Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 15

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nìṣó Nípa Jèhófà?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nìṣó Nípa Jèhófà?

1. Àǹfààní wo ni wàá rí tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìṣó?

Ó dájú pé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì mélòó kan tá a jíròrò nínú ìwé yìí ti mú kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ó yẹ kó o jẹ́ kí iná ìfẹ́ yìí máa jó. (1 Pétérù 2:2) Tó o bá fẹ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun, ó ṣe pàtàkì pé kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.​—Ka Jòhánù 17:3; Júùdù 21.

Bí ìmọ̀ tó o ní nípa Ọlọ́run bá ṣe ń pọ̀ sí i, ìgbàgbọ́ rẹ á túbọ̀ máa lágbára. Ìgbàgbọ́ tó o ní yìí á jẹ́ kó o lè ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Hébérù 11:1, 6) Á mú kó o ronú pìwà dà, kó o sì ṣe àwọn ìyípadà tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní.​—Ka Ìṣe 3:19.

2. Báwo ni ohun tó o mọ̀ nípa Ọlọ́run ṣe lè ṣe àwọn ẹlòmíì láǹfààní?

O lè ní àjọṣe tó dáa gan-an pẹ̀lú Jèhófà

Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì, á máa wù ẹ́ pé kó o sọ àwọn ohun tí ò ń kọ́ fún àwọn ẹlòmíì. Inú àwa èèyàn máa ń dùn láti sọ ìròyìn ayọ̀ fún àwọn ẹlòmíì. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó nínú Bíbélì, wàá mọ bó o ṣe lè fi Bíbélì ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́ nípa Jèhófà àti ìròyìn ayọ̀ náà.​—Ka Róòmù 10:13-15.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé tẹbí tọ̀rẹ́ ni wọ́n kọ́kọ́ máa ń sọ ìròyìn ayọ̀ náà fún. Àmọ́ ó gba ọgbọ́n. Dípò tí wàá fi sọ fún wọn pé ẹ̀sìn èké ni wọ́n ń ṣe, ńṣe ni kó o sọ àwọn ìlérí Ọlọ́run fún wọn. Bákan náà, má gbàgbé pé ìwà rere rẹ máa wú àwọn èèyàn lórí ju ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ lọ.​—Ka 2 Tímótì 2:24, 25.

3. Irú àjọṣe wo lo máa ní pẹ̀lú Ọlọ́run?

Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wàá túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Ó lè mú kó o ní àjọṣe tó dáa gan-an pẹ̀lú Jèhófà. Wàá sì di ọ̀kan lára àwọn tó wà nínú agbo ilé Ọlọ́run.​—Ka 2 Kọ́ríńtì 6:18.

4. Báwo lo ṣe lè máa tẹ̀ síwájú?

O lè tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìṣó. (Hébérù 5:13, 14) Sọ fún ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n wá máa fi ìwé Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ìgbésí ayé rẹ á máa dáa sí i.​—Ka Sáàmù 1:1-3; 73:27, 28.

Ọ̀dọ̀ Jèhófà, Ọlọ́run aláyọ̀ ni ìròyìn ayọ̀ ti wá. Tó o bá túbọ̀ sún mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run, èyí á mú kó o sún mọ́ Ọlọ́run fúnra rẹ̀. (Hébérù 10:24, 25) Tó o bá túbọ̀ ń sapá láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́, èyí á jẹ́ kó o lè ní ìyè tòótọ́, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun. Kò sí ohun tó dà bíi pé kó o sún mọ́ Ọlọ́run.​—Ka 1 Tímótì 1:11; 6:19.