Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 1

“Kí Ìjọba Rẹ Dé”

“Kí Ìjọba Rẹ Dé”

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Ó sọ nípa ohun tí Jésù kọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run

1, 2. Kí ni Jèhófà sọ ní etígbọ̀ọ́ mẹ́ta nínú àwọn àpọ́sítélì Jésù? Kí ni wọ́n ṣe?

TÍ Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ bá ní kó o ṣe ohun kan, ọwọ́ wo lo máa fi mú ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ohun yòówù tó bá ní kó o ṣe, ṣé o kò ní tara ṣàṣà ṣe é? Ó dájú pé wàá ṣe bẹ́ẹ̀!

2 Ohun tó ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ sí mẹ́ta lára àwọn àpọ́sítélì Jésù, ìyẹn Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù nìyẹn, nígbà kan lẹ́yìn àjọyọ̀ Ìrékọjá ti ọdún 32 Sànmánì Kristẹni. (Ka Mátíù 17:1-5.) Nígbà tí àwọn àti Jésù Ọ̀gá wọn wà lórí “òkè ńlá kan,” wọ́n rí ìran kan nípa bó ṣe máa di Ọba ológo ní ọ̀run. Ìran yìí dà bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóòótọ́, débi pé Pétérù gbìyànjú láti kópa nínú rẹ̀. Bí Pétérù ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àwọsánmà ṣíji bò wọ́n. Pétérù àtàwọn tí wọ́n jọ wá síbẹ̀ wá gbọ́ ohùn Jèhófà fúnra rẹ̀ látọ̀run, ohùn tó jẹ́ pé díẹ̀ ni ọmọ aráyé tó tíì gbọ́ ọ rí. Jèhófà jẹ́ kó ṣe kedere pé Ọmọ òun ni Jésù, ó sì wá sọ ní tààràtà pé: “Ẹ fetí sí i.” Àwọn àpọ́sítélì ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà yẹn. Wọ́n fetí sí ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ wọn, wọ́n tún rọ àwọn èèyàn míì pé kí àwọn náà fetí sí i.—Ìṣe 3:19-23; 4:18-20.

Jésù sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ju bó ṣe sọ̀rọ̀ nípa kókó èyíkéyìí míì lọ

3. Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ ká fetí sí Ọmọ rẹ̀? Kókó ọ̀rọ̀ wo ló dára ká ṣàyẹ̀wò?

3 Bí ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ fetí sí i” ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì jẹ́ fún àǹfààní tiwa. (Róòmù 15:4) Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù ni agbọ̀rọ̀sọ Jèhófà. Gbogbo ìgbà tí Jésù bá sì la ẹnu rẹ̀ láti kọ́ni, ohun tí Baba rẹ̀ fẹ́ ká mọ̀ ló máa ń sọ. (Jòh. 1:1, 14) Níwọ̀n bí Jésù sì ti sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ju bó ṣe sọ̀rọ̀ nípa àwọn kókó míì lọ, ó ṣe pàtàkì pé ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba náà. Àwọn tó wà nínú Ìjọba Mèsáyà tí òkè ọ̀run yìí ni Kristi Jésù àti àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí yóò bá a ṣàkóso. (Ìṣí. 5:9, 10; 14:1-3; 20:6) Ṣùgbọ́n, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ìdí tí Jésù fi sọ̀rọ̀ gan-an nípa Ìjọba Ọlọ́run.

“Lára Ọ̀pọ̀ Yanturu Tí Ń Bẹ Nínú Ọkàn-Àyà . . .”

4. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé Ìjọba náà jẹ òun lọ́kàn gan-an?

4 Ìjọba Ọlọ́run yìí jẹ Jésù lọ́kàn gan-an ni. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ ẹnu èèyàn máa ń jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Lédè míì, ọ̀rọ̀ ẹnu wa máa ń jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ ohun tó jẹ wá lógún lóòótọ́. Jésù alára sọ pé: “Lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Mát. 12:34) Ní ti Jésù, tí àyè àtisọ̀rọ̀ bá ti lè yọ pẹ́nrẹ́n, ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ló máa ń sọ. Ó ju ọgọ́rùn-ún ìgbà lọ tí ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin mẹ́nu kan Ìjọba náà, inú ọ̀rọ̀ Jésù lèyí tó pọ̀ jù nínú rẹ̀ sì ti jẹ yọ. Ìjọba Ọlọ́run ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ìwàásù rẹ̀. Ó ní: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43) Kódà lẹ́yìn tí Jésù jíǹde ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ló ṣì ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ. (Ìṣe 1:3) Ó dájú pé Jésù mọyì Ìjọba Ọlọ́run gan-an, ìyẹn ló ṣe máa ń wù ú láti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

5-7. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé Ìjọba náà jẹ Jèhófà lọ́kàn gan-an? Sọ àpèjúwe kan. (b) Kí la ó máa ṣe tí Ìjọba Ọlọ́run bá jẹ wá lọ́kàn gan-an?

5 Ìjọba yìí jẹ Jèhófà náà lọ́kàn gan-an ni. Báwo la ṣe mọ̀? Rántí pé Jèhófà rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sí ayé, àti pé gbogbo ohun tí Ọmọ rẹ̀ yìí sọ àti èyí tó fi kọ́ni jẹ́ ohun tó rán an. (Jòh. 7:16; 12:49, 50) Jèhófà náà ló sì mí sí gbogbo ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nípa ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Wá ronú lórí ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí.

Ó yẹ kí olúkúlùkù wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ Ìjọba Ọlọ́run jẹ mí lọ́kàn?’

6 Jẹ́ ká sọ pé o fẹ́ to fọ́tò ìdílé yín sínú álúbọ́ọ̀mù kan. Fọ́tò tó o ní pọ̀, àmọ́ ìwọ̀nba díẹ̀ ni álúbọ́ọ̀mù náà lè gbà. Kí ni wàá ṣe? Ó dájú pé àwọn tó ṣe pàtàkì jù nínú wọn ni wàá fi síbẹ̀. Álúbọ́ọ̀mù tí wọ́n kó fọ́tò sí yẹn ló dà bí àwọn ìwé Ìhìn Rere tó ṣàlàyé kedere nípa bí Jésù ṣe jẹ́. Kì í ṣe gbogbo ohun tí Jésù sọ àti èyí tó ṣe nígbà tó wà láyé ni Jèhófà mí sí àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere pé kí wọ́n kọ sílẹ̀. (Jòh. 20:30; 21:25) Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ohun tó máa jẹ́ ká lóye ète iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù àti àwọn ohun tí Jèhófà kà sí pàtàkì jù lára ohun tí Jésù sọ àti ohun tó ṣe ni Jèhófà fi ẹ̀mí rẹ̀ darí wọn pé kí wọ́n kọ sílẹ̀. (2 Tím. 3:16, 17; 2 Pét. 1:21) Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run ló kún inú àwọn ìwé Ìhìn Rere, a ò jayò pa tá a bá sọ pé Ìjọba Ọlọ́run jẹ Jèhófà lọ́kàn gan-an ni. Ẹ ò wá rí i pé Jèhófà fẹ́ ká mọ bí Ìjọba rẹ̀ ṣe jẹ́ gan-an!

7 Ó yẹ kí olúkúlùkù wa bi ara rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ Ìjọba Ọlọ́run jẹ mí lọ́kàn?’ Tó bá jẹ wá lọ́kàn, á máa wù wá láti fetí sí ohun tí Jésù sọ àti ohun tó kọ́ni nípa Ìjọba náà, títí kan bí Ìjọba náà ti ṣe pàtàkì tó, bó ṣe máa dé àti ìgbà tó máa dé.

Báwo Ni Ìjọba Ọlọ́run Ṣe Máa Dé?

8. Kí ni ọ̀rọ̀ ṣókí tí Jésù fi sọ bí Ìjọba Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó?

8 Ìwọ wo àdúrà Olúwa ná. Jésù fi ọ̀rọ̀ ṣókí tó tètè yéni, tó sì kún fún ẹ̀kọ́ gan-an sọ bí Ìjọba Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó àti ohun tó máa gbé ṣe. Àdúrà ẹ̀bẹ̀ méje ló wà nínú àdúrà Olúwa. Mẹ́ta àkọ́kọ́ jẹ mọ́ ète Jèhófà, ìyẹn bó ṣe máa sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, bí Ìjọba rẹ̀ ṣe máa dé àti bí ìfẹ́ rẹ̀ ṣe máa ṣẹ ní ayé àtọ̀run. (Ka Mátíù 6:9, 10.) Àdúrà ẹ̀bẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wé mọ́ra gan-an. Ìdí ni pé nípasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà yìí ni Jèhófà máa sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́ tí yóò sì mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.

9, 10. (a) Báwo ni Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa dé? (b) Èwo lo wù ọ́ pé kó ṣẹ lára àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì?

9 Báwo wá ni Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe dé? Tá a bá ń gbàdúrà pé, “Kí Ìjọba rẹ dé,” ńṣe là ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Ìjọba Ọlọ́run mú àyípadà bá gbogbo nǹkan. Nígbà tí Ìjọba náà bá dé, òun ni yóò máa ṣàkóso gbogbo ilẹ̀ ayé. Yóò palẹ̀ ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí mọ́, tó fi mọ́ gbogbo ìjọba èèyàn pátá, á sì mú ayé tuntun òdodo wá. (Dán. 2:44; 2 Pét. 3:13) Gbogbo ilẹ̀ ayé ni yóò di Párádísè lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. (Lúùkù 23:43) Ọlọ́run yóò jí àwọn tó wà nínú ibojì ìrántí dìde, kí wọ́n lè pa dà máa gbé ayé nìṣó pẹ̀lú àwọn èèyàn wọn. (Jòh. 5:28, 29) Àwọn èèyàn tó bá jẹ́ onígbọràn yóò di ẹni pípé, wọ́n á sì máa wà láàyè títí láé. (Ìṣí. 21:3-5) Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, gbogbo nǹkan ní ayé yóò wà níṣọ̀kan lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹ̀lú ti ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí! Ǹjẹ́ kò wù ọ́ láti rí bí àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì yìí ṣe máa ṣẹ? Rántí pé ní gbogbo ìgbà tó o bá ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, ṣe lò ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run mú àwọn ìlérí tó kọyọyọ yẹn ṣẹ.

10 Ó ṣe kedere pé Ìjọba Ọlọ́run kò tíì “dé” lọ́nà tí yóò fi mú kí àdúrà Olúwa ṣẹ. Ó ṣe tán, àwọn ìjọba èèyàn ló ṣì ń ṣàkóso báyìí, ayé tuntun òdodo ò sì tíì dé. Ṣùgbọ́n ìròyìn ayọ̀ kan wà o! Ọlọ́run ti gbé Ìjọba náà kalẹ̀! A máa rí àlàyé rẹ̀ ní orí tó tẹ̀ lé èyí. Ní báyìí ná, jẹ́ ká wo ohun tí Jésù sọ nípa ìgbà tí Ọlọ́run máa gbé Ìjọba náà kalẹ̀ àti ìgbà tó máa dé.

Ìgbà Wo Ni Ọlọ́run Máa Gbé Ìjọba Náà Kalẹ̀?

11. Kí ni Jésù fi hàn nípa ìgbà tí Ọlọ́run máa gbé Ìjọba náà kalẹ̀?

11 Jésù fi hàn pé ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni kọ́ ni Ọlọ́run máa gbé Ìjọba náà kalẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn yàtọ̀ sí ohun tí àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń retí. (Ìṣe 1:6) Wo ohun tó sọ nínú àkàwé méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó sọ ní èyí tí kò tó ọdún méjì síra.

12. Báwo ni àkàwé nípa àlìkámà àti èpò ṣe fi hàn pé kì í ṣe ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni ni a gbé Ìjọba náà kalẹ̀?

12 Àkàwé àlìkámà àti èpò. (Ka Mátíù 13:24-30.) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà ìrúwé ọdún 31 Sànmánì Kristẹni ni Jésù sọ àkàwé yìí. Àmọ́ lẹ́yìn tó sọ ọ́ tán, ó ṣàlàyé rẹ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Mát. 13:36-43) Kókó inú àkàwé yẹn àti ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, Èṣù yóò fún èpò (àwọn ayédèrú Kristẹni) sáàárín àlìkámà (“àwọn ọmọ ìjọba náà,” ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró). Wọ́n á jẹ́ kí àlìkámà àti èpò jọ máa dàgbà pọ̀ títí di ìgbà ìkórè, ìyẹn sì ni “ìparí ètò àwọn nǹkan.” Lẹ́yìn tí ìgbà ìkórè bá ti bẹ̀rẹ̀, a óò kó àwọn èpò jọ. Lẹ́yìn náà, a óò wá kó àlìkámà jọ. Torí náà, àkàwé yìí fi hàn pé kì í ṣe ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni la máa gbé Ìjọba náà kalẹ̀. Yóò jẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí àwọn irúgbìn náà bá ti dàgbà tí wọ́n sì ti gbó. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ wọ́n dàgbà, wọ́n gbó, ìgbà ìkórè sì bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914.

13. Àfiwé wo ni Jésù ṣe tó fi hàn pé kì í ṣe gbàrà tó bá pa dà dé ọ̀run ni Ọlọ́run máa gbé e gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba?

13 Àkàwé nípa mínà. (Lúùkù 19:11-13.) Ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni Jésù sọ àkàwé yìí, nígbà ìrìn àjò rẹ̀ tó kẹ́yìn sí Jerúsálẹ́mù. Ó ṣẹlẹ̀ pé, àwọn kan lára àwọn olùgbọ́ rẹ̀ rò pé ó máa bẹ̀rẹ̀ Ìjọba rẹ̀ ní gbàrà tí àwọn bá dé Jerúsálẹ́mù. Kí Jésù lè tún èrò wọn yẹn ṣe, kó sì jẹ́ kí wọ́n rí i pé ó ṣì máa pẹ́ gan-an kí Ọlọ́run tó gbé Ìjọba náà kalẹ̀, ó fi ara rẹ̀ wé “ọkùnrin kan tí a bí ní ilé ọlá” tó rin ìrìn àjò “lọ sí ilẹ̀ jíjìnnàréré láti gba agbára ọba.” * Ní ti Jésù, ọ̀run ni “ilẹ̀ jíjìnnàréré” yẹn. Ibẹ̀ ló ti máa gba agbára gẹ́gẹ́ bí Ọba lọ́dọ̀ Baba rẹ̀. Ṣùgbọ́n Jésù mọ̀ pé kì í ṣe gbàrà tí òun bá pa dà dé ọ̀run ni Ọlọ́run máa gbé òun gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní láti kọ́kọ́ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run títí di ìgbà tí Ọlọ́run ti pinnu. Ó wá já sí pé ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ló fi dúró.—Sm. 110:1, 2; Mát. 22:43, 44; Héb. 10:12, 13.

Ìgbà Wo Ni Ìjọba Ọlọ́run Máa Dé?

14. (a) Báwo ni Jésù ṣe dáhùn ìbéèrè tí mẹ́rin lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ bi í? (b) Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Jésù tó ṣẹ jẹ́ ká mọ̀ nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀ àti nípa Ìjọba Ọlọ́run?

14 Ní ọjọ́ mélòó kan ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n pa Jésù, mẹ́rin lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ bi í pé: “Kí ni yóò . . . jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mát. 24:3; Máàkù 13:4) Jésù wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ gígùn tó wà nínú Mátíù orí 24 àti25 láti fi dá wọn lóhùn. Ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ onírúurú ohun tó máa ṣẹlẹ̀ kárí ayé, èyí tó máa jẹ́ àmì tí a ó fi mọ àkókò tó pè ní ìgbà “wíwàníhìn-ín” rẹ̀. Ìgbà wíwàníhìn-ín rẹ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run gbé Ìjọba náà kalẹ̀, yóò sì parí nígbà tí Ìjọba náà bá dé, ìyẹn nígbà tó bá ń ṣàkóso ayé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. A ní ẹ̀rí tó pọ̀ tó pé láti ọdún 1914 ni àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù sọ ti ń ṣẹ. * Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé ọdún yẹn ni ìbẹ̀rẹ̀ wíwàníhìn-ín rẹ̀ àti ìgbà tí Ọlọ́run gbé Ìjọba náà kalẹ̀.

15, 16. Àwọn wo ni Jésù pè ní “ìran yìí”?

15 Ìgbà wo gan-an wá ni Ìjọba Ọlọ́run máa dé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́? Jésù kò sọ ìgbà pàtó tó máa dé. (Mát. 24:36) Àmọ́, ó sọ ohun kan tó yẹ kó mú un dá wa lójú pé ó ti sún mọ́lé. Jésù fi hàn pé Ìjọba náà yóò dé lẹ́yìn tí àwọn tó pè ní “ìran yìí” bá ti rí ìmúṣẹ àmì tó sọ tẹ́lẹ̀ náà. (Ka Mátíù 24:32-34.) Àwọn wo ni Jésù pè ní “ìran yìí”? Jẹ́ ká fara balẹ̀ gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò.

16 “Ìran yìí.” Ṣé àwọn aláìgbàgbọ́ ni Jésù pè ní “ìran yìí”? Rárá o. Tá a bá wò ó, a ó rí i pé àwọn àpọ́sítélì mélòó kan tó “tọ̀ ọ́ wá ní ìdákọ́ńkọ́” ló ń bá sọ̀rọ̀. Àwọn ni Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà fún. (Mát. 24:3) Ọlọ́run sì máa tó fi ẹ̀mí mímọ́ yan àwọn àpọ́sítélì yẹn. Tún wo nǹkan tí Jésù ń sọ bọ̀ kó tó mẹ́nu kan “ìran yìí.” Ó ti kọ́kọ́ sọ pé: “Wàyí o, ẹ kẹ́kọ̀ọ́ kókó yìí lára igi ọ̀pọ̀tọ́ gẹ́gẹ́ bí àpèjúwe kan pé: Gbàrà tí ẹ̀ka rẹ̀ tuntun bá yọ ọ̀jẹ̀lẹ́, tí ó sì mú ewé jáde, ẹ mọ̀ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn sún mọ́lé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, kí ẹ mọ̀ pé ó ti sún mọ́ tòsí lẹ́nu ilẹ̀kùn.” Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó jẹ́ ẹni àmì òróró ni yóò rí àwọn nǹkan tó sọ tẹ́lẹ̀, tí wọ́n á sì fòye mọ̀ pé Jésù ti “sún mọ́ tòsí lẹ́nu ilẹ̀kùn,” kì í ṣe àwọn aláìgbàgbọ́. Torí náà, nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa “ìran yìí,” àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àmì òróró ló ní lọ́kàn.

17. Kí ni ọ̀rọ̀ náà “ìran” tí Bíbélì sọ níhìn-ín túmọ̀ sí? Kí ni gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “gbogbo nǹkan wọ̀nyí” túmọ̀ sí?

17 “Kì yóò kọjá lọ lọ́nàkọnà títí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹlẹ̀.” Báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe máa ṣẹ? Ká lè rí ìdáhùn ìbéèrè yìí, ó yẹ ká mọ ohun méjì kan, ìyẹn ni: ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìran” àti gbólóhùn náà “gbogbo nǹkan wọ̀nyí.” Ọ̀rọ̀ náà “ìran” sábà máa ń tọ́ka sí àwọn èèyàn kan tí ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ síra, àmọ́ tí wọ́n bá ara wọn láyé tí wọ́n sì jọ gbé ayé pa pọ̀ láàárín àkókò kan. Ìran kan kì í gùn jàn-ànràn jan-anran, ó sì máa ń ní òpin. (Ẹ́kís. 1:6) Gbólóhùn náà “gbogbo nǹkan wọ̀nyí” kan gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa wáyé nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀, látìgbà tó ti bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914 títí tó fi máa dé ìparí rẹ̀ nígbà “ìpọ́njú ńlá.”—Mát. 24:21.

18, 19. Kí ni òye wa lórí ọ̀rọ̀ Jésù nípa “ìran yìí”? Ibo la wá lè parí ọ̀rọ̀ náà sí?

18 Kí wá ni òye wa lórí ọ̀rọ̀ Jésù nípa “ìran yìí”? Ìran yẹn jẹ́ àwùjọ ẹni àmì òróró méjì tí ọ̀kan bá èkejì láyé tí wọ́n sì jọ gbé ayé láàárín àkókò kan. Àwùjọ àkọ́kọ́ ni àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n rí ìgbà tí àmì náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹ lọ́dún 1914. Àwùjọ kejì ni àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n bá àwùjọ àkọ́kọ́ láyé, tí àwọn méjèèjì sì jọ gbé láyé láàárín ìgbà kan. Ó kéré tán, àwọn kan lára àwùjọ kejì yóò ṣì wà láyé nígbà tí ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ máa bẹ̀rẹ̀. Àwùjọ méjèèjì yìí jẹ́ ìran kan torí pé wọ́n jọ jẹ́ ẹni àmì òróró pa pọ̀ láàárín àkókò kan. *

19 Ibo la wá lè parí ọ̀rọ̀ yìí sí? Ohun kan ni pé a mọ̀ dájú pé àmì tó fi hàn pé Jésù ti wà níhìn-ín gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run hàn kedere kárí ayé. A sì tún rí i pé àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ “ìran yìí” ti ń darúgbó lọ; bẹ́ẹ̀ sì rèé wọn kò ní kú tán kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀. Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run ti dé tán báyìí láti wá máa ṣàkóso ilẹ̀ ayé! Ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó tí àdúrà tí Jésù kọ́ wa ká máa gbà pé “Kí ìjọba rẹ dé,” bá ń ṣẹ níṣojú wa!

20. Kókó pàtàkì wo la máa sọ̀rọ̀ lé lórí nínú ìwé yìí? Kí la máa gbé yẹ̀ wò ní orí tó tẹ̀ lé èyí?

20 Ká má ṣe gbàgbé ọ̀rọ̀ tí Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ látọ̀run nípa Ọmọ rẹ̀ pé: “Ẹ fetí sí i.” Ńṣe làwa Kristẹni tòótọ́ ń tara ṣáṣá láti pa àṣẹ Ọlọ́run yẹn mọ́. Tọkàntara la fi nífẹ̀ẹ́ sí gbogbo ohun tí Jésù sọ àti èyí tó kọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ohun tí Ìjọba yẹn ti gbé ṣe àti ohun tó ń bọ̀ wá ṣe lọ́jọ́ iwájú ni kókó pàtàkì tá a máa sọ̀rọ̀ lé lórí nínú ìwé yìí. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì-pàtàkì tó wáyé nígbà ìbí Ìjọba Ọlọ́run lọ́run la máa gbé yẹ̀ wò ní orí tó tẹ̀ lé èyí.

^ ìpínrọ̀ 13 Ó ṣeé ṣe kí àkàwé Jésù yìí rán àwọn olùgbọ́ rẹ̀ létí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ákíláọ́sì ọmọ Hẹ́rọ́dù Ńlá. Kí Hẹ́rọ́dù tó kú, ó yan Ákíláọ́sì pé òun ló máa jọba lórí Jùdíà àtàwọn àgbègbè míì lẹ́yìn òun. Àmọ́ kí Ákíláọ́sì tó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso, ó ní láti kọ́kọ́ rìnrìn àjò lọ sí iyànníyàn ìlú Róòmù láti lọ gba àṣẹ lọ́dọ̀ Késárì Ọ̀gọ́sítọ́sì.

^ ìpínrọ̀ 18 Ẹnikẹ́ni tó bá di ẹni àmì òróró lẹ́yìn ikú èyí tó gbẹ̀yìn lára àwọn ẹni àmì òróró tó wà nínú àwùjọ àkọ́kọ́, ìyẹn àwùjọ tó rí “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìroragógó wàhálà” lọ́dún 1914, kì í ṣe ara àwọn tí Jésù pè ní “ìran yìí.”—Mát. 24:8.