Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 26

Kí La Lè Ṣe Láti Máa Tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba Wa?

Kí La Lè Ṣe Láti Máa Tọ́jú Gbọ̀ngàn Ìjọba Wa?

Orílẹ̀-èdè Estonia

Orílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè

Orílẹ̀-èdè Mòǹgólíà

Orílẹ̀-èdè Puerto Rico

Orúkọ mímọ́ Ọlọ́run la fi ń pe gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nítorí náà, a gbà pé àǹfààní ló jẹ́ láti máa mú kí ilé yìí wà ní mímọ́ tónítóní, kó dùn-ún wò, ká sì máa tún un ṣe. Èyí jẹ́ apá pàtàkì lára ìjọsìn mímọ́ wa. Gbogbo wa la lè kópa nínú iṣẹ́ yìí.

Yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣe ìmọ́tótó lẹ́yìn ìpàdé. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin máa ń fayọ̀ ṣe iṣẹ́ ìmọ́tótó pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lẹ́yìn ìpàdé, kí Gbọ̀ngàn Ìjọba lè wà ní mímọ́ tónítóní. Wọ́n sì tún máa ń ṣe ìmọ́tótó tó pọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan ló máa ń ṣe kòkáárí iṣẹ́ náà, ó sábà máa ń wo àkọsílẹ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Ẹnì kọ̀ọ̀kan máa ń yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó bá wà, irú bíi gbígbálẹ̀, fífi omi tàbí ẹ̀rọ fọ ilẹ̀ tàbí nínu eruku, títo àga, fífọ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ àti bíbu oògùn apakòkòrò sí i, fífọ fèrèsé àti dígí, kíkó pàǹtírí dà nù tàbí ṣíṣe ìmọ́tótó ara ilé àti ríro àyíká. Ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, a máa ń ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ṣíṣe gbogbo iṣẹ́ ìmọ́tótó Gbọ̀ngàn Ìjọba tinú tòde. A máa ń jẹ́ kí àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ sí iṣẹ́ náà, kí wọ́n lè máa kẹ́kọ̀ọ́ láti bọ̀wọ̀ fún ibi ìjọsìn wa.​—Oníwàásù 5:1.

Yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣe àtúnṣe tó bá yẹ. Lọ́dọọdún, a máa ń yẹ tinú tòde Gbọ̀ngàn Ìjọba wò fínnífínní. Àyẹ̀wò yìí máa ń mú ká tún àwọn nǹkan ṣe látìgbàdégbà kí gbọ̀ngàn náà lè wà bó ṣe yẹ, èyí sì ń jẹ́ ká lè máa ṣọ́ owó ná. (2 Kíróníkà 24:13; 34:10) Gbọ̀ngàn Ìjọba tó mọ́ tónítóní tá a sì tún ṣe dáadáa ni ibi tó yẹ ká ti máa jọ́sìn Ọlọ́run wa. Tá a bá ń kópa nínú iṣẹ́ yìí, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a sì mọyì ibi ìjọsìn wa. (Sáàmù 122:1) Èyí tún máa ń jẹ́ káwọn èèyàn fojú tó dára wò wá ládùúgbò.​—2 Kọ́ríńtì 6:3.

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tọ́jú ibi ìjọsìn wa?

  • Àwọn ètò wo la ṣe láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ tónítóní?