Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 10

Kí Ni Ìjọsìn Ìdílé?

Kí Ni Ìjọsìn Ìdílé?

Orílẹ̀-èdè South Korea

Orílẹ̀-èdè Brazil

Orílẹ̀-èdè Ọsirélíà

Orílẹ̀-èdè Guinea

Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà ti fẹ́ kí ìdílé kọ̀ọ̀kan ní àkókò tí wọ́n á jọ wà pa pọ̀, kí wọ́n lè túbọ̀ sún mọ́ òun kí wọ́n sì wà níṣọ̀kan. (Diutarónómì 6:6, 7) Ìdí nìyẹn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi máa ń ní àkókò kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tí ìdílé á fi jọ́sìn pa pọ̀, tí wọ́n á jókòó pẹ̀sẹ̀, tí wọ́n á sì jọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó máa mú kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Kódà tó bá jẹ́ pé ṣe lò ń dá gbé, ó máa dáa gan-an kó o lo irú àkókò bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, kó o fi kẹ́kọ̀ọ́ kókó kan tó wù ẹ́ nínú Bíbélì.

Ó jẹ́ àkókò láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.” (Jémíìsì 4:8) A máa túbọ̀ mọ Jèhófà nígbà tí a bá mọ púpọ̀ sí i nípa irú ẹni tó jẹ́ àti ìwà rẹ̀ bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọ̀nà kan tó rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn ìdílé rẹ ni pé kí ẹ ka Bíbélì sókè. Ẹ lè máa tẹ̀ lé ètò Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ẹ lè yan apá kan nínú Bíbélì náà fún ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé láti kà, kí gbogbo yín sì jíròrò ohun tí ẹ kọ́ níbẹ̀.

Ó jẹ́ àkókò tí ìdílé túbọ̀ máa ń wà níṣọ̀kan. Àwọn tọkọtaya, àwọn òbí àtàwọn ọmọ túbọ̀ máa ń wà níṣọ̀kan tí wọ́n bá jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ nínú ìdílé. Ó yẹ kó jẹ́ àkókò ayọ̀ àti àlàáfíà, kó sì tún jẹ́ ohun tí wọ́n á máa wọ̀nà fún lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àwọn òbí lè yan ohun tí wọ́n á jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ bí ọjọ́ orí àwọn ọmọ wọn bá ṣe mọ, wọ́n lè yan àkòrí kan nínú Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! tàbí látorí ìkànnì jw.org/yo. Ẹ lè sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro kan tí àwọn ọmọ yín ní nílé ìwé àti bí wọ́n ṣe lè borí rẹ̀. Ẹ lè wò lára àwọn ètò wa lórí Tẹlifíṣọ̀n JW (tv.pr418.com) kẹ́ ẹ sì jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ẹ tún lè fi àwọn orin tí a máa kọ ní ìpàdé dánra wò, kẹ́ ẹ sì gbádùn rẹ̀. Ẹ sì lè jẹ ìpápánu lẹ́yìn ìjọsìn ìdílé yín.

Àkókò pàtàkì tí ẹ̀ ń lò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ yìí máa ran gbogbo yín lọ́wọ́ kí ẹ lè jadùn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Ọlọ́run á sì mú kí ìsapá yín yọrí sí rere.​—Sáàmù 1:1-3.

  • Kí nìdí tá a fi ní àkókò tá a máa ń ṣe ìjọsìn ìdílé?

  • Báwo ni àwọn òbí ṣe lè jẹ́ kí gbogbo ìdílé gbádùn ìjọsìn ìdílé?