ya ọmọ rẹ lẹ́nu débi pé ṣíbí tó fi ń jẹun fẹ́rẹ̀ẹ́ já bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Ó wá béèrè pé: “Ẹ̀-ẹ́n, ṣé pé ẹ ti kọ́kọ́ ń fẹ́ ẹnì kan tẹ́lẹ̀ rí?” O kò sọ ìtàn yìí fún ọmọ rẹ rí. Ó wá fẹ́ mọ̀ sí i nípa rẹ̀ báyìí. Kí lo máa ṣe?

Ó sábà máa ń dáa pé kó o dáhùn ìbéèrè tí ọmọ rẹ bá bi ẹ́. Nítorí pé, ìgbàkigbà tí ọmọ rẹ bá ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ, tó sì ń tẹ́tí gbọ́ ìdáhùn rẹ, ẹ ǹ jùmọ̀ sọ̀rọ̀ nìyẹn, ohun tí ọ̀pọ̀ òbí sì ń fẹ́ nìyẹn.

Báwo ni ohun tó o máa sọ fún ọmọ rẹ nípa ìgbésí ayé rẹ àtẹ̀yìnwá ṣe yẹ kó pọ̀ tó? Òótọ́ ni pé o ò ní fẹ́ mẹ́nu kan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó lè tì ẹ́ lójú. Síbẹ̀, bó o bá jẹ́ káwọn ọmọ rẹ mọ àwọn àṣìṣe kan tó o ti ṣe rí àtàwọn ìṣòro kan tó o ní, ìyẹn láwọn ìgbà tó o bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀, ó máa ṣe wọ́n láǹfààní. Lọ́nà wo?

Wo àpẹẹrẹ yìí. Nígbà kan, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Nígbà tí mo bá fẹ́ láti ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tí ó burú a máa wà pẹ̀lú mi. . . . Èmi abòṣì ènìyàn!” (Róòmù 7:21-24) Jèhófà Ọlọ́run ló mí sí ọ̀rọ̀ yìí, òun ló sì jẹ́ kí wọ́n kọ ọ́ sínú Bíbélì fún àǹfààní wa. Ó dájú pé gbogbo wa la lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, àbí èwo nínú wa ni ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yẹn kì í ṣẹlẹ̀ sí?

Lọ́nà kan náà, bí àwọn ọmọ rẹ bá gbọ́ nípa àwọn ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu tó o ṣe àti àwọn àṣìṣe rẹ, èyí lè mú kí wọ́n túbọ̀ máa sọ tinú wọn jáde fún ẹ. Lóòótọ́, bí nǹkan ṣe rí nígbà tó o wà lọ́mọdé kọ́ ló ṣe rí lóde òní. Síbẹ̀, àwọn àyípadà yìí kò yí bí ọ̀rọ̀ ṣe ń rí lára àwa èèyàn pa dà; bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ìlànà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ kò yí pa dà. (Sáàmù 119:144) Tó o bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tó o ní nígbà yẹn àti bó o ṣe yanjú wọn, ìyẹn lè jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ mọ báwọn ṣe máa bójú tó ìṣòro tiwọn náà. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Cameron sọ pé: “Tó o bá wá mọ̀ pé àwọn òbí rẹ náà ti ní irú àwọn ìṣòro tó ò ń ní báyìí rí, ó máa jẹ́ kó o túbọ̀ rí i pé aláìpé bíi tiẹ̀ làwọn òbí rẹ náà.” Ó tún sọ pé: “Bó o bá ní ìṣòro míì, kíá ló máa sọ sí ẹ lọ́kàn pé ó ṣeé ṣe káwọn òbí rẹ ti ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ rí.”

Àkíyèsí: Kò pọn dandan kó jẹ́ pé gbogbo ìgbà tó o bá sọ ìtàn fún wọn ni wàá máa tẹnu mọ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n ibẹ̀. Lóòótọ́, o lè máa ronú pé ọmọ rẹ lè lọ ṣi ohun tó ò ń sọ lóye tàbí kó tiẹ̀ gbà pé kò burú tí òun náà bá ṣe irú ohun kan náà. Àmọ́ kàkà tí wàá fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé ẹ̀kọ́ tó o fẹ́ kí ọmọ rẹ kọ́ látinú ìrírí rẹ (bóyá tí wàá sọ pé, “Ìdí nìyẹn tí o kò fi gbọ́dọ̀ ṣe báyìí-báyìí”), ṣe ni kó o kàn sọ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ náà ṣe rí lára tìrẹ. (O lè sọ pé, “Àmọ́ ṣá o, ó dùn mí pé mo ṣe báyìí-báyìí torí pé . . . ”) Nípa bẹ́ẹ̀ ọmọ rẹ á lè kẹ́kọ̀ọ́ tó máa ṣe é láǹfààní látinú ìrírí rẹ, tí kò sì ní máa ronú pé ńṣe lo kàn dá òun jókòó láti bá òun wí.​—Éfésù 6:4.

WO ORÍ 1 NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ

Kí ni mo lè ṣe kí ọmọ mi lè máa sọ tinú ẹ̀ fún mi?

Nígbà táwọn ọmọ rẹ ṣì wà ní kékeré, kò sóhun tí wọn kì í sọ fún ẹ. Tó o bá bi wọ́n nípa nǹkan kan, kíá ni wọ́n ti máa dá ẹ lóhùn. Kódà, lọ́pọ̀ ìgbà ìwọ kọ́ lo ṣẹ̀ṣẹ̀ máa bi wọ́n; fúnra wọn ni wọ́n máa to gbogbo rẹ̀ fún ẹ bí ẹyẹ ìbákà. Àmọ́ ní báyìí, bí ìgbà téèyàn ń fẹ́ fa omi jáde nínú kànga kan tó ti gbẹ lọ̀rọ̀ máa ń rí nígbà tó o bá ń fẹ́ káwọn ọmọ rẹ tó ti ń bàlágà sọ ohun tó ń bẹ lọ́kàn wọn fún ẹ. O tiẹ̀ lè máa sọ lọ́kàn ara rẹ pé, ‘Wọ́n ṣáà máa ń bá àwọn ọ̀rẹ́ wọn sọ̀rọ̀. Kí ló wá dé tí wọn kì í sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún èmi?’

Má ronú pé bí àwọn ọmọ rẹ kò ṣe fẹ́ máa bá ẹ sọ̀rọ̀ túmọ̀ sí pé wọ́n ti pa ẹ́ tì tàbí pé wọn ò fẹ́ kó o máa dá sọ́rọ̀ àwọn. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé àsìkò yìí gan-an ni wọ́n nílò rẹ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ohun kan tínú ẹ máa dùn sí ni pé, ìwádìí fi hàn pé àwọn ọmọ tó ń bàlágà ṣì mọyì ìmọ̀ràn àwọn òbí wọn, kódà ju èyí táwọn ojúgbà wọn bá fún wọn tàbí èyí tí wọ́n ń gbọ́ nínú rédíò tàbí lórí tẹlifíṣọ̀n lọ.

Kí wá nìdí tí wọn kì í fi fẹ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún ẹ? Jẹ́ ká wo ohun táwọn ọ̀dọ́ kan sọ pé ó jẹ́ ìdí tí àwọn kì í fi í bá àwọn òbí àwọn sọ̀rọ̀. Kó o wá bi ara rẹ láwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e, kó o sì ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀.

“Ohun tó mú kó ṣòro fún mi láti máa bá Dádì sọ̀rọ̀ ni pé àwọn nǹkan tí wọ́n ń bójú tó níbi iṣẹ́ àti nínú ìjọ ti pọ̀ jù. Ó máa ń dà bíi pé kò sí àyè rárá láti bá wọn sọ̀rọ̀.”​—Andrew.

‘Ǹjẹ́ bí mo ṣe ń ṣe sáwọn ọmọ mi kò ti jẹ́ kí wọ́n máa rò pé ọwọ́ mi ti dí jù láti ráyè tiwọn? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni mo lè ṣe táá fi túbọ̀ rọrùn fún wọn láti sún mọ́ mi? Àkókò wo ni mo lè yà sọ́tọ̀ láti fi máa bá àwọn ọmọ mi sọ̀rọ̀ déédéé?’​—Diutarónómì 6:7.

“Pẹ̀lú omijé lójú ni mò ń sọ fún mọ́mì mi nípa àríyànjiyàn kan tó wáyé láàárín èmi àti ẹnì kan nílé ìwé wa. Mo fẹ́ kí Mọ́mì sọ̀rọ̀ tó máa tù mí nínú, àmọ́ ńṣe ni wọ́n kàn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ sí mi. Látìgbà yẹn ni mi ò ti bá wọn sọ̀rọ̀ pàtàkì kankan mọ́.”​—Kenji.

‘Báwo ni mo ṣe máa ń ṣe táwọn ọmọ mi bá sọ ohun tó ń dùn wọ́n lọ́kàn fún mi? Bó bá tiẹ̀ gba pé kí n tún èrò wọn ṣe, ǹjẹ́ kò ní dáa kí n máa fara balẹ̀ gbọ́ tẹnu wọn ná, kí n lè mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wọn kí n tó fún wọn nímọ̀ràn?’​—Jákọ́bù 1:19.

“Ó jọ pé gbogbo ìgbà táwọn òbí bá sọ pé ká sọ ohun tó bá wà lọ́kàn wa, pé àwọn ò ní bínú, wọ́n ṣì máa ń pàpà bínú. Ìyẹn sì máa ń dun àwa ọ̀dọ́ gan-an.”​—Rachel.

‘Bí ọmọ mi bá sọ ohun kan tó lè bí mi nínú, báwo ni mo ṣe lè máa kọ́kọ́ ṣe sùúrù ná kí n má bàa ṣi nǹkan ṣe?’​—Òwe 10:19.

“Lọ́pọ̀ ìgbà, tí mo bá sọ ọ̀rọ̀ àṣírí kan nípa ara mi fún Mọ́mì, kíá, wọ́n ti lọ sọ fáwọn ọ̀rẹ́ wọn. Ìyẹn ni ò jẹ́ kí n fọkàn tán wọn mọ́ fún ìgbà pípẹ́.”​—Chantelle.

‘Ǹjẹ́ mo máa ń gba ti ọmọ mi rò, kí n má sọ ọ̀rọ̀ àṣírí tó bá fi sí mi lọ́wọ́ fáwọn ẹlòmíì?’​—Òwe 25:9.

“Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà lọ́kàn mi tí mo fẹ́ sọ fáwọn òbí mi. Ṣe ni mo kàn máa ń fẹ́ kó jẹ́ pé àwọn ló máa kọ́kọ́ dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀.”​—Courtney.

‘Ǹjẹ́ mo lè kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ kí èmi àti ọmọ mi lè jọ jíròrò? Ìgbà wo ló dáa jù ká jọ sọ̀rọ̀?’​—Oníwàásù 3:7.

Gẹ́gẹ́ bí òbí, wàá jàǹfààní gan-an tó o bá lè wá ọ̀nà tí ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ á fi jọ máa sọ̀rọ̀ pọ̀. Wo ohun tí ọmọbìnrin ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] kan tó ń jẹ́ Junko, ní orílẹ̀-èdè Japan sọ. Ó ní: “Lọ́jọ́ kan, mo sọ fún màmá mi pé ara máa ń tù mí tí mo bá wà láàárín àwọn ojúgbà mi nílé ìwé ju ìgbà tí mo bá wà láàárín àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni. Lọ́jọ́ kejì, mo rí lẹ́tà kan tí mọ́mì mi kọ sí mi lórí tábìlì mi. Nínú lẹ́tà náà, wọ́n sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn náà nígbà kan, pé àwọn rò pé kò sí ẹni táwọn lè mú lọ́rẹ̀ẹ́ láàárín àwọn táwọn jọ jẹ́ Kristẹni. Wọ́n wá rán mi létí àwọn kan nínú Bíbélì tí wọ́n sin Ọlọ́run nígbà tí kò sí ẹnì kankan tó lè máa fún wọn níṣìírí. Wọ́n tún wá yìn mí pé mò ń gbìyànjú láti ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi. Ó yà mí lẹ́nu láti gbọ́ pé èmi nìkan kọ́ ló ní irú ìṣòro yìí. Mímọ̀ tí mo wá mọ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣe màmá mi náà rí jẹ́ kí inú mi dùn débi pé omijé bọ́ lójú mi. Ohun tí màmá mi sọ fún mi yìí fún mi níṣìírí gan-an, ó sì jẹ́ kí n pinnu láti ṣe ohun tó tọ́.”

Ohun tí ìyá Junko wá mọ̀ ni pé, àwọn ọmọ tó ti ń bàlágà máa ń fẹ́ láti sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn tó bá dá wọn lójú pé àwọn òbí wọn ò ní fojú kéré ọ̀rọ̀ wọn àti bí nǹkan ṣe ń rí lára wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò ní bú àwọn. Àmọ́ kí lo lè ṣe tó bá dà bíi pé ọmọ rẹ ń bínú nígbà tó ń bá ẹ sọ̀rọ̀? Má ṣe fìbínú fèsì ohun tí ọmọ rẹ sọ. (Róòmù 12:21; 1 Pétérù 2:23) Dípò bẹ́ẹ̀, bó ti wù kó nira tó, jẹ́ kí ọmọ rẹ rí àpẹẹrẹ bó ṣe yẹ kí òun máa sọ̀rọ̀ àti bó ṣe yẹ kí òun máa hùwà.

Rántí pé: Bí àwọn ọmọ tó ń bàlágà ṣe ń dàgbà sí i, bí wọ́n ṣe ń ṣe nǹkan á máa yàtọ̀. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kíyè sí i pé nírú àkókò bẹ́ẹ̀, ìwà wọn sábà máa ń dédé yí pa dà. Wọ́n lè hùwà bí àgbàlagbà láwọn ìgbà kan, nígbà míì sì rèé, wọ́n lè hùwà bí ọmọdé. Kí lo lè ṣe bó o bá kíyè sí i pé ìwà ọmọ rẹ yí pa dà, pàápàá nígbà tó bá jẹ́ pé ṣe ló ń hùwà bí ọmọdé?

Má ṣe fìbínú sọ̀rọ̀ sí ọmọ náà, má sì máa bá a fa ọ̀rọ̀ bí ọmọdé. Dípò bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o rọra máa bá a sọ̀rọ̀ bí ẹni tó ti ń dàgbà bọ̀ díẹ̀díẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 13:11) Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọmọ rẹ ṣe ìṣe ọmọdé lọ́jọ́ kan, tó wá sọ fún ẹ pé, “Kí ló dé tẹ́ ẹ fi máa ń rí sí mi ṣáá?” Ó ṣeé ṣe kínú bí ẹ, kó o sì fìbínú sọ̀rọ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní lè fara balẹ̀ sọ̀rọ̀ mọ́, ìyẹn sì lè dá awuyewuye sílẹ̀ láàárín yín. Dípò ìyẹn, o kàn lè sọ pé: “Ó jọ pé inú ti bí ẹ. O ò ṣe jẹ́ ká dá ọ̀rọ̀ yìí dúró dìgbà tí inú kò ní bí ẹ mọ́?” Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ náà ò ní di ariwo. Tó bá yá, á ṣeé ṣe fún yín láti jọ sọ̀rọ̀ dípò tẹ́ ẹ fi máa ní èdè àìyedè.

WO ORÍ 1 ÀTI 2 NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ

 ÒFIN

Ṣé ó yẹ kí n fún ọmọ mi ní òfin nípa àkókò tí mo fẹ́ kó máa wọlé?

Kó o lè dáhùn ìbéèrè yìí, fojú inú wo ìṣẹ̀lẹ̀ yìí: Aago tó o ní kí ọmọ rẹ ọkùnrin máa wọlé ti kọjá ọgbọ̀n ìṣẹ́jú báyìí, àfi bó o ṣe gbọ́ tẹ́nì kan rọra ṣílẹ̀kùn àbáwọlé. O rò ó sínú pé, ‘Ó rò pé mo ti lọ sùn nìyẹn o.’ O ò kúkú tíì sùn. Kódà, látìgbà tó ti yẹ kí ọmọ rẹ wọlé lo ti lọ jókòó sí tòsí ẹnu ọ̀nà. Bó ṣe ṣílẹ̀kùn báyìí, ńṣe lojú ìwọ àti òun ṣe mẹ́rin. Kí lo máa sọ? Kí lo máa ṣe?

Ohun tó o lè ṣe pọ̀. O lè fọwọ́ tí ò tó nǹkan mú ọ̀rọ̀ náà. Bóyá kó o rò ó lọ́kàn pé, ‘Ọmọdé ò lè ṣe kó má hùwà ọmọdé jàre.’ O sì lè bínú gan-an, kó o wá sọ pé: “Òní lo jáde nílé yìí mọ o.” Dípò tí wàá kàn fi ṣe ohun tó bá kọ́kọ́ wá sí ẹ lọ́kàn, ṣe ni kó o kọ́kọ́ gbọ́ ohun tó máa sọ, bóyá ohun kan ló fà á tó fi pẹ́ kó tó dé. Nípa bẹ́ẹ̀, wàá lè lo àìgbọràn tó ṣe láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì. Lọ́nà wo?

Àbá: Sọ fún ọmọ rẹ pé tó bá di ọjọ́ kejì, ẹ ó jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Kó o sì wáyè, kó o pè é jókòó, kó o wá sọ ohun tó o máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ náà. Ìwọ wo ọgbọ́n táwọn òbí kan dá. Bí ọmọ wọn bá kọjá aago tí wọ́n dá pé kó máa dé, wọ́n á sọ fún un pé ó gbọ́dọ̀ máa dé ní ọgbọ̀n ìṣẹ́jú ṣáájú ti tẹ́lẹ̀. Bó bá sì jẹ́ pé ọmọ náà máa ń wọlé lákòókò, tó sì ṣeé fọkàn tán, o lè wò ó bóyá o lè fi kún òmìnira tó ní, kó o gbà á láyè kó máa lo àkókò díẹ̀ sí i lóde lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ó ṣe pàtàkì pé kó o jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ aago tó o fẹ́ kó máa wọlé àti ohun tó o máa ṣe fún un bí kò bá wọlé ní aago yẹn. Kó o sì rí i dájú pé o ṣe ohun tó o sọ bó bá pẹ́ kó tó wọlé.

Àmọ́, kíyè sí ohun tí Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀.” (Fílípì 4:5) Kó o tó dá aago tí ọmọ rẹ gbọ́dọ̀ máa wọlé, kí ìwọ àti ọmọ rẹ kọ́kọ́ jọ jíròrò ọ̀rọ̀ náà, kó o jẹ́ kó dábàá aago pàtó kan, kó sì sọ ìdí tí òun fi mú aago yẹn. Kó o wá gba ohun tó sọ rò. Bí ìwà ọmọ rẹ bá fi hàn pé ó ṣeé fọkàn tán, ìyẹn lè jẹ́ kó o fara mọ́ ohun tó bá sọ, ìyẹn tó bá bọ́gbọ́n mu.

Ká sọ̀rọ̀ ká bá a bẹ́ẹ̀ ni iyì ọmọlúwàbí. Torí náà, kọ́mọ má bàa pẹ́ lóde nìkan kọ́ la ṣe ń dá aago tó gbọ́dọ̀ wọlé fún un. Àmọ́ ó tún jẹ́ ẹ̀kọ́ àtàtà tó máa ṣe é láǹfààní nígbà tó bá bẹ̀rẹ̀ sí í dá gbé.​—Òwe 22:6.

WO ORÍ 3 NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ, ÀTI ORÍ 22 NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ

Kí ni mo lè ṣe bí èrò èmi àtàwọn ọmọ mi kò bá dọ́gba lórí irú aṣọ tó yẹ kí wọ́n máa wọ̀?

Ronú nípa àpèjúwe tá a lò ní ojú ìwé 77 nínú ìwé yìí. Jẹ́ ká sọ pé ọmọ rẹ ni Heather. O wá rí i tó wọ aṣọ péńpé kan tó fi ara sílẹ̀. Lo bá kàn sọ fún un lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé: “Lọ sókè kó o lọ wá aṣọ gidi wọ̀, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ o ò lọ síbì kankan!” Ìyẹn lè mú kí ọmọ rẹ ṣe ohun tó o sọ o, torí kò ní fẹ́ kọ ọ̀rọ̀ sí ẹ lẹ́nu. Àmọ́, báwo lo ṣe lè kọ́ ọ táá fi dẹni tó mọ irú aṣọ tó tọ́ láti máa wọ̀, yàtọ̀ sí pé kó kàn ṣe ohun tó o sọ yẹn?

● Lákọ̀ọ́kọ́ ná, rántí pé ọmọ rẹ gbọ́dọ̀ mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tí òun bá múra lọ́nà tí kò bójú mu, ó tiẹ̀ yẹ kó mọ̀ pé ibi tó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ náà yọrí sí kan òun ju bó ṣe kan ìwọ lọ. Lọ́kàn ọmọ rẹ, kò ní fẹ́ káwọn èèyàn máa fojú òmùgọ̀ wo òun torí bí òun ṣe múra, kò sì ní fẹ́ pe àfiyèsí tí kò yẹ sí ara rẹ̀. Ńṣe ni kó o fi sùúrù ṣàlàyé fún un pé, tó bá wọ aṣọ tí kò bójú mu, ìyẹn ò ní káwọn èèyàn gba tiẹ̀. * Sọ aṣọ míì tó o ronú pé ó lè wọ̀.

● Ohun kejì ni pé kó o fòye bá ọmọ rẹ lò. Bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ aṣọ yìí ta ko ìlànà Bíbélì kan, àbí kò kàn wù mí ni?’ (2 Kọ́ríńtì 1:24; 1 Tímótì 2:9, 10) Tó bá jẹ́ pé ńṣe ni aṣọ náà ò kàn wù ẹ́, ṣé o ṣì lè jẹ́ kí ọmọ rẹ wọ̀ ọ́?

● Ohun kẹta ni pé má kàn sọ irú àwọn aṣọ tí dáa fún ọmọ rẹ, ṣe ni kó o bá a wá àwọn aṣọ tó bójú mu. O ò ṣe lo àwọn ibi tó o lè kọ nǹkan sí ní ojú ìwé 82 àti 83 nínú ìwé yìí láti fi jẹ́ kí ọmọ rẹ mọ irú aṣọ tó bọ́gbọ́n mu pé kí òun máa wọ̀? Wàá rí i pé ìsapá rẹ àti àkókò tó o lò láti fi ṣe é máa ṣàǹfààní gan-an!

WO ORÍ 11 NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ

Ṣé ó yẹ kí n jẹ́ kí ọmọ mi máa gbá géèmù orí kọ̀ǹpútà?

Géèmù orí kọ̀ǹpútà ti yí pa dà gan-an sí tìgbà tó o wà lọ́dọ̀ọ́. Gẹ́gẹ́ bí òbí, báwo lo ṣe lè wá mú kí ọmọ rẹ mọ àwọn ewu tó wà nínú gbígbá géèmù orí kọ̀ǹpútà kó lè máa yàgò fáwọn ewu yẹn?

Bó o bá kàn ń bẹnu àtẹ́ lu gbogbo géèmù orí kọ̀ǹpútà pátá tàbí kó o máa sọ pé wọ́n kàn ń fàkókò ẹni ṣòfò lásán ni, bí ẹni ń yín àgbàdo sẹ́yìn igbá lásán ló máa jẹ́ lára ọmọ rẹ. Má ṣe gbàgbé pé kì í ṣe gbogbo géèmù orí kọ̀ǹpútà ló burú. Ó kàn jẹ́ pé ṣe ló máa ń di bárakú. Nítorí náà, ṣe ni kó o mọ bí àkókò tí ọmọ rẹ ń lò nídìí géèmù náà ṣe pọ̀ tó. Kó o sì tún mọ irú géèmù orí kọ̀ǹpútà tó jọ pé ó máa ń nífẹ̀ẹ́ sí. O tiẹ̀ lè bi í láwọn ìbéèrè bíi:

● Géèmù orí kọ̀ǹpútà wo làwọn ọmọ kíláàsì rẹ fẹ́ràn jù?

● Báwo ni wọ́n ṣe máa ń gbá géèmù náà?

● Kí lo rò pé ó fà á tí wọ́n fi fẹ́ràn géèmù náà?

O lè wá rí i pé ọmọ rẹ mọ̀ nípa géèmù orí kọ̀ǹpútà ju bó o ṣe rò lọ! Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí òun náà ti gbá irú àwọn géèmù orí kọ̀ǹpútà tó o rò pé kò dáa yẹn. Bó bá jẹ́ òótọ́ ló ti gbá irú géèmù bẹ́ẹ̀ rí, má ṣe bínú sódì. Ńṣe ni kó o lo àǹfààní yẹn láti ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè mọ béèyàn ṣe lè fi ọgbọ́n yan ohun tó dáa.​—Hébérù 5:14.

Bi í láwọn ìbéèrè táá jẹ́ kó rí ìdí tí àwọn géèmù tí kò dáa fi lè máa wù ú láti gbá. Bí àpẹẹrẹ, o lè bi í pé:

● Ṣé ó máa ń ṣe ẹ́ bíi pé a fi ohun kan dù ẹ́ tá ò bá jẹ́ kó o gbá géèmù yẹn?

Ó lè jẹ́ nítorí àtimáa rí ọ̀rọ̀ sọ láàárín àwọn ojúgbà wọn làwọn ọ̀dọ́ kan ṣe máa ń gbá irú àwọn géèmù kan. Bó bá jẹ́ pé ohun tó sún ọmọ rẹ dédìí ẹ̀ nìyẹn, a jẹ́ pé ọwọ́ tó o máa fi mú ọ̀ràn náà ò ní le tó ọwọ́ tó o máa fi mú un bó bá jẹ́ pé ńṣe ló dìídì fẹ́ láti máa gbá àwọn géèmù tí wọ́n ti ń tàjẹ̀ sílẹ̀ tàbí tí wọ́n ti ń bára wọn ṣèṣekúṣe.​—Kólósè 4:6.

Bó bá wá jẹ́ pé ohun tí kò dáa nínú géèmù orí kọ̀ǹpútà yẹn gan-an ló máa ń wu ọmọ rẹ ńkọ́? Àwọn ọ̀dọ́ kan lè sọ pé ẹ̀jẹ̀ tó máa ń dà yàà nínú géèmù ò ṣe àwọn ní nǹkan kan, pé géèmù lásán ni. Wọ́n lè ní: ‘Ti pé mò ń gbá a lórí kọ̀ǹpútà ò ní kí n máa ṣe é lójú ayé.’ Bó bá jẹ́ pé bó ṣe rí lára ọmọ rẹ nìyẹn, rán an létí ohun tó wà nínú Sáàmù 11:5. Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ṣe sọ, kò dìgbà téèyàn bá ń hu ìwà ipá kó tó rí ìbínú Ọlọ́run, èèyàn tún lè rí ìbínú Ọlọ́run bó bá fẹ́ràn ìwà ipá. Ìlànà kan náà ló kan ìṣekúṣe tàbí ìwà búburú èyíkéyìí mìíràn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé kò dáa.​—Sáàmù 97:10.

Tí géèmù orí kọ̀ǹpútà bá ti wọ ọmọ rẹ lẹ́wù, gbìyànjú àwọn àbá yìí:

● Má ṣe jẹ́ kó máa gbá géèmù orí kọ̀ǹpútà èyíkéyìí níbi tójú àwọn ẹlòmíì ò ti lè tó, irú bíi nínú iyàrá.

● Jẹ́ kí ìlànà wà táá máa tẹ̀ lé lórí ọ̀rọ̀ géèmù, bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé lẹ́yìn iṣẹ́ àṣetiléwá, lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, tàbí lẹ́yìn àwọn iṣẹ́ ilé pàtàkì mìíràn ló tó lè gbá géèmù.

● Tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa ṣe àwọn nǹkan míì tó gba kéèyàn fara ṣiṣẹ́.

● Má máa fàwọn ọmọ rẹ nìkan sílẹ̀ nídìí géèmù orí kọ̀ǹpútà, o tiẹ̀ lè máa bá wọn gbá a lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.

Àmọ́ ṣá o, kó o bàa lè máa dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ lórí ọ̀ràn eré ìnàjú, ó yẹ kí ìwọ náà máa fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀. Nítorí náà, bi ara rẹ pé, ‘Irú ètò orí tẹlifíṣọ̀n wo tàbí irú fíìmù wo ni mo máa ń wò?’ Bó bá jẹ́ pé àtèyí tó dáa àtèyí tí kò dáa nìwọ náà máa ń wò, jẹ́ kó yé ẹ pé àwọn ọmọ rẹ ń rí ẹ o!

WO ORÍ 30 NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ

Kí ni kí n ṣe tí ọmọ mi bá ń lo àkókò tó pọ̀ jù lórí fóònù, lórí kọ̀ǹpútà tàbí àwọn ohun èlò míì tó ń gbé ìsọfúnni jáde?

Ṣé ọmọ rẹ máa ń lo àkókò tó pọ̀ jù lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ṣé ó ń fi ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ gan-an lórí fóònù tó sì ń gba ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá fi ránṣẹ́ sí i, àbí ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbọ́ orin (MP3) ló máa ń tẹ́tí sí ní gbogbo ìgbà dípò kó máa bá ẹ̀yin òbí rẹ̀ sọ̀rọ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe?

O lè rò pé ohun tó máa yanjú ìṣòro yìí ni pé kó o gba ohun èlò náà kúrò lọ́wọ́ ọmọ rẹ. Àmọ́, má kàn bẹnu àtẹ́ lu gbogbo ohun èlò tó ń gbé ìsọfúnni jáde. Ó ṣe tán, ìwọ náà ń lo àwọn ohun èlò tó ń gbé ìsọfúnni jáde tí àwọn òbí tìrẹ kò lò. Dípò tí wàá fi gba àwọn ohun èlò tí ọmọ rẹ ń lò lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà tí kò bá pọn dandan pé ko o gbà á, o lè lo àǹfààní yẹn láti kọ́ o lẹ́kọ̀ọ́ nípa béèyàn ṣe ń fọgbọ́n lo àwọn ohun èlò náà, tí kò sì ní sọ ọ́ di àṣejù? Báwo lo ṣe lè ṣe é?

Pe ọmọ rẹ jókòó, kẹ́ ẹ jọ jíròrò ọ̀rọ̀ náà. Lákọ̀ọ́kọ́, sọ ohun tó ń kọ ẹ́ lóminú. Lẹ́yìn náà, tẹ́tí gbọ́ ohun tí òun náà fẹ́ sọ. (Òwe 18:13) Kó o wá sọ àwọn ohun tó lè ṣe fún un. Má ṣe bẹ̀rù láti fún un ní ìtọ́ni pàtó, àmọ́ fi òye bá a lò. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Ellen sọ pé: “Lákòókò kan tó jẹ́ pé gbogbo ìgbà ṣáá ni mo máa ń kọ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù, àwọn òbí mi kò gba fóònù mi lọ́wọ́ mi, ńṣe ni wọ́n kàn fún mi ní ìlànà tí màá máa tẹ̀ lé. Bí wọ́n ṣe bójú tó ọ̀ràn náà ràn mí lọ́wọ́ gan-an débi pé mi kì í ṣe é ní àṣejù, kódà tí àwọn òbí mi ò bá tiẹ̀ sí níbẹ̀ láti wo ohun tí mò ń ṣe.”

Bí ọmọ rẹ kò bá wá fẹ́ tẹ̀ lé ohun tó o sọ ńkọ́? Má ṣe parí èrò sí pé ìmọ̀ràn rẹ kò wọ̀ ọ́ létí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe sùúrù, kó o sì fún un láyè láti ronú nípa ọ̀rọ̀ náà. Ó ṣeé ṣe kó gba ohun tó o sọ, kó sì ṣe àyípadà tó yẹ. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ni ọ̀rọ̀ wọn dà bíi ti ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Hailey, tó sọ pé: “Inú kọ́kọ́ bí mi nígbà tí àwọn òbí mi sọ pé mo ti ń ṣàṣejù nínú bí mo ṣe ń lo kọ̀ǹpútà. Àmọ́ nígbà tó yá, tí mo tún wá ń ro ohun tí wọ́n sọ dáadáa, mo wá ń rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ wọn.”

WO ORÍ 36 NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ

 ÒMÌNIRA

Báwo ló ṣe yẹ kí n fún ọmọ mi ní òmìnira tó?

Kì í fi bẹ́ẹ̀ rọrùn láti mọ ohun tó o máa ṣe tó bá di pé ọmọ rẹ fẹ́ máa ṣe àwọn nǹkan kan láṣìírí. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọmọ rẹ ọkùnrin wà nínú yàrá, ó sì ti ilẹ̀kùn. Ǹjẹ́ ó yẹ kó o kàn já wọlé láì kan ilẹ̀kùn? Tàbí kẹ̀, bóyá ọmọ rẹ obìnrin gbàgbé fóònù rẹ̀ sílé nígbà tó ń kánjú lọ sílé ìwé, ṣé ó yẹ kó o ka àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi ránṣẹ́ sórí fóònù rẹ̀?

Kò rọrùn láti dáhùn àwọn ìbéèrè yìí. Gẹ́gẹ́ bí òbí, o lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ ohun tí ọmọ rẹ ń ṣe, ojúṣe rẹ sì ni láti dáàbò bò ó. Àmọ́, o kò ní lè máa ṣọ́ ọmọ rẹ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ ní gbogbo ìgbà, kó o máa fẹ́ mọ gbogbo ohun tó bá ń ṣe. Báwo lo ṣe lè wá ṣe ojúṣe rẹ láìjẹ́ pé o ki àṣejù bọ̀ ọ́?

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, fi sọ́kàn pé kì í ṣe gbogbo ìgbà táwọn ọmọ rẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà bá fẹ́ ṣe nǹkan kan ní àṣírí ló jẹ́ pé ohun tí kò dáa ni wọ́n fẹ́ ṣe. Báwọn ọmọ bá ti ń dàgbà wọ́n máa ń fẹ́ ní àṣírí tiwọn. Ìyẹn máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá àwọn ti lè dá ṣe àwọn ìpinnu kan láàárín àwọn àti ọ̀rẹ́ àwọn, àti bóyá àwọn ti lè lo “agbára ìmọnúúrò” àwọn láti yanjú ìṣòro. (Róòmù 12:1, 2) Níní àṣírí tiwọn máa ń jẹ́ káwọn ọ̀dọ́ mọ béèyàn ṣe ń ronú, èyí sì ṣe pàtàkì tí wọ́n bá máa dàgbà dẹni tó lè dá ìpinnu ṣe. Ó tún máa ń jẹ́ kí wọ́n lè lo làákàyè kí wọ́n tó ṣe ìpinnu èyíkéyìí tàbí kí wọ́n tó fèsì àwọn ìbéèrè tó ṣòro dáhùn.​—Òwe 15:28.

Ohun kejì tó yẹ kó o mọ̀ ni pé tó o bá fẹ́ máa pinnu gbogbo ohun tí ọmọ rẹ máa ṣe, inú ọmọ náà kò ní dùn, ìyẹn sì lè mú kó ya ìyàkuyà. (Éfésù 6:4; Kólósè 3:21) Ṣé ohun tá a wá ń sọ ni pé kó o fi ọmọ náà sílẹ̀ kó máa ṣe bó ṣe wù ú? Rárá o, torí ìwọ ṣì ni òbí rẹ̀. Síbẹ̀, ohun tó yẹ kó jẹ ẹ́ lógún ni bí ọmọ rẹ ṣe máa ní ẹ̀rí ọkàn táá fi máa mọ rere yàtọ̀ sí búburú. (Diutarónómì 6:6, 7; Òwe 22:6) Wàá wá rí i pé ó sàn kó o kàn máa tọ́ ọmọ rẹ sọ́nà ju kó o máa ṣọ́ ọ lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ lọ.

Ohun kẹta ni pé kí ìwọ àti ọmọ rẹ jọ jíròrò ọ̀rọ̀ náà. Kó o fetí sílẹ̀ nígbà tí ọmọ rẹ bá ń sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Wò ó bóyá o lè fara mọ́ ohun tó bá sọ nígbà míì. Sọ fún un pé wàá fún un lómìnira dé ìwọ̀n àyè kan, bí kò bá ti ní ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kó o fọkàn tán an. Jẹ́ kó mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ bó bá ṣe ohun tí kò yẹ, kó o sì dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ. Mọ̀ dájú pé o ṣì jẹ́ kí ọmọ rẹ ní àṣírí tiẹ̀ déwọ̀n àyè kan, tí èyí ò sì ní sọ ẹ́ di òbí tí kò ṣe ojúṣe rẹ̀.

WO ORÍ 3 ÀTI 15 NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ

Ibo ló yẹ kí ọmọ mi kàwé dé?

“Ọ̀rọ̀ àwọn olùkọ́ mi ti sú mi!” “Iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n ń fún mi ti pọ̀ jù!” “Mo ti máa ń ṣe wàhálà púpọ̀ jù kí n tó má fìdí rẹmi, kí tiẹ̀ nìdí tí mo fi ń da ara mi láàmù gan-an?” Irú àwọn nǹkan báyìí ló ń mú kí ilé ìwé sú àwọn ọ̀dọ́ kan, tí wọ́n á fẹ́ pa á tì, láì tíì kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n á fi lè gbọ́ bùkátà ara wọn. Bí ọmọ rẹ bá sọ pé òun fẹ́ pa ilé ìwé tì, kí lo lè ṣe? Gbìyànjú àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí:

Irú ojú wo ni ìwọ òbí fi ń wo ẹ̀kọ́ ìwé? Nígbà tó o wà ní ọ̀dọ́, ṣé fífi àkókò ṣòfò lásán lo ka ilé ìwé sí, tó ò ń wò ó bí ìgbà tó o wà nínú àhámọ́ kan títí dìgbà tí wàá fi lè ṣe àwọn nǹkan míì tó wù ẹ́? Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, irú ojú tó o fi ń wo ẹ̀kọ́ ìwé lè nípa lórí àwọn ọmọ rẹ. Bí àwọn ọmọ rẹ bá parí ilé ìwé wọn, wọ́n á ní “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú,” èyí sì ṣe pàtàkì tí ọwọ́ wọn bá máa lè tẹ ohun tí wọ́n fẹ́ fi ayé wọn ṣe.​—Òwe 3:21.

Fún wọn ní ohun tí wọ́n nílò. Àwọn ọmọ kan wà tó jẹ́ pé torí wọn ò mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ ni wọn ò ṣe ṣe dáadáa nínú ẹ̀kọ́ wọn, ó sì lè jẹ́ pé ṣe ni wọn ò ríbi tó dáa tí wọ́n ti lè máa kàwé. Lára àwọn ohun tó lè wà níbi tí ọmọ rẹ á ti máa kàwé ni tábìlì tí ẹrù kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ lórí rẹ̀, kí ìmọ́lẹ̀ wà dáadáa àtàwọn ohun tí ọmọ náà lè fi ṣe ìwádìí. O lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ máa ṣe dáadáa yálà nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ tàbí nínú àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, tó o bá ṣètò ibi tó dáa tó ti lè máa ro àròjinlẹ̀ lórí àwọn nǹkan tuntun tó bá kọ́.​—Fi wé 1 Tímótì 4:15.

Máa mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí. Gbà pé ìwọ àtàwọn olùkọ́ tó ń kọ́ ọmọ rẹ jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ni, má ṣe máa wò wọ́n bí ọ̀tá. Rí i pé o mọ̀ wọ́n, kó o sì mọ orúkọ wọn. Máa bá wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí ọmọ rẹ fẹ́ ṣe lẹ́yìn tó bá parí ilé ìwé àtàwọn ìṣòro tí ọmọ náà ní. Bí ọmọ rẹ kò bá ṣe dáadáa nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀, gbìyànjú láti mọ ohun tó fà á. Bí àpẹẹrẹ, ṣé kì í ṣe pé ńṣe ni ọmọ rẹ ń rò pé tí òun bá ń ṣe dáadáa jù nílé ìwé àwọn ọmọ kan nílé ìwé lè bẹ̀rẹ̀ sí í halẹ̀ mọ́ òun? Àbí ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ rẹ̀ ló ń dà á láàmù? Ṣé àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nílé ìwé kò máa fún un níṣòro? Ṣe ló yẹ kí àwọn iṣẹ́ ilé ìwé jẹ́ kí ọmọ rẹ lè máa fi ìmọ̀ kún ìmọ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, àwọn iṣẹ́ náà kò gbọ́dọ̀ mu ún lómi ju bó ṣe yẹ lọ. Ó sì tún lè jẹ́ pé àwọn ìṣòro míì ló fà á, irú bí ojú tí kò ríran dáadáa tàbí kó jẹ́ pé ọmọ rẹ ní ìṣòro ẹ̀kọ́ kíkọ́.

Bó o bá ṣe túbọ̀ ń mọ bí ẹ̀kọ́ ọmọ rẹ ṣe ń lọ sí, yálà ẹ̀kọ́ ilé ìwé ni o tàbí ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ni wàá ṣe lè máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí ọmọ rẹ lè ṣàṣeyọrí nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀.​—Sáàmù 127:4, 5.

WO ORÍ 19 NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ

Báwo ni mo ṣe máa mọ̀ bóyá ọmọ mi ti tó ẹni tó lè lọ dá gbé?

Ẹ̀rù ń ba Serena, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní Orí 7 nínú ìwé yìí, láti kó kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀. Kí ló ń bà á lẹ́rù? Ó sọ pé: “Bí mo bá tiẹ̀ fẹ́ fi owó ara mi ra nǹkan, dádì mi ò ní jẹ́ kí n rà á. Wọ́n máa ń sọ pé, ojúṣe àwọn ni láti ra àwọn ohun tí mo bá nílò. Torí náà sísanwó ohun tí mo bá tiẹ̀ lò lásán máa ń bà mí lẹ́rù.” Òótọ́ ni pé, ohun tó dáa ni bàbá Serena ní lọ́kàn, àmọ́ ṣé o rò pé ó ń kọ́ ọmọ rẹ̀ bó ṣe máa lè gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ nígbà tó bá kúrò nílé báyìí?​—Òwe 31:10, 18, 27.

Ṣé kì í ṣe pé ìwọ náà ń kẹ́ àwọn ọmọ rẹ ní àkẹ́jù débi pé wọn ò mọ bí wọ́n ṣe lè dá gbọ́ bùkátà ara wọn nígbà tí wọ́n bá lọ ń dá gbé? Báwo lo ṣe lè mọ̀? Wo àwọn kókó mẹ́rin yìí, tá a ti jíròrò ní Orí 7 nínú ìwé yìí, lábẹ̀ àkòrí tó sọ pé “Ǹjẹ́ Mo Ti Lè Dá Gbé Lóòótọ́?” Wá gbé wọn yẹ̀ wò lọ́nà tí ìwọ òbí á fi lè rí ojúṣe rẹ báyìí.

Béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná. Ǹjẹ́ àwọn ọmọ rẹ tó ti tójú bọ́ mọ bí wọ́n ṣe lè ra oúnjẹ sílé? Ṣé wọ́n mọ iye táwọn èèyàn ń san fún owó ilé àtàwọn nǹkan kòṣeémánìí míì tẹ́ ẹ̀ ń lò nínú ilé? (Róòmù 13:7) Ṣé wọ́n mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná? (Òwe 22:7) Ṣé wọ́n lè ṣètò bí wọ́n á ṣe máa ná owó tó bá ń wọlé fún wọn, kí wọ́n má sì ná ju iye tí wọ́n ní lọ? (Lúùkù 14:28-30) Ṣé wọ́n ti nírú ayọ̀ téèyàn máa ń ní tó bá fowó tó ṣiṣẹ́ fún ra nǹkan? Ǹjẹ́ wọ́n tiẹ̀ ti lo àkókò wọn àtàwọn ohun tí wọ́n ní láti fi ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ rí, tí ìyẹn sì mú inú wọn dùn?​—Ìṣe 20:35.

Àwọn iṣẹ́ ilé. Ǹjẹ́ àwọn ọmọ rẹ obìnrin àtáwọn ọkùnrin pàápàá mọ oúnjẹ sè? Ṣé o ti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń fọ aṣọ àti bí wọ́n ṣe ń lọ̀ ọ́? Bí wọ́n bá ti ń wa mọ́tò, ṣé wọ́n lè ṣe àwọn àtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lára mọ́tò, irú bíi pípààrọ̀ fíùsì, ọ́ìlì tàbí táyà tó bá jò?

Béèyàn ṣe ń wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. Bí èdèkòyédè bá wáyé láàárín àwọn ọmọ rẹ tí wọ́n ti tójú bọ́, ṣé ìwọ lo máa ń bá wọn parí ìjà? Àbí o ti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè máa fi sùúrù yanjú àwọn ọ̀ràn, kí wọ́n sì wá sọ bí wọ́n ṣe yanjú rẹ̀ fún ẹ?​—Mátíù 5:23-25.

Àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Ṣé o kàn máa ń sọ ohun tó yẹ káwọn ọmọ rẹ gbà gbọ́ fún wọn ni, àbí o máa ń jẹ́ kí wọ́n rí ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti gba irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ gbọ́? (2 Tímótì 3:14, 15) Dípò kó o kàn máa dáhùn àwọn ìbéèrè tí àwọn ọmọ rẹ bá ń bi ẹ́ nípa ẹ̀sìn àti nípa ìwà híhù, ṣé ò ń kọ́ wọn lọ́nà tí wọ́n á fi ní “agbára láti ronú”? (Òwe 1:4) Ǹjẹ́ wàá fẹ́ kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àbí àpẹẹrẹ tìẹ kò dáa tó èyí tí wọ́n lè tẹ̀ lé, tó o sì fẹ́ kí wọ́n túbọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tiwọn? *

Kò sí àní-àní pé tó o bá fẹ́ tọ́ àwọn ọmọ rẹ láwọn ọ̀nà tá a mẹ́nu bà yìí, o ní láti lo àkókò tó pọ̀, kó o sì sapá gidigidi. Àmọ́, wàá wá rí i pé àǹfààní rẹ̀ pọ̀ gan-an tó bá fi máa di ọjọ́ tí wọ́n máa dágbére fún ẹ pé àwọn fẹ́ lọ máa dá gbé.

WO ORÍ 7 NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ

 Ọ̀RỌ̀ NÍPA ÌBÁLÒPỌ̀ ÀTI ÀFẸ́SỌ́NÀ

Ṣé ó yẹ kí n bá ọmọ mi sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀?

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kí àwọn ọmọ tó kúrò ní ìkókó ni wọ́n ti ń kọ́ wọn nípa ìbálòpọ̀ báyìí. Ọjọ́ pẹ́ tí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé láwọn “ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà” nítorí pé àwọn èèyàn yóò jẹ́ “aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu” àti “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” (2 Tímótì 3:1, 3, 4) Fífẹ́ táwọn ọ̀dọ́ ń fẹ́ láti máa gbéra wọn sùn jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tá a fi mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń nímùúṣẹ.

Ayé òde òní yàtọ̀ sí ayé ìgbà ti ẹ̀yin òbí. Ó kàn jẹ́ pé láwọn ọ̀nà kan, a lè sọ pé bí ìṣòro ṣe wà nígbà yẹn lọ́hùn-ún náà ló ṣe wà lóde òní. Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ, má sì ṣe fòyà nítorí pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó lè mú àwọn ọmọ rẹ ṣìwà hù ló yí wọn ká. Ńṣe ni kó o pinnu lọ́kàn ara rẹ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n máa ṣe ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún [2,000] sẹ́yìn. Ó sọ pé: “Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.” (Éfésù 6:11) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó jẹ́ ọ̀dọ́ ni wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti rí i pé àwọn ṣe ohun tó tọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan tó lè mú wọn ṣìwà hù ló yí wọn ká. Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ káwọn náà lè máa ṣe bẹ́ẹ̀?

Ọ̀nà kan tó o lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé kó o yan àwọn orí mélòó kan ní Apá Kẹrin nínú ìwé yìí àti ní Apá Kìíní àti Apá Keje nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, kó o sì bá àwọn ọmọ rẹ jíròrò ohun tó wà níbẹ̀. O máa rí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó lè múni ronú jinlẹ̀ nínú àwọn orí yẹn. Àwọn kan dá lórí àpẹẹrẹ àwọn tó dúró lórí òtítọ́ tí wọ́n sì rí ìbùkún gbà àtàwọn tí wọn kò kọbi ara sí àwọn òfin Ọlọ́run tí wọ́n sì jìyà rẹ̀. O tún máa rí àwọn ìlànà tó máa ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ míì táá jẹ́ kí ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ mọ̀ pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti máa tẹ̀ lé àwọn òfin Ọlọ́run. O ò ṣe kúkú ṣètò bó o ṣe máa jíròrò àwọn àlàyé tá a ṣe yìí pẹ̀lú wọn láìfọ̀rọ̀ falẹ̀?

WO ORÍ 23, 25 ÀTI 32 NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ, ÀTI ORÍ 4, 5, 6, 28 ÀTI 29 NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ

Ṣé ó yẹ kí n jẹ́ kí ọmọ mi ní ẹni tó ń fẹ́?

Ó dájú pé bó pẹ́ bó yá, àwọn èèyàn ṣì máa yọ àwọn ọmọ rẹ lẹ́nu lórí ọ̀rọ̀ níní ẹni tí wọ́n ń fẹ́. Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Phillip sọ pé: “Jẹ́jẹ́ ara mi ni mo máa ń wà o, tí àwọn ọmọbìnrin á wá bá mi pé ká jọ máa fẹ́ra. Màá wá máa ronú pé, ‘Kí ni kí n wá ṣe báyìí o?’ Ó máa ń ṣòro fún mi láti sọ pé mi ò ṣe torí pé arẹwà làwọn kan lára wọn!”

Ohun tó dáa kí ìwọ òbí ṣe ni pé kó o bá ọmọ rẹ tó ń bàlágà jíròrò ọ̀rọ̀ nípa àfẹ́sọ́nà. O lè lo àlàyé tá a ṣe sí Orí 1 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, láti fi jíròrò ọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lú ọmọ rẹ. Béèrè ohun tí ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ obìnrin ń rò nípa àwọn ìṣòro tó ń ní nílé ìwé àti nínú ìjọ Kristẹni pàápàá. Nígbà míì o lè dá ìjíròrò náà sílẹ̀ láìjẹ́ pé o dìídì pè é pé ọ̀rọ̀ wà, irú bíi “nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà.” (Diutarónómì 6:6, 7) Ìgbà yòówù kó o dá ọ̀rọ̀ náà sílẹ̀, rántí pé ó yẹ kó o “yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.”​—Jákọ́bù 1:19.

Tí ọmọ rẹ bá sọ pé òun àti ẹnì kan ń fẹ́ra, má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ já. Ọmọbìnrin kan tó ti ń bàlágà sọ pé: “Nígbà tí dádì mi mọ̀ pé èmi àti ọmọkùnrin kan ń fẹ́ra wa, inú bí wọn gan-an! Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í da ìbéèrè bò mí láti dáyà já mi, wọ́n ń bi mí bóyá mo ti fẹ́ lọ́kọ, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ṣe làwọn ìbéèrè yẹn máa ń mú káwa ọmọdé fẹ́ máa bá irú ìfẹ́ yẹn lọ ká lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀rọ̀ yẹn ò rí bí wọ́n ṣe rò rárá!”

Tí ọmọ rẹ tó ti ń bàlágà bá mọ̀ pé o kì í fẹ́ gbọ́ pé òun ní ẹnì kan tí òun ń fẹ́, ìyẹn lè yọrí sí nǹkan míì tí kò dáa. Ó lè máa fẹ́ ẹni náà lọ, tí kò sì ní jẹ́ kó o mọ̀. Ọmọbìnrin kan sọ pé: “Tí àwọn òbí bá ti fi ọwọ́ tó le jù mú ọ̀rọ̀ yìí, ṣe làwọn ọmọ á kúkú máa ṣe ọ̀rọ̀ náà láṣìírí. Ìyẹn ò ní kí wọ́n jáwọ́ nínú rẹ̀. Ṣe ni wọn ò wá ní jẹ́ kí àwọn òbí wọn mọ ohun tó ń lọ rárá.”

Tó o bá ń bá àwọn ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ láìfi nǹkan kan pa mọ́, nǹkan á túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Ọmọ ogún ọdún kan tó ń jẹ́ Brittany sọ pé: “Àwọn òbí mi kì í fi nǹkan kan pa mọ́ fún mi tó bá dọ̀rọ̀ kí ọkùnrin àti obìnrin máa fẹ́ra. Wọ́n máa ń fẹ́ kí n jẹ́ kí àwọn mọ ẹni tó ń wù mí, mo sì rò pé ìyẹn dáa! Dádì mi á wá pe ẹni náà jókòó láti bá a sọ̀rọ̀. Bí wọ́n bá sì kíyè sí ohunkóhun, wọ́n á sọ fún mi. Lọ́pọ̀ ìgbà, màá ti wá pinnu pé mi ò ṣe, kó tiẹ̀ tó débi pé a máa bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra sọ́nà.”

Àmọ́, ó lè jẹ́ pé lẹ́yìn tó o ka àpilẹ̀kọ tó wà ní Orí 2 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, lo wá ń bi ara rẹ pé, ‘Ṣé ó wa lè jẹ́ pé ọmọ mi ti ní ẹni tó ń fẹ́ láìsọ fún mi?’ Kíyè sí ohun táwọn ọ̀dọ́ mélòó kan sọ nípa ohun tó lè mú káwọn ọ̀dọ́ kan máa fẹ́ra wọn tí wọn ò sì ní fẹ́ jẹ́ kí àwọn òbí wọn mọ̀, lẹ́yìn náà kó o wá ronú lórí àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé ohun tí wọ́n sọ.

“Àwọn ọmọ kan wà tí wọn kì í rí ohun tó lè mórí wọn yá nínú ilé, wọ́n á wá torí ìyẹn pinnu pé ó yẹ káwọn lọ́rẹ̀ẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin.”​—Wendy.

Báwo ni ìwọ òbí ṣe lè rí i dájú pé ò ń tẹ́tí gbọ́ ohun táwọn ọmọ rẹ bá ní í sọ? Ṣé àwọn ohun kan wà tó yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí nínú ọ̀ràn yìí? Tó bá sì wà, kí làwọn ohun náà?

“Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni mí nígbà tí ọmọkùnrin kan wá sílé ìwé wa láti orílẹ̀-èdè míì. Ó ní kí n jẹ́ ká jọ máa fẹ́ra, èmi náà sì gbà fún un. Èrò mi ni pé ó dáa kí èmi náà ní ọmọkùnrin kan táá máa fọwọ́ kọ́ mi lọ́rùn.”​—Diane.

Bó bá jẹ́ pé ọmọ rẹ ni Diane, kí lo máa ṣe sọ́rọ̀ tó wà ńlẹ̀ yìí?

“Tẹlifóònù alágbèéká máa ń mú kí nǹkan túbọ̀ rọrùn fáwọn tó ń fẹ́ra wọn, tí wọn ò sì fẹ́ kí ẹlòmíì mọ̀. Àwọn òbí wọn ò ní mọ ohun tó ń lọ rárá!”​—Annette.

Báwọn ọmọ rẹ bá ń lo tẹlifóònù alágbèéká, àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà kọ́ wọn láti máa ṣọ́ra ṣe?

“Ó túbọ̀ máa ń rọrùn fáwọn ọ̀dọ́ láti máa fẹ́ra wọn, tí wọn ò sì ní jẹ́ kí ẹlòmíì mọ̀ báwọn òbí ò bá fojú sí ohun táwọn ọmọ wọn ń ṣe àti irú ẹni tí wọ́n ń bá rìn.”​—Thomas.

Ǹjẹ́ ohun kan wà tó o lè ṣe tí wàá fi máa fojú sí ohun táwọn ọmọ rẹ ń ṣe síbẹ̀ tí wàá sì máa fún wọn lómìnira tó yẹ?

“Lọ́pọ̀ ìgbà àwọn òbí míì ò tíì ní dé sílé nígbà táwọn ọmọ wọn á ti dé láti ilé ìwé. Tàbí kó jẹ́ pé kò sẹ́ni tí wọn ò lè gbà pé kí ọmọ wọn bá jáde lọ síbi tó bá fẹ́.”​—Nicholas.

Ǹjẹ́ o mọ àwọn tí ọmọ rẹ ń bá rìn? Ǹjẹ́ o mọ ohun tí wọ́n ń ṣe bí wọ́n bá jọ wà pa pọ̀?

“Báwọn òbí bá ti le koko jù, àwọn ọmọ wọn lè ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí wọ́n ń fẹ́ láṣìírí.”​—Paul.

Láìjẹ́ pé o pa àwọn òfin àtàwọn ìlànà Bíbélì tì, báwo lo ṣe lè “jẹ́ kí ìfòyebánilò [rẹ] di mímọ̀”?​—Fílípì 4:5.

“Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́tàlá, mi ò fi bẹ́ẹ̀ rí ara mi bí ẹni táwọn èèyàn kà sí, torí náà mo máa ń fẹ́ káwọn èèyàn dá sí mi. Kò pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í kọ lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà sí ọmọkùnrin kan nínú ìjọ tó wà nítòsí wa, bí mo ṣe yófẹ̀ẹ́ fún un nìyẹn o. Ńṣe ló máa ń kẹ́ mi lójú méjèèjì.”​—Linda.

Ṣé o lè ronú nípa àwọn ọ̀nà míì táwọn òbí Linda ì bá ti gbà ràn án lọ́wọ́ nínú ilé?

O ò ṣe lo Orí 2 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì àti apá tá a wà yìí nínú Àfikún yìí láti fi bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀? Bí o kò bá fẹ́ káwọn ọmọ rẹ máa ṣe nǹkan láṣìírí, ṣe ni kó o jẹ́ kí wọ́n rí ẹ bí alábàárò tó máa ń sọ bọ́rọ̀ ṣe rí gan-an.​—Òwe 20:5.

WO ORÍ 1 SÍ 3 NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ

 ÀWỌN OHUN TÓ JẸ MỌ́ Ẹ̀DÙN ỌKÀN

Kí ni kí n ṣe bí ọmọ mi bá sọ pé òun fẹ́ para òun?

Láwọn apá ibì kan láyé, kì í ṣe nǹkan tuntun pé àwọn ọ̀dọ́ ń para wọn, ìyẹn sì ń kọ àwọn èèyàn lóminú. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, nígbà tí wọ́n to àwọn nǹkan tó sábà máa ń fa ikú àwọn ọ̀dọ́ tó wà láàárín ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] sí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25], wọ́n rí i pé ipò kẹta ni pípa táwọn ọ̀dọ́ ń pa ara wọn wà. Àti pé láti nǹkan bí ogún ọdún sígbà tá a wà yìí, iye àwọn ọ̀dọ́ tó ń para wọn nígbà tí wọ́n wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá sí mẹ́rìnlá ti pọ̀ sí i ní ìlọ́po méjì. Àwọn tó sábà máa ń dáṣà yìí làwọn ọ̀dọ́ tó lárùn ọpọlọ, àwọn ọ̀dọ́ tí mọ̀lẹ́bí wọn kan ti para rẹ̀ rí, àtàwọn tó ti gbìyànjú nígbà kan rí láti para wọn. Àwọn àmì tó o lè rí nìyí tí wàá fi mọ̀ bóyá ọ̀dọ́ kan ti ń ronú láti para rẹ̀:

● Á fẹ́ máa dá nìkan wà

● Oúnjẹ lè máa tètè sú u tàbí kó máa jẹun jù, ó sì lè máà máa rí oorun sùn dáadáa

● Àwọn nǹkan tó fẹ́ràn láti máa ṣe tẹ́lẹ̀ lè má wù ú ṣe mọ́

● Ìwà rẹ̀ máa yàtọ̀ gan-an sí ti tẹ́lẹ̀

● Ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í lòògùn nílòkulò, kó sì máa mutí lámujù

● Á bẹ̀rẹ̀ sí í fàwọn nǹkan iyebíye tó ní tọrẹ

● Ọ̀rọ̀ nípa ikú ò ní máa wọ́n lẹ́nu rẹ̀ tàbí kó máa sọ nǹkan tó jọ mọ́ ọn

Àṣìṣe gbáà ló máa jẹ́ tí òbí ò bá ka àwọn àmì yìí sí. Gbogbo àmì tó o bá ń rí ló yẹ kó o kà sí pàtàkì. Má ṣe tètè parí èrò sí pé, ‘àmì pé ó ń bàlágà ni, ó máa tó yí pa dà.’

Bákan náà, má ṣe jẹ́ kójú tì ẹ́ láti mú ọmọ rẹ lọ gba ìtọ́jú tó bá ní ìdààmú ọkàn tàbí tó lárùn ọpọlọ. Tó o bá sì fura pé ọmọ rẹ ń ronú láti para rẹ̀, ṣe ni kó o tètè bi í. Irọ́ gbuu lèrò táwọn èèyàn ní pé táwọn bá sọ̀rọ̀ nípa gbígba ẹ̀mí ara ẹni, ó lè jẹ́ káwọn ọmọ pa ara wọn. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ lara wọn máa ń balẹ̀ wọ̀ọ̀ táwọn òbí wọn bá báwọn sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń ronú láti para wọn. Tí ọmọ rẹ ò bá jiyàn pé òun fẹ́ para òun, tètè béèrè bóyá ó ti ní bó ṣe fẹ́ ṣe é, tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, fara balẹ̀ gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa rẹ̀. Bí kúlẹ̀kúlẹ̀ tó o gbọ́ bá ṣe le tó lo ṣe gbọ́dọ̀ káràmáásìkí ọ̀rọ̀ náà tó.

Má kàn rò pé ìbànújẹ́ tí ọmọ náà ní máa lọ tó bá yá o. Tó bá tiẹ̀ wá dà bíi pé ó rí bẹ́ẹ̀, má rò pé ìṣòro ti tán nìyẹn o. Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá, torí pé ìgbà tí ìbànújẹ́ yẹn bá ti ń lọ kúrò lọ́kàn rẹ̀ ló léwu jù. Nítorí pé lákòókò tí ìbànújẹ́ bá mu ọ̀dọ́ kan lómi, kì í rójú ráyè tó bẹ́ẹ̀ láti ṣekú para rẹ̀. Àmọ́ tí ìṣòro tó ń dà á lọ́kàn rú bá ti lè fúyẹ́ díẹ̀, irú ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ máa lókun tó pọ̀ tó láti pa ara rẹ̀.

Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ tó níṣòro máa ń para wọn torí bí wọ́n ṣe ronú pé ikú yá jẹ̀sín. Àmọ́, tí àwọn òbí àtàwọn àgbàlagbà míì tí kò fi ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ṣeré bá pàfiyèsí sáwọn àmì wọ̀nyẹn tí wọ́n sì ṣe àwọn ohun tó yẹ, wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ “sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́,” kí wọ́n sì wá dà bí ibi ààbò fún irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀.​—1 Tẹsalóníkà 5:14.

WO ORÍ 13, ÀTI 14 NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ, ÀTI ORÍ 26 NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ

Ṣé kí n pa ìbànújẹ́ mi mọ́ra lójú àwọn ọmọ mi?

Ikú ọkọ tàbí aya ẹni máa ń dunni gan-an. Síbẹ̀, ní irú àkókò bẹ́ẹ̀, ọmọ rẹ tó ti ń bàlágà máa nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ lójú méjèèjì. Báwo lo ṣe lè ràn án lọ́wọ́ nígbà tí inú rẹ̀ bà jẹ́ yìí, tí wàá sì tún mọ ohun tó o lè ṣe sí ìbànújẹ́ tìrẹ fúnra rẹ? Wo àwọn àbá tó tẹ̀ lé e yìí:

Má fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ pa mọ́. Ọ̀dọ̀ rẹ lọmọ rẹ ti kọ́ ọ̀pọ̀ lára àwọn nǹkan pàtàkì tó mọ̀. Ọ̀dọ̀ rẹ náà ló sì ti máa kọ́ bó ṣe lè fara da ẹ̀dùn ọkàn. Torí náà, má ṣe rò pé o gbọ́dọ̀ fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ pa mọ́ kó o tó lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́. Ńṣe ló máa jẹ́ kí òun náà máa fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ pa mọ́. Àmọ́, bó o bá fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ hàn, ọmọ rẹ á lè mọ̀ pé ó sàn kéèyàn fi bí ọ̀rọ̀ ṣe dun òun tó hàn ju kó bò ó mọ́ra lọ, àti pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn banú jẹ́, kí nǹkan tojú súni, tàbí kéèyàn bínú pàápàá.

Gba ọmọ rẹ níyànjú láti sọ tinú rẹ̀ jáde. Láìfi ipá mú ọmọ rẹ, gbà á níyànjú láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Bó bá dà bíi pé ó ń lọ́ tìkọ̀, ẹ ò ṣe jọ jíròrò Orí 16 nínú ìwé yìí? Kẹ́ ẹ tún sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ nǹkan tó máa ń wù yín nípa ẹni tó di olóògbé náà. Jẹ́ kó mọ bí nǹkan á ṣe máa ṣòro fún ẹ tó ní báyìí tí ẹrù ẹ̀yin méjì ti di ti ìwọ nìkan. Bó bá rí i pé ò ń sọ tinú ẹ jáde, òun náà á mọ̀ pé kò burú bí òun náà bá ń ṣe bẹ́ẹ̀.

Mọ ibi tí agbára rẹ mọ. Òótọ́ ni pé o kò ní fẹ́ láti já ọmọ rẹ kulẹ̀ lákòókò ìṣòro yìí. Àmọ́, má ṣe gbàgbé pé ikú ọkọ tàbí aya rẹ ọ̀wọ́n ṣì ń dun ìwọ náà. Torí náà, ó ṣì lè máa bà ẹ́ lọ́kàn jẹ́, kó má rọrùn fún ẹ láti ronú lórí ohun tó yẹ láti ṣe, kí ara rẹ má sì yá gágá. (Òwe 24:10) Torí náà, o lè fọ̀rọ̀ rẹ lọ àwọn tó dàgbà nínú ìdílé yín tàbí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí wọ́n jẹ́ olóye. Ó bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn fọ̀rọ̀ ara rẹ̀ lọ àwọn míì. Òwe 11:2 sọ pé: “Ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.”

Jèhófà Ọlọ́run lẹni tó lè fún ẹ ní ìtìlẹ́yìn tó dára jù lọ, torí ó ṣèlérí fáwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ pé: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’”​—Aísáyà 41:13.

WO ORÍ 16 NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ

Báwo ni mo ṣe lè ran ọmọ mi lọ́wọ́ kó má ṣe àṣejù nínú bó ṣe ń ṣọ́ oúnjẹ jẹ?

Kí lo lè ṣe bí ọmọ rẹ bá ń ṣọ́ oúnjẹ jẹ? Lákọ̀ọ́kọ́, gbìyànjú láti lóye ohun tó fà á.

Àwọn èèyàn ti kíyè sí i pé ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í fẹ́ jẹun dáadáa ni wọn kì í fojú tó dáa wo ara wọn, tí wọ́n máa ń fẹ́ láti ṣe ohun gbogbo fínnífínní láìṣe àṣìṣe, tí wọ́n sì máa ń fẹ́ ṣe ju agbára wọn lọ. Rí i pé o ò dá kún àwọn ìṣòro tí ọmọ rẹ ní yìí. Wá bó o ṣe máa ran ọmọ rẹ lọ́wọ́.​—1 Tẹsalóníkà 5:11.

Bákan náà, fara balẹ̀ kíyè sí ojú tí ìwọ náà fi ń wo oúnjẹ jíjẹ àti ìrísí àwọn èèyàn. Ṣé ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ tàbí ìwà rẹ kò fi hàn pé o ti ń ti àṣejù bọ ojú tó o fi wo nǹkan méjèèjì yìí? Má gbàgbé pé àwọn ọ̀dọ́ kì í fi ọ̀rọ̀ bí ara wọn ṣe rí ṣeré rárá. Kódà tó o bá sọ fún ọ̀dọ́ kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà pé ó kàn ń wú tàbí tó o fi ṣe yẹ̀yẹ́ pé ó kàn ń ga, ìyẹn lè bẹ̀rẹ̀ sí í dà á lọ́kàn rú.

Lẹ́yìn tó o bá ti ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí tàdúràtàdúrà, bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa wọ̀ ọ́ lọ́kàn. Kí ọ̀rọ̀ rẹ sì lè wọ̀ ọ́ lọ́kàn, gbìyànjú láti ṣe àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí:

● Fara balẹ̀ ronú lórí ohun tó o fẹ́ bá a sọ àti ìgbà tí wàá bá a sọ ọ́.

● Sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́ ẹ lógún tó àti bó ṣe wù ẹ́ láti ràn án lọ́wọ́.

● Má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu tí ọmọ rẹ bá kọ́kọ́ sọ pé òun ò níṣòro kankan.

● Fara balẹ̀ gbọ́ ohun tó fẹ́ sọ.

Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ti ọmọ rẹ lẹ́yìn bó ṣe ń sapá láti borí ìṣòro tó ní. Ṣe ni kí gbogbo yín nínú ìdílé pawọ́ pọ̀ láti ran ọmọ náà lọ́wọ́!

WO ORÍ 10 NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ, ÀTI ORÍ 7 NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ

  Ọ̀RỌ̀ NÍPA ÌJỌSÌN ỌLỌ́RUN

Báwo ni mo ṣe lè máa bá a nìṣó láti kọ́ ọmọ mi tó ti ń bàlágà ní àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run?

Bíbélì sọ pé “láti ìgbà ọmọdé jòjòló” ni Tímótì ti ń gba ẹ̀kọ́ lórí bó ṣe máa ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, ó sì ṣeé ṣe kí ìwọ náà gẹ́gẹ́ bí òbí ti máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ náà bẹ́ẹ̀. (2 Tímótì 3:15) Àmọ́ táwọn ọmọ rẹ bá ti ń dàgbà sí i, o lè ní láti yí ọ̀nà tó ò ń gbà kọ́ wọn pa dà kó lè bá ipò tí wọ́n wà báyìí mu. Àwọn ọmọ rẹ tó ń bàlágà yìí lè bẹ̀rẹ̀ sí í lóye àwọn ọ̀rọ̀ tó díjú, èyí tó jẹ́ pé wọ́n lè ṣàì lóye dáadáa nígbà tí wọ́n ṣì kéré. Ìsinsìnyí gan-an ló máa gba pé kó o jẹ́ kí wọ́n lo “agbára ìmọnúúrò” wọn dáadáa.​—Róòmù 12:1.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí Tímótì, ó sọ àwọn ohun tí Tímótì “ti kọ́, tí a sì ti [i] lérò padà láti gbà gbọ́.” (2 Tímótì 3:14) Ó lè gba pé kó o yí àwọn ọmọ rẹ tó ti ń bàlágà lérò pa dà kí wọ́n tó lè nígbàgbọ́ nínú àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n ti mọ̀ láti kékeré. Kọ́rọ̀ rẹ lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn, má kàn ṣáà máa sọ ohun tí wọ́n máa ṣe tàbí ohun tó yẹ kí wọ́n gbà gbọ́ fún wọn. Àwọn ló máa kọ́ ìyẹn fúnra wọn. Báwo lo ṣe wá máa ràn wọ́n lọ́wọ́? Bó o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ni pé kó o máa mú kí àwọn fúnra wọn ronú jinlẹ̀ kí wọ́n sì máa sọ èrò inú wọn lórí irú àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí:

● Kí ló jẹ́ kí n gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà?​—Róòmù 1:20.

● Báwo ni mo ṣe mọ̀ pé ẹ̀kọ́ Bíbélì táwọn òbí mi ń kọ́ mi jẹ́ òótọ́?​—Ìṣe 17:11.

● Kí ló jẹ́ kí n gbà gbọ́ pé àǹfààní tara mi ni àwọn ìlànà Bíbélì wà fún?​—Aísáyà 48:17, 18.

● Báwo ni mo ṣe mọ̀ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì máa ṣẹ?​—Jóṣúà 23:14.

● Kí ló jẹ́ kí n gbà gbọ́ pé kò sí ohunkóhun míì nínú ayé yìí tó ṣe pàtàkì, tó sì níye lórí tó “ìmọ̀ nípa Kristi Jésù” tó ta yọ lọ́lá?​—Fílípì 3:8.

● Kí ni ẹbọ ìràpadà Kristi túmọ̀ sí fún èmi?​2 Kọ́ríńtì 5:14, 15; Gálátíà 2:20.

Ó lè má wù ẹ́ pé kó o bi àwọn ọmọ rẹ ní àwọn ìbéèrè yẹn, bóyá torí pé wọ́n lè má mọ ìdáhùn wọn. Àmọ́ ṣe ló dà bí ìgbà tí o kò fẹ́ wo ibi tí epo ọkọ rẹ dé, torí ẹ̀rù ń bà ẹ́ kó má lọ jẹ́ pé epo ti ń tán lọ. Ohun tó dáa jù ni pé kó o mọ̀ bóyá epo ti ń tán lóòótọ́ kó o lè tètè wá nǹkan ṣe sí i! Lọ́nà kan náà, ìsinsìnyí táwọn ọmọ rẹ ṣì wà nílé pẹ̀lú rẹ, ni kó o jẹ́ kí wọ́n ronú lórí àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn lágbára kí wọ́n sì di ẹni tá a ‘yí lérò pa dà láti gbà gbọ́.’ *

Má gbàgbé pé kò sóhun tó burú nínú kí ọmọ rẹ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ obìnrin bi ara rẹ̀ léèrè pé, “Kí nìdí tí mo fi gba ohun yìí gbọ́?” Ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ọdún méjìlélógún [22] kan tó ń jẹ́ Diane rántí pé òun náà béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ nígbà tí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà. Ó sọ pé: “Mi ò kàn fẹ́ gba ohun kan gbọ́ lásán. Àwọn ìdáhùn tó ṣe kedere tó sì dá mi lójú tí mo rí sáwọn ìbéèrè mi ló jẹ́ kí n wá mọ̀ pé ó dìídì wù mí ni láti jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà! Ìgbàkígbà tẹ́nì kan bá bi mí nípa ohun kan tí mi kì í ṣe, dípò kí n kàn sọ pé, ‘A kì í ṣe ìyẹn nínú ẹ̀sìn wa,’ ohun tí mo máa ń sọ ni pé, ‘Èmi ò gbà pé ó tọ́ láti máa ṣe é.’ Ìyẹn ni pé ohun tí Bíbélì sọ ni èmi fúnra mi gbà pé ó tọ̀nà.”

Àbá: Kó o lè mọ ohun tó wà lọ́kàn ọmọ rẹ nípa àwọn ìlànà Bíbélì nígbà tí ìṣòro bá yọjú, ní kó fi ara rẹ̀ sípò òbí. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ọmọbìnrin rẹ bẹ̀ ọ́ pé kó o jẹ́ kóun lọ sí ibi àríyá kan tó o mọ̀ (ó sì ṣeé ṣe kóun náà mọ̀) pé kò dáa kí Kristẹni lọ. Dípò tí wàá kàn fi sọ pé kò sáyè, ó lè sọ pé: ‘Ohun tí mo fẹ́ kó o ṣe ni pé, gbà pé lórí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ yìí, ìwọ ni òbí. Ronú nípa àríyá tó o fẹ́ lọ yìí, kó o sì ṣèwádìí (bóyá nínú Orí 37 nínú ìwé yìí àti Orí 32 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì), kó o wá fún mi lésì lọ́la. Èmi á ṣe ọmọ, màá bi ẹ́ pé kó o jẹ́ kí n lọ síbi àríyá yẹn, ìwọ á wá ṣàlàyé gẹ́gẹ́ bí òbí bóyá ó dáa kí n lọ tàbí kí n má lọ.’

WO ORÍ 38 NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ, ÀTI ORÍ 34 SÍ 36 NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ

Ọmọ wa ò ka ìjọsìn Ọlọ́run sí mọ́. Kí la lè ṣe?

Lákọ̀ọ́kọ́, má ṣe yára parí èrò sí pé ọmọ rẹ kò fẹ́ láti ṣe ẹ̀sìn tó ò ń ṣe. Lọ́pọ̀ ìgbà, nǹkan kan ló máa ń fà á. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ pé ọmọ rẹ ń 

● Níṣòro pẹ̀lú báwọn ojúgbà rẹ̀ ṣe ń dà á láàmú láti hùwà kan, àmọ́ ojú ń tì í láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun yàtọ̀ láàárín wọn torí pé òun ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì

● Rí i pé àwọn ọ̀dọ́ míì (kódà ó lè jẹ́ ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ̀) ń tẹ̀ síwájú dáadáa nínú ìjọsìn wọn, kó sì wá máa ṣe é bíi pé òun ò lè ṣe bíi tiwọn láéláé

● Wá ọ̀rẹ́ lójú méjèèjì, tó sì máa ń ṣe é bíi pé ó dá nìkan wà tàbí kó máa wo ara rẹ̀ bí àjèjì láàárín àwọn tó kù tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́

● Rí àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n ń pera wọn ní Kristẹni síbẹ̀ tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ìwà ìbàjẹ́

● Gbìyànjú láti dẹni tó ń lo ìdánúṣe tiẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ kó fẹ́ mọ ìdí tó o fi fẹ́ kóun máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà tíwọ ń tẹ̀ lé

● Rí àwọn ọmọ tí wọ́n jọ wà ní kíláàsì tí wọ́n ń hùwà ìbàjẹ́ fàlàlà tó sì dà bíi pé kò sí ìyà kankan tó ń tẹ̀yìn ẹ̀ yọ

● Gbìyànjú láti ṣe ohun tó máa mú inú dádì (tàbí mọ́mì) rẹ̀ tí kì í ṣe onígbàgbọ́ dùn

Lóòótọ́, irú àwọn ọ̀rọ̀ báyìí ò fi bẹ́ẹ̀ ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó o gbà gbọ́. Àmọ́ ó jẹ mọ́ àwọn nǹkan tó lè mú kó ṣòro fún ọmọ rẹ láti dúró lórí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ní báyìí. Kí lo wá lè ṣe láti ran ọmọ rẹ lọ́wọ́?

Fún un lómìnira síbẹ̀ má fàyè gbàgbàkugbà. Gbìyànjú láti mọ ohun tó ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọmọ rẹ, kó o sì wá ṣe àwọn àyípadà kan tó máa jẹ́ kára túbọ̀ tù ú táá sì jẹ́ kó lè máa ṣe dáadáa nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (Òwe 16:20) Bí àpẹẹrẹ, àtẹ “Mímúra Sílẹ̀ De Ìṣòro” tó wà lójú ìwé 132 àti 133 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì lè jẹ́ kí ọmọ rẹ ní ìgboyà tó fi jẹ́ pé kò ní tijú láti sọ̀rọ̀ láàárín àwọn ọmọ ilé ìwé rẹ̀. Tó bá sì jẹ́ pé ọmọ rẹ máa ń dá nìkan wà, ó lè gba pé kí ìwọ fúnra rẹ bá a wá àwọn ọ̀rẹ́ gidi táá máa bá rìn.

Bá a wá ẹnì kan tó tún lè máa gbà á nímọ̀ràn. Nígbà míì, àwọn ọ̀dọ́ máa ń ṣe dáadáa tí wọ́n bá rí àgbàlagbà míì kan tí kì í ṣe ará ilé wọn tó ń gbà wọ́n nímọ̀ràn. Ǹjẹ́ o mọ ẹnì kan tó ń ṣe dáadáa nínú ìjọsìn Ọlọ́run tí ọmọ rẹ lè fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? O ò ṣe kúkú ṣètò pé kí ọmọ rẹ àti ẹni náà jọ ṣe àwọn nǹkan kan pa pọ̀? Kì í ṣe torí kó o lè yẹ ojúṣe rẹ sílẹ̀ o. Ìwọ wo àpẹẹrẹ Tímótì. Ó jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ látara àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, Pọ́ọ̀lù náà sì jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ bí Tímótì ṣe jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀.​—Fílípì 2:20, 22.

Bí ọmọ rẹ bá ṣì ń gbé nínú ilé rẹ, o lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ kó mọ̀ pé ìjọsìn kan náà lo fẹ́ kẹ́ ẹ jọ máa ṣe. Ṣùgbọ́n, ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kó o jẹ́ kí ọmọ rẹ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, kì í ṣe pé kó kàn máa fojú lásán ṣe ìjọsìn láìfọkàn ṣe é. Tó o bá fẹ́ kí ọmọ rẹ dẹni tó ń ṣe ìsìn tòótọ́, ó yẹ kí ìwọ náà fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀. Má ṣe retí pé kí ọmọ náà ṣe ju agbára rẹ̀ lọ. Wá ẹnì kan tó ń ṣe dáadáa tó tún lè máa gba ọmọ rẹ nímọ̀ràn kó o sì rí i pé àwọn ọ̀rẹ́ gidi ló ń bá rìn. Bóyá ọmọ rẹ náà á lè sọ lọ́jọ́ kan bíi ti ẹni tó kọ sáàmù yìí pé: “Jèhófà ni àpáta gàǹgà mi àti odi agbára mi àti Olùpèsè àsálà fún mi.”​Sáàmù 18:2.

WO ORÍ 39 NÍNÚ ÌWÉ YÌÍ, ÀTI ORÍ 37 ÀTI 38 NÍNÚ ÌWÉ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ, APÁ KEJÌ

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 23 Àmọ́ ṣá, kì í ṣe pé kó o wá máa ka ẹ̀sùn sí ọmọ rẹ lọ́rùn láti lè mú kó ṣe ohun tó o fẹ́ o.

^ ìpínrọ̀ 64 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọmọ rẹ kì í fẹ́ kéèyàn sọ ohun tí kò dáa nípa ìrísí òun, torí náà, ṣọ́ra kó o má lọ sọ ohun tó máa mú kó rò pé ìrísí òun kò dáa rárá.

^ ìpínrọ̀ 188 Orí 36 nínú ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, Apá Kejì, lè jẹ́ kí àwọn ọmọ lo agbára ìrònú wọn láti fi mọ̀ dájú pé Ọlọ́run wà lóòótọ́.