Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Apá òsì: Arábìnrin kan tó jẹ́ apínwèé-ìsìn-kiri ń wàásù ní Korea, lọ́dún 1931; apá ọ̀tún: Arábìnrin méjì ń fi èdè adití wàásù ní Korea lónìí

APÁ 2

Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run​—À Ń Tan Ìhìn Rere Kárí Ayé

Iṣẹ́ Ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run​—À Ń Tan Ìhìn Rere Kárí Ayé

O Ń MÚRA òde ẹ̀rí láàárọ̀ ọjọ́ kan tó o ní ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́. Àmọ́, o tún wá ń lọ́ tìkọ̀ torí pé ó fẹ́ rẹ̀ ọ́ díẹ̀. Ó ń ṣe ọ́ bíi pé kó o kúkú fi àárọ̀ yẹn sinmi o jàre! Ṣùgbọ́n, o fọ̀rọ̀ náà sádùúrà, ó sì pinnu pé wàá lọ sóde ẹ̀rí. Ìwọ àti arábìnrin àgbàlagbà olóòótọ́ kan lẹ jọ ṣiṣẹ́, inúure arábìnrin yìí àti ìfaradà rẹ̀ wú ọ lórí gan-an ni. Bí o ṣe ń sọ̀rọ̀ òtítọ́ fáwọn èèyàn láti ilé-dé-ilé, ó sọ sí ọ lọ́kàn pé àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin kárí ayé náà ń wàásù ìhìn rere kan náà, wọ́n ń lo irú ìwé kan náà, gbogbo wa sì ń jàǹfààní ìdálẹ́kọ̀ọ́ kan náà. Ìgbà tó o fi máa pa dà délé ara rẹ ti yá gágá. Inú rẹ sì dùn gan-an pé o kò jókòó sílé!

Ní báyìí, iṣẹ́ ìwàásù ni olórí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tí a ń ṣe. Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù náà máa gbòòrò lọ́nà tó ta yọ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. (Mát. 24:14) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yìí ṣe ṣẹ? Ní apá yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó ń wàásù, onírúurú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń wàásù àtàwọn ohun èlò pàtàkì tí wọ́n ń lò lẹ́nu iṣẹ́ náà, tó ń mú kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé lè rí i pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso lóòótọ́.

NÍ APÁ YÌÍ

ORÍ 6

Àwọn Oníwàásù​—Àwọn Òjíṣẹ́ Ọlọ́run Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú

Kí nìdí tó fi dá Jésù lójú pé òun máa ní ẹgbẹ́ ogun oníwàásù tó yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí? Kí ni wàá máa ṣe tí yóò fi hàn pé o ń wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́?

ORÍ 7

Àwọn Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Wàásù​—Gbogbo Ọ̀nà La Fi Ń Mú Ìhìn Rere Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Èèyàn

Mọ̀ nípa ọgbọ́n àrà ọ̀tọ̀ tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ti lò láti fi mú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó kí òpin tó dé.

ORÍ 8

Àwọn Ohun Èlò Iṣẹ́ Ìwàásù​—À Ń Tẹ Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ fún Lílò Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù Kárí Ayé

Báwo ni iṣẹ́ ìtumọ̀ tí à ń ṣe ṣe fi hàn pé Jésù ń bẹ lẹ́yìn wa? Àwọn nǹkan wo nípa àwọn ìtẹ̀jáde wa ló jẹ́ kó dá ọ lójú pé Ìjọba náà ti ń ṣàkóso?

Orí 9

Àwọn Àbájáde Iṣẹ́ Ìwàásù “Àwọn Pápá . . . Ti Funfun fún Kíkórè”

Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ pàtàkì méjì nípa iṣẹ́ ìkórè ńlá tẹ̀mí. Báwo ni àwọn ẹ̀kọ́ náà ṣe kàn wá lónìí?