Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Apá òsì: Ọdún 1926 ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì kẹ́yìn; apá ọ̀tún: Àwọn èèyàn kíyè sí pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá yàtọ̀

APÁ 3

Àwọn Ìlànà Ìjọba Ọlọ́run​—Bá A Ṣe Wá Òdodo Ọlọ́run

Àwọn Ìlànà Ìjọba Ọlọ́run​—Bá A Ṣe Wá Òdodo Ọlọ́run

LẸ́NU àìpẹ́ yìí, o rí i pé aládùúgbò rẹ kan máa ń wo ìwọ àti ìdílé rẹ. Bí o ṣe ń kọjá lọ o juwọ́ sí i, òun náà sì juwọ́ sí ẹ. Ó wá ṣẹ́wọ́ sí ẹ pé kó wá. Ó sọ pé: “Ǹjẹ́ mo lè bí ẹ ní ìbéèrè kan? Kí ló mú kí ẹ dá yàtọ̀?” O wá bi í pé: “Kí lo ní lọ́kàn gan-an?” Ó wá sọ pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, àbí? Ẹ yàtọ̀ sáwọn èèyàn yòókù pátápátá. Ẹ kì í ṣe bí àwọn ẹlẹ́sìn yòókù, torí pé ẹ kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tí wọ́n máa n ṣe, ẹ kì í sì í lọ́wọ́ nínú ìṣèlú àti ogun. Kò sí ẹnì kankan nínú yín tó ń mu sìgá. Àti pé ìwà ọmọlúwàbí ni ìdílé rẹ máa ń hù. Kí ló mú kí ẹ yàtọ̀ pátápátá?”

O mọ̀ pé ohun tó fà á tá a fi yàtọ̀ ni pé: Ìlànà Ìjọba Ọlọ́run là ń tẹ̀ lé. Gẹ́gẹ́ bí Ọba, gbogbo ìgbà ni Jésù ń yọ́ wa mọ́. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, èyí sì ń jẹ́ ká dá yàtọ̀ nínú ayé búburú yìí. Nínú apá yìí, a máa rí bí Ìjọba Mèsáyà ṣe ń yọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run mọ́ nípa tẹ̀mí, ní ti àwọn àṣà àtàwọn ìwà kan àti ní ti ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣètò nǹkan, kí gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe lè máa fi ògo fún Jèhófà.

NÍ APÁ YÌÍ

ORÍ 10

Ọba Náà Yọ́ Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Mọ́ Nípa Tẹ̀mí

Ìjọra wo ló wà láàárín Kérésìmesì àti àgbálèbú?

ORÍ 11

A Yọ́ Wa Mọ́ Kúrò Nínú Àwọn Àṣà àti Ìwà Kan Ká Lè Jẹ́ Mímọ́ Bí Ọlọ́run Ṣe Jẹ́ Mímọ́

Àwọn ẹ̀ṣọ́ àtàwọn ẹnu ọ̀nà tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ní ìtumọ̀ àrà ọ̀tọ̀ fún àwọn èèyàn Ọlọ́run láti ọdún 1914.

ORÍ 12

A Ṣètò Wa Láti Jọ́sìn “Ọlọ́run Àlàáfíà”

Kí nìdí tí Bíbélì kò fi ètò ṣe ìdàkejì rúdurùdu, àmọ́ àlááfíà ló fi ṣe ìdàkejì rẹ̀? Ipa wo ni ìdáhùn sí ìbéèrè yìí ní lórí àwa Kristẹni lóde òní?