Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Lápá òsì: Àwọn ohun tí àwọn ará láti orílẹ̀-èdè Switzerland kó ránṣẹ́ sí àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Jámánì lọ́dún 1946; lápá ọ̀tún: Wọ́n ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ́ lórílẹ̀-èdè Japan lẹ́yìn tí àkúnya omi tó ń jẹ́ sùnámì wáyé lọ́dún 2011

APÁ 6

Ṣíṣètìlẹyìn fún Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run​—À Ń Kọ́ Ibi Ìjọsìn A sì Ń Ṣèrànwọ́ Nígbà Àjálù

Ṣíṣètìlẹyìn fún Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run​—À Ń Kọ́ Ibi Ìjọsìn A sì Ń Ṣèrànwọ́ Nígbà Àjálù

O WỌ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba yín o sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máà dá ibẹ̀ mọ̀ mọ́. Ìgbà gbogbo ni Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí máa ń múnú rẹ dùn. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó o máa láyọ̀ bó o ṣe ń rántí ìgbà tẹ́ ẹ jọ kọ́ ọ ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn. Àmọ́, ohun tó túbọ̀ wá múnú rẹ dùn ni pé ní báyìí ná, wọ́n ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba náà láti máa pèsè ìrànwọ́ fún àwọn ará tí àjálù dé bá. Lẹ́yìn tí ìjì kan tó jà láìpẹ́ yìí fa àkúnya omi tó ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́ ní àgbègbè ibi tó ò ń gbé, Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka yára ṣètò bí àwọn tí àjálù dé bá náà á ṣe rí oúnjẹ, aṣọ, omi tó mọ́ àti àwọn ìrànwọ́ míì gbà. Wọ́n to àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ fi ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá nigín-nigín. Àwọn ará wá ń tò wọlé, wọ́n ń gba ohun tí wọ́n nílò, èyí tó pọ̀ jù nínú wọn sì ń nu omijé ayọ̀ tó ń bọ́ lójú wọn.

Jésù sọ pé ìfẹ́ tí àwọn èèyàn òun ní síra wọn ni àmì pàtàkì tí àwọn èèyàn á fi máa dá wọn mọ̀. (Jòh. 13:34, 35) Nínú apá yìí, a máa jíròrò bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń lo ìfẹ́ Kristẹni yìí nígbà tá a bá ń kọ́ àwọn ibi ìjọsìn àti nígbà tá a bá ń pèsè àwọn ohun tá a fi ń ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ìjábá bá. Bá a ṣe ń fi ìfẹ́ hàn lọ́nà yìí fi hàn dájú pé a wà lábẹ́ àkóso Ìjọba Jésù.

NÍ APÁ YÌÍ

ORÍ 18

Bí A Ṣe Ń Rí Owó Bójú Tó Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run

Ibo la ti ń rí owó? Báwo la ṣe ń lò ó?

ORÍ 19

Àwọn Ilé Tá À Ń Kọ́ Ń Bọlá fún Jèhófà

Àwọn ilé tá à ń kọ́ fún ìjọsìn ń bọlá fún Jèhófà, àmọ́ ọ̀tọ̀ ni ohun tí Ọlọ́run kà sí ohun tó ṣeyebíye jù lọ.

ORÍ 20

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tá A Fi Ń Ṣe Ìrànwọ́

Báwo la ṣe mọ̀ pé iṣẹ́ ṣíṣẹ́ ìrànwọ́ nígbà àjálù jẹ́ ará iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Jèhófà?