Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Orin 146

Èmi Lẹ Ṣe É Fún

Èmi Lẹ Ṣe É Fún

Wà á jáde:

(Mátíù 25:34-40)

  1. Jésù ní àgùntàn mìíràn tó ń  sìn pẹ̀lú

    àwọn tó f’ẹ̀mí yàn, táá jẹ́ aya rẹ̀.

    Gbogbo ohun tá  a bá ṣe

    kára lè tù wọ́n

    Jésù máa san èrè rẹ̀ fún wa pátá.

    (ÈGBÈ)

    “Tẹ́  ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú.

    Tẹ́  ẹ bá ti ṣe  é fún wọn, ẹ ti ṣe  é fún mi.

    Tẹ́  ẹ bá ṣiṣẹ́ sìn wọ́n, èmi lẹ ṣe  é fún.

    Ẹ ti ṣe  é fún wọn; ẹ ti ṣe  é fún mi.

    Tẹ́  ẹ bá ti ṣe  é fún wọn, ẹ ti ṣe  é fún mi.”

  2. “Ebi pa mí, òùngbẹ gbẹ mí, ẹ tọ́jú mi,

    gbogbo ohun tí mo nílò lẹ fún mi.”

    Wọ́n bi  í pé: “Sọ fún wa

    ìgbà wo la ṣe bẹ́ẹ̀?”

    Ọba wá fèsì ó dá wọn lóhùn pé:

    (ÈGBÈ)

    “Tẹ́  ẹ bá tù wọ́n nínú, ẹ tù mí nínú.

    Tẹ́  ẹ bá ti ṣe  é fún wọn, ẹ ti ṣe  é fún mi.

    Tẹ́  ẹ bá ṣiṣẹ́ sìn wọ́n, èmi lẹ ṣe  é fún.

    Ẹ ti ṣe  é fún wọn; ẹ ti ṣe  é fún mi.

    Tẹ́  ẹ bá ti ṣe  é fún wọn, ẹ ti ṣe  é fún mi.”

  3. “Ẹ j’ólóòótọ́ sí mi, iṣẹ́ rere lẹ̀ ń  ṣe,

    ẹ̀ ń  wàásù pẹ̀l’áwọn arákùnrin mi.”

    Ọba máa sọ f’áwọn

    àgùntàn ọ̀tún rẹ̀:

    “Ẹ jogún ayé àti ìjẹ́pípé.”