Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 11

A Yọ́ Wa Mọ́ Kúrò Nínú Àwọn Àṣà àti Ìwà Kan Ká Lè Jẹ́ Mímọ́ Bí Ọlọ́run Ṣe Jẹ́ Mímọ́

A Yọ́ Wa Mọ́ Kúrò Nínú Àwọn Àṣà àti Ìwà Kan Ká Lè Jẹ́ Mímọ́ Bí Ọlọ́run Ṣe Jẹ́ Mímọ́

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ

Bí Ọba náà ṣe kọ́ àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba rẹ̀ pé kí wọ́n tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run nípa ìwà rere

Fojú inú wò ó pé ò ń gba ẹnu ọ̀nà wọlé síbi àgbàlá òde nínú tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí ti Jèhófà

1. Kí ni Ìsíkíẹ́lì rí tó jẹ́ àgbàyanu fún wa?

KÁ SỌ pé ìwọ náà rí ohun tí wòlíì Ìsíkíẹ́lì rí ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ ọdún sẹ́yìn, kí lo máa ṣe? Rò ó wò ná: O sún mọ́ tẹ́ńpìlì gìrìwò kan tó ń dán gbinrin. Áńgẹ́lì alágbára kan ti wà ní sẹpẹ́ tó máa mú ẹ rìn yí ká ilé àgbàyanu yìí! O bẹ̀rẹ̀ sí í gun àtẹ̀gùn onípele méje tó já sí ọ̀kan lára ẹnu ọ̀nà mẹ́ta tó wọ tẹ́ńpìlì náà. Ńṣe lò ń wo àwọn ẹnu ọ̀nà yìí tìyanu-tìyanu. Wọ́n ga tó ilé alájà mẹ́wàá. O rí àwọn ẹ̀ṣọ́ tó dúró wámúwámú láwọn ẹnu ọ̀nà náà. Àwọn ọwọ̀n tó wà nínú tẹ́ńpìlì náà dà bí igi ọ̀pẹ rírẹwà tó dúró sán-ún.—Ìsík. 40:1-4, 10, 14, 16, 22; 41:20.

2. (a) Kí ni tẹ́ńpìlì tẹ̀mí náà ṣàpẹẹrẹ? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.) (b) Kí la lè kọ́ lára àwọn apá tó wà ní àwọn ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì náà?

2 Bí tẹ́ńpìlì tẹ̀mí tí Ìsíkíẹ́lì rí lójú ìran ṣe rí nìyẹn. Wòlíì Ìsíkíẹ́lì ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà tó kún rẹ́rẹ́ tó fi jẹ́ pé àlàyé rẹ̀ gba orí 40 sí orí 48 nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì. Tẹ́ńpìlì yìí ń ṣàpẹẹrẹ ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn mímọ́. Apá kọ̀ọ̀kan nínú tẹ́ńpìlì náà ló ní ohun tó dúró fún nínú ìjọsìn wa láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. * Kí làwọn ẹnu ọ̀nà gíga náà dúró fún? Wọ́n ń rán wa létí pé àwọn tó máa wọlé sínú ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn mímọ́ gbọ́dọ̀ pa àwọn ìlànà gíga Ọlọ́run mọ́. Kódà bí àwọn ọwọ̀n ilé náà ṣe dúró bí igi ọ̀pẹ ti kókó yìí lẹ́yìn, torí pé tí Bíbélì bá mẹ́nu kan igi ọ̀pẹ, nígbà míì ó máa ń tọ́ka sí ẹni tó jẹ́ adúróṣánṣán. (Sm. 92:12) Àwọn ẹ̀ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ńkọ́? Ó ṣe kedere pé àwọn tí wọ́n kọ̀ láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run kò ní lè wọlé sínú ìjọsìn mímọ́ tó ń fúnni ní ìyè yìí.—Ìsík. 44:9.

3. Kí nìdí tó fi gba pé kí á máa yọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi mọ́ látìgbàdégbà?

3 Báwo ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣe ń ṣẹ? Bá a ṣe sọ ní Orí 2 ìwé yìí, Jèhófà lo Kristi kó lè yọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ mọ́ lọ́nà àkànṣe láti ọdún 1914 títí wọ ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919. Ṣé ìyọ́mọ́ náà ti parí sígbà yẹn ni? Rárá o! Láti bí ọgọ́rùn-ún ọdún tó kọjá ni Kristi ti ń rí i dájú pé a ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà mímọ́ tí Jèhófà fi lélẹ̀ nípa ìwà rere. Torí náà, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nílò ìyọ́mọ́ látìgbàdégbà. Kí nìdí? Ìdí ni pé bí Kristi ṣe ń kó àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jọ látinú ayé tí ìwàkiwà kúnnú rẹ̀ yìí, bẹ́ẹ̀ náà ni Sátánì ń sapá láti fà wọ́n sínú ẹrẹ̀ ìwà ìbàjẹ́. (Ka 2 Pétérù 2:20-22.) Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀nà mẹ́ta tí Kristi gbà ń yọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ́ látìgbàdégbà. Lákọ̀ọ́kọ́, a máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn àtúnṣe tó ti bá àwọn àṣà àtàwọn ìwà kan, lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun pàtàkì kan táá jẹ́ kí ìjọ máa wà ní mímọ́, ní paríparí rẹ̀, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìdílé.

Bá A Ṣe Ń Yọ́ Wa Mọ́ Kúrò Nínú Àwọn Àṣà àti Ìwà Kan Láti Àwọn Ọdún Yìí Wá

4, 5. Ọgbọ́nkọ́gbọ́n wo ni Sátánì ti ń lò tipẹ́tipẹ́, kí ló sì ti yọrí sí?

4 Àwọn èèyàn Jèhófà ò fìgbà kan fi ọwọ́ kékeré mú ọ̀rọ̀ ìwà rere. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ìtọ́ni tó ṣe kedere la máa ń fúnni lórí kókó yìí. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ díẹ̀ ná.

5 Ìṣekúṣe. Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìbálòpọ̀ jẹ́ fún àwọn tọkọtaya, ó sì fẹ́ kó jẹ́ mímọ́ àtèyí tó ń buyì kúnni. Sátánì ń wá bó ṣe máa sọ ẹ̀bùn tó ṣeyebíye yẹn dìdàkudà. Ó fẹ́ sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin, kó lè máa fa ìkọ̀sẹ̀ fáwọn èèyàn Jèhófà, èyí tó lè mú kí Ọlọ́run bínú sí wọn. Sátánì lo ọgbọ́nkọ́gbọ́n yìí nígbà ayé Báláámù, aburú ló sì gbẹ̀yìn rẹ̀. Ó ti wá ń lo ọgbọ́nkọ́gbọ́n yẹn gan-an ju ti ìgbàkígbà rí lọ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.—Núm. 25:1-3, 9; Ìṣí. 2:14.

6. Ẹ̀jẹ́ wo ló wà nínú Ilé Ìṣọ́, báwo ni wọ́n ṣe lò ó, kí sì nìdí tí wọn ò fi lò ó mọ́ nígbà tó yá? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

6 Ká lè borí ogun tí Sátánì ń gbé yìí, Ilé Ìṣọ́ June 15, 1908, lédè Gẹ̀ẹ́sì mẹ́nu kan ẹ̀jẹ́ kan táwọn èèyàn Ọlọ́run jẹ́, tó sọ lápá kan pé: “Màá máa hùwà tó bójú mu sí ọkùnrin tàbí obìnrin nígbà gbogbo àti níbi gbogbo, bí mo ṣe máa ṣe sí wọn ní gbangba náà ni màá máa ṣe sí wọn táwọn èèyàn ò bá sí níbẹ̀.” * Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò fi dandan mú ẹnikẹ́ni láti jẹ́ ẹ̀jẹ́ náà, ọ̀pọ̀ ló jẹ́ ẹ̀jẹ́ náà, tí wọ́n fi orúkọ wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì tẹ̀ ẹ́ jáde nínú Zion’s Watch Tower. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ètò Ọlọ́run rí i pé bí ẹ̀jẹ́ yìí tiẹ̀ ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́, ó ti fẹ́ máa di ọ̀rọ̀ ẹnu lásán, torí náà, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ wọn ò lò ó mọ́. Àmọ́ ṣá o, ìlànà ìwà rere tó wà nínú ẹ̀jẹ́ náà kò yí pa dà títí dòní.

7. Ìṣòro wo ni Ilé Ìṣọ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ọdún 1935, ìtọ́ni tó ṣe kedere wo ló sì túbọ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀?

7 Ńṣe ni àtakò Sátánì túbọ̀ ń lágbára sí i. Ilé Ìṣọ́ March 1, 1935 lédè Gẹ̀ẹ́sì, dìídì sọ̀rọ̀ lórí ìṣòro kan tó ń gbèèràn láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run. Àwọn kan gbà pé táwọn bá ṣáà ti ń wàásù, kò pọn dandan káwọn máa tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà lórí ìwà rere táwọn bá dá wà. Ilé Ìṣọ́ yẹn sọ ní tààràtà pé: “Ó yẹ ká máa rántí pé kéèyàn kàn máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù nìkan kò tó. Aṣojú Jèhófà ni àwa ẹlẹ́rìí Jèhófà, ojúṣe wa sì ni láti máa ṣojú Jèhófà àti ìjọba rẹ̀ lọ́nà tó tọ́.” Àpilẹ̀kọ yẹn wá fún àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ìtọ́ni tó ṣe kedere lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó àti ìbálòpọ̀, èyí sì jẹ́ kí wọ́n lè máa “sá fún àgbèrè.”—1 Kọ́r. 6:18.

8. Kí nìdí tí Ilé Ìṣọ́ fi ṣàlàyé léraléra pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí àgbèrè gbòòrò ju ìbálòpọ̀ nìkan lọ?

8 Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, léraléra ni Ilé Ìṣọ́ ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà por·neiʹa tá a túmọ̀ sí àgbèrè nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì ṣe gbòòrò tó. Ọ̀rọ̀ yẹn ò mọ sí ìbálòpọ̀ nìkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, por·neiʹa kan ìṣekúṣe lọ́nà èyíkéyìí, ó kan gbogbo ìwà ìṣekúṣe tó ń wáyé nílé àwọn aṣẹ́wó. Èyí tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ààbò fáwọn ọmọlẹ́yìn Kristi kí wọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ aburú tí ìṣekúṣe máa ń fà, èyí tó ti ṣàkóbá fún ọ̀pọ̀ nínú ayé lónìí.—Ka Éfésù 4:17-19.

9, 10. (a) Àṣà wo ni Ilé Ìṣọ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ọdún 1935? (b) Kí ni Bíbélì sọ nípa ìgbà tó yẹ kéèyàn mu ọtí àti ìwọ̀n tó yẹ kéèyàn mu?

9 Ọtí àmujù. Ilé Ìṣọ́ March 1, 1935, lédè Gẹ̀ẹ́sì tún sọ̀rọ̀ nípa àṣà míì, ó ní: “A tún kíyè sí i pé lẹ́yìn táwọn kan bá ti mu [ọtí] tán, wọ́n máa ń lọ sóde ẹ̀rí, wọ́n sì máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ míì nínú ètò Ọlọ́run. Àwọn ìgbà wo ni Ìwé Mímọ́ sọ pé èèyàn lè mu ọtí? Ǹjẹ́ ó dáa kéèyàn mu ọtí débi táá fi wá ṣàkóbá fún onítọ̀hún lẹ́nu iṣẹ́ Olúwa?”

10 Ilé Ìṣọ́ yẹn dáhùn ìbéèrè náà, ó sì jíròrò ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ lórí ìgbà téèyàn lè mu ọtí àti ìwọ̀n tó yẹ kéèyàn mu. Bíbélì kò sọ pé ó burú kéèyàn mu wáìnì àti àwọn ọtí míì níwọ̀nba, àmọ́ ó sọ pé ọtí àmujù burú jáì. (Sm. 104:14, 15; 1 Kọ́r. 6:9, 10) Ǹjẹ́ ó yẹ kí ìránṣẹ́ Ọlọ́run mu ọtí nígbà tó bá fẹ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́? Ó ti pẹ́ tí ètò Ọlọ́run ti ń rán àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run létí ìtàn àwọn ọmọ Áárónì tí Ọlọ́run pa torí pé wọ́n rú ẹbọ tí kò bá ìlànà mu lórí pẹpẹ Ọlọ́run. Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tó jọ pé ó sún àwọn ọkùnrin yẹn dé ìdí ohun àìtọ́ tí wọ́n ṣe, torí kété lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ni Ọlọ́run ṣe òfin pé àlùfáà èyíkéyìí kò gbọ́dọ̀ mu ọtí tí wọ́n bá máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́. (Léf. 10:1, 2, 8-11) Lóde òní, ìlànà tó wà nínú òfin Ọlọ́run yìí ni àwa ọmọlẹ́yìn Kristi ń tẹ̀ lé, ní ti pé a máa ń yẹra fún ọtí mímu tí a bá fẹ́ ṣe àwọn iṣẹ́ tó jẹ́ mọ́ iṣẹ́ ìsìn mímọ́.

11. Kí nìdí tó fi jẹ́ ìbùkún pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi ní òye tó ṣe kedere sí i lórí ọ̀rọ̀ sísọ ọtí di bárakú?

11 Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ìbùkún ló jẹ́ fún àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi láti ní òye tó ṣe kedere sí i lórí ohun tó túmọ̀ sí láti sọ ọtí di bárakú, ìyẹn sì kan pé kéèyàn máa fìgbà gbogbo mu ọtí, débi pé ara rẹ̀ kò ní balẹ̀ tí kò bá rí ọtí mu. A dúpẹ́ fún oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sákòókò tá à ń rí gbà, torí pé ọ̀pọ̀ ló ti bọ́ nínú ìgbèkùn ọtí àmujù. Ọ̀pọ̀ ló sì ti gba ìrànlọ́wọ́ tí kò jẹ́ kí wọ́n kó sínú ìṣòro yẹn rárá. Kò sídìí tó fi yẹ kẹ́nì kan jẹ́ kí àmujù ọtí sọ òun di ẹni yẹ̀yẹ́ tàbí kó ṣàkóbá fún ìdílé rẹ̀. Èyí tó wá burú jù lọ ni pé ọtí àmujù lè gba ìjọsìn mímọ́ sí Jèhófà mọ́ni lọ́wọ́.

“Báwo la ṣe rò pé ó máa rí ná, kí èéfín sìgá máa rú túú lẹ́nu Olúwa wa tàbí kó máa fi ohun tó lè sọni di ẹlẹ́gbin sẹ́nu rẹ̀?” —C. T. Russell

12. Ojú wo làwọn ìránṣẹ́ Kristi fi ń wo lílo tábà, kódà kó tó di pé ọjọ́ ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀?

12 Lílo tábà. Kódà, kó tó di pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn bẹ̀rẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ Kristi ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọminú sí lílo tábà. Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, arákùnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Charles Capen rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó kọ́kọ́ pàdé Arákùnrin Charles Taze Russell ní apá ìparí ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún. Nígbà yẹn, Arákùnrin Capen wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá. Òun àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ méjì wà lórí àtẹ̀gùn ní Ilé Bíbélì tó wà ní ìlú Allegheny, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania. Bí Arákùnrin Russell ṣe ń kọjá, ó bi wọ́n pé: “Ṣé kì í ṣe pé ẹ̀ ń mu sìgá? Mò ń gbóòórùn sìgá.” Wọ́n dá a lóhùn pé àwọn ò mu sìgá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ kó dá wọn lójú pé Russell ò fi ojú tó dára wo sìgá mímu. Russell sọ̀rọ̀ lórí 2 Kọ́ríńtì 7:1 nínú Ilé Ìṣọ́ August 1, 1895, lédè Gẹ̀ẹ́sì, ó ní: “Tí Kristẹni èyíkéyìí bá ń lo tábà ní ọ̀nà èyíkéyìí, mi ò rí bí ìyẹn ṣe máa fi ògo fún Ọlọ́run tàbí bó ṣe máa ṣe òun fúnra rẹ̀ láǹfààní. . . . Báwo la ṣe rò pé ó máa rí ná, kí èéfín sìgá máa rú túú lẹ́nu Olúwa wa tàbí kó máa fi ohun tó lè sọni di ẹlẹ́gbin sẹ́nu rẹ̀?”

13. Àṣà wo la yọ́ wa mọ́ kúrò nínú rẹ̀ lọ́dún 1973?

13 Lọ́dún 1935, Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì pe tábà ní “ewéko ẹlẹ́gbin,” ó sì sọ pé kò sí ẹnikẹ́ni tó bá ń lo tábà tàbí tó ń mu ún tó lè máa bá a nìṣó láti jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tàbí tó lè jẹ́ aṣojú ètò Ọlọ́run lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn aṣáájú-ọ̀nà tàbí arìnrìn-àjò. Lọ́dún 1973, a tún yọ́ wa mọ́ kúrò nínú àṣà míì. Ilé Ìṣọ́ June 1 ṣàlàyé pé kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan tó ń lọ́wọ́ nínú àṣà tó ń ṣekú pani, tó ń sọni di ẹlẹ́gbin tó sì lè pa àwọn míì lára tó lè jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ìjọ. Ó ní ṣe ni ká yọ àwọn tó bá kọ̀ láti jáwọ́ nínú àṣà lílo tábà kúrò nínú ìjọ. * Ìgbésẹ̀ pàtàkì míì nìyí tí Kristi gbé láti yọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ́.

14. Kí ni ìlànà Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀, báwo sì ni ìfàjẹ̀sínilára ṣe wá gbalẹ̀ gbòde lónìí?

14 Jíjẹ ẹ̀jẹ̀ tàbí gbígbà á sára. Nígbà ayé Nóà, Ọlọ́run sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀. Nínú Òfin tó fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ó tún ohun kan náà sọ, ó sì tún sọ pé kí ìjọ Kristẹni “ta kété . . . sí ẹ̀jẹ̀.” (Ìṣe 15:20, 29; Jẹ́n. 9:4; Léf. 7:26) Àmọ́ kò yà wá lẹ́nu pé Sátánì ti mú kí ọ̀pọ̀ lóde òní ṣàìgbọràn sí òfin Ọlọ́run yẹn. Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kọkàndínlógún, àwọn dókítà bẹ̀rẹ̀ sí í lo ẹ̀jẹ̀ nínú ìtọ́jú ìṣègùn, àmọ́ àṣà yẹn tún wá wọ́pọ̀ gan-an nígbà tí wọ́n ṣàwárí pé ẹ̀jẹ̀ ẹni méjì lè bára mu. Lọ́dún 1937, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gba ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn, wọ́n sì ń tọ́jú rẹ̀ pa mọ́. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àṣà yìí tún wá wọ́pọ̀ gan-an, kò sì pẹ́ tí àṣà ìfàjẹ̀sínilára fi di ohun tó gbòde kárí ayé.

15, 16. (a) Kí ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìfàjẹ̀sínilára? (b) Ìrànlọ́wọ́ wo ni àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi rí gbà lórí ọ̀rọ̀ ìfàjẹ̀sínilára àti ìtọ́jú ìṣègùn láìlo ẹ̀jẹ̀, kí ló sì ti jẹ́ àbájáde rẹ̀?

15 Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1944 ni Ilé Ìṣọ́ ti jẹ́ ká mọ̀ pé gbígba ẹ̀jẹ̀ sára kò yàtọ̀ sí pé èèyàn ń jẹ ẹ̀jẹ̀. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ètò Ọlọ́run wá ṣe àlàyé tó túbọ̀ ṣe kedere lórí kókó tí a rí nínú Bíbélì yìí. Nígbà tó fi máa di ọdún 1951, wọ́n gbé àwọn ìbéèrè àti ìdáhùn kan jáde kó lè ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá lọ rí dókítà. Kárí ayé, àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn Kristi ń fi hàn pé àwọn jẹ́ onígboyà, kódà nígbà táwọn èèyàn bá ń fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà, tí wọ́n ń kanra mọ́ wọn tàbí tí wọ́n tiẹ̀ ṣe inúnibíni sí wọn torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Àmọ́ ṣá o, Kristi ń bá a nìṣó láti máa darí ètò rẹ̀ kó lè máa pèsè ìrànwọ́ tí wọ́n nílò. Wọ́n tẹ àwọn ìwé pẹlẹbẹ kan jáde àtàwọn àpilẹ̀kọ́ tó ṣàlàyé tó kún rẹ́rẹ́ lórí kókó yìí.

16 Lọ́dún 1979, àwọn alàgbà kan bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ilé ìwòsàn kí wọ́n lè túbọ̀ ṣàlàyé ohun tá a gbà gbọ́ fún àwọn dókítà àti ìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mu tá a fi gbà gbọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì tún sọ àwọn ọ̀nà míì tí wọ́n lè gbà tọ́jú aláìsàn dípò ìfàjẹ̀sínilára. Lọ́dún 1980, àwọn alàgbà láti ìlú mọ́kàndínlógójì [39] lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gba àkànṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí iṣẹ́ yìí. Nígbà tó yá, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé kí Àwọn Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ karí ayé. Ǹjẹ́ àwọn ìsapá yìí ṣe àṣeyọrí èyíkéyìí látọdún yìí wá? Lónìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn onímọ̀ ìṣègùn, títí kan àwọn dókítà, àwọn oníṣẹ́ abẹ àtàwọn dókítà apàmọ̀lára ni wọ́n ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n bá ṣàìsàn, wọ́n ń bọ̀wọ̀ fún ìpinnu tá a ṣe láti gba ìtọ́jú láìlo ẹ̀jẹ̀. Ọ̀pọ̀ ilé ìwòsàn ló túbọ̀ ń gbà láti máa tọ́jú aláìsàn láìlo ẹ̀jẹ̀, àwọn míì lára wọn tiẹ̀ gbà pé ọ̀nà ìtọ́jú ìṣègùn yẹn ló dára jù lọ. Ǹjẹ́ inú wa ò dùn láti mọ àwọn ọ̀nà tí Jésù gbà ń dáàbò bo àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́ Sátánì bó ṣe ń sapá láti kó èèràn ràn wọ́n?—Ka Éfésù 5:25-27.

Ọ̀pọ̀ ilé ìwòsàn ló túbọ̀ ń gbà láti máa tọ́jú aláìsàn láìlo ẹ̀jẹ̀, àwọn míì lára wọn tiẹ̀ gbà pé ọ̀nà ìtọ́jú ìṣègùn yẹn ló dára jù lọ

17. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì ọ̀nà tí Kristi gbà ń yọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ́?

17 Ó máa dáa ká bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ a mọyì ọ̀nà tí Kristi gbà ń yọ́ àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ́, tó ń kọ́ wa bá a ṣe máa fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà gíga Jèhófà?’ Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká fi sọ́kàn pé Sátánì ńṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kó lè mú ká yapa sí Jèhófà àti Jésù, ńṣe ló fẹ́ ká máa fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìlànà Ọlọ́run lórí ìwà rere. Ká lè borí ogun tí Sátánì ń gbé, ìgbà gbogbo ni ètò Jèhófà máa ń fìfẹ́ kìlọ̀ fún wa, tí wọ́n sì máa ń rán wa létí pé ìwà ìbàjẹ́ kúnnú ayé yìí. Ẹ jẹ́ ká wà lójúfò, ká máa kọbi ara sí ìmọ̀ràn, ká sì máa ṣègbọràn sírú àwọn ìkìlọ̀ àti ìránnilétí bẹ́ẹ̀.—Òwe 19:20.

À Ń Dáàbò Bo Ìjọ Lọ́wọ́ Ìwà Ìbàjẹ́

18. Tó bá kan ọ̀rọ̀ àwọn tó mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sáwọn ìlànà Ọlọ́run, ìránnilétí tó ṣe kedere wo la rí nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí?

18 Ọ̀nà kejì tá a gbà ń yọ́ wa mọ́ nínú àwọn ìwà àtàwọn àṣà kan ni pé a máa ń gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan láti mú kí ìjọ wà ní mímọ́. Ó ṣeni láàánú pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó ṣàdéhùn láti máa tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà lórí ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù, tí wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́ sí Ọlọ́run ló ń pa àdéhùn wọn mọ́ délẹ̀délẹ̀. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn kan yẹ àdéhùn wọn, wọ́n sì mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sáwọn ìlànà yẹn. Kí ló yẹ ká ṣe fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀? A lè rí ohun kan nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa tẹ́ńpìlì tẹ̀mí tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ orí yìí. Ṣé ẹ rántí àwọn ẹnu ọ̀nà gíga yẹn? Àwọn ẹ̀ṣọ́ wà lẹ́nu ọ̀nà kọ̀ọ̀kan, wọ́n dúró wámúwámú. Àwọn ẹ̀ṣọ́ ń dáàbò bo tẹ́ńpìlì náà, iṣẹ́ wọn ni láti má ṣe jẹ́ kí àwọn “aláìdádọ̀dọ́ ọkàn-àyà” wọ inú tẹ́ńpìlì náà. (Ìsík. 44:9) Ìránnilétí tó ṣe kedere nìyẹn, pé àwọn tó bá ń sapá láti gbé ìgbé ayé wọn níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà mímọ́ Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ ìwà rere nìkan ló láǹfààní láti máa jọ́sìn Jèhófà lọ́nà mímọ́. Bákan náà, lóde òní, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló láǹfààní láti jọ́sìn pẹ̀lú àwọn ará nínú ìjọ Kristẹni.

19, 20. (a) Báwo ni Kristi ṣe ń ran àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ kí wọ́n lè máa sunwọ̀n sí i lórí bí wọ́n ṣe ń bójú tó àwọn tó bá hùwà àìtọ́ tó burú jáì? (b) Kí ni ìdí mẹ́ta tá a fi máa ń yọ àwọn oníwà àìtọ́ tí kò ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ?

19 Lọ́dún 1892, Ilé Ìṣọ́ lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ pé “ojúṣe wa (bíi Kristẹni) ni láti rí i pé àwọn tó bá sọ pé Kristi kò fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà [owó ìtanràn tó ṣe rẹ́gí] nítorí gbogbo èèyàn, ni a yọ lẹ́gbẹ́, yálà wọ́n sọ bẹ́ẹ̀ ní gbangba tàbí tí ìwà wọn fi hàn bẹ́ẹ̀.” (Ka 2 Jòhánù 10.) Lọ́dún 1904, ìwé The New Creation sọ pé ewu ńlá làwọn tó kọ̀ láti jáwọ́ nínú ìwà ìbàjẹ́ jẹ́ fún ìjọ. Nígbà yẹn, gbogbo ìjọ ló máa ń péjú tí “ṣọ́ọ̀ṣì bá fẹ́ ṣe ìgbẹ́jọ́” àwọn tó bá hùwà àìtọ́. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan nirú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń wáyé. Lọ́dún 1944, Ilé Ìṣọ́ sọ pé àwọn arákùnrin kan tó wà nípò àbójútó nìkan ni kó máa bójú tó irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Lọ́dún 1952, ètò Ọlọ́run gbé ìlànà tó bá Bíbélì mu jáde nínú Ilé Ìṣọ́ lórí bó ṣe yẹ ká máa bójú tó ìgbẹ́jọ́, ó sì sọ ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa yọ àwọn tí kò bá ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ. Ìdí náà ni láti mú kí ìjọ wà ní mímọ́.

20 Látìgbà yẹn wá ni Kristi ti ń ran àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní òye tó ṣe kedere sí i kí wọ́n sì lè máa sunwọ̀n sí i lórí bí wọ́n ṣe lè máa bójú tó àwọn tó bá hùwà àìtọ́. Àwọn alàgbà ìjọ ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó jíire lórí bí wọ́n ṣe lè bójú tó àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìgbẹ́jọ́ lọ́nà tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu, kí wọ́n lè máa ṣe ìdájọ́ òdodo, síbẹ̀ kí wọ́n fi àánú hàn. Lóde òní, ó kéré tán, a rí ìdí mẹ́ta tó ṣe kedere tó fi yẹ ká yọ ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí kò ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ: (1) láti mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ Jèhófà, (2) láti dáàbò bo ìjọ kí ìwà àìtọ́ tó burú jáì má bàa kó èèràn ran ìjọ, àti (3) tó bá ṣeé ṣe, láti mú kí oníwà àìtọ́ náà ronú pìwà dà.

21. Báwo ló ṣe jẹ́ àǹfààní fún àwọn èèyàn Ọlọ́run pé à ń yọ àwọn oníwà àìtọ́ tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́?

21 Ǹjẹ́ ìwọ náà rí i pé ó ṣàǹfààní fún àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lóde òní bá a ṣe ń yọ àwọn oníwà àìtọ́ tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́? Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn oníwà àìtọ́ sábà máa ń ṣàkóbá fún orílẹ̀-èdè náà, kódà nígbà míì wọ́n máa ń pọ̀ ju àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì fẹ́ ṣe ohun tó tọ́. Ìdí nìyẹn tí orílẹ̀-èdè náà fi sábà máa ń mú ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà, ìyẹn kì í sì í jẹ́ kí wọ́n rí ojú rere Ọlọ́run. (Jer. 7:23-28) Àmọ́ lóde òní, àwùjọ ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹni tẹ̀mí làwọn èèyàn Jèhófà. Torí pé a máa ń yọ àwọn oníwà àìtọ́ tí kò ronú pìwà dà kúrò láàárín wa, Sátánì ò ní lè lò wọ́n láti fa jàǹbá púpọ̀ sí i nínú ìjọ, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kó àbàwọ́n bá gbogbo ìjọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwọ̀nba ni ipa tí wọ́n á lè ní lórí ìjọ. Ìdí nìyẹn tó fi dá wa lójú pé gẹ́gẹ́ bí àwùjọ, a ó rí ojú rere Jèhófà. Rántí pé Jèhófà ṣèlérí pé: “Ohun ìjà yòówù tí a bá ṣe sí ọ kì yóò ṣe àṣeyọrí sí rere.” (Aísá. 54:17) Ǹjẹ́ a máa ń fi tọkàntọkàn ṣètìlẹ́yìn fun àwọn alàgbà tí wọ́n ní ojúṣe ńlá láti máa bójú tó àwọn ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́?

À Ń Ṣe Ohun Tó Fògo fún Ẹni Tí Olúkúlùkù Ìdílé Gba Orúkọ Wọn Látọ̀dọ̀ Rẹ̀

22, 23. Kí nìdí tá a fi mọrírì àwọn Kristẹni bíi tiwa tí wọ́n gbé láyé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ogún, síbẹ̀, ẹ̀rí wo ló fi hàn pé ó ṣì yẹ kí wọ́n wà kíyè sára kí ojúṣe ti inú ìjọ má ṣe pa ti ìdílé lára?

22 Ọ̀nà kẹta tí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ń gbà jàǹfààní nínú ìyọ́mọ́ tó ń bá a nìṣó yìí jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó àti ìdílé. Ǹjẹ́ àtúnṣe ti bá ọwọ́ tá a fi ń mú ọ̀rọ̀ ìdílé láti àwọn ọdún yìí wá? Bẹ́ẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá kà nípa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ogún, ẹ̀mí ìyọ̀ǹda ara-ẹni tí wọ́n ní máa ń wú wa lórí, ó sì máa ń yà wá lẹ́nu gan-an. A mọrírì rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí wọ́n ṣe fi iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wọn. Àmọ́ lẹ́sẹ̀ kan náà, ó ṣe kedere pé ó yẹ kí wọ́n túbọ̀ kíyè sára kí ojúṣe kan má pa èkejì lára. Lọ́nà wo?

23 Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé kí àwọn arákùnrin rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn fún ọ̀pọ̀ oṣù nígbà míì, torí iṣẹ́ ìwàásù tàbí iṣẹ́ arìnrìn-àjò. Nígbà míì, a máa ń rọ àwọn ará pé kí wọ́n wà ní láì lọ́kọ tàbí láì láya, àmọ́ ọ̀nà tí a máa ń gbà sọ ọ́ ti le ju ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lọ. Bákan náà, a kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn tọkọtaya Kristẹni ṣe lè ṣe ara wọn lọ́kan. Ǹjẹ́ bí ọ̀ràn ṣe rí nìyẹn láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lónìí? Rárá o!

A kì í jẹ́ kí àwọn ojúṣe wa nínú ètò Ọlọ́run pa ojúṣe wa nínú ìdílé lára

24. Báwo ni Kristi ṣe ran àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ máa fi ojú tó tọ́ wo ìgbéyàwó àti ìdílé?

24 Lóde òní, a kì í jẹ́ kí àwọn ojúṣe wa nínú ètò Ọlọ́run pa ojúṣe wa nínú ìdílé lára. (Ka 1 Tímótì 5:8.) Bákan náà, Kristi ń rí i dájú pé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé ń rí ìrànlọ́wọ́ tí kò fì síbì kan gbà látìgbàdégbà látinú Ìwé Mímọ́ nípa ìgbéyàwó àti ọ̀rọ̀ ìdílé. (Éfé. 3:14, 15) Lọ́dún 1978, ètò Ọlọ́run gbé ìwé Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ jáde. Ní nǹkan bí ọdún méjìdínlógún lẹ́yìn náà, ìwé mìíràn tún jáde, ìyẹn ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Kò tán síbẹ̀ o, Ilé Ìṣọ́ tún ń gbé onírúurú àpilẹ̀kọ jáde tó dá lórí bí àwọn tọkọtaya ṣe lè fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò nínú ìgbéyàwó wọn.

25-27. Láti àwọn ọdún yìí wá, báwo ni ètò Ọlọ́run ṣe ń fún àwọn ọmọ ní àfiyèsí tó pọ̀ gan-an níbàámu pẹ̀lú ọjọ́ orí wọn?

25 Àwọn ọ̀dọ́ ńkọ́? Láti àwọn ọdún yìí wá la ti túbọ̀ ń fún àwọn ọ̀dọ́ láfiyèsí. Ọjọ́ pẹ́ tí ètò Ọlọ́run ti ń pèsè àwọn ohun rere fún àwọn ọmọ ní ìbámu pẹ̀lú ọjọ́ orí wọn, ohun tó dà bí ìsun omi térétéré nígbà yẹn ti wá di odò tó ń ṣàn báyìí. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn The Golden Age gbé àpilẹ̀kọ kan tó ń jẹ́ “Juvenile Bible Study,” ìyẹn ẹ̀kọ́ Bíbélì fún àwọn ọmọdé jáde, lọ́dún 1919 sí 1921. Èyí tó tẹ̀ lé e ni ìwé pẹlẹbẹ kan tó ń jẹ́ The Golden Age ABC tó jáde lọ́dún 1920 àti ìwé Children tó jáde lọ́dún 1941. Ìwé Fifetisilẹ si Olukọ Nla Na jáde lọ́dún 1971. Lọ́dún 1976, a gbé ìwé Igba Ewe rẹBi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ jáde. A sì gbé Iwe Itan Bibeli Mi jáde lọ́dún 1978. Lọ́dún 1982, ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” bẹ̀rẹ̀ sí í jáde nínú ìwé ìròyìn Jí!, òun ló sì wá para pọ̀ di ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń BéèrèAwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, tó jáde lọ́dún 1989.

Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi gba ìwé pẹlẹbẹ Ẹ̀kọ́ Bíbélì ní àpéjọ àgbègbè yìí lórílẹ̀-èdè Jámánì

26 Ní báyìí, a ti ní apá kìíní àti apá kejì ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé, èyí tó bóde mu, síbẹ̀, a ṣì ń gbé àwọn àpilẹ̀kọ náà jáde lórí Ìkànnì jw.org. A tún ní ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Ìkànnì wa kún fún oríṣiríṣi apá tá a ṣe fún àwọn ọmọdé, irú bí ìtàn àwọn kan nínú Bíbélì tá a ṣe sórí káàdì, àwọn eré ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà fáwọn ọ̀dọ́ àtàwọn ọmọ, àwọn eré ta-ń-mọ̀-ọ́n, fídíò àti ìtàn Bíbélì tá a fi àwòrán ṣàlàyé, bákan náà làwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó wà fáwọn ọmọ tí ọjọ́ orí wọn wà ní ọdún mẹ́ta sísàlẹ̀. Dájúdájú, bọ́rọ̀ àwọn ọmọdé ṣe rí lára Kristi látìgbà tó ti fà wọ́n mọ́ra ní ọgọ́rùn-ún kìíní náà ló ṣì ṣe rí lára rẹ̀ lónìí. (Máàkù 10:13-16) Ó fẹ́ káwọn ọmọdé tí wọ́n wà láàárín wa mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, kí wọ́n sì máa rí oúnjẹ tẹ̀mí jẹ déédéé.

27 Jésù tún fẹ́ ká dáàbò bo àwọn ọmọ lọ́wọ́ ewu. Bí ayé yìí ṣe túbọ̀ ń rì sínú ìwà ìbàjẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìṣòro bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe túbọ̀ ń peléke sí i. Torí náà, ètò Ọlọ́run ti gbé àwọn ìsọfúnni tó ṣe kedere tó sì ṣe tààràtà jáde kó lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ àṣà burúkú yìí. *

28. (a) Níbàámu pẹ̀lú ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí, kí la gbọ́dọ̀ máa ṣe kí ìjọsìn wa lè jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run? (b) Kí lo pinnu pé wàá máa ṣe báyìí?

28 Ǹjẹ́ inú wa ò dùn bá a ṣe ṣàyẹ̀wò lórí bí Kristi ṣe ń bá a nìṣó láti yọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ́, tó ń kọ́ wọn kí wọ́n lè máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ìlànà gíga tí Jèhófà fún wọn, kí wọ́n máa fi sílò nínu ìgbésí ayé wọn, kí wọ́n sì máa jàǹfààní nínú rẹ̀? Jẹ́ ká tún wo tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran. Ṣé ẹ rántí ẹnu ọ̀nà gíga yẹn? Lóòótọ́, tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ni, kì í ṣe tẹ́ńpìlì tá a lè fojú rí. Síbẹ̀, ǹjẹ́ a gbà pé ó wà lóòótọ́? Tá a bá ń lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, tá à ń ka Bíbélì tàbí tá à ń lọ wàásù, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé a ti wọnú tẹ́ńpìlì náà. Àwọn nǹkan téèyàn ń ṣe tó lè hàn sí gbogbo èèyàn nìyẹn. Èèyàn lè máa ṣe àwọn nǹkan yẹn síbẹ̀ kó má wọ inú tẹ́ńpìlì Jèhófà tó bá jẹ́ alágàbàgebè. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé bá a ṣe ń ṣe àwọn nǹkan yẹn náà là ń tẹ̀ lé ìlànà gíga Jèhófà, tá a sì ń kópa nínú ìjọsìn mímọ́ pẹ̀lú ọkàn tí ó tọ́, a jẹ́ pé inú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí la wà tá a ti ń jọ́sìn yẹn, ìyẹn sì ni ètò tí Jèhófà Ọlọ́run ṣe ká lè máa ṣe ìjọsìn mímọ́! Ẹ jẹ́ ká máa gbé àǹfààní yẹn gẹ̀gẹ̀ títí láé. Bákan náà, ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti máa fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà òdodo Jèhófà kó lè máa hàn nínú ìwà àti ìṣe wa pé Jèhófà jẹ́ mímọ́!

^ ìpínrọ̀ 2 Lọ́dún 1932, Apá Kejì ìwé Vindication jẹ́ ká kọ́kọ́ mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó dá lórí bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe máa pa dà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn tún ní ìmúṣẹ lóde òní, àmọ́ kì í ṣe ara àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ló ṣẹ sí bí kó ṣe Ísírẹ́lì tẹ̀mí. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ń tọ́ka sí ìmúbọ̀sípò ìjọsìn mímọ́. Ilé Ìṣọ́ March 1, 1999, ṣàlàyé pé ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí jẹ́ ará àsọtẹ́lẹ̀ tó fi hàn pé ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ́ sípò, torí náà ìran náà máa kó ipa pàtàkì nínú ìjọsìn ní ọjọ́ ìkẹyìn.

^ ìpínrọ̀ 6 Ẹ̀jẹ́ náà ò fàyè gba kí ọkùnrin kan àti obìnrin kan jọ wà pa pọ̀ nínú yàrà kan náà, àyàfi tí wọ́n bá ṣí ilẹ̀kùn sílẹ̀ gbayawu tàbí tí wọ́n bá jẹ́ tọkọtaya tàbí ìbátan tímọ́tímọ́. Fún ọdún bíi mélòó kan, wọ́n máa ń ka ẹ̀jẹ́ yìí lójoojúmọ́ ní Bẹ́tẹ́lì nígbà Ìjọsìn Òwúrọ̀.

^ ìpínrọ̀ 13 Ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń lo tábà nílòkulò ni pé wọ́n máa ń mu ún tàbí kí wọ́n jẹ ẹ́ tàbí kí wọ́n gbìn ín fún àwọn ìdí yìí.

^ ìpínrọ̀ 27 Bí àpẹẹrẹ, wo orí 32 nínú ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà; tún wo “Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín!Jí! October 2007, ojú ìwé 3 sí 11.