Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Ọwọ́ Mi Ṣe Lè Tẹ Àwọn Ohun Tí Mo Fẹ́ Lé Bá?

Báwo Ni Ọwọ́ Mi Ṣe Lè Tẹ Àwọn Ohun Tí Mo Fẹ́ Lé Bá?

ORÍ 39

Báwo Ni Ọwọ́ Mi Ṣe Lè Tẹ Àwọn Ohun Tí Mo Fẹ́ Lé Bá?

Èwo nínú àwọn nǹkan yìí ló wù ẹ́?

□ Mo fẹ́ túbọ̀ dá ara mi lójú

□ Mo fẹ́ ní àwọn ọ̀rẹ́ púpọ̀ sí i

□ Mo fẹ́ túbọ̀ láyọ̀

KÁ SÒÓTỌ́, ọwọ́ rẹ lè tẹ àwọn nǹkan mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí. Báwo lo ṣe lè tẹ̀ ẹ́? Ṣe ni kó o ní àwọn ohun kan tó o fẹ́ lé bá, kó o sì sapá kí ọwọ́ rẹ lè tẹ̀ ẹ́. Wo àwọn ohun tá a sọ yìí:

O lè túbọ̀ dá ara rẹ lójú. Tó o bá lépa àwọn nǹkan kéékèèké tí ọwọ́ rẹ sì tẹ̀ wọ́n, ìyẹn á jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ọwọ́ rẹ máa tẹ ohun tó ju ìyẹn lọ. Á túbọ̀ dá ẹ lójú pé o lè mọ ohun tí wàá ṣe sí àwọn ìṣòro tó máa ń jẹ yọ lójoojúmọ́, irú bí ìgbà tí àwọn ojúgbà rẹ bá fẹ́ kó o ṣe ohun tí kò dáa.

O lè ní àwọn ọ̀rẹ́ púpọ̀ sí i. Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ láti wà pẹ̀lú àwọn tó máa ń ní ohun kan tí wọ́n fẹ́ lé bá, ìyẹn àwọn tó mọ ohun tí wọ́n ń fẹ́, tí wọ́n á sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe kí ọwọ́ wọn lè tẹ̀ ẹ́.

O lè túbọ̀ láyọ̀. Ká sòótọ́, ayé máa ń súni téèyàn bá kàn jókòó dẹngbẹrẹ tó ń retí pé ayé òun máa dáa lọ́jọ́ kan. Àmọ́, tó o bá ní ohun tó ò ń lé, tí ọwọ́ rẹ sì tẹ̀ ẹ́, inú rẹ máa dùn pé ò ń ṣàṣeyọrí. Ṣé o ti ṣe tán láti ní àwọn ohun kan tí wàá máa lé? Àwọn ojú ìwé tó tẹ̀ lé e yìí máa ṣèrànwọ́ gan-an! *

✔ ÀKỌ́KỌ́ MỌ OHUN TÓ O FẸ́ LÉ BÁ

1. Ronú nípa àwọn ohun tí ọwọ́ rẹ lè tẹ̀. Ṣe ni kó o kàn máa kọ oríṣiríṣi nǹkan tó bá ti wá sí ẹ lọ́kàn sílẹ̀. Má wulẹ̀ tíì ronú lórí bó o ṣe fẹ́ ṣe wọ́n, ṣáà ti kọ ohunkóhun tó o bá ti ronú kàn. Gbìyànjú láti kọ nǹkan mẹ́wàá, ó kéré tán.

2. Fara balẹ̀ wo àwọn ohun tó o kọ sílẹ̀. Èwo ló ṣeé ṣe kó o gbádùn jù? Èwo ló ṣeé ṣe kó fún ẹ níṣòro jù? Èwo ló máa mú inú rẹ dùn jù bí ọwọ́ rẹ bá tẹ̀ ẹ́? Rántí pé, àwọn ohun tó bá jẹ ìwọ fúnra rẹ lógún jù nínú àwọn ohun tó o fẹ́ lé bá ló ṣe pàtàkì jù.

3. Tò wọ́n bí wọ́n ti ṣe pàtàkì sí. To àwọn ohun tó o fẹ́ lé bá yẹn tẹ̀ lé ara wọn, kó o bẹ̀rẹ̀ látorí èyí tó o fẹ́ kí ọwọ́ rẹ kọ́kọ́ tẹ̀.

✔ ÌKEJÌ MÚRA SÍLẸ̀

Ṣe àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun tó o fẹ́ lé bá:

Kọ àwọn ohun tó o fẹ́ lé bá sílẹ̀.

Mo fẹ́ kọ́ Èdè Àwọn Adití kí n lè máa wàásù fún àwọn adití

Dá ìgbà tó o fẹ́ kí ọwọ́ rẹ tẹ̀ wọ́n. Béèyàn bá ní ohun tó fẹ́ lé bá, àmọ́ tí kò dá ìgbà tó fẹ́ kí ọwọ́ òun tẹ̀ ẹ́, bí àlá lásán ló máa rí!

Ó pẹ́ tán ní July 1

Ṣètò ohun tó o fẹ́ ṣe.

Ohun tí màá ṣe

1. Màá ra ìwé tó ń kọ́ni lédè náà.

2. Màá máa kọ́ ọ̀rọ̀ mẹ́wàá lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

3. Nígbà táwọn èèyàn bá ń fi Èdè Àwọn Adití bára wọn sọ̀rọ̀, màá máa wò wọ́n.

4. Màá ní kí ẹnì kan tó bá mọ èdè náà dáadáa máa sọ ibi tí mo bá ti ṣe àṣìṣe.

Fi sọ́kàn pé ìṣòro lè yọjú. Kó o sì ronú nípa bó o ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro náà.

Àwọn ìṣòro tó lè yọjú

Kò sí ẹni tó mọ Èdè Àwọn Adití ní àdúgbò mi

Pinnu pé o ò ní jẹ́ kó sú ẹ. Pinnu pé wàá ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe kí ọwọ́ rẹ lè tẹ̀ ẹ́. Buwọ́ lu ohun tó o kọ sílẹ̀, kó o sì kọ ọjọ́ tó o buwọ́ lù ú.

Bí mo ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro náà

Màá wa fídíò tí wọ́n ṣe ní Èdè Àwọn Adití jáde látorí Ìkànnì www.pr418.com.

․․․․․ ․․․․․

Ìbuwọ́lùwé Déètì

✔ ÌKẸTA DÁWỌ́ LÉ E!

Tètè bẹ̀rẹ̀. Bi ara rẹ pé, ‘Kí ni mo lè ṣe lónìí láti fi hàn pé mo ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí àwọn ohun tí mo fẹ́ lé bá?’ Òótọ́ ibẹ̀ ni pé o lè máà tíì mọ gbogbo ọ̀nà tó o máa gbé e gbà o, àmọ́ ṣáà rí i pé o dáwọ́ lé e. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣọ́ ẹ̀fúùfù kì yóò fún irúgbìn; ẹni tí ó bá sì ń wo àwọsánmà kì yóò kárúgbìn.” (Oníwàásù 11:4) Ronú nípa nǹkan tó o lè ṣe lónìí kó o sì ṣe é, ì báà tiẹ̀ jẹ́ nǹkan kékeré.

Máa ṣàyẹ̀wò rẹ̀ lójoojúmọ́. Máa rán ara rẹ létí ìdí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ohun náà fi ṣe pàtàkì. Máa fi àmì ✔ (tàbí kó o kọ déètì tí ọwọ́ rẹ tẹ̀ ẹ́) síwájú èyí tí ọwọ́ rẹ bá ti tẹ̀ nínú rẹ̀, èyí ló máa jẹ́ kó o mọ ibi tó o dé.

Fọkàn yàwòrán. Fojú inú wò ó pé ọwọ́ rẹ ti tẹ ohun tó ò ń lé. Wò ó bíi pé o ti ṣàṣeyọrí. Lẹ́yìn náà, ronú pa dà sẹ́yìn lórí àwọn ohun tó yẹ kó o ṣe kí ọwọ́ rẹ lè tẹ ohun tó ò ń lé yẹn, kó o sì fọkàn yàwòrán wọn lọ́kọ̀ọ̀kan. Wàyí o, wò ó bíi pé o ti ń ṣe àwọn ohun tó yẹ kó o ṣe, bíi pé o ti ń ṣàṣeyọrí bí o ṣe ń gbé ìgbésẹ̀ kọ̀ọ̀kan, kó o wá ronú nípa bí inú rẹ ṣe máa dùn tó nígbà tí ọwọ́ rẹ bá ti tẹ gbogbo rẹ̀. Ó yá, bẹ̀rẹ̀ báyìí!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ ìpínrọ̀ 10 Àwọn àbá tó wà níbẹ̀ máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ọwọ́ rẹ lè tẹ àwọn ohun tó ṣeé lé bá láàárín àkókò kúkúrú, àmọ́ ìlànà tó wà níbẹ̀ wúlò fún àwọn nǹkan míì tó máa gba ọ̀pọ̀ àkókó pẹ̀lú.

ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́

“Dájúdájú, àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.”​—Òwe 21:5.

ÌMỌ̀RÀN

Má ṣe rin kinkin mọ́ ọ̀nà tó o ti rò pé o fẹ́ gbà ṣe ohun tó o ní lọ́kàn. Mọ àwọn nǹkan míì tó o lè ṣe bí ọ̀rọ̀ ò bá lọ bó o ṣe rò, kó o sì máa ṣe àwọn àyípadà kọ̀ọ̀kan bó o ṣe ń tẹ̀ síwájú débi tí ọwọ́ rẹ á fi tẹ ohun tó o fẹ́ lé bá.

ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?

Bí ohun tó o fẹ́ lé bá bá ti ṣe pàtàkì tó, bẹ́ẹ̀ ni inú rẹ ṣe máa dùn tó nígbà tọ́wọ́ rẹ bá tẹ̀ ẹ́!

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí àwọn ohun téèyàn ń lé lẹ́ẹ̀kan náà pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ?​—Fílípì 1:10.

● Ṣé ohun tó túmọ̀ sí láti ní àwọn ohun tó o fẹ́ lé bá ni pé kó o ti pinnu gbogbo ohun tó o bá máa ṣe ní ìgbésí ayé rẹ?​—Fílípì 4:5.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 283]

“Ìrẹ̀wẹ̀sì lè bá ẹ bí o kò bá ní ohun kan tó ò ń lé tàbí tó ò ń retí. Àmọ́ tó o bá ní àwọn ohun tó o fẹ́ lé bá, tí ọwọ́ rẹ sì ń tẹ̀ wọ́n, ìyẹn á jẹ́ kó o máa láyọ̀.”​—Reed

[Àpótí/​Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 283]

Àpẹẹrẹ Àwọn Ohun Tó O Lè Fẹ́ Lé Bá

Ọ̀rẹ́ Mo fẹ́ ní ọ̀rẹ́ kan tí kì í ṣe ojúgbà mi. Mo túbọ̀ fẹ́ sún mọ́ ọ̀rẹ́ mi àtijọ́ kan.

Ìlera Mo fẹ́ máa fi wákàtí kan ààbọ̀, ó kéré tán, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ṣe eré ìmárale. Mo fẹ́ máa rí i pé mò ń sun oorun wákàtí mẹ́jọ mọ́jú.

Ilé ìwé Mo fẹ́ túbọ̀ ṣe dáadáa sí i nínú ìmọ̀ ìṣirò. Mi ò fẹ́ ṣe ohun tí kò dára àní bí àwọn ọmọ kíláàsì mi bá tiẹ̀ fẹ́ kí n ṣe é.

Ìjọsìn Mo fẹ́ máa ka Bíbélì fún ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lójúmọ́. Mo fẹ́ wàásù fún ọmọ kíláàsì mi kan lọ́sẹ̀ yìí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 284, 285]

Àwọn ohun tó o fẹ́ lé bá dà bí àwòrán ilé tó o fẹ́ kọ́, o gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára kí ọwọ́ rẹ tó lè tẹ̀ ẹ́