Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 19

Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye?

Ta Ni Ẹrú Olóòótọ́ àti Olóye?

Gbogbo wa là ń jàǹfààní látinú oúnjẹ tẹ̀mí

Nígbà tí ikú Jésù ti sún mọ́lé gan-an, ó bá mẹ́rin lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ní ìdákọ́ńkọ́, ìyẹn Pétérù, Jémíìsì, Jòhánù àti Áńdérù. Bó ṣe ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àmì tó máa fi hàn pé òun ti wà níhìn-ín ní ọjọ́ ìkẹyìn, ó béèrè ìbéèrè pàtàkì kan pé: “Ní tòótọ́, ta ni ẹrú olóòótọ́ àti olóye tí ọ̀gá rẹ̀ yàn pé kó máa bójú tó àwọn ará ilé rẹ̀, kó máa fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tó yẹ?” (Mátíù 24:​3, 45; Máàkù 13:​3, 4) Jésù fi dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lójú pé òun tí òun jẹ́ “ọ̀gá” wọn, máa yan àwọn táá máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí déédéé fún àwọn ọmọlẹ́yìn òun ní àkókò òpin. Àwọn wo ló máa para pọ̀ jẹ́ ẹrú náà?

Ó jẹ́ àwùjọ kékeré lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yàn. “Ẹrú” náà ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó máa ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sákòókò fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ olùjọsìn Jèhófà. A gbára lé ẹrú olóòótọ́ yìí láti máa fún wa ní “ìwọ̀n oúnjẹ” wa “ní àkókò tó yẹ.”​—Lúùkù 12:42.

Ó ń bójú tó agbo ilé Ọlọ́run. (1 Tímótì 3:15) Jésù gbé iṣẹ́ ńlá fún ẹrú náà láti máa bójú tó iṣẹ́ tó jẹ́ ti apá orí ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà, ìyẹn bíbójútó àwọn ohun ìní rẹ̀, dídarí iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ wa nípasẹ̀ ìjọ. Nítorí náà, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè ohun tá a nílò fún wa ní àkókò tó yẹ, wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí wọ́n ṣe ń fún wa ní oúnjẹ tẹ̀mí nípasẹ̀ àwọn ìwé tí à ń lò nínú iṣẹ́ ìwàásù àti nípasẹ̀ àwọn ohun tí à ń kọ́ ní àwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa.

Ẹrú náà jẹ́ olóòótọ́ sí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni àti iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere tí Bíbélì pa láṣẹ, ó sì jẹ́ olóye torí pé ó ń fi ọgbọ́n bójú tó àwọn ohun ìní Kristi láyé. (Ìṣe 10:42) Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ ẹrú náà, ó ń jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ pọ̀ sí i, ó sì ń mú kí wọ́n ní oúnjẹ tẹ̀mí tó pọ̀ gan-an.​—Àìsáyà 60:22; 65:13.

  • Ta ni Jésù yàn pé kó máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?

  • Kí ni ẹrú náà ń ṣe tó fi hàn pé ó jẹ́ olóòótọ́ àti olóye?