Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 9

Ó Ń Dàgbà ní Násárẹ́tì

Ó Ń Dàgbà ní Násárẹ́tì

MÁTÍÙ 13:55, 56 MÁÀKÙ 6:3

  • JÓSẸ́FÙ ÀTI MÀRÍÀ BÍ ÀWỌN ỌMỌ MÍÌ

  • JÉSÙ KỌ́ IṢẸ́ ỌWỌ́

Jésù ń dàgbà ní Násárẹ́tì, ìyẹn ìlú kékeré kan tí ò fi bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀. Agbègbè Gálílì ni ìlú yìí wà, ó sì wà ní apá ìwọ̀ oòrùn Òkun Gálílì.

Nígbà tí Jésù wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún méjì, Jósẹ́fù àti Màríà kúrò ní Íjíbítì, wọ́n sì kó wá sí Násárẹ́tì. Ó jọ pé òun nìkan ni wọ́n ṣì bí nígbà yẹn. Nígbà tó yá, Màríà bí àwọn ọmọkùnrin míì, orúkọ wọn ni Jémíìsì, Jósẹ́fù, Símónì àti Júdásì. Jósẹ́fù àti Màríà tún bí àwọn ọmọbìnrin. Ó kéré tán, àbúrò ọkùnrin àti obìnrin mẹ́fà ni Jésù ní.

Jésù tún ní àwọn mọ̀lẹ́bí míì. Lára wọn ni Èlísábẹ́tì àti Jòhánù ọmọ rẹ̀. Apá gúúsù nílẹ̀ Jùdíà ni Jòhánù ń gbé. Jésù tún ní àwọn mọ̀lẹ́bí míì tó ń gbé nítòsí wọn ní Gálílì. Ọ̀kan lára wọn ni Sàlómẹ̀ tó ṣeé ṣe kó jẹ́ arábìnrin Màríà. Sébédè ni ọkọ Sàlómẹ̀, wọ́n sì ní ọmọkùnrin méjì tó ń jẹ́ Jémíìsì àti Jòhánù. Torí náà, á jẹ́ pé ìbátan làwọn ọmọ yìí jẹ́ sí Jésù. A ò mọ̀ bóyá Jésù àtàwọn ọmọ yìí jọ máa ń ṣeré nígbà tí wọ́n ṣì kéré. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn àti Jésù di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, kódà wọ́n di àpọ́sítélì rẹ̀.

Jósẹ́fù ṣiṣẹ́ kára gan-an kó lè tọ́jú ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀, iṣẹ́ káfíńtà ló sì ń ṣe. Jósẹ́fù mú Jésù bí ọmọ, Bíbélì tiẹ̀ pe Jésù ní “ọmọ káfíńtà.” (Mátíù 13:55) Jósẹ́fù kọ́ Jésù ní iṣẹ́ káfíńtà, ó sì mọṣẹ́ náà dáadáa. Kódà nígbà tó yá, ohun táwọn èèyàn sọ nípa Jésù ni pé: “Káfíńtà yẹn nìyí.”—Máàkù 6:3.

Ìjọsìn Jèhófà ni ìdílé Jósẹ́fù fi sípò àkọ́kọ́. Jósẹ́fù àti Màríà máa ń ṣe ohun tí Òfin Ọlọ́run sọ, wọ́n sì máa ń kọ́ àwọn ọmọ wọn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ‘nígbà tí wọ́n bá jókòó nínú ilé, nígbà tí wọ́n bá ń rìn lójú ọ̀nà, nígbà tí wọ́n bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí wọ́n bá dìde.’ (Diutarónómì 6:6-9) Sínágọ́gù kan wà ní Násárẹ́tì, ó sì dájú pé Jósẹ́fù máa ń kó ìdílé rẹ̀ lọ síbẹ̀ déédéé láti jọ́sìn. Nígbà tó yá, Bíbélì sọ pé Jésù lọ sí sínágọ́gù “bó ṣe máa ń ṣe ní ọjọ́ Sábáàtì.” (Lúùkù 4:16) Inú ìdílé wọn tún máa ń dùn gan-an lásìkò tí wọ́n bá rìnrìn àjò lọ sí tẹ́ńpìlì Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù.