Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 7

Kí Là Ń Kọ́ Láwọn Ìpàdé Wa?

Kí Là Ń Kọ́ Láwọn Ìpàdé Wa?

Orílẹ̀-èdè New Zealand

Orílẹ̀-èdè Japan

Orílẹ̀-èdè Uganda

Orílẹ̀-èdè Lithuania

Nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni bẹ̀rẹ̀, ohun tí wọ́n máa ń ṣe ní àwọn ìpàdé ìjọ ni pé wọ́n máa ń kọrin, wọ́n máa ń gbàdúrà, wọ́n ń ka Ìwé Mímọ́, wọ́n sì ń jíròrò wọn, wọn ò ní àwọn àṣà ìkọ̀kọ̀ tí wọ́n ń tẹ̀ lé nínú ìsìn wọn. (1 Kọ́ríńtì 14:26) Ohun kan náà là ń ṣe láwọn ìpàdé wa.

Ẹ̀kọ́ tó wúlò látinú Bíbélì. Láwọn òpin ọ̀sẹ̀, ìjọ kọ̀ọ̀kan máa ń pé jọ láti gbọ́ Àsọyé Bíbélì fún ọgbọ̀n (30) ìṣẹ́jú, ó máa ń dá lórí bí Ìwé Mímọ́ ṣe lè mú kí ìgbésí ayé wa dára, ó sì máa ń jẹ́ ká mọ ìtumọ̀ àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lásìkò yìí. Wọ́n máa ń rọ gbogbo wa pé ká gbé Bíbélì wa ká sì máa fojú bá ibi tí wọ́n ń kà lọ. Lẹ́yìn àsọyé náà, a máa ń ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ “Ilé Ìṣọ́” fún wákàtí kan, a sì máa ń rọ gbogbo ará ìjọ pé kí wọ́n dá sí àpilẹ̀kọ tá à ń jíròrò lọ́sẹ̀ yẹn nínú Ilé Ìṣọ́ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Ìjíròrò yìí máa ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nínú ìgbé ayé wa. Àpilẹ̀kọ kan náà la máa ń kẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ìjọ wa tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́fà (110,000) lọ kárí ayé.

Wọ́n ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa kọ́ni lọ́nà tó sunwọ̀n sí i. A tún máa ń pé jọ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀ fún ìpàdé alápá mẹ́ta tí à ń pè ní Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni. Ohun tó wà nínú ìwé ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni la máa ń tẹ̀ lé. Apá àkọ́kọ́ lára ìpàdé náà ni Àwọn Ìṣúra Inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó máa ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye apá kan nínú Bíbélì táwọn ará ti kà ṣáájú. Lẹ́yìn ìyẹn ni Máa Lo Ara Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù níbi tí a ti máa ń rí àpẹẹrẹ bá a ṣe lè bá àwọn èèyàn jíròrò látinú Bíbélì. Agbani-nímọ̀ràn kan wà tó máa ń kíyè sí ọ̀rọ̀ wa kó lè ràn wá lọ́wọ́ láti sunwọ̀n sí i nínú bá a ṣe ń kàwé àti bá a ṣe ń sọ̀rọ̀. (1 Tímótì 4:13) Apá tó gbẹ̀yìn nínú ìpàdé náà ni Máa Hùwà Tó Yẹ Kristẹni níbi tí a ti máa ń jíròrò bá a ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́. Ó tún máa ń ní ìbéèrè àti ìdáhùn tó máa ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye Bíbélì.

Tó o bá wá sí àwọn ìpàdé wa, ó dájú pé àwọn ẹ̀kọ́ àtàtà tó o máa kọ́ látinú Bíbélì máa wú ẹ lórí gan-an.​—Àìsáyà 54:13.

  • Kí lo máa kọ́ láwọn ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

  • Èwo nínú àwọn ìpàdé wa ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ló wù ẹ́ láti lọ?