Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbádùn Ìjọsìn Ọlọ́run?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbádùn Ìjọsìn Ọlọ́run?

ORÍ 38

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbádùn Ìjọsìn Ọlọ́run?

Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kan tó ń jẹ́ Joshua nà gbalaja sórí ibùsùn rẹ̀. Mọ́mì rẹ̀ dúró sẹ́nu ọ̀nà yàrá rẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Joshua, dìde ńlẹ̀! Ṣé wàá ló ò mọ̀ pé àsìkò ìpàdé ti tó ni!” Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn òbí Joshua, òun àtàwọn òbí ẹ̀ sì máa ń lọ sí ìpàdé ìjọ déédéé. Àmọ́ lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, ó dà bíi pé kò wù ú láti máa lọ sípàdé mọ́.

Joshua wá dáhùn pé: “Mọ́-ọ́-mì, ṣé dandan ni kí n lọ ni?”

Mọ́mì rẹ̀ wá sọ pé: “Mi ò fẹ́ gbẹ́jọ́ o, ṣáà lọ múra. Torí mi ò tún fẹ́ pẹ́ lónìí o!” Mọ́mì rẹ̀ wá yí pa dà, ó sì ń lọ.

Joshua ò tíì jẹ́ kí mọ́mì rẹ̀ lọ tán tó fi sọ tiẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹ wò ó, Mọ́mì, pé ẹ̀yin ń ṣe ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò sọ pé dandan ni kí èmi náà ṣe é.” Ó mọ̀ pé mọ́mì òun gbọ́ ohun tóun sọ, torí pé kò gbúròó ẹsẹ̀ rẹ̀ mọ́. Lẹ́yìn náà, láì fèsì, mọ́mì rẹ̀ bá tirẹ̀ lọ.

Joshua dára ẹ̀ lẹ́bi nítorí ohun tó ṣe yẹn. Kò wù ú kó sọ̀rọ̀ sí mọ́mì rẹ̀ bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀, kò fẹ́ tọrọ àforíjì. Kí ló máa wá ṣe báyìí o . . . ?

Ó mí kanlẹ̀, ó dìde lórí ibùsùn, ó sì wọ ẹ̀wù rẹ̀. Ó wá ń kùn lọ pé: “Tó bá yá, màá kúkú yan ẹ̀sìn tó wù mí. Tèmi yàtọ̀ sí tàwọn yòókù tá a jọ wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Èmi ò rò pé màá ṣe ẹ̀sìn Kristẹni yìí ní tèmi o!”

ǸJẸ́ ó ti ṣe ìwọ náà bíi ti Joshua tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ̀rọ̀ rẹ̀ tán yìí rí? Nígbà míì, ṣé o máa ń wò ó pé báwọn míì tiẹ̀ ń gbádùn lílọ sípàdé, òde ẹ̀rí, tàbí kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣe ni ìwọ kàn ń ṣe é láìjẹ́ pé ọkàn rẹ wà níbẹ̀? Bí àpẹẹrẹ:

● Ṣé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń dà bí ìgbà tí wọ́n bá gbé iṣẹ́ fún ẹ láti ṣe wá nílé ìwé?

● Ṣé ó máa ń ni ẹ́ lára láti wàásù láti ilé dé ilé?

● Ṣé ìpàdé máa ń sú ẹ?

Bí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni sí èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè yìí, má ṣe rẹ̀wẹ̀sì. O lè dẹni tó wá ń gbádùn ìjọsìn Ọlọ́run. Jẹ́ ká wo àwọn ohun tó o lè ṣe.

ÌṢÒRO ÀKỌ́KỌ́ Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Ìdí tí kò fi rọrùn. O lè máa wò ó pé kò mọ́ ẹ lára láti máa kẹ́kọ̀ọ́. Ó lè jẹ́ pé ìwé kì í pẹ́ sú ẹ, ó sì máa ń ṣòro fún ẹ láti kàn jókòó kó o máa fọkàn sí ohun tó ń lọ. Yàtọ̀ síyẹn, ṣé ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ nílé ìwé kò tíì wá pọ̀ tó ni?

Ìdí tó fi yẹ kó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Yàtọ̀ sí pé Ọlọ́run mí sí Bíbélì, ó tún “wúlò fún kíkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ àti ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti fún títọ́ wọn sọ́nà àti fún fífi bá a ṣe lè gbélé ayé hàn wọ́n.” (2 Tímótì 3:16, Bíbélì Contemporary English Version) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ṣíṣe àṣàrò lórí ohun tó o bá kà lè jẹ́ kí ojú rẹ là sí ọ̀pọ̀ nǹkan tí o kò tíì mọ̀. Ká sòótọ́, kò sí bọ́wọ́ èèyàn ṣe lè tẹ nǹkan rere láìjẹ́ pé èèyàn ṣiṣẹ́ fún un. Bí àpẹẹrẹ, bó o bá fẹ́ mọ béèyàn ṣe ń ṣeré ìdárayá kan dáadáa, o gbọ́dọ̀ kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe eré náà, kó o sì máa tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀. Bó o bá fẹ́ kí ara rẹ jí pépé, o gbọ́dọ̀ máa ṣeré ìmárale. Bákan náà, bó o bá fẹ́ mọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá rẹ, o gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Ohun táwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ sọ. “Ìgbà tí mo délé ìwé girama ni mo tó mọ̀ pé ìpinnu pàtàkì kan wà tó yẹ kí n ṣe. Oríṣiríṣi ìwà tí kò dáa ló kún ọwọ́ àwọn ọmọ ilé ìwé wa, torí náà, mo ní láti ṣe àwọn ìpinnu tó dá lórí àwọn ìbéèrè bíi: ‘Ṣé ohun témi náà fẹ́ láti ṣe nìyẹn? Ṣé ẹ̀kọ́ òtítọ́ làwọn òbí mi ń kọ́ mi lóòótọ́?’ Àfi kí èmi fúnra mi wádìí ọ̀ràn náà wò.”​Tshedza.

“Mo mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ mi, ohun tó wá kù ni pé kí n mú un dá ara mi lójú. Mo gbọ́dọ̀ fi ẹ̀sìn yìí ṣe ẹ̀sìn tèmi, kó má wulẹ̀ jẹ́ pé torí tàwọn òbí mi ni mo ṣe ń ṣe é.”​Nelisa.

Ohun tó o lè ṣe. Ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan fún ara rẹ tí wàá lè máa lò fún dídá kẹ́kọ̀ọ́. Kó o wá fúnra rẹ yan àwọn ohun tí wàá fẹ́ láti ṣèwádìí lé lórí. Ibo lo ti lè bẹ̀rẹ̀? O ò ṣe ṣèwádìí nínú Bíbélì fúnra rẹ kó o sì ṣàyẹ̀wò ohun tó o gbà gbọ́ fínnífínní, bóyá nípa lílo ìwé bíi Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? *

Ó ti yá wàyí! Láti bẹ̀rẹ̀, fi àmì ✔ sí méjì tàbí mẹ́ta lára àwọn àkòrí Bíbélì tó tẹ̀ lé e yìí tó o fẹ́ mọ̀ sí i, o sì lè kọ tìẹ náà síbẹ̀, bó o bá fẹ́.

□ Ǹjẹ́ Ọlọ́run wà?

□ Báwo ló ṣe lè dá mi lójú pé Ọlọ́run mí sí àwọn tó kọ Bíbélì?

□ Kí nìdí tó fi yẹ kí n gbà pé Ọlọ́run ló dá èèyàn dípò kí n gba ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n gbọ́?

□ Kí ni Ìjọba Ọlọ́run, báwo ni mo sì ṣe lè ṣàlàyé pé ó wà lóòótọ́?

□ Báwo ni mo ṣe lè ṣàlàyé ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn téèyàn bá ti kú?

□ Kí nìdí tó fi yẹ kó dá mi lójú pé àjíǹde máa wà?

□ Báwo ni mo ṣe lè mọ ìsìn tòótọ́ yàtọ̀?

․․․․․

ÌṢÒRO KEJÌ Lílọ sí Òde Ẹ̀rí

Ìdí tí kò fi rọrùn. Fífi ọ̀rọ̀ inú Bíbélì kọ́ àwọn ẹlòmíràn tàbí bíbá ọmọ ilé ìwé ẹni pàdé lóde ẹ̀rí, máa ń bani lẹ́rù nígbà míì.

Ìdí tó fi yẹ kó o wàásù. Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ . . . sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn, . . . ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Àmọ́, ọ̀pọ̀ ìdí tún wà tó fi yẹ kó o máa wàásù. Ìwádìí fi hàn pé láwọn ibì kan, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló gba Ọlọ́run àti Bíbélì gbọ́, síbẹ̀, tí wọn ò gbà pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. Látinú ẹ̀kọ́ tó o ti kọ́ nínú Bíbélì, o ti mọ àwọn nǹkan tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ojúgbà ẹ ń wá kiri, tó sì jẹ́ kòṣeémánìí fún wọn. Tó o bá ń sọ ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn èèyàn, inú ìwọ fúnra rẹ máa dùn, èyí tó tiẹ̀ tún wá ṣe pàtàkì jù ni pé, wàá mú ọkàn Jèhófà yọ̀.​—Òwe 27:11.

Ohun táwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ sọ. “Èmi àti ọ̀rẹ́ mi múra bá a ṣe máa gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ lọ́nà tó múná dóko, a sì kọ́ bá a ṣe lè borí àtakò àti bá a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò. Látìgbà tí mo ti túbọ̀ ń sapá láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi dáa sí i ni mo ti túbọ̀ ń gbádùn rẹ̀.”​—Nelisa.

“Ìrànlọ́wọ́ tí arábìnrin kan ṣe fún mi kúrò ní kékeré! Ọdún mẹ́fà ló fi jù mí lọ, ó máa ń mú mi lọ sóde ẹ̀rí, ó sì máa ń fún mi lóúnjẹ àárọ̀ nígbà míì. Ó fi àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ń gbéni ró hàn mí. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà sì jẹ́ kí n fúnra mi tún inú rò. Àpẹẹrẹ rere tó fi lélẹ̀ fún mi ti wá mú kó ṣeé ṣe fún èmi náà láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́. Mo mọrírì oore ńlá tó ṣe fún mi yẹn!”​Shontay.

Ohun tó o lè ṣe. Gbàyè lọ́wọ́ àwọn òbí rẹ, kó o wá wá ẹnì kan tó jù ẹ́ lọ nínú ìjọ yín tẹ́ ẹ lè jọ máa lọ sóde ẹ̀rí. (Ìṣe 16:1-3) Bíbélì sọ pé: “Irin ni a fi ń pọ́n irin. Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn kan ṣe máa ń pọ́n ojú òmíràn.” (Òwe 27:17) Ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kéèyàn máa báwọn àgbàlagbà tó nírìírí rìn. Alexis, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] sọ pé: “Ó máa ń dáa gan-an o láti máa bá àwọn àgbàlagbà rìn.”

Ó ti yá wàyí! Nínú àlàfo tó wà nísàlẹ̀, kọ orúkọ ẹnì kan nínú ìjọ yín, yàtọ̀ sáwọn òbí rẹ, tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ lóde ẹ̀rí.

․․․․․

ÌṢÒRO KẸTA Lílọ sí Ìpàdé Ìjọ

Ìdí tí kò fi rọrùn. Lẹ́yìn tó o ti jókòó látàárọ̀ nínú kíláàsì, ó lè wá ni ẹ́ lára gan-an láti tún jókòó fún nǹkan bíi wákàtí méjì láti máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì.

Ìdí tó fi yẹ kó o máa lọ sípàdé. Bíbélì gba àwọn Kristẹni níyànjú pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.”​—Hébérù 10:24, 25.

Ohun táwọn ọ̀dọ́ bíi tìẹ sọ. “Ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn máa múra ìpàdé ìjọ sílẹ̀. Ìgbà míì tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé ṣe ni wàá ní láti sọ ọ́ di dandan fún ara rẹ. Bó o bá sì múra ìpàdé sílẹ̀, wàá gbádùn ìpàdé náà torí pé ohun tí wọ́n ń jíròrò máa yé ẹ, wàá sì lè dáhùn nípàdé.”​Elda.

“Nígbà tó yá, mo wá rí i pé àwọn ìpàdé tí mo bá tí dáhùn ní mo máa ń gbádùn jù.”​Jessica.

Ohun tó o lè ṣe. Wá àyè láti máa múra ìpàdé sílẹ̀, kó o sì máa dáhùn bí wọ́n bá béèrè ìbéèrè. Èyí ò ní jẹ́ kó dà bíi pé ńṣe lo kàn lọ mú ìjókòó gbóná lásán.

Wo àpèjúwe yìí ná: Èwo ló máa ń gbádùn mọ́ni jù nínú kéèyàn kàn jókòó, kó máa wo eré ìdárayá kan lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí kí òun fúnra rẹ̀ máa bá wọn ṣe eré náà lórí pápá? Dájúdájú, ó máa ń dùn mọ́ni kéèyàn máa ṣeré ìdárayá lórí pápá ju kéèyàn kàn jẹ́ òǹwòran lásán lọ. O ò ṣe fi ojú kan náà wo lílọ sáwọn ìpàdé ìjọ?

Ó ti yá wàyí! Kọ ìgbà tí wàá lè máa lo ọgbọ̀n ìṣẹ́jú péré lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fi múra ìpàdé ìjọ sínú àlàfo tó wà nísàlẹ̀ yìí.

․․․․․

Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ti wá ń rí i báyìí pé òtítọ́ lọ̀rọ̀ inú Sáàmù 34:8, èyí tó sọ pé: “Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.” Ǹjẹ́ ọ̀nà ọ̀fun tìẹ kì í dá tòlótòló tó o bá gbọ́ nípa oúnjẹ aládùn kan? Ṣé kò ní dáa kó o fẹnu ara rẹ tọ́ oúnjẹ náà wò? Bí ọ̀rọ̀ ìjọsìn Ọlọ́run náà ṣe rí nìyẹn. Tọ́ ọ wò fúnra rẹ, kó o sì rí bí lílọ sípàdé, kíkẹ́kọ̀ọ́, àti wíwàásù ti ṣàǹfààní tó. Bíbélì sọ pé ẹni tó jẹ́ olùṣe ọ̀rọ̀ náà, tí kì í wulẹ̀ ṣe olùgbọ́ nìkan “yóò láyọ̀ nínú ṣíṣe é.”​—Jákọ́bù 1:25.

NÍNÚ ORÍ TÓ KÀN

Kọ́ nípa bó o ṣe lè ní àwọn nǹkan tó ò ń lé àti bí ọwọ́ rẹ ṣe lè tẹ̀ wọ́n

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 19 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”​—Róòmù 12:2.

ÌMỌ̀RÀN

Wá ìwé kan, kó o bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn ohun pàtàkì tó o bá gbọ́ nípàdé sínú rẹ̀. Wàá rí i pé kó o tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, ìpàdé á ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí, á sì máa rọ̀ ẹ́ lọ́rùn láti kẹ́kọ̀ọ́!

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Kò sóhun tó burú nínú kó o fẹ́ láti mọ ohun tó o gbà gbọ́ àti ìdí tó o fi gbà á gbọ́. Kódà, ọ̀nà kan tó dáa jù tí wàá fi mọ̀ bóyá ohun tó o gbà gbọ́ nípa Ọlọ́run jẹ́ òótọ́ ni pé kó o máa béèrè ìbéèrè, kó o sì máa ṣèwádìí.​—Ìṣe 17:11.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE!

Màá máa ya ìṣẹ́jú ․․․․․ sọ́tọ̀ lójoojúmọ́ láti fi ka Bíbélì, màá sì máa lo ․․․․․ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fi múra àwọn ìpàdé sílẹ̀.

Kí n lè pọkàn pọ̀ dáadáa nígbà tí mo bá wà nípàdé, màá ․․․․․

Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí ló lè mú kó sú ọ̀dọ́ kan láti máa lọ sípàdé, láti máa kẹ́kọ̀ọ́, àti láti máa wàásù?

● Èwo ni wàá fẹ́ láti ṣiṣẹ́ lé lórí nínú apá mẹ́ta tí ìjọsìn wa pín sí tá a sọ̀rọ̀ lé lórí nínú orí yìí?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 278]

“Kì í ṣe torí pé àwọn òbí mi ń ṣe ẹ̀sìn kan ni mo ṣe ń ṣe é, ṣe ni mo gbà pé ẹ̀sìn tèmi fúnra mi ni. Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run mi, mi ò sì fẹ́ ṣe ohunkóhun tó máa ba àjọṣe tó wà láàárín èmi àti òun jẹ́.”​—Samantha

[Àpótí/​Àwọn Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 280, 281]

Wọ́n Ní Àwọn Ohun Kan Tí Wọ́n Ń Lé

Bíbélì sọ pé: “Ẹ kò mọ ohun tí ìwàláàyè yín yóò jẹ́ lọ́la.” (Jákọ́bù 4:14) Nígbà míì, àwọn ẹlòmíì lè kú láìrò tẹ́lẹ̀, wọ́n sì lè máà tíì dàgbà púpọ̀. Wo àpẹẹrẹ ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Catrina àti ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Kyle. Bó o ṣe ń ka ìrírí wọn, kíyè sí bí wọ́n ṣe ní orúkọ rere lọ́dọ̀ọ́ Jèhófà Ọlọ́run nípa bí wọ́n ṣe lépa àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run àti bí ọwọ́ wọn ṣe tẹ̀ ẹ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò dàgbà púpọ̀ kí wọ́n tó kú.​—Oníwàásù 7:1.

Catrina kú nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún [18], àmọ́ ìgbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá [13] ló ti kọ àwọn ohun tó fẹ́ kọ́wọ́ òun tẹ̀ sílẹ̀. Lára àwọn ohun náà ni bó ṣe máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún, bó ṣe máa sìn lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i, àti bó ṣe máa ran bàbá rẹ̀ lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó kọ̀wé pé: “Mo ti ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run!” Ohun tí Catrina ń fẹ́ ni pé kóun “máa tẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run kóun lè máa ṣe ohun tó dùn mọ́ ọn nínú.” Níbi ìsìnkú rẹ̀, wọ́n ní Catrina jẹ́ “ọmọbìnrin dáadáa tó pinnu láti fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ sin Jèhófà.”

Láti kékeré ni wọ́n ti kọ́ Kyle pé kó ní àwọn ohun kan táá máa lé. Lẹ́yìn tó kú nínú jàǹbá ọkọ̀ kan ní ọmọ ogún [20] ọdún, àwọn ẹbí rẹ̀ rí ìwé kan tí màmá rẹ̀ bá a kọ àwọn ohun kan tó ń fẹ́ kí ọwọ́ òun tẹ̀ nígbèésí ayé sí, ìyẹn sì jẹ́ nígbà to wà lọ́mọ ọdún mẹ́rin péré. Ara àwọn ohun náà ní pé kó ṣèrìbọmi, kó máa sọ àsọyé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, kó sì lọ sìn ní orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kó lè máa ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń tẹ àwọn ìwé táwọn èèyàn fi ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí màmá rẹ̀ yẹ ìwé tó bá Kyle kọ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn wò, ó sọ pé: “Gbogbo ohun tá a kọ síbí pátá lọwọ́ rẹ̀ tẹ̀.”

Àwọn nǹkan wo ni ìwọ ń lé? O ò kúkú mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà lọ́la. Nítorí náà, má ṣe fi ọjọ́ kankan ṣòfò rárá. Máa lo àkókò rẹ láti fi ṣe ohun tó ṣeni láǹfààní jù bíi ti Catrina àti Kyle. Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó sọ nígbà tó kù díẹ̀ tó máa kú pé: “Mo ti ja ìjà àtàtà náà, mo ti sáré ní ipa ọ̀nà eré ìje náà dé ìparí, mo ti pa ìgbàgbọ́ mọ́.” (2 Tímótì 4:7) Orí tó tẹ̀ lé èyí máa jẹ́ kó o mọ bí ìwọ náà ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 274, 275]

Bó o bá fẹ́ kí ara rẹ jí pépé, o gbọ́dọ̀ máa ṣeré ìmárale. Bó o bá fẹ́ kí ara rẹ jí pépé nípa tẹ̀mí, o gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run