Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 5

Ọba Ìjọba Ọlọ́run Mú Ká Túbọ̀ Lóye Ìjọba Náà

Ọba Ìjọba Ọlọ́run Mú Ká Túbọ̀ Lóye Ìjọba Náà

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Àwọn èèyàn Ọlọ́run dẹni tó lóye àwọn òtítọ́ pàtàkì nípa Ìjọba náà, nípa àwọn alákòóso rẹ̀ àtàwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀, àti ohun tó gbà láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ìjọba náà

1, 2. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ afinimọ̀nà tó gbọ́n?

KÁ SỌ pé afinimọ̀nà kan ń mú yín mọ ìlú àgbàyanu kan tó lẹ́wà gan-an, ó sì mọ ibẹ̀ dáadáa. Ìwọ àti àwọn tí ẹ jọ ń rìn kò dé ìlú náà rí, torí náà ńṣe lẹ ń tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ohun tí ẹni tó ń mú yín mọ̀lú ń sọ. Nígbà míì, ìwọ àti àwọn yòókù máa ń hára gàgà láti mọ̀ nípa àwọn nǹkan míì tó wà ní ìlú náà kí ẹ tó débi tó wà. Àmọ́ tí ẹ bá bi ẹni tó ń fi yín mọ̀nà nípa nǹkan wọ̀nyẹn, kò ní tíì sọ ọ́ fún yín, àfìgbà tó bá tásìkò gẹ́lẹ́, lọ́pọ̀ ìgbà ó sì máa ń jẹ́ ìgbà tẹ́ ẹ bá fẹ́ yọ síbi nǹkan ọ̀hún. Nígbà tó yá, ọgbọ́n tó ń lò yìí ń wú ẹ̀yin pàápàá lórí, torí pé ó ń sọ ohun tó yẹ kí ẹ mọ̀ fún yín nígbà tó yẹ kí ẹ mọ̀ ọ́n gan-an.

2 Irú ipò tí àwọn tí wọ́n fi ń mọ̀lú yìí wà làwa Kristẹni tòótọ́ náà wà. A ń fi ìháragàgà kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìlú tó jẹ́ àgbàyanu jù lọ, tí í ṣe “ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́,” ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run. (Héb. 11:10) Nígbà tí Jésù wà láyé, òun fúnra rẹ̀ ló ń fi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ̀nà, tó ń mú kí wọ́n ní ìmọ̀ tó jinlẹ̀ nípa Ìjọba náà. Ṣé gbogbo ìbéèrè tí wọ́n bi í ló dáhùn pátá, tó sì sọ gbogbo nǹkan nípa Ìjọba náà fún wọn lẹ́ẹ̀kan náà? Rárá. Ó sọ pé: “Mo ṣì ní ohun púpọ̀ láti sọ fún yín, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n mọ́ra nísinsìnyí.” (Jòh. 16:12) Jésù ni afinimọ̀nà tó gbọ́n jù lọ. Torí náà, tó bá rí i pé àwọn nǹkan kan kò tíì lè yé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, kì í sọ ọ́, kó má bàa fi ìyẹn dà wọ́n láàmú.

3, 4. (a) Báwo ni Jésù ṣe ń bá a lọ láti kọ́ àwọn olóòótọ́ èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run? (b) Kí la máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní orí yìí?

3 Alẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé ló sọ ọ̀rọ̀ tó wà ní Jòhánù 16:12 yẹn. Báwo ni yóò ṣe wá máa bá a lọ láti kọ́ àwọn olóòótọ́ èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run lẹ́yìn ikú rẹ̀? Ó fi dá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lójú pé: “Ẹ̀mí òtítọ́ náà, yóò ṣamọ̀nà yín sínú òtítọ́ gbogbo.” * (Jòh. 16:13) Torí náà, a lè fi ẹ̀mí mímọ́ wé afinimọ̀nà tó ń fi sùúrù ṣamọ̀nà ẹni. Ẹ̀mí mímọ́ ni Jésù ń lò láti fi kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ohunkóhun tó bá yẹ kí wọ́n mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, nígbà tó yẹ kí wọ́n mọ̀ ọ́n gẹ́lẹ́.

4 Ẹ jẹ́ ká wá wo bí ẹ̀mí Jèhófà ṣe ti ń ṣamọ̀nà àwọn Kristẹni olóòótọ́ lọ́nà tí wọ́n fi túbọ̀ ń ní ìmọ̀ púpọ̀ sí i nípa Ìjọba náà. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe dẹni tó lóye ìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso. Lẹ́yìn náà, a ó sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe wá dá àwọn tí yóò ṣàkóso Ìjọba náà mọ̀ yàtọ̀ àti ìrètí wọn, àtàwọn tó jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba náà àti ìrètí wọn. Paríparí rẹ̀, a ó sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ṣe wá ní òye kedere nípa ohun tó wé mọ́ jíjẹ́ adúróṣinṣin sí Ìjọba náà.

A Lóye Ọdún Pàtàkì Kan

5, 6. (a) Àwọn èrò tó kù díẹ̀ káàtó wo làwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní nípa bí Ọlọ́run ṣe máa gbé Ìjọba náà kalẹ̀ àti nípa ìkórè? (b) Kí nìdí táwọn èrò tó kù díẹ̀ káàtó yìí kò fi hàn pé bóyá ni Jésù ń ṣamọ̀nà àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀?

5 Bí a ṣe rí i ní Orí 2 ìwé yìí, ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ń tọ́ka sí ọdún 1914 pé ó jẹ́ ọdún pàtàkì kan tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì máa ṣẹ. Àmọ́ nígbà yẹn, wọ́n gbà gbọ́ pé ọdún 1874 ni wíwàníhìn-ín Kristi ti bẹ̀rẹ̀, pé ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́run ní ọdún 1878 àti pé ó di October 1914 kí Ìjọba náà tó fìdí múlẹ̀ dáadáa. Wọ́n gbà pé ìkórè yóò máa bá a lọ láti ọdún 1874 sí ọdún 1914 àti pé níparí rẹ̀ wọ́n á kó àwọn ẹni àmì òróró lọ sí ọ̀run. Ǹjẹ́ irú èrò tó kù díẹ̀ káàtó wọ̀nyí fi hàn pé bóyá ni Jésù ń fi ẹ̀mí mímọ́ ṣamọ̀nà àwọn olóòótọ́ wọ̀nyẹn?

6 Rárá o! Ronú nípa àpèjúwe tá a fi bẹ̀rẹ̀ orí yìí ná. Ṣé àwọn èrò tó kù díẹ̀ káàtó tí àwọn tí wọ́n fi ń mọ̀lú yìí kọ́kọ́ ní àti àwọn ìbéèrè tí wọ́n ń fi ìhára gàgà béèrè máa fi hàn pé bóyá ni ẹni tó ń fi wọ́n mọ̀nà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé? Ó tì o! Bákan náà ni ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe rí. Lóòótọ́, àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń gbìyànjú láti ṣàlàyé àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan nípa ète Jèhófà kó tó tákòókò tí ẹ̀mí mímọ́ máa ṣamọ̀nà wọn débi tí òye òtítọ́ wọ̀nyẹn á fi yé wọn, síbẹ̀ ó dájú pé Jésù ló ń ṣamọ̀nà wọn. Ìdí nìyẹn tí àwọn olóòótọ́ lára wọn fi máa ń ṣe tán láti gba ìtọ́sọ́nà, tí wọ́n sì máa ń fi ìrẹ̀lẹ̀ yí èrò wọn pa dà.—Ják. 4:6.

7. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ òtítọ́ wo ni Ọlọ́run ń mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ túbọ̀ lóye?

7 Lẹ́yìn ọdún 1919, Ọlọ́run wá ń mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ túbọ̀ lóye ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ òtítọ́ síwájú sí i. (Ka Sáàmù 97:11.) Lọ́dún 1925, wọ́n gbé àpilẹ̀kọ pàtàkì kan jáde nínú Ilé Ìṣọ́, tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ìbí Orílẹ̀-Èdè Náà.” Ó sọ àwọn ẹ̀rí látinú Ìwé Mímọ́, tó fi dáni lójú pé ọdún 1914 la ti bí Ìjọba Mèsáyà, èyí tó jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tí ìwé Ìṣípayá orí 12 sọ pé obìnrin Ọlọ́run ní ọ̀run bímọ. * Àpilẹ̀kọ náà tún fi hàn pé inúnibíni tí wọ́n ṣe sí àwọn èèyàn Jèhófà àti wàhálà tó bá wọn láwọn ọdún tí ogun jà yẹn jẹ́ àmì tó ṣe kedere pé wọ́n ti lé Sátánì sí ayé láti ọ̀run, àti pé “ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”—Ìṣí. 12:12.

8, 9. (a) Kí nìdí tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí í ka Ìjọba Ọlọ́run sí ohun tó ṣe pàtàkì jù? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa dáhùn?

8 Báwo wá ni Ìjọba náà ti ṣe pàtàkì tó? Lọ́dún 1928, Ilé Ìṣọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í tẹnu mọ́ ọn pé Ìjọba náà ṣe pàtàkì ju ọ̀rọ̀ bí ìràpadà Jésù yóò ṣe mú kí kálukú wa rí ìgbàlà lọ. Ìjọba Mèsáyà yìí ni Jèhófà yóò lò láti fi sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́, láti dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run láre, òun sì ni yóò fi mú gbogbo ète rẹ̀ fún ìran èèyàn ṣẹ.

9 Àwọn wo ló máa bá Kristi ṣàkóso nínú Ìjọba náà? Àwọn wo ló máa jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba náà láyé? Iṣẹ́ wo ló sì yẹ kí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi gbájú mọ́?

Àwọn Ẹni Àmì Òróró Ni Wọ́n Kọ́kọ́ Ń Kórè

10. Kí ló ti yé àwọn èèyàn Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún nípa àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000]?

10 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú 1914, ló ti yé àwọn Kristẹni tòótọ́ pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tó jẹ́ olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni yóò bá Kristi jọba lọ́run. * Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn rí i pé iye tí àwọn tó máa lọ sọ́run máa jẹ́ gan-an nìyẹn àti pé láti ọgọ́rùn-rún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni la ti bẹ̀rẹ̀ sí í yàn wọ́n.

11. Báwo ni àwọn tó máa di ara ìyàwó Kristi lọ́jọ́ iwájú ṣe túbọ̀ ń lóye iṣẹ́ wọn lórí ilẹ̀ ayé?

11 Àmọ́ kí ni iṣẹ́ tí àwọn tó máa di ara ìyàwó Kristi lọ́jọ́ iwájú yìí yóò máa ṣe nígbà tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé? Wọ́n rí i pé Jésù tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù, ó sì fi hàn pé ó jẹ mọ́ ìgbà ìkórè. (Mát. 9:37; Jòh. 4:35) Bí a ṣe sọ ní Orí 2, láwọn àkókò kan, wọ́n gbà pé ìkórè náà yóò gba ogójì [40] ọdún, àti pé ní ìparí rẹ̀ wọ́n á kó àwọn ẹni àmì òróró lọ sọ́run. Àmọ́ nígbà tí ìkórè náà ṣì wá ń bá a lọ lẹ́yìn tí ogójì ọdún kọjá, ó ṣe kedere pé wọ́n nílò ìlàlóye síwájú sí i. Ní báyìí ṣá o, a ti wá mọ̀ dájú pé ọdún 1914 ni àsìkò ìkórè náà bẹ̀rẹ̀. Ìgbà yẹn jẹ́ àsìkò tí a ya èpò kúrò lára àlìkámà, ìyẹn ìgbà tí a ya àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró olóòótọ́ kúrò lára àwọn Kristẹni afàwọ̀rajà. Àsìkò wá tó wàyí láti gbájú mọ́ kíkó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn tó ń lọ sọ́run jọ!

Ọdún 1914 ni àsìkò ìkórè bẹ̀rẹ̀ (Wo ìpínrọ̀ 11)

12, 13. Báwo ni àkàwé Jésù nípa àwọn wúńdíá mẹ́wàá àti ti tálẹ́ńtì ṣe ṣẹ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn?

12 Láti ọdún 1919, Kristi ń darí ẹrú olóòótọ́ àti olóye kí wọ́n máa tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù. Ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ló pàṣẹ pé ká máa ṣe iṣẹ́ náà. (Mát. 28:19, 20) Ó sì tún sọ àwọn ohun tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró máa ṣe tí wọ́n á fi lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà yanjú. Báwo ló ṣe sọ ọ́? Nínú àkàwé àwọn wúńdíá mẹ́wàá, ó fi hàn pé àwọn ẹni àmì òróró gbọ́dọ̀ máa ṣọ́nà kí wọ́n sì wà lójúfò nípa tẹ̀mí, bí wọ́n bá fẹ́ kí ọwọ́ wọn tẹ èrè tó ga jù, ìyẹn ni pé kí wọ́n nípìn-ín nínú àsè ìgbéyàwó ńlá tó máa wáyé ní ọ̀run. Nígbà àsè náà, Kristi àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], ìyẹn àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ “ìyàwó” rẹ̀, yóò dọ́kàn ṣoṣo. (Ìṣí. 21:2) Bákan náà, nínú àkàwé tí Jésù ṣe nípa tálẹ́ńtì, ó kọ́ni pé àwọn ìránṣẹ́ òun tó jẹ́ ẹni àmì òróró yóò fi tọkàntara ṣiṣẹ́ ìwàásù tí òun gbé lé wọn lọ́wọ́.—Mát. 25:1-30.

13 Àwọn ẹni àmì òróró yìí wà lójúfò wọ́n sì fi tọkàntara ṣiṣẹ́ láàárín ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá. Ó dájú pé wọ́n á jèrè bí wọ́n ṣe wà lójúfò! Àmọ́ ṣá o, ṣé kìkì èyí tó ṣẹ́ kù lára ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tó máa bá Kristi jọba nìkan ni wọ́n fẹ́ fi àsìkò ìkórè ńlá náà kó jọ ni?

Ìjọba Náà Ń Kó Àwọn Ọmọ Abẹ́ Rẹ̀ Jọ Láyé!

14, 15. Ẹgbẹ́ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wo ni ìwé The Finished Mystery sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?

14 Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn olóòótọ́ lọ́kùnrin lóbìnrin ti ń wọ́nà lójú méjèèjì láti mọ̀ nípa “ogunlọ́gọ̀ ńlá” náà (“ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn,” Bíbélì Mímọ́) tí Ìṣípayá 7:9-14 mẹ́nu kàn. Abájọ tó jẹ́ pé kó tó tásìkò tí Kristi máa jẹ́ ká mọ bí àwùjọ ńlá yìí ṣe jẹ́, èyí tó pọ̀ jù nínú àlàyé táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe nípa rẹ̀ ló jìnnà gan-an sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ṣe kedere, tó rọrùn láti lóye, tí a mọ̀ nípa rẹ̀ tí a sì fẹ́ràn gan-an lónìí.

15 Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1917, ìwé The Finished Mystery fi yéni pé “oríṣi méjì làwọn ẹni ìgbàlà tó máa lọ sọ́run, oríṣi méjì sì làwọn ẹni ìgbàlà tó máa wà láyé.” Àwọn wo ló wà nínú ẹgbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n sọ pé ó ń retí ìgbàlà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yìí? Wọ́n ní ẹgbẹ́ àkọ́kọ́ ni ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], tó máa bá Kristi jọba. Ẹgbẹ́ kejì ni ti àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. Láyé ìgbà yẹn, èrò wọn ni pé àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni àmọ́ tí wọ́n ṣì wà láàárín àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yìí. Pé wọ́n nígbàgbọ́ díẹ̀, àmọ́ ìyẹn kò tó láti mú kí wọ́n pa ìwà títọ́ wọn mọ́ délẹ̀délẹ̀. Nítorí náà, ipò tó rẹlẹ̀ ni wọ́n máa fi wọ́n sí lọ́run. Ní ti orí ilẹ̀ ayé, wọ́n rò pé ẹgbẹ́ kẹta tí wọ́n pè ní “àwọn ẹni ìgbàanì tí ìgbàlà tọ́ sí,” ìyẹn àwọn olóòótọ́ bí Ábúráhámù, Mósè àtàwọn míì, yóò wà nípò àṣẹ lórí ẹgbẹ́ kẹrin, èyí tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ aráyé yòókù.

16. Ìlàlóye òtítọ́ wo ló wá ní ọdún 1923 àti lọ́dún 1932?

16 Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe wá ṣamọ̀nà àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tí wọ́n fi ní òye tí a wá mọyì rẹ̀ gan-an lónìí? Ṣe ló ń ṣamọ̀nà wọn ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, nípasẹ̀ ìlàlóye òtítọ́ tó ń wá lẹ́sẹẹsẹ. Bí àpẹẹrẹ, láti ọdún 1923 ni Ilé Ìṣọ́ ti ń pàfiyèsí sí àwùjọ kan tí kò ní èrò lílọ sí ọ̀run lọ́kàn, tó jẹ́ pé ilẹ̀ ayé níbí ni wọ́n máa gbé lábẹ́ Ìjọba Kristi. Lọ́dún 1932, Ilé Ìṣọ́ sọ̀rọ̀ nípa Jónádábù (Jèhónádábù), tó wá bá Jéhù Ọba Ísírẹ́lì tí Ọlọ́run fòróró yàn, tó sì tì í lẹ́yìn nínú bó ṣe gbéjà ko ìsìn èké. (2 Ọba. 10:15-17) Àpilẹ̀kọ náà sọ pé àwùjọ èèyàn kan wà lóde òní tó dà bí Jónádábù, pé Jèhófà yóò mú àwùjọ yìí “la ìyọnu Amágẹ́dọ́nì já,” kí wọ́n lè máa gbé lórí ilẹ̀ ayé níbí.

17. (a) Ìlàlóye ẹ̀kọ́ òtítọ́ wo ló ṣe kedere lọ́dún 1935? (b) Ipa wo ni òye tuntun táwọn Kristẹni olóòótọ́ ní nípa àwọn tó jẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní lórí wọn? (Wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní, ‘ Ọkàn Ti Wá Balẹ̀ Dáadáa Wàyí.’)

17 Lọ́dún 1935, wọ́n wá ní ìlàlóye tó ṣe kedere nípa ẹ̀kọ́ òtítọ́ kan. Ní àpéjọ àgbègbè tí wọ́n ṣe ní ìlú Washington, D.C., wọ́n fi hàn pé àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí Bíbélì sọ jẹ́ àwùjọ èèyàn tó máa wà ní ayé, pé àwọn náà ni àwọn àgùntàn tí Jésù sọ nínú àkàwé àwọn àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́. (Mát. 25:33-40) Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn náà yóò sì jẹ́ ara àwọn “àgùntàn mìíràn” tí Jésù sọ pé: “Àwọn pẹ̀lú ni èmi yóò mú wá.” (Jòh. 10:16) Nígbà tí J. F. Rutherford tó jẹ́ alásọyé sọ pé: “Kí gbogbo àwọn tó ń retí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé jọ̀wọ́ dìde dúró,” ó ju ìdajì àwọn tó wà níbẹ̀ lọ tó dìde dúró! Ni Rutherford wá kéde pé: “Ẹ wò ó! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn náà nìyí!” Inú ọ̀pọ̀ èèyàn dùn gan-an ni pé àwọn ti wá mọ ohun tí àwọn ń retí lọ́jọ́ ọ̀la wàyí.

18. Kí làwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ṣe tó fi hàn pé wọ́n gbájú mọ́ iṣẹ́ ìwàásù, kí ló sì yọrí sí?

18 Látìgbà náà títí di báyìí, Kristi ń darí àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n gbájú mọ́ kíkó àwọn tó máa di ara ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí jọ, ìyẹn àwọn tó jẹ́ pé yóò la ìpọ́njú ńlá náà jà láìséwu. Lákọ̀ọ́kọ́, ó jọ pé iye tí wọ́n ń rí kó jọ lára wọn kò fi bẹ́ẹ̀ wúni lórí. Kódà nígbà kan Arákùnrin Rutherford sọ pé: “Ó dà bíi pé ‘ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn’ náà kò ní pọ̀ tó bí a ṣe rò tẹ́lẹ̀.” Ṣùgbọ́n ní báyìí, a ti rí bí Jèhófà ṣe ń fi ìbùkún ńlá sí iṣẹ́ ìkórè yìí látìgbà náà wá! Lábẹ́ ìdarí Jésù àti ẹ̀mí mímọ́, àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn “àgùntàn mìíràn” alábàákẹ́gbẹ́ wọn ti di “agbo kan” tí wọ́n ń sìn pa pọ̀ lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan,” bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀.

Arákùnrin Rutherford kò mọ bí ogunlọ́gọ̀ ńlá náà ṣe máa wá pọ̀ tó lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn (A to orúkọ láti ọwọ́ òsì lọ sí ọwọ́ ọ̀tún: Nathan H. Knorr, Joseph F. Rutherford, àti Hayden C. Covington)

19. Báwo la ṣe lè nípìn-ín nínú mímú kí iye àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá náà túbọ̀ máa pọ̀ sí i?

19 Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn olóòótọ́ ni yóò gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé nínú Párádísè, tí Kristi àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tó máa bá a jọba yóò máa ṣàkóso wọn. Ǹjẹ́ kò dùn mọ́ wa nínú gan-an bí a ṣe ṣàyẹ̀wò ọ̀nà tí Kristi ti gbà ṣamọ̀nà àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n fi ní irú òye tó ṣe kedere bẹ́ẹ̀ nípa ìrètí ọjọ́ ọ̀la tí Ìwé Mímọ́ sọ? Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti máa sọ ìrètí yẹn fún àwọn tí a bá bá pàdé lóde ẹ̀rí! Ẹ jẹ́ ká máa sa gbogbo ipá wa lẹ́nu iṣẹ́ yìí bó bá ti lè ṣeé ṣe fún wa tó, kí àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá náà lè túbọ̀ máa pọ̀ sí i, kí òkìkí ìyìn orúkọ Jèhófà lè túbọ̀ máa ròkè lálá!—Ka Lúùkù 10:2.

Ńṣe ni ogunlọ́gọ̀ ńlá náà túbọ̀ ń pọ̀ sí i

Ohun Tó Gbà Láti Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Ìjọba Náà

20. Àwọn nǹkan wo ló para pọ̀ jẹ́ ètò Sátánì, kí ló gbà láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Ìjọba Ọlọ́run?

20 Bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba ọ̀run náà, ó yẹ kí wọ́n ṣì ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa ohun tó gbà láti jẹ́ adúróṣinṣin sí ìjọba yẹn. Lórí kókó yìí, lọ́dún 1922, Ilé Ìṣọ́ fi hàn pé ètò méjì tó yàtọ̀ síra ló ń fẹ́ kí àwọn ẹ̀dá olóye wà lábẹ́ àwọn, ìyẹn ètò Jèhófà àti ètò Sátánì. Àwọn ohun tó para pọ̀ jẹ́ ètò Sátánì ni ètò ìṣòwò, ètò ìsìn àti ètò ìṣèlú. Àwọn tó bá dúró ṣinṣin sí Ìjọba Ọlọ́run tí Kristi ń ṣàkóso kò gbọ́dọ̀ bá apá èyíkéyìí nínú ètò Sátánì ní àjọṣe àìtọ́, kí ìyẹn má bàa ba ìdúróṣinṣin wọn jẹ́. (2 Kọ́r. 6:17) Kí nìyẹn túmọ̀ sí?

21. (a) Báwo ni ẹrú olóòótọ́ ti ṣe ń kìlọ̀ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run nípa ètò ìṣòwò ńláńlá? (b) Kí ni Ilé Ìṣọ́ fi hàn kedere nípa “Bábílónì Ńlá” lọ́dún 1963?

21 Ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jẹ́ oúnjẹ tẹ̀mí tí ẹrú olóòótọ́ ń pèsè ń bá a lọ láti táṣìírí ìwà ìbàjẹ́ tó rọ̀ mọ́ ètò ìṣòwò ńláńlá, bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe ń kìlọ̀ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run pé kí wọ́n yẹra fún ìfẹ́ ọrọ̀ tí ètò ìṣòwò yìí ń mú kó gbilẹ̀. (Mát. 6:24) Bákan náà làwọn ìtẹ̀jáde wa ṣe ń fi àwọn tó para pọ̀ jẹ́ ètò ìsìn tí í ṣe apá kan lára ètò Sátánì hàn kedere. Lọ́dún 1963, Ilé Ìṣọ́ fi hàn kedere pé kì í ṣe àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì nìkan ni “Bábílónì Ńlá” dúró fún, pé gbogbo ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé ni. Torí náà, bí a ṣe máa rí i lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ní Orí 10 ìwé yìí, a ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ ní gbogbo ilẹ̀ àti àwùjọ èèyàn, tí wọ́n fi “jáde kúrò nínú rẹ̀,” tí wọ́n sì wẹ ara wọn mọ́ kúrò nínú gbogbo àwọn àṣà àti ìṣe ìsìn èké.—Ìṣí. 18:2, 4.

22. Báwo ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe lóye ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà ní Róòmù 13:1 nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní?

22 Àmọ́ ní ti ètò òṣèlú tóun náà jẹ́ apá kan lára ètò Sátánì ńkọ́? Ǹjẹ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ lè lọ́wọ́ sí ogun àti ìjà àwọn orílẹ̀-èdè? Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ohun kan tó ṣáà dá àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú ni pé àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi kò gbọ́dọ̀ pààyàn. (Mát. 26:52) Ṣùgbọ́n bí ọ̀pọ̀ nínú wọn ṣe lóye ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà ní Róòmù 13:1 pé ká ṣègbọràn sí “àwọn aláṣẹ onípò gíga” ni pé kí àwọn wọṣẹ́ ológun, kí wọ́n wọ aṣọ ológun, kí wọ́n tiẹ̀ gbé ohun ìjà; àmọ́ tí wọ́n bá ní kí àwọn pa àwọn ọ̀tá, inú afẹ́fẹ́ ni kí àwọn yìnbọn sí.

23, 24. Báwo la ṣe lóye Róòmù 13:1 nígbà Ogun Àgbáyé Kejì? Òye tó tọ̀nà wo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣamọ̀nà àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi kí wọ́n ní?

23 Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀ lọ́dún 1939, àpilẹ̀kọ kan jáde nínú Ilé Ìṣọ́ tó ṣàlàyé gan-an nípa ohun tí ṣíṣàì dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú àti ogun túmọ̀ sí. Àpilẹ̀kọ náà fi hàn kedere pé àwọn Kristẹni kò ní lọ́wọ́ sí gbogbo ogun àti ìjà àwọn orílẹ̀-èdè ayé Sátánì rárá. Ìtọ́sọ́nà yẹn bọ́ sákòókò gan-an ni! Bí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ṣe bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tó burú jáì tó wà lórí àwọn orílẹ̀-èdè tó ja ogun ìgbà náà nìyẹn. Àmọ́ bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1929, àwọn ìwé wa tún ń ṣàlàyé pé Jèhófà àti Jésù ni àwọn aláṣẹ onípò gíga tí ìwé Róòmù 13:1 sọ, pé kì í ṣe àwọn aláṣẹ ayé rárá. Èyí fi hàn pé òye wa ṣì kù díẹ̀ lórí kókó yẹn.

24 Ẹ̀mí mímọ́ wá ṣamọ̀nà àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tí wọ́n fi ní òye yẹn lọ́dún 1962, nígbà tí wọ́n gbé àwọn àpilẹ̀kọ pàtàkì kan jáde lórí ìwé Róòmù 13:1-7 nínú Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì, èyí tó wà nínú Ile-Iṣọ Na ti January 1 1964 àti February 1, 1964. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àwọn èèyàn Ọlọ́run wá lóye ìlànà ìtẹríba tó ní ààlà tí Jésù ti sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa yìí, pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” (Lúùkù 20:25) Ó wá yé àwọn Kristẹni tòótọ́ pé àwọn aláṣẹ ìjọba ayé yìí ni àwọn aláṣẹ onípò gíga náà, pé àwọn Kristẹni sì gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn. Àmọ́ ṣá o, ṣe la máa tẹrí ba fún àwọn aláṣẹ ìjọba dé ààlà ibi tí àṣẹ wọn mọ. Tí àwọn aláṣẹ ayé bá ni ká ṣe ohun tó máa mú ká ṣàìgbọràn sí Jèhófà Ọlọ́run, ṣe la máa sọ bíi ti àwọn àpọ́sítélì ìgbàanì pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Ní Orí 13 àti 14 ìwé yìí, a máa mọ̀ sí i nípa bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe fi ìlànà tó sọ pé kí Kristẹni má ṣe lọ́wọ́ sí ìṣèlú àti ogun sílò.

Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti máa sọ ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun tó wà nínú Bíbélì!

25. Kí nìdí tó o fi mọyì bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ṣamọ̀nà wa ká lè ní òye nípa Ìjọba Ọlọ́run?

25 Ronú nípa gbogbo ẹ̀kọ́ tí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ti ń kọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run láti ọgọ́rùn-ún ọdún kan sẹ́yìn báyìí. A ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbà tí a gbé Ìjọba Ọlọ́run kalẹ̀ ní ọ̀run àti bí Ìjọba náà ti ṣe pàtàkì tó. Òye wa ṣe kedere nípa ìrètí méjì tí Ọlọ́run fún àwọn olóòótọ́, ìyẹn ni ìrètí lílọ sọ́run àti gbígbé lórí ilẹ̀ ayé. A mọ bí a ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Ìjọba Ọlọ́run síbẹ̀ ká ní ìtẹríba tó ní ààlà fún àwọn aláṣẹ ìjọba ayé. Wá bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ mo lè mọ àwọn òtítọ́ tó ṣeyebíye wọ̀nyí tí kì í bá ṣe pé Jésù Kristi ṣamọ̀nà ẹrú rẹ̀ olóòótọ́ tó wà láyé láti lóye àwọn òtítọ́ náà tí ẹrú náà sì wá kọ́ wa láwọn òtítọ́ yìí?’ Ìbùkún gbáà ló jẹ́ fún wa o pé Kristi àti ẹ̀mí mímọ́ ń ṣamọ̀nà wa!

^ ìpínrọ̀ 3 Ìwé ìwádìí kan sọ pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n pè ní “ṣamọ̀nà” nínú ẹsẹ yẹn túmọ̀ sí “fi ọ̀nà hanni.”

^ ìpínrọ̀ 7 Ṣáájú ìgbà yẹn wọ́n rò pé ìran yìí tọ́ka sí ogun láàárín Ẹ̀sìn Kátólíìkì àti àwọn abọ̀rìṣà Ilẹ̀ Ọba Róòmù tó fi mọ́ àwọn alákòóso wọn.

^ ìpínrọ̀ 10 Ní June 1880, ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower sọ pé ó ní láti jẹ́ pé àwọn Júù nípa tara tí wọ́n máa yí pa dà di Kristẹni tó bá fi máa di ọdún 1914 làwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000]. Àmọ́, lẹ́yìn ìgbà yẹn lọ́dún 1880, wọ́n gbé òye tuntun kan jáde tó sún mọ́ òye tá a ní nípa kókó yìí gan-an lónìí.